Jesu Fi Awọn Alátakò Rẹ̀ Bú
Orí 109
Jesu Fi Awọn Alátakò Rẹ̀ Bú
JESU ti kó ìdààmú bá awọn onísìn alátakò rẹ̀ pátápátá tobẹẹ tí wọn fi bẹ̀rù lati bi í leere ohunkohun siwaju sii. Nitori naa ó lo ìdánúṣe lati túdìí àìmọ̀kan wọn. “Ki ni ẹyin rò nipa Kristi naa?” ni oun beere. “Ọmọkunrin ta ni oun jẹ́?”
“Ti Dafidi,” ni awọn Farisi naa dahun.
Bí ó tilẹ jẹ́ pe Jesu kò sẹ́ pe Dafidi jẹ́ babanla Kristi, tabi Mesaya naa nipa ti ara, ó beere pe: “Nigba naa, bawo ni Dafidi, nipasẹ ìmísí [ní Saamu 110] ṣe pè é ní ‘Oluwa,’ wipe, ‘Jehofa wí fun Oluwa mi pe: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí emi yoo fi fi awọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’? Nitori naa, bí Dafidi bá pè é ní ‘Oluwa,’ bawo ni oun ṣe jẹ́ ọmọkunrin rẹ̀?”
Awọn Farisi naa dákẹ́, nitori wọn kò mọ ẹni tí Kristi, tabi ẹni àmì-òróró naa jẹ́ nitootọ. Mesaya naa kìí wulẹ ṣe ènìyàn ọmọ-ìran Dafidi, gẹgẹ bi ó ti hàn gbangba pe awọn Farisi gbàgbọ́ pe ó jẹ́, ṣugbọn oun ti wà ní ọ̀run rí ó sì ti jẹ Oluwa Dafidi, tabi ẹni tí ó ga lọ́lá jù ú lọ.
Ní yíyípadà nisinsinyi sí awọn ogunlọgọ naa ati sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu kìlọ̀ nipa awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi. Niwọn bi awọn wọnyi ti ńkọ́ni ní Òfin Ọlọrun, tí ‘wọn ti fi araawọn jókòó ní ìjókòó Mose,’ Jesu rọ̀ wọn pe: “Ohun gbogbo tí wọn bá sọ fun yin, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pamọ́.” Ṣugbọn ó fikun un pe: “Ẹ maṣe ṣe gẹgẹ bi awọn ìṣe wọn, nitori wọn a maa wí ṣugbọn wọn kìí ṣe.”
Alágàbàgebè ni wọn, Jesu sì fi wọn bú ní èdè kan naa gan-an tí oun lò nigba tí ó njẹun ní ilé Farisi kan ní ọ̀pọ̀ oṣu ṣaaju. Ó sọ pe, “Gbogbo iṣẹ́ tí wọn ńṣe ni wọn ńṣe kí eniyan ba lè rí wọn.” Ó sì pèsè awọn apejuwe, ní wiwi pe:
“Wọn sọ awọn àpò tí wọn ní iwe mimọ ninu di fífẹ̀ eyi tí wọn gbéwọ̀ gẹgẹ bi awọn ohun ìdáàbòbò.” Awọn àpò wọnyi tí wọn kéré ní ifiwera, tí wọn ńfi sí iwájú orí tabi wọ̀ sí apá, ní apá mẹrin lara Òfin ninu: Ẹkisodu 13:1-10, 11-16; ati Deutaronomi 6:4-9; 11:13-21. Ṣugbọn awọn Farisi sọ ìtóbi awọn àpò wọnyi di pupọ sii lati fúnni ní èrò pe wọn jẹ́ onítara nipa ti Òfin.
Jesu nba ọ̀rọ̀ rẹ lọ pe wọn “sọ ìṣẹ́tí ẹ̀wù wọn di títóbi.” Ní Numeri 15:38-40 awọn ọmọ Isirẹli ni a pa á láṣẹ fun lati ṣe ìṣẹ́tí sí etí ẹ̀wù wọn, ṣugbọn awọn Farisi mú kí tiwọn tubọ tóbi jù bí ti awọn ẹlomiran ti rí lọ. Ohun gbogbo ni wọn ṣe fun àṣehàn! “Wọn fẹ́ ibi ọlá julọ,” ni Jesu polongo.
