Ìbínú Ọlọ́run Parí
Orí 32
Ìbínú Ọlọ́run Parí
1. Kí ni yóò ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ti da ohun tó wà nínú àwokòtò méje náà jáde pátápátá, àwọn ìbéèrè wo ló sì wà nílẹ̀ báyìí nípa àwọn àwokòtò náà?
JÒHÁNÙ ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run gbé iṣẹ́ dída ohun tó wà nínú àwokòtò méje náà jáde lé lọ́wọ́. Ó sọ fún wa pé “àwọn wọ̀nyí ni ó kẹ́yìn, nítorí pé nípasẹ̀ wọn ni a mú ìbínú Ọlọ́run wá sí ìparí.” (Ìṣípayá 15:1; 16:1) Àwọn ìyọnu wọ̀nyí, tí ń ṣí àwọn ìdájọ́ Jèhófà payá nítorí ìwà burúkú orí ilẹ̀ ayé, ni a gbọ́dọ̀ dà jáde pátápátá. Nígbà tí wọ́n bá ti tán, ìdájọ́ Ọlọ́run yóò ti di mímúṣẹ. Ayé tí Sátánì ń ṣàkóso kì yóò sí mọ́! Ìkìlọ̀ kí ni ìyọnu wọ̀nyí jẹ́ fún aráyé àtàwọn alákòóso ètò burúkú ti ìsinsìnyí? Kí làwọn Kristẹni lè ṣe tí wọn ò fi ní dẹni tí ìyọnu kọ lù pa pọ̀ mọ́ ayé tí ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìparun yìí? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an, ìsinsìnyí la sì máa rí ìdáhùn wọn. Gbogbo àwọn tí ń hára gàgà láti rí ìṣẹ́gun òdodo yóò fẹ́ láti mọ ohun tí Jòhánù rí báyìí.
Ìrunú Jèhófà Lòdì sí “Ilẹ̀ Ayé”
2. Kí ló ṣẹlẹ̀ látàrí dídà tí áńgẹ́lì àkọ́kọ́ da ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ jáde sórí ilẹ̀ ayé, kí sì ni “ilẹ̀ ayé” ṣàpẹẹrẹ?
2 Áńgẹ́lì àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́! “Èkíní sì lọ, ó sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú ilẹ̀ ayé. Egbò adunniwọra àti afòòró ẹ̀mí sì wá wà lára àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àmì ẹranko ẹhànnà náà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère rẹ̀.” (Ìṣípayá 16:2) Bíi ti ìró kàkàkí àkọ́kọ́, “ilẹ̀ ayé” níhìn-ín ṣàpẹẹrẹ ètò ìṣèlú tó dà bíi pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, èyí tí Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé kalẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé nígbà ayé Nímírọ́dù, ní ohun tó lé ní ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn.—Ìṣípayá 8:7.
3. (a) Kí ló fi hàn pé ohun tí ọ̀pọ̀ ìjọba fẹ́ káwọn ọmọ abẹ́ wọn ṣe ni pé kí wọ́n máa jọ́sìn wọn? (b) Kí làwọn orílẹ̀-èdè ṣe láti fi rọ́pò Ìjọba Ọlọ́run, àkóbá wo sì ni èyí ń ṣe fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀?
3 Ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ohun tí ọ̀pọ̀ ìjọba fẹ́ kí àwọn ọmọ abẹ́ wọn ṣe ni pé kí wọ́n máa jọ́sìn wọn, ìyẹn ni wọ́n fi ń rin kinkin pé kí wọ́n gbé orílẹ̀-èdè ga ju Ọlọ́run tàbí ohun èyíkéyìí mìíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí lọ. (2 Tímótì ; fi wé 3:1Lúùkù 20:25; Jòhánù 19:15.) Látọdún 1914, ó ti di àṣà àwọn orílẹ̀-èdè láti máa fipá mú àwọn èwe wọn wọṣẹ́ ológun kí wọ́n lè lọ jagun, tàbí kí wọ́n lè múra sílẹ̀ fún irú ogun àjàkú akátá tó ti ń fi ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣòfò látọjọ́ pípẹ́. Ní ọjọ́ Olúwa, àwọn orílẹ̀-èdè tún ti ṣe ère ẹranko ẹhànnà náà láti fi rọ́pò Ìjọba Ọlọ́run. Ère náà ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àjọ tó rọ́pò rẹ̀, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ọ̀rọ̀ òdì gbáà ló jẹ́ láti máa pòkìkí pé àjọ táwọn ẹ̀dá èèyàn dá sílẹ̀ yìí ni ìrètí kan ṣoṣo tí gbogbo orílẹ̀-èdè ní fún àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí àwọn póòpù òde òní ti sọ! Àjọ yìí ta ko Ìjọba Ọlọ́run pátápátá. Ńṣe làwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ń di aláìmọ́, tàbí elégbò nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe kó ìyọnu bá àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n ta kò ó ní ọjọ́ Mósè, tó fi ooju àti egbò gidi jẹ wọ́n níyà.—Ẹ́kísódù 9:10, 11.
4. (a) Kí làwọn ohun tó wà nínú àwokòtò kìíní ti ìbínú Ọlọ́run jẹ́ kó hàn gbangba gbàǹgbà? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó tẹ́wọ́ gba àmì ẹranko ẹhànnà náà?
4 Àwọn ohun tó wà nínú àwokòtò yìí jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe hàn gbangba gbàǹgbà. Yálà kí wọ́n gbà kí ayé ṣá wọn tì tàbí kí wọ́n rí ìbínú Jèhófà. Ètò Sátánì ń mú aráyé lápàpàǹdodo láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà “kí ẹnì kankan má [bàa] lè rà tàbí tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà, orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.” (Ìṣípayá 13:16, 17) Ṣùgbọ́n ìjìyà wà fáwọn ẹni tó bá gba àmì náà o! Jèhófà kà wọ́n sí ẹni tí “egbò adunniwọra àti afòòró ẹ̀mí” kọ lù. Ọdún 1922 ni wọ́n ti gba àmì ní gbangba gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ti ṣá Ọlọ́run alààyè tì. Àwọn ètò òṣèlú tí wọ́n ń gbé kalẹ̀ kò ṣe àṣeyọrí kankan, làásìgbò sì ń bá wọn. Aláìmọ́ ni wọ́n nípa tẹ̀mí. Wọ́n gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àmódi “adunniwọra” yìí yóò já sí ikú, nítorí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ló dé yìí. Èèyàn ò lè jẹ́ kò-ṣeku kò-ṣẹyẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí rárá torí pé èèyàn ní láti yan ọ̀kan, yálà kó jẹ́ apá kan ètò àwọn nǹkan ayé tàbí kó máa sin Jèhófà níhà ọ̀dọ̀ Kristi rẹ̀.—Lúùkù 11:23; fi wé Jákọ́bù 4:4.
Òkun Di Ẹ̀jẹ̀
5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kejì da ohun tó wà nínú àwokòtò kejì jáde? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tí ń gbé nínú òkun ìṣàpẹẹrẹ náà?
5 Ìrunú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kejì ni a gbọ́dọ̀ dà jáde nísinsìnyí. Kí lèyí yóò mú bá aráyé? Jòhánù sọ fún wa pé: “Èkejì sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú òkun. Ó sì di ẹ̀jẹ̀ bí ti òkú ènìyàn, gbogbo alààyè ọkàn sì kú, bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ohun tí ó wà nínú òkun.” (Ìṣípayá 16:3) Bíi ti ìró kàkàkí kejì, inú “òkun” ni áńgẹ́lì kejì da ohun tó wà nínú àwokòtò yìí sí, ohun tí “òkun” yìí sì dúró fún ni àwọn èèyàn ọlọ̀tẹ̀ àti oníjàgídíjàgan tí wọ́n ti sọ ara wọn di àjèjì sí Jèhófà. (Aísáyà 57:20, 21; Ìṣípayá 8:8, 9) Lójú Jèhófà, ńṣe ni “òkun” yìí dà bí ẹ̀jẹ̀, èyí tí kò yẹ fún àwọn ẹ̀dá láti máa gbé nínú rẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé. (Jòhánù 17:14) Dídà ìrunú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kejì jáde fi hàn pé gbogbo aráyé tí ń gbé nínú òkun yìí jẹ́ òkú lójú Jèhófà. Nítorí ẹ̀bi àjùmọ̀pín, aráyé ti jẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu. Nígbà tí ọjọ́ ìrunú Jèhófà bá dé, wọn yóò kú ní ti gidi nígbà táwọn ọmọ ogun Jèhófà amúdàájọ́ṣẹ bá pa wọ́n run.—Ìṣípayá 19:17, 18; fi wé Éfésù 2:1; Kólósè 2:13.
