Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nibo Ni Iwọ Ti Le Rí Itọsọna?

Nibo Ni Iwọ Ti Le Rí Itọsọna?

Ori 3

Nibo Ni Iwọ Ti Le Rí Itọsọna?

KINNI ohun tí ndena ayọ̀ rẹ? Awọn ọran-iṣoro tí ìwọ dojukọ ha ni bi? Awọn wọnyi lè jẹ ti ara-ẹni—tí ó niiṣe pẹlu ilera, owô, ibalopọ takọtabo, idile rẹ. Wọn lè ní ninu ewu ti iwa-ọdaran, àìtó awọn ohun koṣeemani fun iwalaaye, ijakulẹ lẹnu iṣẹ, ẹ̀tanú, ihalẹmọni ogun. Bẹẹ ni, ọpọ julọ ninu awọn eniyan ni wọn ní awọn ọran-iṣoro tí nṣe idiwọ fun ayọ.

2 Laika isapa awọn ọmọwe ati oniriri ẹda-eniyan sí, awọn ọran-iṣoro naa nbá a niṣo tí wọn sì tún nburu si i. Ohun tí a kọ ní ọjọ pípẹ́ sẹhin ni a ti fihan pe ó jẹ otitọ pe: ‘Ọna eniyan kò sí ní ipa ara rẹ̀; kò sí ní ipa eniyan tí nrìn, lati tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.’ * Eyiini kò ha ṣe kedere pe a nfẹ itọsọna lati orisun kan tí ọgbọn rẹ̀ ju ti eniyan lọ bi awa bá ní ireti lati rí ayọ̀ tí ô wà pẹtiti? Ṣugbọn nibo ni iru itọsọna bayii wà?

3 Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn gbagbọ pe agbaye, lọna ironu kan, jẹ ‘iwe iṣẹda’ kan tí njẹrii nipa Ẹlẹdaa. Ọba Hebrew igbaani kan fohunṣọkan ní kikọwe pe: Awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun. Ô tún sọ pe Ẹlẹdaa naa ti pese isọfunni ninu iwe gidi kan tí a kọ tí ó lè ’sọ òpè di ọlọgbọn’ ati onidunnu-nla. *

4 Niwọn bi awọn ẹda-eniyan ti ní agbara lati banisọrọ—ani tí wọn nranṣẹ si ori ilẹ-aye lati gbangba ojude ofuurufu—njẹ kò ha bọgbọnmu pe ki Ẹlẹdaa eniyan lè ṣe bẹẹ pẹlu? Ju eyiini lọ, niwọn bi ô ti jẹ pe awọn nkan pupọ lô wà nipa ilẹ-aye tí nfi ẹri ifẹ Rẹ̀ ninu araye hàn, ó jẹ ohun tí a lè loye pe oun yoo fẹ́ lati ran awọn ẹda-eniyan lọwọ. Ṣiṣe bẹẹ rẹ̀ yoo wà ní ibamu pẹlu ohun tí a rí ninu awọn idile onifẹẹ: awọn obi nta atare ìmọ ati itọsọna sọdọ awọn ọmọ wọn. Ṣugbọn bawo ni Ẹlẹdaa eniyan ṣe lè ṣe eyi fun anfaani wa?

5 Iwe kíkọ fun igba pípẹ́ ti jẹ ọna kan tí ô pegede fun mímú isọfunni lọ sọdọ ẹnikan lọna pipeye tí yoo sì wà pẹtiti lọ bẹẹ. Isọfunni alakọsilẹ kan kò lè fi bẹẹ ní aṣiṣe ninu lọna pupọ tô ìhìn-iṣẹ kan tí a tankalẹ kiki nipasẹ ọrọ-ẹnu lasan. Pẹlupẹlu, a lè tún mú iwe kan jade ki a sì tumọ rẹ̀ tí yoo fi jẹ pe awọn eniyan tí nlo ede eyikeyi yoo lè ka ìhìn-iṣẹ rẹ̀. Njẹ kò ha dabi ohun tí ô bọgbọnmu pe Elẹdaa wa ti lo iru ọna bẹẹ lati pese isọfunni bi?