Ó baninínújẹ́ pe, awọn ọmọ-ẹhin oun tìkáraarẹ̀ ni èèràn ìfẹ́ fun ọlá yii ti ràn. Nitori naa ó gbà wọn nímọ̀ràn pe: “Ṣugbọn ẹyin, kí a maṣe pè yin ní Rabi, nitori ọ̀kan ni olukọ yin, nigba tí gbogbo yin jẹ́ arakunrin. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ maṣe pe ẹnikẹni ní baba yin lórí ilẹ̀-ayé, nitori ọ̀kan ni Baba yin, Ẹni tí nbẹ ní ọ̀run. Bẹẹ ni kí a maṣe pè yin ní ‘aṣaaju,’ nitori ọ̀kan ni Aṣaaju yin, Kristi.” Awọn ọmọ-ẹhin gbọdọ mú ìfẹ́-ọkàn lati di ẹni àkọ́kọ́ kuro láàárín araawọn! “Ẹni tí ó tóbi jùlọ láàárín yin gbọdọ jẹ́ òjíṣẹ́ yin,” ni Jesu ṣí wọn létí.
Lẹhin eyiini ni oun kéde ọ̀wọ́ awọn ègbé lé awọn akọwe ati awọn Farisi lórí, ní pípè wọn ní àgàbàgebè léraléra. Ó sọ pe, wọn “sénà ijọba awọn ọrun niwaju awọn eniyan,” ati pe “awọn sì ni awọn ẹni tí ńjẹ ilé awọn opó run ati nitori àṣehàn wọn ńgbàdúrà gígùn.”
“Ègbé ni fun yin, ẹyin afọ́jú amọ̀nà,” ni Jesu wí. Ó sọ̀rọ̀ lodisi àìní ero ìdíyelé tẹmi awọn Farisi, gẹgẹ bi ó ti hàn ninu ìyàsọ́tọ̀ aláìnírònú tí wọn maa nṣe. Fun apẹẹrẹ, wọn sọ pe, ‘Kò jẹ́ nǹkankan bí ẹnikan bá fi tẹmpili búra, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi wúrà tẹmpili búra wà lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe.’ Nipa gbígbé ìtẹnumọ́ ka wúrà tí ó wà ní tẹmpili dípò kí ó jẹ́ lórí iniyelori tẹmi ibi ìjọsìn yẹn, wọn ṣí ìfọ́jú wọn nipa ti ìwàrere payá.
Lẹhin naa, gẹgẹ bi ó ti ṣe ní iṣaaju, Jesu dẹ́bi fún awọn Farisi fun ṣíṣàìnáání “awọn ọ̀ràn Òfin wíwúwo jù, eyiini ni, ìdájọ́ òdodo ati àánú ati ìṣòtítọ́” nigba tí ó jẹ́ pe wọn nfi àfiyèsí ti o pọ fun sísan ìdámẹ́wàá, tabi apákan ninu mẹ́wàá ti awọn ewé aláìjámọ́ nǹkan.
Jesu pe awọn Farisi naa ní “afọ́jú amọ̀nà, tí ńyọ kantíkantí kuro ṣugbọn tí ńgbé ìbákasíẹ mì!” Wọn maa ńyọ kantíkantí kuro ninu wáìnì wọn, kìí wulẹ ṣe kìkì nitori pe ó jẹ́ kòkòrò, ṣugbọn nitori pe ó jẹ́ aláìmọ́ lọna ayẹyẹ ìsìn. Sibẹ, ṣíṣàìnáání awọn ọ̀ràn Òfin wíwúwo jù ṣeefiwera pẹlu gbígbé ìbákasíẹ mì, ẹranko kan tí kò mọ́ lọna ayẹyẹ ìsìn bakan-naa. Matiu 22:41–23:24; Maaku 12:35-40; Luuku 20:41-47; Lefitiku 11:4, 21-24.
▪ Eeṣe tí awọn Farisi fi dákẹ́ nigba ti Jesu bi wọn ní ibeere nipa ohun tí Dafidi sọ ninu Saamu 110?
▪ Eeṣe tí awọn Farisi fi sọ awọn àpò tí wọn ní Iwe Mimọ ninu ati ìṣẹ́tí ẹ̀wù wọn di títóbi?
▪ Ìmọ̀ràn wo ni Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀?
▪ Ìyàsọ́tọ̀ aláìnírònú wo ni awọn Farisi maa ńṣe, bawo sì ni Jesu ṣe dẹ́bi fún wọn fun ṣíṣàìnáání awọn ọ̀ràn wíwúwo jù?