Fífún Wọn Ní Ẹ̀jẹ̀ Mu
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kẹta da àwokòtò kẹta jáde, àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jòhánù sì gbọ́ látẹnu áńgẹ́lì kan àti láti inú pẹpẹ?
6 Bíi ti ìró kàkàkí kẹta, àwọn ìsun omi aláìníyọ̀ ni áńgẹ́lì kẹta da ìrunú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kẹta sí. “Ẹkẹta sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú àwọn odò àti àwọn ìsun omi. Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. Mo sì gbọ́ tí áńgẹ́lì ti orí àwọn omi wí pé: ‘Ìwọ, Ẹni tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo, nítorí pé ìwọ ti ṣe ìpinnu wọ̀nyí, nítorí pé wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ti àwọn wòlíì jáde, ìwọ sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ó tọ́ sí wọn.’ Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà wí pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.’”—Ìṣípayá 16:4-7.
7. Kí ni “àwọn odò àti àwọn ìsun omi” ṣàpẹẹrẹ?
7 “Àwọn odò àti àwọn ìsun omi” wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun táwọn èèyàn gbà pé ó lè jẹ́ káwọn rí ojúlówó ìtọ́sọ́nà àti ọgbọ́n, ìyẹn àwọn nǹkan bí èrò àwọn olóṣèlú, èrò àwọn tó mọ̀ nípa ọrọ̀ ajé, èrò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, èrò àwọn olùkọ́, èrò àwọn tó ń tún ìlú tò àti ti àwọn onísìn, èyí táwọn ọmọ aráyé ń tẹ̀ lé tí wọ́n fi ń hùwà tí wọ́n sì ń gbé ìpinnu wọn kà. Kàkà kí wọ́n yíjú sí Jèhófà, Orísun ìyè, kó lè kọ́ wọn ní òtítọ́ tí ń fúnni ní ìyè, àwọn èèyàn ti ‘gbẹ́ àwọn ìkùdu fífọ́ fún ara wọn’ wọ́n sì ti mu “ọgbọ́n ayé yìí [tó] jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run” ní àmuyó.—Jeremáyà 2:13; 1 Kọ́ríńtì 1:19; 2:6; 3:19; Sáàmù 36:9.
8. Àwọn ọ̀nà wo ni aráyé ti gbà fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ara wọn?
8 Irú “àwọn omi” alábààwọ́n bẹ́ẹ̀ ti mú káwọn èèyàn di ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ti jẹ́ kí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ nínú àwọn ogun, èyí tó ti gba ẹ̀mí ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn ní ọ̀rúndún tó kọjá. Àwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ ni ogun àgbáyé méjèèjì ti bẹ́ sílẹ̀. Àwọn ilẹ̀ yìí gan-an ló sì jẹ́ pé àwọn èèyàn ti “ṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀,” ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sì wà lára èyí tí wọ́n ta sílẹ̀. (Aísáyà 59:7; Jeremáyà 2:34) Aráyé pẹ̀lú ti fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wá sórí ara wọn nípa lílo ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ gan-an lọ́nà àìtọ́ fún ìfàjẹ̀sínilára, èyí tó lòdì sí àwọn òfin òdodo Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3-5; Léfítíkù 17:14; Ìṣe 15:28, 29) Látàrí èyí, wọ́n ti kárúgbìn ìkárísọ nítorí pé ṣe ni àrùn éèdì, àrùn mẹ́dọ̀wú àtàwọn àrùn mìíràn tí ìfàjẹ̀sínilára ń fà ń gbèèràn. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san fún gbogbo ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ yóò dé láìpẹ́ nígbà táwọn tó ń rú òfin Ọlọ́run bá gba ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó ga jù lọ, ìyẹn nígbà táwọn ọmọ ogun ọ̀run bá tẹ̀ wọ́n rẹ́ nínú “ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 14:19, 20.
9. Kí ni dída ohun tó wà nínú àwokòtò kẹta jáde jẹ mọ́?
9 Nígbà tí Odò Náílì di ẹ̀jẹ̀ nígbà ayé Mósè, àwọn ará Íjíbítì wá omi lọ sáwọn orísun omi mìíràn kí wọ́n má bàa kú. (Ẹ́kísódù 7:24) Ṣùgbọ́n, lónìí tí ìyọnu àjàkálẹ̀ tẹ̀mí ń jà ràn-ìn, kò sí ibì kankan nínú ayé Sátánì táwọn èèyàn ti lè rí omi afúnni-ní-ìyè. Dída ohun tó wà nínú àwokòtò kẹta yìí jáde jẹ mọ́ pípòkìkí pé “àwọn odò àti àwọn ìsun omi” ayé dà bí ẹ̀jẹ̀, èyí tí ń fi ikú tẹ̀mí pa gbogbo àwọn tí ń mu wọ́n. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìdájọ́ Ọlọ́run á dé sórí wọn.—Fi wé Ìsíkíẹ́lì 33:11.
10. Kí ni “áńgẹ́lì ti orí àwọn omi” sọ, kí sì ni “pẹpẹ náà” jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba?
10 “Áńgẹ́lì ti orí àwọn omi,” ìyẹn áńgẹ́lì tó da ohun tó wà nínú àwokòtò yìí sínú omi, gbé Jèhófà ga lọ́lá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ Àgbáyé, ẹni tí àwọn ìpinnu òdodo rẹ̀ pé pérépéré láìkù síbì kan. Abájọ tó fi sọ nípa ìdájọ́ yìí pé: “Ó tọ́ sí wọn.” Láìsí àní-àní, áńgẹ́lì náà fúnra rẹ̀ ti fojú rí púpọ̀ lára ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìwà ìkà tí àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ọgbọ́n ayé burúkú yìí ti ń ṣokùnfà rẹ̀ látọjọ́ pípẹ́. Fún ìdí yìí, ó mọ̀ pé ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà tọ́. Kódà “pẹpẹ” Ọlọ́run pàápàá sọ̀rọ̀ jáde. Nínú Ìṣípayá 6:9, 10, ọkàn àwọn tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni Bíbélì sọ pé ó wà ní ìsàlẹ̀ pẹpẹ yẹn. Nítorí náà “pẹpẹ náà” jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba pé òdodo làwọn ìpinnu Jèhófà. a Dájúdájú, ó bá a mu rẹ́gí pé ká fi ẹ̀jẹ̀ rọ àwọn tí wọ́n ti tàjẹ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì ti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ nílòkulò, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ ìyà ikú tí Jèhófà máa fi jẹ wọ́n.
Fífi Iná Jó Àwọn Èèyàn Gbẹ
11. Kí ni áńgẹ́lì kẹrin dojú ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kẹrin kọ, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó dà á jáde?
11 Oòrùn ni áńgẹ́lì kẹrin dojú ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kẹrin kọ. Jòhánù sọ fún wa pé: “Ẹ̀kẹ́rin sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún oòrùn láti fi iná jó àwọn ènìyàn náà gbẹ. A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn náà gbẹ, ṣùgbọ́n wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ lórí àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ wọ̀nyí, wọn kò sì ronú pìwà dà láti lè fi ògo fún un.”—Ìṣípayá 16:8, 9.
12. Kí ni “oòrùn” ayé yìí, kí ni Ọlọ́run sì yọ̀ǹda fún oòrùn ìṣàpẹẹrẹ yìí láti ṣe?
12 Lónìí, ní òpin ètò àwọn nǹkan, àwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí ń “tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.” (Mátíù 13:40, 43) Jésù fúnra rẹ̀ ni “oòrùn òdodo.” (Málákì 4:2) Àmọ́ ṣá, aráyé náà ní “oòrùn” tiwọn, ìyẹn àwọn alákòóso wọn tó ń gbìyànjú láti tàn bí wọ́n ti ń ṣàtakò sí Ìjọba Ọlọ́run. Ìró kàkàkí kẹrin pòkìkí pé orísun òkùnkùn ni ‘oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀’ tó wà ní ọ̀run ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́, pé wọn kì í ṣe orísun ìmọ́lẹ̀. (Ìṣípayá 8:12) Ní báyìí, àwokòtò kẹrin ti ìrunú Ọlọ́run ń fi hàn pé “oòrùn” ayé yóò gbóná débi tí kò fi ní ṣeé mú mọ́ra. Àwọn tí wọ́n ń wò gẹ́gẹ́ bí aṣáájú atàn-bí-oòrùn yóò “jó” aráyé. Ọlọ́run yóò yọ̀ǹda fún oòrùn ìṣàpẹẹrẹ náà láti ṣe èyí. Lédè mìíràn, Jèhófà yóò yọ̀ǹda kí èyí ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara ìdájọ́ rẹ̀ amú-bí-iná lórí aráyé. Lọ́nà wo ni oòrùn á yìí gbà jó aráyé?
