Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?
ORÍ 21
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Mi?
Wákàtí mélòó ni ì bá wù ẹ́ kó o máa rí lò láfikún sí èyí tó ò ń lò lójúmọ́? ․․․․․
Kí lo máa fi àfikún wákàtí tó ò ń fẹ́ yẹn ṣe?
□ Láti lọ fi jókòó ti àwọn ọ̀rẹ́ ẹ
□ Láti fi sùn
□ Láti fi kàwé
□ Nǹkan míì ․․․․․
ṢE NI àkókò dà bí ẹṣin tó ń sáré gan-an, tó o bá máa rí i lò bó o ṣe fẹ́, o ní láti mọ bí wàá ṣe máa fọgbọ́n darí rẹ̀. Tó o bá ń fọgbọ́n lo àkókò rẹ, ó lè jẹ́ kí wàhálà rẹ dín kù, ó lè jẹ́ kó o túbọ̀ máa ṣe dáadáa nílé ìwé, ó sì lè mú káwọn òbí rẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Àmọ́ ṣá, o lè máa sọ lọ́kàn ara rẹ pé: “Ìyẹn mà dáa o, àmọ́ ó kàn rọrùn láti sọ ni, kò rọrùn láti ṣe!” Lóòótọ́, wàá kọ́kọ́ ní àwọn ìṣòro kan. Ṣùgbọ́n o lè borí wọn. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
Ìṣòro Àkọ́kọ́: Bó O Ṣe Lè Ṣètò Àkókò
Ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́. Èrò pé o tiẹ̀ fẹ́ ṣètò àkókò rẹ lè jẹ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lómìnira láti ṣe ohun tó wù ẹ́! Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí nǹkan bá kàn wá sí ẹ lọ́kàn lo fẹ́ máa ṣe é, o ò fẹ́ ṣe ètò kankan sílẹ̀ táá máa darí ohun tó o bá fẹ́ ṣe.
Ìdí tó fi yẹ kó o ṣètò àkókò rẹ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Àwọn Òwe 21:5) Ọwọ́ Sólómọ́nì máa ń dí gan-an. Ó láya, ó lọ́mọ, ó sì tún jẹ́ ọba. Ó sì ṣeé ṣe kí ọwọ́ rẹ̀ túbọ̀ máa dí sí i bó ṣe ń dàgbà. Bákan náà, ọwọ́ tìẹ náà dí báyìí. Àmọ́, ọwọ́ rẹ á tún máa dí sí i bó o ṣe ń dàgbà. Torí náà, ó sàn kó o tètè ṣètò àkókò ẹ báyìí, dípò kó o sún un síwájú!
ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí mo ṣe ń lo àkókò mi. Ìdí tí mo fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé mo fẹ́ mú nǹkan rọrùn fún ara mi, ó sì dà bíi pé ohun tó jẹ́ kí n lè rí i ṣe ni pé mo ṣètò àkókò mi!”—Joey.
“Bí mo ṣe ń kọ ohun tí mo fẹ́ ṣe sílẹ̀ mú kó rọrùn fún mi láti tẹ̀ lé ètò tí mo ṣe. Bí àwọn nǹkan míì bá wà tí mo ní láti bójú tó, èmi àti mọ́mì mi á kọ ọ́ sílẹ̀, a ó sì jọ ṣètò bá a ṣe máa ran ara wa lọ́wọ́ táá fi di ṣíṣe.”—Mallory.
Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wò ó báyìí ná: Ká sọ pé ẹ fẹ́ gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ sí ìrìn àjò. Olúkúlùkù yín kàn wá ń gbé báàgì tiẹ̀ síbi ìkẹ́rùsí ọkọ̀ náà bó ṣe wù ú. Ó wá dà bíi pé àyè kò ní gba ẹrù yín. Kí lẹ máa wá ṣe? Ṣe lẹ máa tún kó ẹrù náà jáde, tí ẹ ó wá kọ́kọ́ to àwọn tó tóbi sí i kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ti àwọn kéékèèké bọ àyè tó bá ṣẹ́ kù.
Ìwọ náà lè máa lo irú ọgbọ́n yìí láti fi ṣètò àwọn nǹkan rẹ. Bó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lo máa ń kọ́kọ́ dáwọ́ lé, o ò ní lè máa rí àkókò fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì. Kọ́kọ́ máa wáyè fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, ìyàlẹ́nu ló sì máa jẹ́ fún ẹ pé wàá máa rí àkókò tó pọ̀ tó láti fi ṣe àwọn nǹkan tó bá ṣẹ́ kù!—Fílípì 1:10.
Àwọn nǹkan wo ló ṣe pàtàkì jù tó o gbọ́dọ̀ ṣe?
․․․․․
Wá kọ nọ́ńbà sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe yìí láti fi to gbogbo wọn tẹ̀ léra bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí. Bó o bá kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan tó
ṣe pàtàkì, wàá rí i pé àkókò tó pọ̀ á ṣẹ́ kù fún ẹ láti fi ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì.Ohun tó o lè ṣe. Wá ibì kan tí wàá máa kọ ohun tó o bá fẹ́ ṣe sí, kó o sì tò wọ́n síbẹ̀ bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tá a kọ síbí yìí sì lè wúlò fún ẹ.
