A Mú Ọmọdekunrin Tí O Ni Ẹ̀mí Buburu Láradá
Orí 61
A Mú Ọmọdekunrin Tí O Ni Ẹ̀mí Buburu Láradá
LÁÀÁRÍN ìgbà tí Jesu, Peteru, Jakọbu, ati Johanu kò fi si nitosi, tí ó ṣeeṣe kí wọn wà ni ilẹ̀-gíga àyíká Òkè Hamoni, awọn ọmọ-ẹhin yooku kó wọnú ìṣòro kan. Nigba tí Jesu pada dé, lẹsẹkẹsẹ ni o ti ríi pe ohun kan ti ṣàìtọ́. Ogunlọgọ kan kórajọ yí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ká, awọn akọwe-ofin sì ńbá wọn jiyàn. Bí wọn ti rí Jesu, ẹnu ya awọn eniyan naa gidigidi wọn sì sáré lọ kí i. “Ọpẹ́-aláyé ki ni ẹyin ńní pẹlu wọn?” ni oun beere.
Ní bíbọ́ síwájú, láàárín ogunlọgọ naa, ọkunrin kan kúnlẹ̀ niwaju Jesu ó sì ṣàlàyé pe: “Olùkọ́, mo mú ọmọkunrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ nitori ó ní ẹ̀mí aláìlèsọ̀rọ̀; ibi yoowu tí ó bá sì ti gbá a mú ó maa ńgbé e lulẹ̀, ó sì maa ńyọ ìfóòfó a sì maa jẹ ehín rẹ̀, ó sì maa ńpàdánù okun rẹ̀. Mo sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”
Lọna ti o han gbangba kò sí ohun tí awọn akọwe-ofin kò fẹrẹẹ ṣe tán nitori ìkùnà awọn ọmọ-ẹhin lati mú ọmọdekunrin naa láradá, boya ní pípẹ̀gàn ìsapá wọn. Ní akoko aṣekoko yii gan-an ni Jesu dé. “Óò ìran ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni oun wí, “bawo ni mo ti gbọdọ wà pẹlu yin pẹ́ tó? Bawo ni mo ti gbọdọ faradà yin pẹ́ tó?”
Ó dabi ẹni pe Jesu ńdarí awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí olukuluku ẹni tí ó wà níbẹ̀, ṣugbọn láìsí iyemeji ó darí wọn ní pataki sí awọn akọwe-ofin, tí wọn ti ńbá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fà ijàngbọ̀n. Lẹhin eyiini, Jesu sọ nipa ọmọdekunrin naa pe: “Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi.” Ṣugbọn bí ọmọdekunrin naa ti nbọ lọdọ Jesu, ẹ̀mí-èṣù tí ńṣàkóso rẹ̀ fi gìrì onípá mú un. Ọmọdekunrin naa yí gbirigbiri lórí ilẹ̀ ó sì ńyọ ìfóòfó lẹ́nu.
“Bawo ni ó ti pẹ́ tó tí eyi ti ńṣẹlẹ̀ sí i?” ni Jesu beere.
“Lati ìgbà ọmọ kekere wá,” ni baba rẹ̀ dáhùn. “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà [ẹ̀mí-èṣù naa] a maa gbé e jù sínú iná ati sínú omi lati pá a run.” Lẹhin eyi ni baba naa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe: “Bí iwọ bá lè ṣe ohunkohun, ṣàánú wa kí o sì ràn wa lọwọ.”
Boya fun ọ̀pọ̀ ọdun, baba naa ti ńwá iranwọ. Ati nisinsinyi, pẹlu ìkùnà awọn ọmọ-ẹhin Jesu, ìjakulẹ rẹ̀ ga. Ní dídẹ́nulé ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ onígbèékútà ọkunrin naa, Jesu wí lọna ti nfunni níṣìírí pe: “Ọ̀rọ̀ ìsọjáde yẹn, ‘Bí iwọ bá lè’! Họ́wù, ohun gbogbo ni a lè fun ẹnikẹni bí olúwarẹ̀ bá ní ìgbàgbọ́.”