13. Báwo làwọn alákòóso a-tàn-bí-oòrùn ayé yìí ṣe “jó” aráyé?
13 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn alákòóso ayé yìí dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ bí wọ́n ti ń sapá láti yanjú ìṣòro àìsí ààbò láyé, ṣùgbọ́n èyí kùnà. Nítorí náà, wọ́n gbìyànjú irú àwọn ìjọba mìíràn, irú bí Ìjọba oníkùmọ̀ àti ìjọba Násì. Ìjọba Kọ́múníìsì náà ń gbilẹ̀ sí i. Àmọ́, kàkà kí àwọn alákòóso a-tàn-bí-oòrùn yìí mú kí ipò aráyé sunwọ̀n sí i, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ‘fi ooru ńláǹlà jó aráyé.’ Àwọn ogun abẹ́lé tó jà ní orílẹ̀-èdè Sípéènì, Etiópíà, àti Manchuria wà lára ohun tó fa Ogun Àgbáyé Kejì. Ìtàn òde òní jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ bíi Mussolini, Hitler, àti Stalin ti lọ́wọ́ nínú ikú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní tààràtà tàbí láwọn ọ̀nà míì, títí kan ikú ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tiwọn fúnra wọn. Láìpẹ́ yìí, àwọn ogun tó ń bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ogun abẹ́lé ti “jó” àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè bíi Vietnam, Kampuchea, Iran, Lebanon, àti Ireland, àti àwọn orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà àti Áfíríkà. Yàtọ̀ sí gbogbo èyí, ìjà àjàkú-akáta tún ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lágbára jù lọ láyé, àwọn tí ohun ìjà runlé-rùnnà wọn ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ lè sun gbogbo aráyé deérú. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, kò sí àní-àní pé oòrùn ajónigbẹ, èyí tó dúró fún àwọn alákòóso aláìṣòdodo, ti ń jó aráyé. Ìrunú Ọlọ́run tí wọ́n dà jáde látinú àwokòtò kẹrin ti ṣí àwọn ohun wọ̀nyí tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn payá, àwọn èèyàn Ọlọ́run sì ti pòkìkí wọn jákèjádò ilẹ̀ ayé.
14. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn èèyàn látọjọ́ pípẹ́ pé ó jẹ́ ojútùú kan ṣoṣo sí àwọn ìṣòro aráyé, kí sì ni aráyé lódindi ṣe sí èyí?
14 Ọjọ́ pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn èèyàn pé ojútùú kan ṣoṣo sáwọn ìṣòro tó ń bá àwọn ẹ̀dá èèyàn fínra ni Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jèhófà ti pinnu láti fi sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Sáàmù 83:4, 17, 18; Mátíù 6:9, 10) Ṣùgbọ́n, aráyé lódindi ti kọ etí ikún sí ojútùú yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí Ìjọba náà tún ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, bíi ti Fáráò, tí kò gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé àti ọ̀run. (Ẹ́kísódù 1:8-10; 5:2) Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ Ìjọba Mèsáyà ò ti jọ àwọn alátakò wọ̀nyí lójú, ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n jìyà lábẹ́ “oòrùn” tiwọn tó ń gbóná janjan, èyí tó dúró fún ìṣàkóso aninilára àwọn ẹ̀dá èèyàn.
Ìtẹ́ Ẹranko Ẹhànnà Náà
15. (a) Orí kí ni áńgẹ́lì karùn-ún da ohun tó wà nínú àwokòtò karùn-ún sí? (b) Kí ni “ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà,” kí sì ni dída ohun tó wà nínú àwokòtò náà jáde sórí rẹ̀ jẹ mọ́?
15 Orí kí ni áńgẹ́lì tó kàn tú ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ dà sí? “Ìkarùn-ún sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà.” (Ìṣípayá 16:10a) “Ẹranko ẹhànnà náà” jẹ́ ètò ìṣàkóso Sátánì. Kò ní ìtẹ́ gidi kan, gẹ́gẹ́ bí ẹranko ẹhànnà náà fúnra rẹ̀ kì í ti í ṣe ẹranko gidi. Àmọ́, bí ibí yìí ṣe mẹ́nu kan ìtẹ́ fi hàn pé ẹranko ẹhànnà náà ń lo agbára láti ṣàkóso lórí aráyé; èyí bá àpèjúwe ẹranko náà mu ní ti pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí rẹ̀ ló ní adé dáyádémà táwọn ọba ń dé. Àní, “ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà” náà ni ìpìlẹ̀, tàbí orísun, agbára tó fi ń ṣàkóso yìí. b Bíbélì jẹ́ ká mọ ibi tí agbára ìṣàkóso ẹranko ẹhànnà náà ti wá nígbà tó sọ pé “dírágónì náà sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.” (Ìṣípayá 13:1, 2; 1 Jòhánù 5:19) Nípa báyìí, dídà tí áńgẹ́lì náà da ohun tó wà nínú àwokòtò náà sórí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà jẹ mọ́ ìpòkìkí kan tó ń jẹ́ ká mọ ipa tí Èṣù ti kó tó sì ń kó lọ́wọ́ bó ṣe ń ṣètìlẹyìn fún ẹranko ẹhànnà náà tó sì ń gbé e lárugẹ.
16. (a) Ta ni àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn, yálà wọ́n mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀? Ṣàlàyé. (b) Báwo ni ayé ṣe ń hùwà bíi ti Sátánì? (d) Ìgbà wo ni Ọlọ́run yóò bi ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà wó?
16 Kí ló ń mú kí àjọṣe tó wà láàárín Sátánì àtàwọn orílẹ̀-èdè máa bá a nìṣó? Nígbà tí Sátánì dẹ Jésù wò, ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé hàn án nínú ìran ó sì fi “gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn” lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n o, Jésù ní láti ṣe ohun kan kó tó lè gbà á. Ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jọ́sìn Sátánì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Lúùkù 4:5-7) Ṣé a wá lè rò pé ohun táwọn ìjọba ayé ní láti ṣe kí wọ́n tó gba agbára ìṣàkóso wọn máa yàtọ̀ síyẹn? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, Sátánì ni ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí, ìyẹn ló fi jẹ́ pé, yálà àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀, òun ni wọ́n ń sìn. (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) c Ó gbangba pé Èṣù ló ń darí ayé yìí tá a bá wo gbogbo ohun tó para pọ̀ wà nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni láìro ohun tó túmọ̀ sí, ìkórìíra, àti ìmọtara-ẹni-nìkan. Bó ṣe wu Sátánì ló ṣe ń darí ètò nǹkan yìí nítorí pé ńṣe ló fẹ́ kí aráyé wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Ìwà ìbàjẹ́ àwọn alákòóso, fífi ìwàǹwára wá agbára, irọ́ táwọn olóṣèlú ń pa fún ara wọn, àti ohun ìjà táwọn orílẹ̀-èdè ń kó jọ jẹ́ àwọn ohun tó fi irú ìwà burúkú tí Sátánì ń hù hàn. Ayé ti tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà àìṣòdodo Sátánì, ó sì tipa báyìí sọ Sátánì di ọlọ́run rẹ̀. Ọlọ́run yóò bi ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà wó nígbà tí Jésù Kristi Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run bá pa ẹranko yẹn run yán-ányán-án, tó sì gbé Sátánì fúnra rẹ̀ sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níkẹyìn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣípayá 19:20, 21; 20:1-3.
Òkùnkùn àti Ìrora Tí Ń Jáni Jẹ
17. (a) Báwo ni ìdàjáde ohun tó wà nínú àwokòtò karùn-ún ṣe jẹ mọ́ òkùnkùn nípa tẹ̀mí tó ti fi ìgbà gbogbo bo ìjọba ẹranko ẹhànnà náà mọ́lẹ̀? (b) Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí áńgẹ́lì náà da ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò karùn-ún jáde?
17 Ìjọba ẹranko ẹhànnà yìí ti wà nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀. (Fi wé Mátíù 8:12; Éfésù 6:11, 12.) Àwokòtò karùn-ún túbọ̀ mú kí ìkéde gbangba nípa òkùnkùn yìí rinlẹ̀ sí i. Àní, ó jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere sí i, ní ti pé orí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà gan-an ni áńgẹ́lì náà da àwokòtò ìrunú Ọlọ́run yìí sí. “Ìjọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora wọn, ṣùgbọ́n wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ wọn.”—Ìṣípayá 16:10b, 11.