6 Ju iwe kíkọ ti isin eyikeyi miiran lọ Bibeli ni a ti fi oju wò gẹgẹ bi ibanisọrọpọ kan lati ọ̀dọ̀ Ẹlẹdaa wa, ati fun idi yẹn ó ti ní ipinkiri alárà-ọ̀tọ̀ kan. Eyi jẹ ohun pataki. Bi Ọlọrun yoo bá pese iwe kan tí ô ní ìhìn-iṣẹ rẹ̀ ninu fun gbogbo eniyan, awa yoo reti pe ki ô wà larọwọto jakejado. Bayii ni Bibeli ṣe rí. A lè kà á ní awọn ede tí ipindọgba rẹ̀ jẹ ida 97 lori ọgọrun ninu awọn iye-eniyan ayé. Kò tíì si iwe isin miiran kan tí a tíì pese tí a sì ti pinkiri ní awọn ẹ̀dà ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ tí ô pọ̀ tobẹẹ.

7 Niti tootọ Bibeli ni iwe isin naa fun gbogbo araye. Eeṣe? A bẹrẹ kikọ rẹ̀ lẹba ibi tí ọ̀làjú ti gbé bẹrẹ. Oun nikan ni iwe mímọ́ tí ó tọpasẹ ọrọ-itan gbogbo araye pada lọ si ibẹrẹ rẹ̀. Pẹlupẹlu, ô sọ nipa ete Ọlọrun lati pese anfaani fun awọn eniyan ní gbogbo orilẹ-ede ayé” lati gbadun awọn ibukun pipẹ titi.—Genesis 22:18.

8 Encyclopaedia, Britannca pe Bibeli ní ikojọpọ awọn iwe tí ô ní agbara-idari giga julọ ninu ọrọ-itan ẹda-eniyan. Ô ti ní agbara-idari ati ipa gbigbooro julọ lori ọrọ-itan awọn iwe mímọ eyikeyi. Fun idi yii, ó tọna lati sọ pe a kò lè sọ pe ẹnikan jẹ ọmọwe patapata bi kò bá tíì ka Bibeli.

9 Sibẹ awọn eniyan kan ti yẹra fun Bibeli. Eeṣe? Nigba pupọ julọ ô jẹ nititori ti iwa awọn eniyan ati ti awọn orilẹ-ede tí a lero pe wọn ntẹle Bibeli. Ní awọn ilẹ kan bayii a ti sọ pe Bibeli jẹ iwe kan tí nṣamọna si ogun jíjà, pé ô jẹ iwe fun mímú orilẹ-ede kan sinrú fun omiran, tabi pe ô jẹ ’iwe awọn alawọ-funfun.’ Ṣugbọn gbogbo awọn wọnyi jẹ awọn oju-iwoye tí wọn kún fun iṣina. A kọ Bibeli ní Aarin Gbungbun Ila-oorun Ayé. Oun kò fọwọsi awọn ogun ìmúnìsìnrú ati ìkóni-nífà olojukokoro tí a ti ṣe lorukọ isin Kristian. Sí odikeji rẹ̀, ní kika Bibeli iwọ yoo rí i pe ô dẹbi lọna tí ô lagbara fun ogun jíjà onimọtara-ẹni-nikan, ìwà pálapàla ati kíkó awọn ẹlomiran nífà. Ariwisi naa wà pẹlu awọn eniyan olojukokorko, kii ṣe pẹlu Bibeli. (James 4:1-3; 5:1-6) Nitori naa maṣe jẹ ki iwa-buburu awọn eniyan onimọtara-ẹni-nikan tí wọn ngbé ní ilodisi imọran Bibeli jẹ idena fun ọ lati jere ninu awọn iṣura rẹ̀.

