Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Láyọ̀ Bí Òbí Mi Bá Jẹ́ Anìkàntọ́mọ?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Láyọ̀ Bí Òbí Mi Bá Jẹ́ Anìkàntọ́mọ?

ORÍ 25

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Láyọ̀ Bí Òbí Mi Bá Jẹ́ Anìkàntọ́mọ?

“Àwọn ọmọ tó jẹ́ pé bàbá àti màmá wọn ló ń tọ́ wọn lè dá yàrá tiwọn ní, káwọn òbí wọn sì máa raṣọ sí wọn lọ́rùn. Àmọ́ yàrá kan lèmi àti mọ́mì mi ń lò; wọn kì í sì í sábàá ra irú aṣọ tó wù mí fún mi. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn ò lówó. Bí mo bá sì tún ro ti gbogbo iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí mo ní láti ṣe láyìíká ilé, ṣe ni mo máa ń dà bí ọmọ ọ̀dọ̀, á wá dà bíi pé wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọmọdé dù mí.”—Shalonda, ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13].

KÒ SÍ iyè méjì pé ilé tí bàbá àti ìyá tó mọwọ́ ara wọn bá wà máa ń jẹ́ ilé aláyọ̀. Bàbá àti ìyá tó wà níṣọ̀kan kì í sábàá dá àwọn ọmọ dá ara wọn, wọ́n máa ń tọ́jú wọn dáadáa, wọ́n sì máa ń jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún wọn. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn.”—Oníwàásù 4:9.

Síbẹ̀, irú ilé tí bàbá àti ìyá bẹ́ẹ̀ wà ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ju ìdajì lọ lára àwọn ọmọ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ń bára wọn nínú ilé òbí anìkàntọ́mọ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

Bí ilé òbí anìkàntọ́mọ sì ti ń pọ̀ sí i tó yìí, ó máa ń ti àwọn ọ̀dọ́ kan lójú pé wọ́n bára wọn nínú irú ilé bẹ́ẹ̀. Ìṣòro àti wàhálà táwọn míì lára wọn ń dojú kọ sì ti wá ń kó ìdààmú bá wọn. Bí òbí rẹ bá jẹ́ anìkàntọ́mọ, àwọn ìṣòro wo ló ń báa yín fínra? Kọ àwọn ìṣòro tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu jù lọ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ṣó o rò pé nǹkan ò ní ṣẹnuure fún ẹ torí pé ò ń pàdánù ìfẹ́ tó yẹ kí ọ̀kan yòókù lára àwọn òbí ẹ máa fi hàn sí ẹ? Rárá o! Ojú tó o bá fi wo ọ̀ràn náà ló jà jù. Òwe 15:15 sọ pé: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” Gẹ́gẹ́ bí òwe yìí ṣe sọ, ìwà èèyàn ló sábà máa ń pinnu bí ọkàn èèyàn ṣe máa rí, kì í ṣe ipò téèyàn wà. Kí wá lohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ‘ọkàn-àyà rẹ á fi máa yá gágá’ láìka ipò yòówù kó o bára ẹ sí?

Má Ṣe Gba Èròkérò Láyè

Lákọ̀ọ́kọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àbùkù táwọn míì bá ń sọ bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùkọ́ kan máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí òbí wọn jẹ́ anìkàntọ́mọ. Àwọn kan sì máa ń rò pé bí ọmọ òbí anìkàntọ́mọ bá ṣe ohun tí kò tọ́, ilé tó ti jáde wá ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bi ara ẹ pé: ‘Ṣáwọn tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí mọ èmi àti bàbá tàbí màmá mi ni? Àbí ohun tí wọ́n gbọ́ táwọn ẹlòmíì ń sọ nípa ìdílé anìkàntọ́mọ ni wọ́n ń rò kiri?’

Gbólóhùn náà, “ọmọdékùnrin aláìníbaba” ò ṣàdédé fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Ìwé Mímọ́. Kò sì sígbà kankan tí Bíbélì lo gbólóhùn náà lọ́nà tó ń tàbùkù síni. Kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo ibi tọ́rọ̀ náà ti fara hàn ni Jèhófà ti sọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn tí òbí anìkàntọ́mọ tọ́ dàgbà. *

Nígbà míì ẹ̀wẹ̀, àwọn míì tí wọn ò ní èrò búburú lọ́kàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ra ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa sá fún lílo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “bàbá,” “ìgbéyàwó,” “ìkọ̀sílẹ̀,” tàbí “ikú,” torí ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè bí ẹ nínú tàbí kí wọ́n kótìjú bá ẹ. Ṣó ò fẹ́ kí wọ́n máa firú ojú yẹn wò ẹ́? Kúkú fọgbọ́n ṣàlàyé fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé ohun tí wọ́n rò yẹn ò rí bẹ́ẹ̀. Tony tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] ò mọ bàbá tó bí i lọ́mọ. Ó sọ pé báwọn èèyàn kan bá ń bá òun sọ̀rọ̀ ńṣe ni wọ́n máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ. Àmọ́, Tony máa ń lo irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn bóun bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ipò tí mo bára mi ò tì mí lójú.”