18. Kí ló jọra láàárín ìró ìpè kàkàkí karùn-ún àti àwokòtò karùn-ún ti ìbínú Ọlọ́run?
18 Ìró kàkàkí karùn-ún kì í ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú àwokòtò karùn-ún ti ìrunú Ọlọ́run, níwọ̀n bí ìró kàkàkí náà ti polongo ìyọnu eéṣú. Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí pé nígbà tí áńgẹ́lì tú ìyọnu àwọn eéṣú yẹn sílẹ̀, oòrùn àti afẹ́fẹ́ ṣókùnkùn. (Ìṣípayá 9:2-5) Àti pé ní Ẹ́kísódù 10:14, 15, ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn eéṣú tí Jèhófà lò láti fi mú ìyọnu bá Íjíbítì ni pé: “Ìnira gbáà ni wọ́n jẹ́. Ṣáájú wọn, kò tíì sí eéṣú tí ó wá báyìí bí tiwọn rí, kò sì ní sí èyíkéyìí tí yóò wá báyìí lẹ́yìn wọn láé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bo ojú ibi tí a lè rí lórí gbogbo ilẹ̀ náà pátá, ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ńṣe ni òkùnkùn bolẹ̀! Lónìí, òkùnkùn tẹ̀mí tí ayé wà nínú rẹ̀ ti hàn gbangba gbàǹgbà nítorí dídún kàkàkí karùn-ún àti dída ìrunú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò karùn-ún jáde. Ìhìn ajónilára táwọn eéṣú agbáyìn-ìn òde òní ń pòkìkí rẹ̀ ń fa ìdálóró àti ìrora fáwọn ẹni ibi tí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀.”—Jòhánù 3:19.
19. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 16:10, 11 ṣe sọ, kí ni títú Sátánì fó ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yóò fà?
19 Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé ti fa ìbànújẹ́ àti ìyà púpọ̀ bá aráyé. Ìyàn, ogun, ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn, lílo oògùn olóró, ìṣekúṣe, àwọn àrùn tí wọ́n ń kó látara ìbálòpọ̀, àbòsí, àgàbàgebè àwọn ẹlẹ́sìn àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn jẹ́ ká mọ bí ètò àwọn nǹkan tí Sátánì ń ṣàkóso ṣe burú tó. (Fi wé Gálátíà 5:19-21.) Àní, títú Sátánì fó ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí tún ń fa ìrora àti ìtìjú fáwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Sátánì. “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gé ahọ́n wọn jẹ nítorí ìrora wọn,” pàápàá jù lọ láwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ò nífẹ̀ẹ́ sí bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ṣe ń tú ìwà tí wọ́n ń hù fó. Ṣe ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ń dáyà fo àwọn kan, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí àwọn tó ń kéde rẹ̀. Wọ́n ṣá Ìjọba Ọlọ́run tì wọ́n sì kẹ́gàn orúkọ mímọ́ Jèhófà. Títú tá a tú wọn fó pé ipò aláìmọ́ ni wọ́n wà nípa tẹ̀mí mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run. Wọn “kò . . . ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ wọn” rárá. Nítorí náà, a ò lè retí pé kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn yí ọkàn wọn padà ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan yìí.—Aísáyà 32:6.
Odò Yúfírétì Gbẹ Táútáú
20. Báwo ni ìró kàkàkí kẹfà àti dída ohun tó wà nínú àwokòtò kẹfà jáde ṣe jẹ kan odò Yúfírétì?
20 Ìró kàkàkí kẹfà kéde ìtúsílẹ̀ “àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a dè síbi odò ńlá Yúfírétì.” (Ìṣípayá 9:14) Nínú ìtàn, Bábílónì ni ìlú ńlá tó wà lórí odò Yúfírétì. Lọ́dún 1919, títú tí wọ́n tú àwọn áńgẹ́lì ìṣàpẹẹrẹ mẹ́rin náà sílẹ̀ bá ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì mìíràn rìn, ìyẹn ni ìṣubú Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá 14:8) Abájọ tí àwokòtò kẹfà ti ìbínú Ọlọ́run ṣe jẹ mọ́ odò Yúfírétì: “Ìkẹfà sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sórí odò ńlá Yúfírétì, àwọn omi rẹ̀ sì gbẹ ráúráú, kí a lè palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn.” (Ìṣípayá 16:12) Èyí náà jẹ́ ìròyìn búburú fún Bábílónì Ńlá!
21, 22. (a) Báwo ni omi odò Yúfírétì tó ń dáàbò bo Bábílónì ṣe gbẹ mọ́ Bábílónì lójú ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni? (b) Kí ni “àwọn omi” tí Bábílónì Ńlá jókòó lé, báwo sì ni omi ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyí ṣe ń gbẹ nísinsìnyí pàápàá?
21 Nígbà tí Bábílónì ìgbàanì ṣì wà lójú ọpọ́n, omi púpọ̀ yanturu tó wà lódò Yúfírétì wà lára àwọn ohun pàtàkì tó ń dáàbò bò ó. Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni, omi yẹn gbẹ táútáú nígbà tí Kírúsì aṣáájú Páṣíà darí ẹ̀ gba ọnà ibòmíràn. Èyí wá ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Kírúsì ará Páṣíà àti Dáríúsì ará Mídíà, àwọn ọba láti “yíyọ oòrùn” (ìyẹn ìlà oòrùn), láti wọ Bábílónì kí wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ní wákàtí yánpọnyánrin náà, odò Yúfírétì ò lè dáàbò bo ìlú ńlá yẹn. (Aísáyà 44:27-45:7; Jeremáyà 51:36) Irú ohun yìí kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sí Bábílónì òde òní, ètò ìsìn èké kárí ayé.
22 Bábílónì Ńlá “jókòó lórí omi púpọ̀.” Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 17:1, 15 ti wí, ìwọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n,” ìyẹn ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tó wà nínú Bábílónì Ńlá tí Bábílónì Ńlá kà sí ààbò. Ṣùgbọ́n “àwọn omi” náà ti ń gbẹ lọ! Ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù, níbi tí Bábílónì Ńlá ti ní agbára ńláǹlà tẹ́lẹ̀ rí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ti kẹ̀yìn sí ìsìn láìsí pé wọ́n ń fi èyí bò rárá. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n kéde ìlànà kan tí kò ní jẹ́ kí ìsìn lè máa darí àwọn èèyàn mọ́. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń gbé láwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn ni ò dìde fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àkókò bá dé fún ìparun Bábílónì Ńlá, àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí iye wọn ń kéré sí i, kò ní dáàbò bò ó rárá. (Ìṣípayá 17:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn ló wà lábẹ́ Bábílónì Ńlá, kò ní rí olùgbèjà tí “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn” bá kọ lù ú.
23. (a) Ta làwọn ọba “láti ibi yíyọ oòrùn” lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni? (b) Ta ni “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn” ní ọjọ́ Olúwa, báwo sì ni wọ́n ṣe máa pa Bábílónì Ńlá run?
23 Ta làwọn ọba wọ̀nyí? Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni, àwọn ni Dáríúsì ará Mídíà àti Kírúsì ará Páṣíà, àwọn tí Jèhófà lò láti ṣẹ́gun ìlú Bábílónì ìgbàanì. Ní ọjọ́ Olúwa tá a wà yìí, àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ alákòóso ni yóò pa ètò ìsìn èké ti Bábílónì Ńlá run. Ṣùgbọ́n ìdájọ́ Ọlọ́run lèyí náà máa jẹ́. Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn,” yóò ti fi “ìrònú” náà sínú ọkàn àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ alákòóso pé kí wọ́n yí padà sí Bábílónì Ńlá kí wọ́n sì pa á run pátápátá. (Ìṣípayá 17:16, 17) Bí áńgẹ́lì ṣe da ohun tó wà nínú àwokòtò kẹfà jáde jẹ́ ìpòkìkí ní gbangba pé ìdájọ́ yìí ti fẹ́ nímùúṣẹ ní kíkún báyìí!
24. (a) Báwo ni a ṣe kéde àwọn ohun tó wà nínú àwokòtò mẹ́fà àkọ́kọ́ ti ìrunú Jèhófà, kí ni èyí sì yọrí sí? (b) Kí ìwé Ìṣípayá tó sọ fún wa nípa àwokòtò ti ìrunú Ọlọ́run tó ṣẹ́ kù, kí ló jẹ́ ká mọ̀?
24 Àwokòtò mẹ́fà àkọ́kọ́ ti ìbínú Jèhófà jẹ́ ìròyìn tí ń múni ronú jinlẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé, táwọn áńgẹ́lì ń tì lẹ́yìn, ni ọwọ́ wọn dí fún kíkéde àwọn ohun tó wà nínú àwokòtò wọ̀nyí kárí ayé. Lọ́nà yìí, a ti fún gbogbo ẹ̀ka ayé Sátánì ní ìkìlọ̀ tó yẹ, Jèhófà sì ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láǹfààní láti máa ṣe òdodo kí wọ́n lè wà láàyè títí láé. (Ìsíkíẹ́lì 33:14-16) Síbẹ̀, ó ṣì ku ọ̀kan lára àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kí ìwé Ìṣípayá tó sọ fún wa nípa rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ bí Sátánì àtàwọn aṣojú rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ṣe ń gbìyànjú láti ta ko ìpolongo àwọn ìdájọ́ Jèhófà.