KINNI OHUN TÍ IWỌ YOO RÍ?

10 Iyalẹnu ni ô jẹ fun ọpọlọpọ nigba, akọkọ tí wọn bá ka Bibeli. Wọn ríi pe kii ṣe pe ní pataki ni ô jẹ iwe kan nipa awọn ọna tí a gbà npa isin mọ́ tabi ti awọn ijẹwọ isin. Bẹẹ ni kii ṣe akojọpọ awọn àpíilẹ̀sọ-ọ̀rọ̀ alaini itumọ jíjágaara tabi imọ-ọran tí itumọ rẹ̀ kere níye fun púrúntù eniyan. Ô niiṣe pẹlu awọn eniyan gidi tí wọn ní awọn aniyan ati awọn ọran-iṣoro gẹgẹ bi tiwa. Pẹlupẹlu, nipa pipese awọn ibalo Ọlọrun pẹlu araye nigba atijọ, ô fun wa ní imọlẹ-òye niti ohun tí ifẹ-inu rẹ̀ jẹ fun wa lonii. A gbà ọ niyanju lati ka Genesis, iwe tí ô bẹrẹ Bibeli. Lati inu awọn akọsilẹ tí wọn gba afiyesi tí wọn wà ninu rẹ̀ iwọ yoo lè kẹkọọ nipa eto Ọlọrun fun gbogbo araye. Iwọ yoo rí awọn ẹkọ-àríkọ́gbọn niti ohun tí ô lẹ̀ ba ayọ̀ ẹnikan jẹ́. Pẹlupẹlu, ìwọ yoo kẹkọọ nipa awọn iṣarasihuwa ati awọn iṣe tí nmú aṣeyọrisi rere wá tí wọn si wu Ọlọrun.

11 Awọn kan ninu awọn ọkọọkan iwe mẹrindinlaadọrin Bibeli niiṣe pẹlu ọrọ-itan ati awọn igbokegbodo-iṣẹ isin Israel igbaani. (Ekodus, Joshua ati Samuel Kìn-ín-ní jẹ awọn apẹẹrẹ diẹ tí ô daju pe iwọ yoo gbadun.) Ọrọ-itan yẹn ni a ṣe akọsilẹ rẹ̀ ki iwọ baa lè janfaani lati inu rẹ̀. (1 Corinth 10:11) Fun idi yii, ani bi ó tilẹ jẹ pe Ọlọrun kò tún maa bá a lọ ní didari orilẹ-ede kan ní pato mọ́, tabi ki ô reti pe ki ẹnikọọkan maa pa awọn ofin tí oun fi fun kiki Israel igbaani mọ́, ohun pupọ ni a lè kọ́ lati inu awọn iwe Bibeli bawọnni. Ati pe, bi a o ti ríi nigba tí ô bá yá, ohun tí Ọlọrun ṣe fun awọn ọmọ Israel (ati pẹlu awọn ẹbọ rírú pẹlu awọn ẹran tí wọn rú sii) ní itumọ fun igbesi-aye wa.

12 Lati ní oju-iwoye Bibeli tí ó kunrẹrẹ, ô yẹ ki o kà ô keretan ọ̀kan ninu awọn akọsilẹ igbesi-aye Jesu pẹlu. Ihinrere ti Mark tí a kọ ní ṣoki jẹ apẹẹrẹ kan tí ô dara. Lẹhin eyiini, gbadun akọsilẹ tí ntaniji nipa bi a ṣe dá isin Kristian silẹ tí a kọ sinu Iṣe Awọn Apostle. Lẹhin naa fi awọn imọran wiwulo fun awọn Kristian danrawo, gẹgẹ bi a ti ríi ninu lẹta James. Ṣiṣe itọwo ipilẹ gbogbo oniruuru awọn apá Bibeli yoo ràn ọ lọwọ lati rí idi rẹ̀ tí a fi bọla fun un lọna giga bẹẹ la gbogbo awọn ọgọrọọrun ọdun já.