“Mo ní ìgbàgbọ́!” ni baba naa ké jáde lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn oun bẹ̀bẹ̀ pe: “Ràn mi lọwọ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”
Ní ṣíṣàkíyèsí nisinsinyi pe ogunlọgọ naa ńkórajọpọ̀ lé wọn lórí, Jesu bá ẹ̀mí-èṣù naa wí lọna lílekoko: “Iwọ aláìlèsọ̀rọ̀ ati adití ẹ̀mí, mo pàṣẹ fun ọ, jáde kuro lára rẹ̀ kí o má sì ṣe wọ inú rẹ̀ mọ́.” Bí ẹ̀mí-èṣù naa ti ńlọ kúrò, ó mú ọmọdekunrin naa lati ké jáde lẹẹkan sii tí ó sì fi ipá mú un ní ọpọlọpọ gìrì. Lẹhin naa ni ọmọdekunrin naa dùbúlẹ̀ láìmira lórí ilẹ̀, tí ó fi jẹ́ pe eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan naa bẹrẹsii wipe: “Ó ti kú!” Ṣugbọn Jesu mú ọmọdekunrin naa ní ọwọ́, ó sì dìde.
Ṣaaju àkókò naa, nigba ti a ti rán awọn ọmọ-ẹhin jáde lati lọ waasu, wọn ti lé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde. Nitori naa, nigba ti wọn wọ inú ilé kan, wọn beere lọwọ Jesu níkọ̀kọ̀ pe: “Eeṣe tí awa kò lè lé e jáde?”
Ní títọ́ka pe ó jẹ́ nitori àìní ìgbàgbọ́ wọn, Jesu dáhùn pe: “Irú eyi kò lè jáde nipa ohunkohun àyàfi nipa adura.” Bí ó ti hàn kedere ìmúrasílẹ̀ ni a beere fun lati lé ẹ̀mí-èṣù alágbára àkànṣe tí ó wà ninu ọ̀ràn yii jáde. Ìgbàgbọ́ alágbára ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu adura tí ńfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ beere fun iranlọwọ Ọlọrun tí ńfi agbara fúnni ni a nílò.
Ati lẹhin naa Jesu fikun un pe: “Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, Bí ẹyin bá ní ìgbàgbọ́ bíi ìwọ̀n hóró ọkà musitadi kan, ẹyin yoo wí fun òkè yii, ‘Ṣípò kuro níhìn-ín lọ sọ́hùn-ún,’ yoo sì ṣípò, kò sì sí ohunkohun tí kì yoo ṣeeṣe fun yin.” Ẹ wo bí ìgbàgbọ́ ti lè lágbára tó!
Awọn ìdíwọ́ ati awọn ìṣòro tí ó lè dí ọ̀nà ìlọsíwájú ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa lè dabi aláìṣeéborí ati aláìṣeé gbékúrò gẹgẹ bi òkè títóbi gidi kan. Sibẹ, Jesu fihàn pe bí awa bá mú ìgbàgbọ́ dàgbà ninu ọkàn-àyà wa, ní bíbomirin ín kí á sì fun un ní ìṣírí lati dàgbà, yoo dagba gidigidi yoo sì lè mú irúfẹ́ awọn ìdíwọ́ bí òkè ati awọn ìṣòro kuro. Maaku 9:14-29; Matiu 17:19, 20; Luuku 9:37-43, NW.
▪ Ipò wo ni Jesu ba pade nigba ti ó ńti Òkè Hamoni bọ̀?
▪ Ìṣírí wo ni Jesu fun baba ọmọdekunrin ti o ni ẹ̀mí-èṣù naa?
▪ Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin kò fi lè lé ẹ̀mí-èṣù naa jáde?
▪ Bawo ni Jesu ṣe fi bí ìgbàgbọ́ ṣe lè lágbára tó hàn?