Ìkójọpọ̀ sí Amágẹ́dọ́nì
25. (a) Kí ni Jòhánù sọ fún wa nípa “àwọn àgbéjáde onímìísí” àìmọ́ tí wọ́n dà bí àkèré? (b) Báwo ni àwọn ohun tó dà bí àkèré tí ń ríni lára tí Bíbélì pè ní “àwọn àgbéjáde onímìísí àìmọ́” ṣe wà ní ọjọ́ Olúwa, kí sì ni èyí yọrí sí?
25 Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí tí àwọn àgbéjáde onímìísí àìmọ́ mẹ́ta tí wọ́n rí bí àkèré jáde wá láti ẹnu dírágónì náà àti láti ẹnu ẹranko ẹhànnà náà àti láti ẹnu wòlíì èké náà. Ní ti tòótọ́, wọ́n jẹ́ àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí, wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì, wọ́n sì jáde lọ bá àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá, láti kó wọn jọpọ̀ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:13, 14) Nígbà ayé Mósè, Jèhófà lo àwọn àkèré akóninírìíra láti fi mú ìyọnu bá ilẹ̀ Íjíbítì tí Fáráò ti ń ṣàkóso, tó fi jẹ́ pé “ilẹ̀ náà . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣíyàn-án.” (Ẹ́kísódù 8:5-15) Ní ọjọ́ Olúwa, àwọn ohun tó dà bí àkèré tí ń ríni lára ti wà pẹ̀lú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀. Àwọn ni “àwọn àgbéjáde onímìísí àìmọ́” ti Sátánì, kò sì sí àní-àní pé ohun tí wọ́n dúró fún ni ìpolongo ẹ̀tàn tí Sátánì ń lò láti fi darí gbogbo àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ alákòóso, ìyẹn “àwọn ọba,” kó lè mú kí wọ́n máa ṣàtakò sí Jèhófà Ọlọ́run. Sátánì ń tipa bẹ́ẹ̀ rí i dájú pé ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwọn àwokòtò náà tí wọ́n dà jáde kò ní mú wọn yí èrò wọn padà, ṣùgbọ́n wọ́n á dúró gbọn-in gbọn-in níhà ọ̀dọ̀ Sátánì nígbà tí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” bá bẹ̀rẹ̀.
26. (a) Láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ta wo ni àwọn ìpolongo ẹ̀tàn Sátánì ti ń wá? (b) Kí ni “wòlíì èké náà,” báwo la sì ṣe mọ̀?
26 Ìpolongo ẹ̀tàn náà wá láti ọ̀dọ̀ “dírágónì náà” (ìyẹn Sátánì) àti “ẹranko ẹhànnà náà” (ìyẹn ètò ìṣèlú ti Sátánì lórí ilẹ̀ ayé), a sì ti kọ́ nípa àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá. Àmọ́, kí ni “wòlíì èké náà”? Orúkọ yìí nìkan ló jẹ́ tuntun sí wa. Ní ìṣáájú, a kà nípa ẹranko ẹhànnà tó ní ìwo méjì bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn, èyí tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńlá níwájú ẹranko ẹhànnà olórí méje náà. Ẹ̀dá atannijẹ yìí ṣe bíi wòlíì fún ẹranko ẹhànnà yẹn. Ó gbé ìjọsìn ẹranko ẹhànnà náà lárugẹ, àní ó tiẹ̀ tún mú kí wọ́n ṣe ère kan fún un. (Ìṣípayá 13:11-14) Ẹranko ẹhànnà tó ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn yìí ní láti jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú “wòlíì èké” tí ibí yìí mẹ́nu kàn. Ohun tó fìdí èyí múlẹ̀ lohun tá a kà lẹ́yìn ìgbà náà pé, bíi ti ẹranko ẹhànnà oníwo méjì ìṣàpẹẹrẹ náà, wòlíì èké náà “ṣe àwọn iṣẹ́ àmì níwájú [ẹranko ẹhànnà olórí méje náà], èyí tí ó fi ṣi àwọn tí ó gba àmì ẹranko ẹhànnà náà lọ́nà àti àwọn tí ó ṣe ìjọsìn fún ère rẹ̀.”—Ìṣípayá 19:20.
27. (a) Ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò wo ni Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi fúnni? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fúnni nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? (d) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tún ìkìlọ̀ Jésù sọ?
27 Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìpolongo ẹ̀tàn Sátánì tó wà káàkiri, ọ̀rọ̀ tí Jòhánù kọ sílẹ̀ tẹ̀ lé e bọ́ sí àkókò gan-an ni, ó sọ pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò, tí ó sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.” (Ìṣípayá 16:15) Ta ní ń bọ̀ “bí olè”? Jésù fúnra rẹ̀ ni, ẹni tí yóò wá lójijì gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ Jèhófà. (Ìṣípayá 3:3; 2 Pétérù 3:10) Nígbà tí Jésù ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú, ó fi bíbọ̀ rẹ̀ wé ti olè, ó wí pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:42, 44; Lúùkù 12:37, 40) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún ìkìlọ̀ yìí sọ, ó ní: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Sátánì ló wà lẹ́yìn ìpòkìkí èké èyíkéyìí nípa “Àlàáfíà àti ààbò.”—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.
28. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún wa nípa ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní kó wàhálà ayé lékàn, kí sì ni “ọjọ́ yẹn” táwọn Kristẹni kò fẹ́ kó dé bá wọn “gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn”?
28 Jésù tún kìlọ̀ nípa irú àwọn wàhálà tí ayé tó kún fún ìpolongo ẹ̀tàn yìí lè mú kó gba àwọn Kristẹni lọ́kàn. Ó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. . . . Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) “Ọjọ́ yẹn” ni “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14) Bí “ọjọ́ yẹn,” tó máa hàn gbangba pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run ti ń sún mọ́lé, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti kojú àwọn àníyàn ìgbésí ayé. Ó pọn dandan fáwọn Kristẹni láti máa ṣọ́nà, kí wọ́n sì máa wà lójúfò títí ọjọ́ yẹn yóò fi dé.
29, 30. (a) Kí ni ìtumọ̀ ìkìlọ̀ Jésù pé ojú á ti àwọn tí òun bá dé bá lójú oorun ní ti pé wọn yóò pàdánù “ẹ̀wù àwọ̀lékè” wọn? (b) Kí ni ẹ̀wù àwọ̀lékè ń fi hàn pé ẹni tó wọ̀ ọ́ jẹ́? (d) Báwo lẹnì kan ṣe lè pàdánù ẹ̀wù àwọ̀lékè ìṣàpẹẹrẹ tirẹ̀, kí sì ni èyí yóò yọrí sí?
29 Ṣùgbọ́n, kí ni ìtumọ̀ ìkìlọ̀ Jésù pé ojú á ti àwọn tí òun bá dé bá lójú oorun ní ti pé wọn yóò pàdánù “ẹ̀wù àwọ̀lékè” wọn? Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àlùfáà tàbí ọmọ Léfì èyíkéyìí tó bá wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣọ́nà ní tẹ́ńpìlì kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn Júù kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé sọ fún wa pé bí wọ́n bá gbá ẹnikẹ́ni mú pé ó ń sùn lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n lè bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ̀ kí wọ́n dáná sun ún, kí ojú bàa lè tì í ní gbangba.
30 Ìkìlọ̀ tí Jésù ń ṣe ni pé ohun tó fara jọ èyí lè ṣẹlẹ̀ lónìí. Àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù làwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì dúró fún. (1 Pétérù 2:9) Ṣùgbọ́n ìkìlọ̀ Jésù tún kan ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú. Ẹ̀wù àwọ̀lékè tí ibí yìí tọ́ka sí ń fi hàn pé Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹni tó wọ̀ ọ́. (Fi wé Ìṣípayá 3:18; 7:14.) Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ kí àníyàn ayé Sátánì kun òun lóorun tàbí kó mú òun di aláìṣiṣẹ́mọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pàdánù ẹ̀wù àwọ̀lékè yìí—lédè mìíràn, ó lè pàdánù àmì ìdánimọ̀ rẹ̀ mímọ́ tónítóní gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Nǹkan ìtìjú gbáà lèyí máa jẹ́ o. Ó lè mú kéèyàn pàdánù pátápátá.
31. (a) Báwo ni Ìṣípayá 16:16 ṣe túbọ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni ní láti wà lójúfò? (b) Kí làwọn aṣáájú ìsìn kan ti sọ nípa Amágẹ́dọ́nì?