13 Bi diẹ ninu awọn nkan tí o kà ninu Bibeli bá daamu rẹ, ní suuru. Ô ní awọn ọpọlọpọ ohun ijinlẹ ninu, gẹgẹ bi a o ti reti niti iwe kan tí a pese lati ọ̀dọ̀ Ẹlẹdaa fun ikẹkọọ araye la awọn ọgọrọọrun ọdun já. (2 Peter 3:15, 16) Ô pẹ́ ni ó yá ni iwọ yoo rí awọn idahun si awọn ibeere pupọ, nitori pe awọn akọsilẹ Bibeli jẹ eyi tí ó bá ara wọn tan. Ibeere kan tí ô dide nipa ẹsẹ iwe kan ni a o dahun rẹ̀ lati ọ̀dọ̀ ẹsẹ iwe-mimọ miiran. Bi o bá ti ṣe nkà á síi tô bẹẹ ni iwọ yoo tubọ maa rí bi Bibeli ṣe nrannilọwọ tí ô si ntẹnilọrun pupọ sii tô. Pẹlupẹlu, laipẹ ni iwọ yoo ríi pe ohun tí Bibeli sọ yatọ gedegbe si awọn ẹkọ ati awọn iṣe-aṣa ọpọ julọ awọn ṣọọṣi. Eyi yoo sún ọ lati fẹ lati ka gbogbo Iwe-mimọ, iwọ yoo sì tún maa rí ara rẹ tí o tún npada tọ iwe naa lọ siwaju ati siwaju sii.

BIBELI—LATI ORISUN WO?

14 O ṣeeṣe ki o mọ awọn eniyan tí wọn bọwọ fun Bibeli gẹgẹ bi iwe-ikẹkọọ kan tabi gẹgẹ bi ọgbọn igbaani, ṣugbọn tí wọn rò pe ô jẹ ohun tí eniyan mú jade, kii ṣe Ọrọ Ọlọrun. Kinni awọn otitọ-iṣẹlẹ?

15 Bi iwọ ti nka Bibeli iwọ yoo ríi pe oriṣiriṣi awọn eniyan ni wọn kọ ohun tí ô wà ninu rẹ̀ silẹ. Moses ni ẹni akọkọ, tí ó bẹrẹ ní 1513 B.C.E. Ọkunrin tí ô kẹhin ni apostle Jesu naa John, tí ô kọwe nigba tí ô kú diẹ ki ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E. pari. Lapapọ, awọn nkan bii 40 ọkunrin ni wọn kọ awọn oriṣiriṣi iwe Bibeli. Iru awọn eniyan wo ni wọn jẹ? Wọn jẹ awọn onirẹlẹ eniyan, tí wọn ṣetan lati fi awọn aṣiṣe ti ara wọn ati ti awọn orilẹ-ede wọn hàn sita. Àìṣàbòsí wọn yẹ ní gbígbé yẹwo, nititori pe wọn tún sọ pẹlu pe awọn nkọ ohun tí Ọlọrun sọ fun wọn lati kọ. Iwọ lè ṣakiyesi awọn apẹẹrẹ eyi ní 2 Samuel 23:1, 2; Jeremiah 1:1, 2 ati Ezekiel 13:1, 16 Njẹ kò ha yẹ ki eyi sún wa lati fi pẹlu ijẹpataki ṣayẹwo idaniloju Bibeli naa pe gbogbo Iwe-mimọ tí ô ní imisi Ọlọrun ni ô si ní èrè?—2 Timothy 3:16; 2 Peter 1:20, 21.