Má Ṣe Kábàámọ̀

Báwọn òbí ẹ bá kọra wọn sílẹ̀ tàbí tí ọ̀kan lára wọn bá ṣàìsí, ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kó o banú jẹ́, kó o sì ní ẹ̀dùn ọkàn. Àmọ́, kò sígbà tó ò ní gba kámú. Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’” (Oníwàásù 7:10) Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] ni Sarah, àwọn òbí ẹ̀ sì ti kọra wọn sílẹ̀ látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé: “Má ṣe kárí sọ nítorí ipò tó o bára ẹ, má ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kábàámọ̀, tàbí kó o máa rò pé wíwà tó o wà nínú ilé òbí anìkàntọ́mọ ló mú kó o nírú ìṣòro tó o ní, tàbí kó o máa rò pé ọjọ́ gbogbo bí ọdún ni fáwọn ìdílé tí òbí méjèèjì ti wà pa pọ̀.” Ìmọ̀ràn àtàtà lèyí. Ó ṣe tán, ìdílé táwọn òbí ti pé méjì náà ní ìṣòro tiwọn.

O ò ṣe fi ìdílé ẹ wé àwọn awakọ̀ ojú omi? Ohun tó máa ń dáa jù ni pé káwọn awakọ̀ náà pọ̀ tó. A wá lè sọ pé nínú ilé òbí anìkàntọ́mọ, ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ náà kò sí níbẹ̀, torí náà àwọn tó kù ní láti fún ṣòkòtò wọn le. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé irú ìdílé bẹ́ẹ̀ ò lè kẹ́sẹ járí? Rárá o! Báwọn tó kù nínú ìdílé náà bá ti ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ńṣe ni ọkọ̀ ìdílé wọn á máa léfòó tá á sì fi bẹ́ẹ̀ gúnlẹ̀ sí èbúté ayọ̀.

Ṣó Ò Ń Ṣe Ojúṣe Tìẹ?

Kí lo lè ṣe gan-an tí wàá fi rí i dájú pé ò ń ṣe ojúṣe tìẹ láfikún sí tàwọn yòókù nínú ìdílé? Gbé àwọn àbá mẹ́ta wọ̀nyí yẹ̀ wò:

Máa ṣọ́ owó ná. Ìṣòro ńlá lọ̀ràn owó máa ń jẹ́ fáwọn ìdílé anìkàntọ́mọ. Ìrànlọ́wọ́ wo lo lè ṣe? Tony, tá a ti sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Àwọn ọmọléèwé mi máa ń ní káwọn òbí wọn ra bàtà káńfáàsì àti aṣọ ìgbàlódé fáwọn. Bí wọn ò bá rà á fún wọn, wọn ò ní wá síléèwé. Èmi ò ní aṣọ ìgbàlódé, àmọ́ mo máa ń mọ́ tónítóní, mo sì máa ń tọ́jú ìwọ̀nba ohun tí mo ní. Mọ́mì mi ń sa gbogbo ipá wọn, mi ò sì fẹ́ fayé ni wọ́n lára.” Bó o bá sapá díẹ̀ sí i, o lè fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ . . . láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi . . . nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo.”—Fílípì 4:11, 12.

Ọ̀nà míì téèyàn lè gbà máa ṣọ́ owó ná ni pé kó má máa fi nǹkan ṣòfò. (Jòhánù 6:12) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Rodney sọ pé: “Mo máa ń ṣọ́ra gan-an bí mo bá ń ṣiṣẹ́ nínú ilé, kí ohunkóhun má bàa bà jẹ́ tàbí kó sọ nù, níwọ̀n bó ti máa ń náni lówó láti tún wọn ṣe tàbí láti pààrọ̀ wọn. Mo máa ń paná àtàwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tí mi ò bá lò. Ìyẹn ń dín owó tá à ń san fún iná mànàmáná kù.”

Máa lo ìdánúṣe. Ọ̀pọ̀ òbí anìkàntọ́mọ máa ń lọ́ra láti bá ọmọ tó bá ṣẹ̀ wí tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn níṣẹ́ ilé ṣe. Kí nìdí? Àwọn kan máa ń rò pé ó yẹ káwọn fi nǹkan mìíràn rọ́pò òbí kan yòókù tí kò sí níbẹ̀, torí náà wọ́n máa ń fẹ́ máyé rọrùn fáwọn ọmọ. Wọ́n lè ronú pé: ‘Mi ò fẹ́ kí ìyà jẹ àwọn ọmọ mi jàre.’