31 Ẹsẹ Bíbélì tó kàn nínú Ìṣípayá, èyí tí ìmúṣẹ rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́lé, jẹ́ ká mọ bó ṣe ṣe pàtàkì gidigidi tó pé káwa Kristẹni wà lójúfò, ó ní: “Wọ́n [àwọn àgbéjáde táwọn ẹ̀mí èṣù mí sí] sì kó wọn [àwọn ọba ilẹ̀ ayé, tàbí àwọn alákòóso] jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.” (Ìṣípayá 16:16) Ibì kan ṣoṣo ni orúkọ yìí, tí a sábà máa ń pè ní Amágẹ́dọ́nì, wà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n aráyé ò yéé ronú nípa rẹ̀ ṣáá. Àwọn aṣáájú ayé ti kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí Amágẹ́dọ́nì tó jẹ́ ogun tí wọ́n á ti lo ohun ìjà runlé-rùnnà ṣẹlẹ̀. Nígbà táwọn kan bá ń sọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì wọ́n tún máa ń mẹ́nu kan ìlú Mẹ́gídò ìgbàanì, níbi tí wọ́n ti ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun àjàmọ̀gá ní àwọn àkókò ìtàn inú Bíbélì. Ní tìtorí èyí, àwọn aṣáájú ìsìn kan ti sọ pé ibi kékeré yẹn ni ogun àjàgbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé yóò ti wáyé. Èrò ọkàn wọn yìí jìnnà pátápátá sí òtítọ́.
32, 33. (a) Dípò ibi gidi kan, kí ni orúkọ náà Ha-Mágẹ́dọ́nì, tàbí Amágẹ́dọ́nì, dúró fún? (b) Àwọn ọ̀rọ̀ wo ló tún wà nínú Bíbélì tó fara jọ “Amágẹ́dọ́nì” tàbí tó jẹ mọ́ ọn? (d) Ìgbà wo ni àkókò máa tó fún áńgẹ́lì keje láti da àwokòtò ìkẹyìn ti ìbínú Ọlọ́run jáde?
32 Orúkọ náà Ha-Mágẹ́dọ́nì túmọ̀ sí “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” Ṣùgbọ́n dípò kó jẹ́ ibi gidi kan, ó dúró fún ipò kan jákèjádò ayé tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé kóra wọn jọ sí ní títa ko Jèhófà Ọlọ́run ó sì jẹ́ ipò tí Jèhófà yóò ti pa wọ́n run níkẹyìn. Jákèjádò ayé lèyí jẹ́. (Jeremáyà 25:31-33; Dáníẹ́lì 2:44) Ó fara jọ “ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run” àti “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu,” tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì,” níbi tí a kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ sí kí Jèhófà lè pa wọ́n run. (Ìṣípayá 14:19; Jóẹ́lì 3:12, 14) Ó tún jẹ mọ́ “ilẹ̀ Ísírẹ́lì” níbi tí Jèhófà yóò ti pa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sátánì tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù. bẹ́ẹ̀ ló sì tún jẹ mọ́ àgbègbè náà tó wà ‘láàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge’ níbi tí ọba àríwá yóò ti wá “sí òpin rẹ̀” ní ọwọ́ Máíkẹ́lì ọmọ aládé ńlá náà.—Ìsíkíẹ́lì 38:16-18, 22, 23; Dáníẹ́lì 11:45-12:1.
33 Nígbà tí ìpolongo ẹ̀tàn tó ń dún bí igbe àkèré tó pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Sátánì àti àwọn aṣojú rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé bá ti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè wà nínú ipò yìí, á jẹ́ pé àkókò ti tó nìyẹn fún áńgẹ́lì keje láti da ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò tó kẹ́yìn náà jáde.
“Ó Ti Ṣẹlẹ̀!”
34. Inú kí ni áńgẹ́lì keje da ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ sí, ìpòkìkí wo ló sì jáde “láti inú ibùjọsìn níbi ìtẹ́ náà”?
34 “Ìkeje sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú afẹ́fẹ́. Látàrí èyí, ohùn rara jáde wá láti inú ibùjọsìn níbi ìtẹ́ náà, tí ó wí pé: ‘Ó ti ṣẹlẹ̀!’”—Ìṣípayá 16:17.
35. (a) Kí ni “afẹ́fẹ́” tí Ìṣípayá 16:17 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí ni áńgẹ́lì keje tó da ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ jáde sínú afẹ́fẹ́ ń fi hàn?
35 “Afẹ́fẹ́” ni ohun agbẹ́mìíró ìkẹyìn tí ìyọnu máa bá. Ṣùgbọ́n èyí kì í ṣe afẹ́fẹ́ gidi. Kò sí ohun kankan tí afẹ́fẹ́ gidi ṣe tí Jèhófà fi ní láti dá a lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ Jèhófà kò ti tọ́ sí ilẹ̀ ayé, òkun, àwọn ìsun omi aláìníyọ̀, tàbí oòrùn gidi. Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí ni “afẹ́fẹ́” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó pe Sátánì ní “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́.” (Éfésù 2:2) Ó jẹ́ “afẹ́fẹ́” Sátánì tí ayé ń mí sínú lónìí, ìyẹn ẹ̀mí tàbí ìrònú tó ń darí àwọn èèyàn, èyí tó ti fara hàn gbangba nínú ètò àwọn nǹkan burúkú Sátánì lódindi. Èyí ni ìrònú tó jọ ti Sátánì tó gbilẹ̀ débi gbogbo àyàfi inú ètò Jèhófà nìkan. Nítorí náà, ńṣe ni áńgẹ́lì keje tó da ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ jáde sínú afẹ́fẹ́ ń fi ìrunú Ọlọ́run hàn lòdì sí Sátánì, ètò rẹ̀, àti gbogbo nǹkan tó ń sún aráyé láti ṣètìlẹyìn fún Sátánì bó ṣe ń pe ipò ọba aláṣẹ Jèhófà níjà.
36. (a) Kí ni ìyọnu méje náà para pọ̀ jẹ́? (b) Kí ni ìpòkìkí Jèhófà pé: “Ó ti ṣẹlẹ̀!” fi hàn?
36 Èyí àtàwọn ìyọnu mẹ́fà tó ṣáájú jẹ́ ká mọ gbogbo àwọn ìdájọ́ Jèhófà látòkèdélẹ̀ lòdì sí Sátánì àti ètò rẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìpolongo ìdájọ́ ìparun fún Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀. Nígbà tí áńgẹ́lì náà bá da ohun tó wà nínú àwokòtò ìkẹyìn yìí jáde, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò polongo pé: “Ó ti ṣẹlẹ̀!” Kò sí ohunkóhun mìíràn mọ́ láti sọ. Nígbà tí ohun tó wà nínú àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run bá ti di èyí tí a kéde débi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, kì yóò sí ìjáfara kankan lọ́dọ̀ rẹ̀ láti mú àwọn ìdájọ́ táwọn ìhìn wọ̀nyí pòkìkí ṣẹ.
37. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn dída ìbínú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò keje jáde?
37 Jòhánù ń bá a lọ pé: “Mànàmáná sì kọ, ohùn sì dún, ààrá sì sán, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá sì sẹ̀ irú èyí tí kò tíì sẹ̀ láti ìgbà tí ènìyàn ti wá wà lórí ilẹ̀ ayé, ìsẹ̀lẹ̀ kan tí ó lọ jìnnà, tí ó pọ̀ jọjọ. Ìlú ńlá títóbi náà sì pín sí apá mẹ́ta, àwọn ìlú ńlá àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú; a sì rántí Bábílónì Ńlá níwájú Ọlọ́run, láti fún un ní ife wáìnì ìbínú ìrunú rẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo erékùṣù sá lọ, a kò sì rí àwọn òkè ńláńlá. Yìnyín ńláǹlà, tí òkúta rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìwọ̀n tálẹ́ńtì kan sì bọ́ láti ọ̀run sórí àwọn ènìyàn náà, àwọn ènìyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ yìnyín náà, nítorí ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀ pọ̀ lọ́nà kíkàmàmà.”—Ìṣípayá 16:18-21.
38. Kí làwọn nǹkan wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ: (a) “ìsẹ̀lẹ̀ ńlá” náà? (b) pípín tí “ìlú ńlá títóbi” náà, Bábílónì Ńlá, pín sí “apá mẹ́ta”? (d) bí ‘gbogbo erékùṣù ṣe sá lọ, tí a kò sì rí àwọn òkè ńláńlá’? (e) “ìyọnu àjàkálẹ̀ yìnyín náà”?