16 Ohun tí awọn akọwe Bibeli kọ yatọ ní ọpọlọpọ ọna si pupọ julọ ninu awọn akọsilẹ igbaani. Gẹgẹ bi akẹkọọ ọrọ-itan igbaani eyikeyi ti mọ, awọn akọsilẹ lati Egypt, Persia, Babylon ati awọn orilẹ-ede igbaani miiran ní ninu itan-àlẹ́ lasan ati sisọrọ ní àsọrégéé tí ô ga pupọ julọ nipa awọn alakoso ati awọn iwa-akin wọn. Bibeli, ní iyatọ si eyiini, ni a sami si nipasẹ otitọ ati ìpéye. O kún fun awọn orukọ ati kúlẹ̀kúlẹ̀ isọfunni tí wọn ṣe pato tí a lè fidii wọn mulẹ, ani tí a tilẹ kọ ọjọ wọn silẹ paapaa. Fun apẹẹrẹ, ori karun iwe Daniel ní isọfunni nipa alakoso Babylon kan tí orukọ rẹ̀ njẹ Belshazzar. Fun igba pipẹ ni awọn ọlọfintoto-alariwisi ti sọ pe Belshazzar kò gbé ayé rí rara, ṣugbọn pe Daniel ni ó kàn hùmọ̀ rẹ̀ funraarẹ̀. Ní awọn ọdun lọọlọọ yii, bi o ti wu ki o ri, awọn akọsilẹ lori wálàá amọ̀ ni a ti wú jade lati inu ilẹ tí ô sì ní itumọ tí ô wà ní ibamu pẹlu ẹkunrẹrẹ alaye akọsilẹ Daniel. Fun idi yii, Professor R. P. Dougherty (Yale University) kọwe pe ìpéye Bibeli pọ̀ ju ti awọn iwe miiran lọ tí ó sì fi ẹri hàn pe a kọ iwe Daniel nigba tí Bibeli tọkafihan pe a kọ ọ́.—Nabonidaus and Belshazzar.

17 Bi iwọ bá rin irin-ajo lọ si Jerusalem iwọ lè kọja lori ọna omi abẹ ilẹ igbaani kan tí a là kọja ninu apata. Ọna omi abẹ ilẹ gigun yii ni a rí tí a tún inu rẹ̀ ṣe kiki ní ọ̀rúndún tí ô kọja yii. Eeṣe tí eyi fi gba afiyesi wa? Nitori pe ô fi idi ohun tí a ti kọ sinu Bibeli mulẹ ní eyi tí ô ju 2,000 ọdun sẹhin lọ nipa pe Ọba Hezekiah mú omi wọ Jerusalem.—2 Awọn Ọba 20:20; 2 Chronicles 32:30.

18 Awọn ohun tí a mẹnukan loke yii kàn wulẹ jẹ meji ninu ọpọ jántírẹrẹ awọn apẹẹrẹ tí nfidi rẹ̀ mulẹ pe Bibeli ṣee gbarale lọna ti ọrọ-itan ati ti ẹkọ nipa ayé. Ṣugbọn ohun tí ô wemọ ọn ju kiki ìpéye lasan lọ, nitori pe awọn kan ninu awọn iwe ọrọ-itan ti ode-oni péye. Bibeli ní ninu awọn nkan tí a kò lè ṣalaye bi ô bá jẹ pe iwe kan tí ô ní orisun lati ọ̀dọ̀ ẹda-eniyan lasan ni. Awọn wọnyi ti mú ki ô dá awọn pupọ tí wọn fi pẹlu iṣọra ṣe ayẹwo Bibeli loju lati gbà pe ô wá lati ọ̀dọ̀ Ẹni Giga Julọ kan.

19 Bi o tilẹ jẹ pe a kò kọ Bibeli gẹgẹ bi iwe ẹkọ ijinlẹ kan, nigba tí ó bá mẹnukan awọn ọrọ tí wọn jẹwọ imọ-ijinlẹ ó péye ô sì ntanmọlẹ sori imọ tí kò sí larọwọto awọn ẹda-eniyan nigba tí a kọ ọ. Fun apẹẹrẹ, Dr. Arno Penzias (ẹni tí ô gba ẹ̀bùn Nobel ti 1978) sọ nipa ipilẹṣẹ agbaye pe:

“Ijiyan mi ni pe isọfunni tí ô dara julọ tí a ní jẹ ohun kan naa pẹlu eyi tí emi ìbá ti sọ àsọtẹlẹ rẹ̀, bi ô bá ti jẹ pe emi kò ní ohun miiran kankan lati lò yatọ si awọn iwe marun Moses, awọn Psalm, Bibeli lodi-ndi.