Bó ò bá kíyè sára, o lè máa ṣe bó ṣe wù ẹ́ torí pé òbí ẹ ò fẹ́ ẹ fúnyà jẹ. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni wàá tún dì kún ẹrù òbí ẹ. Torí náà, ìwọ fúnra ẹ ò ṣe wá àwọn ohun tó o lè bá òbí ẹ ṣe láyìíká ilé? Gbé ohun tí Tony máa ń fẹ́ láti ṣe yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Ọsibítù ni mọ́mì mi ti ń ṣiṣẹ́, ó sì di dandan kí aṣọ wọn wà ní lílọ̀. Torí náà, mo máa ń bá wọn lọ̀ ọ́.” Ṣé iṣẹ́ obìnrin kọ́ laṣọ lílọ̀ ni? Tony fèsì pé: “Ohun táwọn kan máa ń sọ nìyẹn. Àmọ́, mo máa ń fìyẹn ran mọ́mì mi lọ́wọ́.”

Máa fìmọrírì hàn. Yàtọ̀ sí ríran òbí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe, o tún lè ṣe púpọ̀ sí i láti fún òbí ẹ níṣìírí nípa fífi ìmọrírì hàn. Òbí kan tó jẹ́ anìkàntọ́mọ kọ̀wé pé: “Mo sábà máa ń rí i pé nígbà tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí inú bá ń bí mi lẹ́yìn iṣẹ́ tó nira, nígbà tí màá bá fi pa dà délé, ọmọbìnrin mi á ti gbọ́únjẹ á sì ti gbé e sórí tábìlì.” Ó fi kún un pé: “Ọmọkùnrin mi á fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn á sì gbá mi mọ́ra.” Báwo ni gbogbo èyí ṣe máa ń rí lára òbí anìkàntọ́mọ yìí? Ó sọ pé: “Ńṣe lara mi máa ń yá gágá.”

Èwo lára àwọn kókó mẹ́ta yìí ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí jù lọ? Kọ ọ́ sórí ìlà yìí. ․․․․․

Béèyàn bá ní òbí tó jẹ́ anìkàntọ́mọ, ó máa láǹfààní láti máa fàwọn ànímọ́ bí àánú, àìmọtara-ẹni-nìkan àti jíjẹ́ ẹni tó ṣe é gbára lé ṣèwà hù. Láfikún sí ìyẹn, Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Wàá láyọ̀ tó pọ̀ bó o bá ń fi gbogbo ara ran òbí ẹ tó jẹ́ anìkàntọ́mọ lọ́wọ́.

Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà kan wà táá máa wù ẹ́ pé kó o láwọn òbí méjèèjì nínú ilé. Síbẹ̀, o kọ́ ọ̀nà tí wàá gbà mú nǹkan sunwọ̀n sí i. Ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Nia ṣe gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí dádì mi kú, ẹnì kan sọ fún mi pé ‘ọwọ́ ẹ ni àṣeyọrí ìgbésí ayé ẹ wà,’ mi ò sì jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn láé. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn máa ń jẹ́ kí n rántí pé kò pọn dandan kí n máa fìyà jẹra mi nítorí ipò tí mo wà.” Ìwọ náà lè máa ronú lọ́nà yẹn. Rántí pé, kì í ṣe ipò tó o bára ẹ ló yẹ kó máa pinnu bóyá wàá láyọ̀ tàbí wàá banú jẹ́. Ojú tó o bá fi wò ó àtohun tó o bá ṣe nípa ẹ̀ ló ṣe pàtàkì.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 4, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara . . . yín nìkan, ṣùgbọ́n ire . . . ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.Fílípì 2:4.

ÌMỌ̀RÀN

Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé iṣẹ́ tí wọ́n ń fún ẹ ṣe ti pọ̀ jù, fọgbọ́n dábàá pé kí òbí ẹ ṣe àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí:

Ẹ wá ibì kan lẹ àkọsílẹ̀ iṣẹ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan á máa ṣe nínú ilé mọ́.

Bí iṣẹ́ náà bá fì sọ́dọ̀ ẹnì kan jù, ẹ tún un pín láàárín gbogbo ẹni tó bá lè ṣe é nínú ìdílé.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o bá níṣẹ́ tó ò ń bójú tó nínú ilé, wàá tètè gbọ́n ju àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń gbé lọ́dọ̀ bàbá àti ìyá wọn lọ, torí pé lọ́pọ̀ ìgbà, ojúṣe wọn ò ní tó tìẹ.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Màá mú èrò òdì tí mo bá ní kúrò nípa ․․․․․

Báwọn èèyàn bá ń tìtorí mi ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ, màá sọ pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí nìdí táwọn kan fi máa ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn ọmọ òbí anìkàntọ́mọ?

Kí nìdí tí òbí ẹ fi lè máa lọ́ra láti sọ fún ẹ pé kó o báwọn ṣiṣẹ́ ilé?

Báwo lo ṣe lè máa fìmọrírì hàn fún òbí ẹ?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 211]

“Látìgbà táwọn òbí mi ti kọra wọn sílẹ̀, èmi àti mọ́mì mi máa ń bára wa sọ̀rọ̀ gan-an; a sì ti wá mọwọ́ ara wa.”—Melanie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 211]

Bí ọkọ̀ ojú omi táwọn awakọ̀ rẹ̀ ò pé ni ìdílé òbí anìkàntọ́mọ rí. Àfi káwọn tó kù ṣiṣẹ́ kára. Wọ́n sì lè kẹ́sẹ járí bí wọ́n bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