38 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà yóò yíjú sí aráyé, yóò sì ṣe àwọn ohun tó kàmàmà, ohun tó sì fi èyí hàn ni “mànàmáná àti ohùn àti ààrá.” (Fi wé Ìṣípayá 4:5; 8:5.) Aráyé ni a ó mì lọ́nà tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí, àfi bíi pé ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó fakíki kan ló ń wáyé. (Fi wé Aísáyà 13:13; Jóẹ́lì 3:16.) Mímì jìgìjìgì yìí yóò fọ́ Bábílónì Ńlá, “ìlú ńlá títóbi náà” túútúú, débi pé yóò pín sí “apá mẹ́ta,” èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìparun yán-ányán tí yóò dé bá a. Pẹ̀lúpẹ̀lù, “àwọn ìlú ńlá àwọn orílẹ̀-èdè” yóò ṣubú. “Gbogbo erékùṣù” àti “àwọn òkè ńláńlá,” ìyẹn àwọn ètò táwọn ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀ àtàwọn àjọ tó dà bíi pé mìmì kan ò lè mì wọ́n nínú ètò yìí, ni yóò lọ. “Yìnyín ńláǹlà,” èyí tó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ju èyí tó pọ́n Íjíbítì lójú lákòókò ìyọnu keje, tó jẹ́ pé òkúta yìnyín kọ̀ọ̀kan tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bíi tálẹ́ǹtì kan, yóò máa bọ́ lu aráyé, ara yóò sì ro wọ́n. d (Ẹ́kísódù 9:22-26) Ó dà bíi pé ohun táwọn omi dídì tí yóò máa já bọ́ látọ̀run láti fìyà jẹ àwọn aṣebi wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ ni àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ Jèhófà tó wúwo rinrin, èyí tó ń fi hàn pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ti dé nígbẹ̀yìngbẹ́yín! Àní Jèhófà lè lo yìnyín gidi náà pàápàá nígbà ìparun.—Jóòbù 38:22, 23.
39. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ó da àwọn ìyọnu méje náà jáde, kí ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìran èèyàn yóò máa ṣe?
39 Nípa báyìí, Jèhófà yóò fi òdodo rẹ̀ ṣèdájọ́ ayé Sátánì. Títí dé òpin, ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìran èèyàn yóò máa rí Ọlọ́run fín tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ òdì sí i nìṣó. Bíi ti Fáráò ìgbàanì, àwọn ìyọnu tí ń wáyé léraléra tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ aṣekúpani tí yóò wáyé lẹ́yìn táwọn ìyọnu wọnnì bá ti tán kò ní mú kí ọkàn wọn rọ̀. (Ẹ́kísódù 11:9, 10) Kò ní sí pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ń yí ọkàn wọn padà nígbà tí ẹ̀pa ò bá bóró mọ́. Pẹ̀lú èémí tí wọ́n á mí kẹ́yìn lẹ́nu wọn, wọn yóò fìkanra sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run tó polongo pé: “Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 38:23) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, yóò ti hàn gbangba pé Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ rí àpẹẹrẹ àwọn ohun aláìlẹ́mìí tí ń ṣe ẹlẹ́rìí, tún wo Jẹ́nẹ́sísì 4:10; 31:44-53; Hébérù 12:24.
b Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “ìtẹ́” lọ́nà tó jọ èyí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ nípa Jésù nínú àsọtẹ́lẹ̀, tó sọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Sáàmù 45:6) Jèhófà ni orísun, tàbí ìpìlẹ̀, agbára ìṣàkóso Jésù.
c Tún wo Jóòbù 1:6, 12; 2:1, 2; Mátíù 4:8-10; 13:19; Lúùkù 8:12; Jòhánù 8:44; 12:31; 14:30; Hébérù 2:14; 1 Pétérù 5:8.
d Bó bá jẹ́ pé tálẹ́ǹtì àwọn Gíríìkì ni Jòhánù ní lọ́kàn, á jẹ́ pé òkúta yìnyín kọ̀ọ̀kan yóò tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí ogún kìlógíráàmù. Ìjì yìnyín apanirun gan-an nìyẹn á jẹ́.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 221]
“Sínú Ilẹ̀ Ayé”
Ẹgbẹ́ Jòhánù ti lo irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí láti fi polongo ìrunú Jèhófà lòdì sí “ilẹ̀ ayé”:
“Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún táwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ti ń ṣakitiyan, ẹ̀rí ti fi hàn pé wọn ò lè rí nǹkan ṣe sáwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè yanjú àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú báni. Àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé àtàwọn gbajúmọ̀ òṣèlú tó ń wá ojútùú sọ́rọ̀ yìí ti rí i pé kò sí nǹkan táwọn lè ṣe.”—Millions Now Living Will Never Die, 1920, ojú ìwé 61.
“Kò sí ìjọba kankan lórí ilẹ̀ ayé lónìí tó ń tẹ́ àwọn tó pọ̀ tó nínú ayé lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ń ṣàkóso. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ayé ló ti wọ oko gbèsè.”—A Desirable Government, 1924, ojú ìwé 5.
“Ṣiṣe bayi fi opin si eto awọn nkan yi ni ọna kanṣoṣo ti a le fi mu ibi kuro ni aiye, ki a si jẹki aye wa fun alafia ati ododo lati gbilẹ.”—“Ihin Rere ti Ijọba Na,” 1955, ojú ìwé 22.
“Eto ayé isinsinyii ti fi ara rẹ̀ han tayọ nipasẹ ilọsiwaju iṣẹ ẹṣẹ, aiṣododo ati iṣọtẹ lodi si Ọlọrun ati ifẹ rẹ̀. . . . A ko le ṣe atunṣe rẹ̀. . . . Nitori naa, ó nilati lọ kuro ni ṣaa!”—Ile-Iṣọ Naa, May 15, 1982, ojú ìwé 6.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 223]
“Sínú Òkun”
Díẹ̀ lára àwọn ohun tí ẹgbẹ́ Jòhánù ti tẹ̀ jáde bí ọdún ti ń gorí ọdún ló wà nísàlẹ̀ yìí, èyí tí wọ́n fi ń pòkìkí ìrunú Ọlọ́run lòdì sí “òkun” tó dúró fún àwọn èèyàn ọlọ̀tẹ̀, oníjàgídíjàgan tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run tó ti di àjèjì sí Jèhófà:
“Ìtàn gbogbo orílẹ̀-èdè fi hàn pé ìjàkadì máa ń wà láàárín àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn èèyàn kéréje sábà máa ń bá àwọn tó pọ̀ gan-an jà. . . . Ìjàkadì wọ̀nyí ti yọrí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣọ̀tẹ̀ síjọba, ìyà ńláǹlà, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀.”—Government, 1928, ojú ìwé 244.
Nínú ayé tuntun, ‘“òkun” tó dúró fún àwọn èèyàn ọlọ̀tẹ̀, oníjàgídíjàgan tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà jáde látinú rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn fún ìlò Èṣù, kò ní sí mọ́.’—Ile-Iṣọ Na, March 15, 1970, ojú ìwé 184.
“Ẹgbẹ awọn enia loni nṣaisan nipa ti ẹmi nwọn si li arun lara. Ko si ẹnikan ninu wa ti o le gba a la, nitoripe Ọrọ Ọlọrun fihan pe aisan rẹ̀ yio yọrisi iku rẹ̀.”—Alafia àti Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, 1976, ojú ìwé 130.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 224]
“Sínú Àwọn Odò àti Àwọn Ìsun”
Ìyọnu kẹta ti lo irú àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí láti tú “àwọn odò àti àwọn ìsun omi” fó:
“Àwọn àlùfáà, tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ [Kristi], ti ya ogun sí mímọ́ wọ́n sì ti sọ ọ́ di ohun mímọ́. Inú wọn dùn sí i pé ká gbé àwòrán wọn àti ère ìrántí wọn sí ojútáyé lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwòrán àwọn jagunjagun tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì), September 15, 1924, ojú ìwé 275.
“Ìbókùúsọ̀rọ̀ [ìbẹ́mìílò] ni a gbé ka orí irọ́ ńlá kan, ìyẹn ni pé ìwàláàyè ń bá a nìṣó lẹ́yìn ikú àti pé ọkàn èèyàn kì í kú.”—What Do the Scriptures Say About “Survival After Death?,” 1955, ojú ìwé 51.
“Ọgbọ́n ẹ̀dá èèyàn, irú bí èrò àwọn tó mọ̀ nípa òṣèlú, èrò àwọn tó ń ṣe onírúurú ètò fún ìlọsíwájú àwùjọ, èrò àwọn tó ń gba ìjọba nímọ̀ràn lórí ọrọ̀ ajé, àti èrò àwọn tó ń gbé àṣà ẹ̀sìn àtọwọ́dọ́wọ́ lárugẹ kò tíì mú ojúlówó ìtura tó lè fúnni níyè wá . . . Àní, irú àwọn omi bẹ́ẹ̀ ti mú káwọn tó ń mu ún ṣẹ̀ sí òfin Ẹlẹ́dàá nípa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n sì lọ́wọ́ nínú àwọn inúnibíni ìsìn.”—Ìpinnu tí a tẹ́wọ́ gbà ní Àpéjọ Àgbáyé “Ìhìn rere Àìnípẹ̀kun,” 1963.