Siwaju sii, Genesis ṣe itolẹsẹẹsẹ bi iru awọn ohun abẹ̀mí tí nfarahan ní ṣisẹ-ntẹle lọna eto naa gan-an tí awọn onimọ-ijinlẹ ní gbogbogboo tẹwọgba nisinsinyi. (Genesis 1:1-27) Ati pe, nigba tí ô jẹ pe awọn orilẹ-ede miiran nkọni ní awọn itan àlọ bi iru pe ilẹ-aye duro lori awọn irin tabi òmìrán kan, Bibeli lọna ti ô tọna sọ pe ô duro lori òfo ati pe roboto ni ilẹ-aye rí. (Job 26:7; Isaiah 40:22) Bawo ni awọn akọwe Bibeli ṣe mọ awọn nkan ti a ṣawari wọn lati ọ̀dọ̀ awọn onimọ-ijinlẹ kiki ní awọn akoko lọọlọọ yii? Isọfunni naa ti nilati wá lati orisun kan tí ô ju ti awọn tikaraawọn lọ.

20 Ohun kan tún wà ani tí ó tilẹ tún ṣe pataki pupọ jù tí ó tanmọlẹ sori ipilẹṣẹ Bibeli. Eyiini ni asọtẹlẹ. Awọn eniyan lè méfò nipa awọn iṣẹlẹ tí nbọ, ṣugbọn wọn kò lè fi pẹlu iṣedeedee-ṣọkan-delẹ sọ asọtẹlẹ ọjọ-ọla pẹlu iwọn ìpéye eyikeyi. (James 4:13, 14) Sibẹ Bibeli nṣe bẹẹ. Tipẹtipẹ ṣaaju ki Babylon tó di ilẹ-ọba ayé ati ki ô tó sọ Jerusalem di ahoro, Ọlọrun ti mú ki wolii Isaiah sọtẹlẹ pe a o rẹ Babylon silẹ ninu ìlùbolẹ̀. Ní nkan bii ọ̀rúndún meji ṣaaju, Ọlọrun ti sọ orukọ Cyrus gẹgẹ bi ajagun-ṣẹgun Babylon, ô si sọ bi a o ti ṣe ké ilu naa lẹ̀rú. Isaiah tún ṣe akọsilẹ awọn kúlẹ̀kúlẹ̀ alaye tí ó ṣe rẹgi nipa isọdahoro ikẹhin Babylon, nigba tí iru àjálù bẹẹ nigba naa ṣì wà lọjọ iwaju fun eyi tí ô ju 1,000 ọdun lọ. (Isaiah 13:17-22; 44:24-45:3) Gbogbo rẹ̀ patapata ni a muṣẹ. Bẹẹ pẹlu ni awọn asọtẹlẹ Bibeli nipa Tyre ati Nineveh. (Ezekiel 26:1-5; Zephaniah 2:13-15) Iwọ lè ṣe ibẹwo si awọn iparun-bajẹ ní Aarin Gbungbun Ila-oorun Ayé ki o sì rí ẹri naa funraarẹ.

