Iṣẹ Iyanu Keji ni Kana
Orí 20
Iṣẹ Iyanu Keji ni Kana
NIGBA ti Jesu pada si ibugbe rẹ̀ lẹhin igbokegbodo iwaasu gbigbooro ni Judia, kii ṣe lati sinmi. Kaka bẹẹ, oun bẹrẹ ani iṣẹ ojiṣẹ ti o gbooro sii ni Galili paapaa, ilẹ ibi ti oun gbé dàgbà. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹhin rẹ̀, kaka ki wọn duro pẹlu rẹ̀, pada sile sọdọ awọn idile wọn ati sidi iṣẹ wọn atẹhinwa.
Ihin iṣẹ wo ni Jesu bẹrẹsii waasu rẹ̀? Eyi: “Ijọba Ọlọrun kù sí dẹ̀dẹ̀: Ẹ ronupiwada, ki ẹ sì gba ihinrere gbọ́.” Ki sì ni idahunpada wọn? Awọn ara Galili tẹwọgba Jesu. Gbogbo eniyan bọla fun un. Bi o ti wu ki o ri, eyi ni pataki kii ṣe nitori ihin iṣẹ rẹ̀, bikoṣe, nitori ọpọlọpọ wọn ti wà ni ibi Irekọja ni Jerusalẹmu ni ọpọ oṣu ṣaaju ti wọn sì rí awọn iṣẹ́ ami ti wọn kàmàmà ti oun ti ṣe.
Dajudaju Jesu bẹrẹ iṣẹ ojiṣẹ Galili titobi rẹ̀ ni Kana. Ṣaaju akoko naa, iwọ lè ranti, nigba ti ó npada bọ lati Judia, oun yí omi pada sí ọti waini nibi àsè igbeyawo kan nibẹ. Ní akoko iṣẹlẹ keji yii, ọmọ ijoye oṣiṣẹ akoso Ọba Hẹrọdu Antipa kan nṣaisan gidigidi. Ni gbigbọ pe Jesu ti de lati Judia sí Kana, ijoye oṣiṣẹ naa rinrin ajo lati ile rẹ̀ jíjìnnà ní Kapanaomu lati wá Jesu rí. Bi ẹdun ọkan ti kọlù ú, ọkunrin naa rọ̀ ọ́: ‘Jọwọ wá lẹsẹkẹsẹ, ṣaaju ki ọmọ mi tó kú.’
Jesu fesi pe: ‘Pada si ile. A ti mú ọmọkunrin rẹ larada!’ Ijoye oṣiṣẹ Hẹrọdu gbagbọ ó sì bẹrẹ irin ajo gígùn pada si ile. Ni oju ọna awọn iranṣẹ rẹ̀ pade rẹ̀, ti wọn ti sáré wá lati sọ fun un pe nǹkan ti padabọsipo—ara ọmọkunrin rẹ̀ ti yá! ‘Nigba wo ni ara rẹ̀ yá?’ ni oun beere.
‘Lanaa ni aago kan ọsan,’ ni wọn dahun.
Ijoye oṣiṣẹ naa mọ daju pe eyi ni wakati naa gan-an nigba ti Jesu wipe, ‘A ti mu ọmọkunrin rẹ larada!’ Lẹhin eyiini, ọkunrin naa ati gbogbo agbo ile rẹ̀ di ọmọ ẹhin Kristi.
Nipa bẹẹ Kana di eyi ti o rí ojurere gẹgẹ bi ibi ti, ni jijẹ ami ipada rẹ̀ lati Judia, Jesu ṣe iṣẹ iyanu nigba meji. Iwọnyi, dajudaju, kii ṣe kiki awọn iṣẹ iyanu ti oun ṣe titi di akoko yii, ṣugbọn wọn ṣe pataki nitori pe wọn samisi ipada rẹ̀ sí Galili.
Nisinsinyi Jesu kọri sí ile ni Nasarẹti. Ki ni o duro dè é nibẹ? Johanu 4:43-54; Maaku 1:14, 15; Luuku 4:14, 15.
▪ Nigba ti Jesu pada sí Galili, ki ni o ṣẹlẹ si awọn ọmọ ẹhin rẹ̀, bawo sì ni awọn eniyan ṣe tẹwọgba a?
▪ Iṣẹ iyanu wo ni Jesu ṣe, bawo ni o sì ṣe nipa lori awọn wọnni ti ọran kan?
▪ Bawo ni Kana ṣe tipa bayii rí ojurere Jesu?