‘Kiṣe igbala nipa ọgbọn ijinlẹ, bikoṣe iparun iran enia li ohun ti a nilati reti lọdọ enia tikararẹ̀. . . . Awa ko le gbe ireti wa sọdọ awọn ọjọgbọn ọpọlọ ori ati ero inu tabi awọn oniṣegun ọpọlọ ori inu aiye lati yi ọna ironu araiye pada . . . Awa ko le gbẹkẹle agbara ọlọpa larin awọn orilẹ-ede ti ao da silẹ . . . ki o si mu aiye jẹ ibi alafia ati ailewu lati mã gbe.’—Gbigba Iran Enia La—lọna Ijọba na, 1972, ojú ìwé 5.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 225]
“Sórí Oòrùn”
Bí “oòrùn” tó dúró fún ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn ti ń “jó” aráyé ní ọjọ́ Olúwa, ẹgbẹ́ Jòhánù ti lo irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí láti jẹ́ kí aráyé mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀:
“Lónìí Hitler àti Mussolini, àwọn kòdúrógbẹ́jọ́ aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀, ń jin àlàáfíà gbogbo ayé lẹ́sẹ̀, àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ olórí Ìjọ Kátólíìkì sì tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá nínú bí wọ́n ṣe fẹ́ fòpin sí òmìnira.”—Fascism or Freedom, 1939, ojú ìwé 12.
“Látọdúnmọdún, ìlànà táwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ń lò ni, Gbà mí lọ́ba tàbí kí n pa ọ́! Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìlànà tí Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run fi jẹ, yóò lò lórí gbogbo ayé ni, Gba àkóso Ọlọ́run tàbí kó o pa run.”—When All Nations Unite Under God’s Kingdom, 1961, ojú ìwé 23.
“Lati ọdún 1945, o ti lé ni miliọnu mẹẹdọgbọn awọn eniyan ti a ti pa ninu awọn ogun ti o tó 150 ti a ja kaakiri gbogbo agbaye.”—Ilé-Ìṣọ́nà, July 15, 1980, ojú ìwé 6.
‘Àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé . . . kò bìkítà nípa àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù sí ẹlòmíràn. Láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn, àwọn orílẹ̀-èdè kan gbà pé àwọn ò jẹ̀bi rárá táwọn bá ṣe ohunkóhun tí àwọn bá rò pé ó pọn dandan—ìpakúpa, ìṣìkàpànìyàn, fífi ìwà ipá já ọkọ̀ òfuurufú gbà, bọ́ǹbù jíjù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ . . . Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi máa fara da irú ìwà aláìnírònú àti aláìmọ́gbọ́ndání bẹ́ẹ̀?’—Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1985, ojú ìwé 4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 227]
“Sórí Ìtẹ́ Ẹranko Ẹhànnà Náà”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà payá wọ́n sì ti fi irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí polongo ìdálẹ́bi Jèhófà fún un:
‘Àwọn ẹ̀mí burúkú tí wọ́n lágbára ju ẹ̀dá èèyàn lọ ló ń fi tipátipá darí àwọn aláṣẹ àtàwọn tó jẹ́ aṣáájú nídìí ọ̀rọ̀ òṣèlú ayé, tí wọ́n sì ń tì wọ́n gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sínú ogun ńlá Amágẹ́dọ́nì tí yóò pa wọ́n run.’—Lẹhin Armagẹddọn—Aiye Titun ti Ọlọrun, 1955, ojú ìwé 8.
‘“Ẹranko ẹhànnà” náà tó dúró fún ìjọba èèyàn tó lòdì sí ìjọba Ọlọ́run gba agbára, àṣẹ àti ìtẹ́ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Dírágónì náà. Nítorí náà. wọ́n ní láti máa ṣe ohun tó bá ìlànà ẹgbẹ́ wọn mú, ìyẹn ìlànà Dírágónì ọ̀hún.’—Lẹhin Armagẹddọn—Aiye Titun ti Ọlọrun, 1955, ojú ìwé 14.
“Àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí lè rí ara wọn kìkì ní . . . ìhà ọ̀dọ̀ Olórí Elénìní Ọlọ́run, Sátánì Èṣù.”—Ìpinnu tí a tẹ́wọ́ gbà ní Àpéjọ Àgbáyé “Ìṣẹ́gun Àtọ̀runwá” lọ́dún 1973.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 229]
“Omi Rẹ̀ . . . Gbẹ Ráúráú”
Ní báyìí o, ọ̀pọ̀ ibi ni wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹyìn fáwọn ìsìn Bábílónì mọ́, èyí ń fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn” bá kọ lu Bábílónì ńlá hàn.
“Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè fi hàn pé ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin lára àwọn tó ń gbé láwọn ìlú tó ní ìjọba ìbílẹ̀ [nílẹ̀ Thailand] kì í lọ sí tẹ́ńpìlì àwọn onísìn Búdà rárá láti lọ gbọ́ ìwàásù, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni iye àwọn ará ìgbèríko tó ń lọ sí tẹ́ńpìlì túbọ̀ ń dín kù, àní wọn ò ju nǹkan bí ìdajì lọ.”—Bangkok Post, September 7, 1987, ojú ìwé 4.
“Idán kankan kò sí mọ́ nínú ìsìn Tao ní orílẹ̀-èdè [Ṣáínà] tí wọ́n ti dá a sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. . . . Níwọ̀n bí kò ti sí àwọn ọgbọ́n onídán táwọn àlùfáà òde òní àtàwọn tí wọ́n ṣáájú wọn ń lò láti fi wá ọmọlẹ́yìn púpọ̀, wọ́n ti rí i pé kò sáwọn tó máa rọ́pò àwọn, èyí tó túmọ̀ sí pé ìsìn Tao tó jẹ́ ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà yóò kú àkúrun.”—The Atlanta Journal and Constitution, September 12, 1982, ojú ìwé 36-A.
“Japan . . . jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè ayé táwọn míṣọ́nárì láti ilẹ̀ òkèèrè ti pọ̀ gan-an, tí wọ́n sún mọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé igba [5,200], síbẹ̀ . . . ohun tó dín sí ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ibẹ̀ ni wọ́n jẹ́ Kristẹni. . . . Àlùfáà kan tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ Franciscan tó ti ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti àwọn ọdún 1950 . . . gbà gbọ́ pé ‘ìgbà àwọn míṣọ́nárì ti lọ ní Japan.’”—The Wall Street Journal, July 9, 1986, ojú ìwé 1.
Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, “iye tó sún mọ́ ẹgbàá [2,000] lára ẹgbàájọ [16,000] àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà ni wọ́n ti tì pa nítorí pé kò sẹ́ni tó ń lò wọ́n. Iye àwọn tí ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì ti wálẹ̀ gan-an débi pé ti orílẹ̀-èdè yìí ló kéré jù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń sọ pé Kristẹni làwọn. . . . ‘Ní báyìí o, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kì í ṣe orílẹ̀-èdè Kristẹni mọ́,’ ni [Bíṣọ́ọ̀bù Durham] wí.”—The New York Times, May 11, 1987, ojú ìwé A4.
“Lẹ́yìn ìjiyàn tí kì í ṣe kékeré, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin [ilẹ̀ Gíríìsì] fọwọ́ sí òfin náà lónìí, èyí tó fún Ìjọba Elétò Àjùmọ̀ní lágbára láti gba dúkìá púpọ̀ jaburata tó jẹ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì . . . Ìyẹn nìkan kọ́ o, òfin náà sọ pé káwọn tí kì í ṣe àlùfáà máa ṣe àkóso àwọn àjọ àtàwọn ìgbìmọ̀ tó jẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń mójú tó àwọn okòwò ṣọ́ọ̀ṣì tó ṣeyebíye gan-an, irú bí òtẹ́ẹ̀lì, ibi ìfọ́kùúta mábìlì àtàwọn ilé ńlá táwọn ọ́fíìsì wà.”—The New York Times, April 4, 1987, ojú ìwé 3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 222]
Àwokòtò ìbínú Ọlọ́run mẹ́rin àkọ́kọ́ fa àwọn ìyọnu tó jọ ìyọnu tí ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ fà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 226]
Àwokòtò karùn-ún ṣí ìtẹ́ ẹranko ẹhànnà náà payá pé ó jẹ́ agbára ìṣàkóso tí Sátánì ti fi fún ẹranko ẹhànnà náà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 231]
Ìpolongo ẹ̀tàn àwọn ẹ̀mí èṣù ń kó àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé jọ sí ipò kan tí Bíbélì pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì, níbi tí a ó ti da àwọn ìdájọ́ Jèhófà jáde sórí wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 233]
Àwọn tó ń mí “afẹ́fẹ́” Sátánì tó jẹ́ afẹ́fẹ́ burúkú símú gbọ́dọ̀ jìyà nígbà tí Jèhófà bá mú àwọn ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