21 Ṣaaju tipẹtipẹ ki ó tó ṣẹlẹ ni iwe Bibeli ti Daniel ti sọ asọtẹlẹ awọn iṣẹlẹ agbaye lẹkunrẹrẹ laiku sibikan. A o ṣẹgun Babylon lati ọwọ Medo-Persia, tí, oun naa ẹ̀wẹ̀, yoo di eyi tí a lùbolẹ̀ lati ọwọ Greece. Lẹhin tí aṣaaju Greece olokiki naa (Alexander the Great) bá ti ṣubu ninu iku, mẹrin ninu awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni wọn yoo tẹwọgba ipo iṣakoso ti ilẹ-ọba nla tẹlẹri naa. (Daniel 8:3-8, 20-22) Eyiini jẹ ọrọ-itan ọjọ-iwaju gígùn-réré tí a kọ ṣaaju ki ó tó ṣẹlẹ, tí ô si ṣẹlẹ gan-an bi a ti sọtẹlẹ. Bawo ni Daniel ṣe mọ̀? Idahun kanṣoṣo tí ô tẹnilọrun ni a sọ sinu Bibeli tikaraarẹ̀: Gbogbo Iwe-mimọ ni ô ní imisi Ọlọrun. Eyi jẹ ohun tí ô kàn wa, nitori pe bi a o ṣe ṣe ayẹwo rẹ̀ ninu ori-iwe kan nikẹhin, Bibeli ní awọn asọtẹlẹ nipa awọn nkan tí wọn ti ṣẹlẹ ní akoko tiwa. Siwaju sii, ô ṣapejuwe awọn nkan tí ô ṣì wà lọjọ iwaju sibẹ ní yékéyéké. *

22 Ní afikun si kikoju ọjọ-iwaju, Bibeli ràn wa lọwọ lati dojukọ isinsinyi pẹlu aṣeyọrisi rere. O ṣalaye idi tí ijiya tí ô pọ̀ tobẹẹ fi wà, ô sì ràn wa lọwọ lati moye ete tí ó wà fun igbesi-aye. Ô funni ní itọsọna lati ọ̀dọ̀ Elẹdaa lori bi awa gẹgẹ bi ẹnikan ṣe lè bori awọn iṣoro ki a sì rí ayọ̀ tí ô pọ̀ julọ ninu igbesi-aye, nisinsinyi ati lọjọ iwaju. Awọn ori-iwe tí wọn ṣì wà niwaju yoo ṣayẹwo awọn kan ninu awọn ọran-iṣoro igbesi-aye, ati pẹlu, imọran Bibeli tí ô gbeṣẹ. Lakọkọ ná, bi o ti wu ki o ri, ô yẹ ki a tubọ jẹ ojulumọ Ẹni naa tí ô ti pese ìṣíníyè yii.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 21 Bi iwọ yoo bá fẹ lati kẹkọọ sii nipa Bibeli gẹgẹ bi iwe kan tí orisun kíkọ rẹ̀ jẹ ti Atọrunwa, jọwọ gba ẹ̀dà iwe naa tí akọle rẹ̀ njẹ Is the Bible Really the Word of God? tí a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí ô fi bọgbọnmu pe Ọlọrun ti pese iwe itọsọna kan? (1-5)

Awọn idi wo ló wà tí ó fi yẹ ki a ṣayẹwo Bibeli? (6-9)

Iru isọfunni wo ni a rí ninu Bibeli? (10-13)

Ẹri-ami wo ló ntọkafihan yala Bibeli kàn wulẹ wá lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan? (14-19)

Kinni ohun tí ô ṣe pataki nipa awọn alaye Bibeli lori awọn iṣẹlẹ ọjọ-ọla? (20-22)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Awọn oṣupa atọwọda eniyan nfi ìhìn-iṣẹ ranṣẹ si ilẹ-aye. Ẹlẹdaa kò ha lè ṣe jù bẹẹ lọ bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Njẹ kò ha bá ọgbọn ironu tí ó tọna mu pe Ọlọrun yoo pese iwe kan fun araye bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

ỌNA OMI ABẸ ILẸ HEZEKIAH

Iwọ lè kọja lori ọna omi abẹ ilẹ yii ní Jerusalem. Ô fidii ìpéye Bibeli mulẹ.