□ Kàlẹ́ńdà inú fóònù
□ Ìwé kékeré
□ Kàlẹ́ńdà orí kọ̀ǹpútà
□ Kàlẹ́ńdà tó ṣeé gbé sórí tábìlì
Ìṣòro Kejì: Bí Wàá Ṣe Máa Tẹ̀ Lé Ètò Tó O Ṣe
Ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́. Nígbà tó o ti ilé ìwé dé, o rò pé wàá kàn jókòó wo tẹlifíṣọ̀n fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, ṣùgbọ́n kó o tó mọ̀ o ti pẹ́ nídìí rẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé o ti ṣètò pé o fẹ́ kàwé láti fi múra sílẹ̀ fún ìdánwò, tí ẹnì kan wá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù rẹ pé kó o wá wo fíìmù kan. O wá sọ lọ́kàn ara rẹ pé o ò ní lè dá fíìmù yẹn dúró dìgbà míì, pé wàá kàwé yẹn lọ́wọ́ alẹ́ jàre. O tiẹ̀ tún lè máa sọ fún ara rẹ pé, ‘Ó ṣe tán ìgbà tí nǹkan bá ń lé mi léré gan-an ni mo kúkú máa ń ṣe dáadáa jù.’
Ìdí tó fi yẹ kó o tẹ̀ lé ètò tó o ṣe. Tó o bá ń kàwé nígbà tí kò sí nǹkan kan tó ń lé ẹ lére wàá lè túbọ̀ ṣe dáadáa nínú ìdánwò rẹ. Ó ṣe tán, àkókò tó o ní ò kúkú tíì tó ẹ lò tẹ́lẹ̀ fún gbogbo nǹkan tó o ní láti ṣe. Kí wá nìdí tí wàá tún fi kó ara rẹ sí wàhálà, tó ò ní sùn lóru torí pé o fẹ́ sáré kàwé láti múra sílẹ̀ fún ìdánwò? Kí lo wá mọ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ tó o bá fi máa jí láàárọ̀? O tiẹ̀ lè sùn kọjá àkókò, ó lè rẹ̀ ẹ́ gan-an, bóyá ṣe lo tiẹ̀ máa sáré jáde nílé, o sì lè wá pẹ́ délé ìwé.—Òwe 6:10, 11.
Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Mo fẹ́ràn kí n máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí n máa ta gìtá, kí n sì máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Kì í ṣe pé nǹkan wọ̀nyí burú o; àmọ́ nígbà míì, wọn kì í jẹ́ kí n tètè bójú tó àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, á wá di pé kí n máa kánjú ṣe wọ́n bó bá yá.”—Julian.
Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má kàn ṣètò àwọn nǹkan tó di dandan
pé kó o ṣe nìkan, ó yẹ kó o tún ṣètò àwọn nǹkan míì tó kàn máa ń wù ẹ́ láti ṣe pẹ̀lú. Julian sọ pé: “Ó máa ń yá mi lára láti ṣe ohun tó jẹ́ dandan pé kí n ṣe, torí mo mọ̀ pé ètò ti wà pé màá ṣì lè ṣe àwọn nǹkan míì tó wù mí tó bá yá.” Ohun míì tún rèé: Ní ohun pàtó kan tó o fẹ́ ṣe, kó o sì wá pín bó o ṣe fẹ́ ṣe é sí ọ̀nà kéékèèké míì tí wàá lè máa lé bá lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ọkàn rẹ kò fi ní kúrò lórí ohun pàtó tó o fẹ́ ṣe yẹn.Ohun tó o lè ṣe. Kí ni ohun pàtó kan tàbí méjì tó o mọ̀ pé wàá lè ṣe láàárín oṣù mẹ́fà sí ìgbà tá a wà yìí?
․․․․․
Kí ni ohun pàtó kan tó o mọ̀ pé wàá lè ṣe láàárín ọdún méjì sí ìgbà tá a wà yìí, kí ló sì yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí kọ́wọ́ rẹ lè tẹ ohun tó o fẹ́ ṣe yẹn? *
․․․․․
Ìṣòro Kẹta: Bó O Ṣe Lè Wà Ní Mímọ́ Tónítóní àti Létòlétò
Ohun tó lè dí ẹ lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò tíì yé ẹ dáadáa bí wíwà
ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò ṣe kan fífọgbọ́n lo àkókò rẹ. Ó ṣe tán, ohun tó máa ń rọrùn jù ni pé kéèyàn kàn fi gbogbo ilé sílẹ̀ jákujàku. Bí àpẹẹrẹ, béèyàn ò gbálẹ̀ ilé lónìí, ó ṣáà lè gbá a lọ́la, tàbí kó má tiẹ̀ gbá a rárá! Bó ṣe wu èèyàn ló lè ṣe yàrá ẹ̀, ó ṣáà tẹ́ ẹ lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ni. Àbí kí ni ìwọ náà ti rò ó sí?Ìdí tó fi yẹ kó o wà ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò. Bí àwọn nǹkan rẹ bá ń wà ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò, ó máa dín àkókò tí wàá fi máa wá nǹkan kù. O kò sì ní máa dààmú jù.—1 Kọ́ríńtì 14:40.
Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Tí mi ò bá ti ráyè kó àwọn aṣọ mi kúrò nílẹ̀, mo máa ń ṣe wàhálà gan-an tí mo bá ń wá nǹkan, torí á ti há sáàárín àwọn aṣọ mi tí mo kàn fi sílẹ̀ jákujàku!”—Mandy.
“Odindi ọ̀sẹ̀ kan ni mo fi wá pọ́ọ̀sì mi tí mi ò rí i. Mo dààmú gan-an ni. Ìgbà tí mò ń tún yàrá mi ṣe ni mo wá rí i.”—Frank.
Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bó o bá mú ohun kan, rí i pé o tètè ń dá a pa dà síbi tó o ti mú un. Máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, má ṣe dúró dìgbà tí gbogbo yàrá á fi rí jákujàku.
Ohun tó o lè ṣe. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa jẹ́ káwọn nǹkan rẹ
wà ní mímọ́ tónítóní. Tó o bá ń jẹ́ kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, wàá rí i pé nǹkan á túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.Iye àkókò kan náà ni ìwọ, àtàwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ, àtàwọn òbí rẹ jọ ní lójúmọ́, ohun pàtàkì sì ni. Tó o bá fi ṣòfò, wàá kábàámọ̀ rẹ̀. Tó o bá fọgbọ́n lò ó, yóò ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an. Ó kù sọ́wọ́ ẹ láti yan èyí tó o bá fẹ́.
Ṣé orílẹ̀-èdè míì ni àwọn òbí ẹ ti kó wá síbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá yàtọ̀ nílé àti ní ilé ìwé? Kà nípa bó o ṣe lè sọ nǹkan wọ̀nyí di ohun tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 32 Wo Orí 39 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
ÌMỌ̀RÀN
Má ṣe gbìyànjú láti lo gbogbo àbá tá a mẹ́nu kàn ní orí yìí pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, kàn lo ẹyọ kan nínú wọn láàárín oṣù kan sí ìgbà tá a wà yìí. Tí ìyẹn bá ti wá mọ́ ẹ lára dáadáa, kó o tún gbìyànjú òmíràn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tí ohun tó o ṣètò pé o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kan bá ti pọ̀ jù, wàá kó ara rẹ sí ìdààmú. Tó o bá pín wọn sí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti ṣe pàtàkì tó, wàá lè mọ àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe lọ́jọ́ náà àtàwọn tó o lè ṣe lọ́jọ́ míì.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Ohun tí mi ò ní jẹ́ kó gbà mí lákòókò púpọ̀ ni
Màá fi àkókò tó bá ṣẹ́ kù lára ìyẹn ṣe
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Tó o bá mọ bó o ṣe lè máa ṣètò àkókò rẹ báyìí, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa ṣètò àwọn ohun tó bá jẹ́ ojúṣe rẹ lọ́jọ́ iwájú?
● Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára àwọn òbí rẹ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa fọgbọ́n lo àkókò?
● Tó o bá ti ní ètò tó o máa ń tẹ̀ lé, àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ máa tẹ̀ lé ètò náà?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 154]
“Mo gbọ́ tẹ́nì kan ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé béèyàn bá fẹ́ kí n wá síbì kan láago mẹ́rin, ṣe ni kó yáa sọ fún mi pé kí n débẹ̀ láago mẹ́ta. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé mo gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí bí mo ṣe ń lo àkókò mi!”—Ricky
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 155]
Kí Ni Mò Ń Fi gbogbo Àkókò mi Ṣe?
Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, bí àwọn ọmọ ọdún mẹ́jọ sí méjìdínlógún ṣe lo àkókò wọn rèé, wọ́n fi wákàtí:
17
wà lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn
30
wà ní iléèwé
44
wo tẹlifíṣọ̀n, gbá géèmù orí fóònù, ti fídíò tàbí ti kọ̀ǹpútà, gbọ́ orin àti láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ
Ka iye wákàtí tó ò ń lò lọ́sẹ̀ láti fi
wo tẹlifíṣọ̀n ․․․․․
gbá géèmù orí fóònù, ti fídíò tàbí ti kọ̀ǹpútà ․․․․․
lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ․․․․․
gbọ́ orin ․․․․․
Àròpọ̀ ․․․․․
Iye wákàtí tí mo lè rí lò lára rẹ̀ fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù ni ․․․․․
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 153]
Àkókò dà bí ẹṣin tó ń sáré gan-an, o ní láti mọ bí wàá ṣe máa fọgbọ́n darí rẹ̀