Awọn Farisi Mọ̀ọ́mọ̀ Ṣaigbagbọ
Orí 71
Awọn Farisi Mọ̀ọ́mọ̀ Ṣaigbagbọ
AWỌN òbí alágbe tí ó jẹ́ afọ́jú tẹlẹri naa fòyà nigba ti a pè wọn wá síwájú awọn Farisi. Wọn mọ̀ pe a ti pinnu lati lé ẹnikẹni tí ó bá fi ìgbàgbọ́ hàn ninu Jesu jáde kuro ninu sinagọgu. Irú kíké ìbákẹ́gbẹ́ pẹlu awọn ẹlomiran ni àdúgbò kuro bẹẹ lè mú ìnilára tí ó pabambarì wá, paapaa sórí idile tálákà kan. Nitori eyi awọn òbí naa kún fun ìṣọ́ra.
“Eyi ni ọmọkunrin yin, ẹni tí ẹyin wipe, a bí i ní afọ́jú?” ni awọn Farisi beere. “Bawo ni ó ti ṣe ríran nisinsinyi?”
“Awa mọ̀ pe ọmọ wa ni eyi, ati pe a bí i ní afọ́jú,” ni awọn òbí naa tubọ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. “Ṣugbọn bí ó ti ṣe ríran nisinsinyi awa kò mọ̀; tabi ẹni tí ó là á lójú, awa kò mọ̀.” Dajudaju ọmọkunrin wọn ti gbọdọ sọ fun wọn gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ṣugbọn awọn òbí naa fi ọgbọ́n sọ pe: “Ẹni tí ó lọ́jọ́lórí niiṣe; ẹ bi í léèrè: yoo wí fúnraarẹ̀.”
Nitori naa, awọn Farisi pe ọkunrin naa lẹẹkan sí i. Ní àkókò yii wọn gbìyànjú lati kó jìnnìjìnnì bá a nipa títọ́ka pe wọn ti kó ẹ̀rí awémọnilẹ́sẹ̀ jọ lòdìsí Jesu. “Fi ògo fun Ọlọrun,” ni wọn fi dandangbọ̀n béèrè. “Awa mọ̀ pe ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkunrin yii.”
Ọkunrin tí ó ti jẹ́ afọ́jú tẹlẹri naa kò sẹ́ ìfẹ̀sùnkanni wọn, ní sisọ pe: “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, emi kò mọ̀.” Ṣugbọn ó fikun un pe: “Ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọ́jú rí, mo sì ríran nisinsinyi.”
Ní gbígbìyànjú lati fa àlébù kan yọ ninu gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀, awọn Farisi lẹẹkan sí i beere pe: “Ki ni ó ṣe sí ọ? Bawo ni ó ti ṣe là ọ́ lójú?”
“Emi ti sọ fun yin ná,” ni ọkunrin naa ráhùn, “ẹyin kò sì gbọ́: nitori ki ni ẹyin ṣe ńfẹ́ tún un gbọ́?” Lọ́nà ẹdà ọ̀rọ̀ tí kò báradé, ó beere pe: “Ẹyin pẹlu ńfẹ́ di ọmọ-ẹhin rẹ̀ bí?”
Ìfèsìpadà yii bi awọn Farisi ninu. “Iwọ ni ọmọ-ẹhin rẹ̀,” ni wọn polongo, “ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose ni awa. Awa mọ̀ pe Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀: ṣugbọn bí ó ṣe ti ọkunrin yii, awa kò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”
Ní fífi ìyàlẹ́nu hàn, alágbe onírẹ̀lẹ̀ naa dáhùn pe: “Ohun ìyanu ṣáà ni eyi, pe, ẹyin kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, ṣugbọn oun ṣáà ti là mi lójú.” Ìparí èrò wo ni a nilati dé lati inú eyi? Alágbe naa tọ́kasí ọrọ ti o ṣee tẹwọgba ti o sì ba ọgbọ́n mu naa pe: “Awa mọ̀ pe Ọlọrun kìí gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀: ṣugbọn bí ẹnikan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọrun, tí ó bá sì ńṣe ìfẹ́ rẹ̀, oun ni ńgbọ́ tirẹ̀. Lati ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò tíì gbọ́ pe, ẹnikan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.” Nipa bayii, ìparí èrò naa nilati hàn gbangba pe: “Ìbáṣepé ọkunrin yii kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, kì bá ti lè ṣe ohunkohun.”
Awọn Farisi kò ní ìdáhùn kankan fun irúfẹ́ ìrònú aláìfibọpobọyọ̀ tí ó ṣe kedere kan bẹẹ. Wọn kò lè kojú otitọ naa, nitori naa wọn kẹ́gàn ọkunrin naa pe: “Ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni a bí iwọ patapata, iwọ ha sì ńkọ́ wa bí?” Lẹhin eyi, wọn ju ọkunrin naa síta, ní lílé e jáde kuro ninu sinagọgu lọna tí ó hàn kedere.
Nigba ti Jesu mọ̀ nipa ohun tí wọn ṣe, ó wá ọkunrin naa rí ó sì wipe: “Iwọ gba Ọmọkunrin Ọlọrun gbọ́ bí?”
Ní ìfèsìpadà, alágbe tí ó jẹ́ afọ́jú tẹlẹri naa beere pe: “Ta ni, Oluwa, kí emi kí ó lè gbà á gbọ́?”
“Oun naa ni ẹni tí ó ńbá ọ sọ̀rọ̀ yii,” ni Jesu fèsìpadà.
Lẹsẹkẹsẹ, ọkunrin naa tẹríba niwaju Jesu ó sì wipe: “Oluwa, mo gbàgbọ́.”
Lẹhin naa Jesu ṣàlàyé pe: “Nitori ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yii, kí awọn tí kò ríran lè ríran; ati kí awọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”
Bí wọn ti gbọ́ bẹẹ, awọn Farisi tí wọn ńfetísílẹ̀ naa beere pe: “Awa pẹlu ha fọ́jú bí?” Bí wọn yoo bá jẹ́wọ́ pe awọn fọ́jú niti èrò-orí, àwíjàre yoo wà fun àtakò wọn sí Jesu. Gẹgẹ bi Jesu ti sọ fun wọn: “Ìbáṣepé ẹyin fọ́jú, ẹyin kì bá ti ní ẹṣẹ̀.” Sibẹ, wọn ńfi ọkàn-líle tẹnumọ́ ọn pe awọn kò fọ́jú wọn kò sì nílò ìlàlóye nipa tẹ̀mí. Nitori naa Jesu sọ pe: “Nisinsinyi ẹyin wipe, ‘Awa ríran’; nitori naa ẹ̀ṣẹ̀ yin wà sibẹ.” Johanu 9:19-41.
▪ Eeṣe tí awọn òbí alágbe tí ó ti jẹ́ afọ́jú tẹlẹri naa fi fòyà nigba ti a pè wọn wá síwájú awọn Farisi, nitori naa bawo ni wọn sì ṣe dáhùn pẹlu ìṣọ́ra?
▪ Bawo ni awọn Farisi ṣe gbìyànjú lati kó jìnnìjìnnì bá ọkunrin tí ó ti jẹ́ afọ́jú tẹlẹri naa?
▪ Ìjiyàn ọkunrin naa tí ó bá ọgbọ́n mu wo ni ó mú ìrunú bá awọn Farisi?
▪ Eeṣe tí awọn Farisi kò fi ní àwíjàre fun àtakò wọn sí Jesu?