Ṣé Mi Ò Ti Sọ Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?
ORÍ 36
Ṣé Mi Ò Ti Sọ Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?
“Mi ò lè ṣe kí n má fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù! Ohun tí mo gbádùn jù lọ nìyẹn. Ẹ lè máa wò ó pé mi ò tiẹ̀ wá ní nǹkan míì tí mò ń rò mọ́ àfi fóònù ṣáá.”—Alan.
NÍGBÀ tí àwọn òbí rẹ wà ní ọ̀dọ́, tẹlifíṣọ̀n àti rédíò ni ohun pàtàkì tó ń gbé ìsọfúnni jáde tí wọ́n mọ̀. Nígbà yẹn, kò sí ohun méjì tí wọ́n ń fi fóònù ṣe ju kí wọ́n fi pe èèyàn lọ, ṣe ni wọ́n sì máa ń so ó mọ́ wáyà ara ògiri. Ó jọ pé ayé àtijọ́ nìyẹn, àbí? Bó ṣe rí lójú ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà táwọn òbí mi wà lọ́dọ̀ọ́, wọn ò mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń gbé ìsọfúnni jáde lóde òní rárá. Ńṣe ni wọ́n tiẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n tún ṣe lè máa lo fóònù alágbèéká wọn báyìí!”
Lóde òní, o lè gba ìpè, kó o gbọ́ orin, kó o wo fídíò, kó o gbá géèmù, kó o fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ, kó o ya fọ́tò, kó o sì lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí ẹ̀rọ kékeré kan tó o kàn lè jù sí àpò aṣọ rẹ. Tó bá jẹ́ pé láti kékeré lo ti ń lo kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè máà rí ohun tó burú nínú pé kó o máa lò ó ní gbogbo ìgbà. Àmọ́ àwọn òbí ẹ lè máa wò ó pé ó ti di bárakú fún ẹ. Tí wọ́n bá sọ ohun tí wọ́n kíyè sí yìí fún ẹ, má ṣe ronú pé àsìkò tiwọn ti kọjá lọ. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí àwọn òbí ẹ fi lè kọminú sí ọ̀nà tí ò ń gbà lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde? Ṣe ìdánrawò tó wà níbí yìí kó o lè mọ̀ bóyá lílo àwọn ohun kan tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti di bárakú fún ẹ.
Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá O Ti Sọ Ọ́ Di Bárakú
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan túmọ̀ ohun tó ti di bárakú sí “àṣàkaṣà kan tí èèyàn ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, tí èèyàn kò sì fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ láìka ti ìpalára tó lè tìdí ẹ̀ yọ sí.” Wo bí a ṣe fọ́ ìtumọ̀ yẹn sí wẹ́wẹ́ níbí yìí. Ka ohun tí àwọn ọ̀dọ́ kan sọ níbẹ̀, kó o sì wò ó bóyá ìwọ náà ti sọ ohun kan tàbí bóyá o ti ṣe ohun kan tó jọ ọ́. Kó o wá kọ ìdáhùn rẹ.
Àṣejù. “Àìmọye wákàtí ni mo máa fi ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà. Kì í jẹ́ kí n ráyè sùn, ọ̀rọ̀ géèmù náà ló sì máa ń pọ̀ jù nínú nǹkan tí mò ń bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe ni mo máa ń dá wà lọ́tọ̀ nínú ilé, tí màá máa ronú nípa géèmù yẹn ṣáá ní gbogbo ìgbà.”—Andrew.
Lójú tìẹ, báwo ló ṣe yẹ kéèyàn pẹ́ tó nídìí àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde? ․․․․․
Báwo ni àwọn òbí ẹ ṣe fẹ́ kó o pẹ́ tó nídìí rẹ̀? ․․․․․
Wákàtí mélòó lò ń lò lójúmọ́ láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, láti wo
tẹlifíṣọ̀n, láti fi àwòrán sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ síbẹ̀, láti fi gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ? ․․․․․Tó o bá wo àwọn ìdáhùn tó o kọ sókè yìí, ǹjẹ́ o lè sọ pé àkókò tí ò ń lò nídìí àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde ti pọ̀ jù?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ ni àbí kò tiẹ̀ wù ẹ́ láti jáwọ́ níbẹ̀? “Àwọn òbí mi kíyè sí i pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, wọ́n sì sọ fún mi pé ó ti pọ̀ jù. Bí mo bá sì fi wé tàwọn ojúgbà mi, èmi ò tíì ṣe nǹkan kan rárá. Òótọ́ ni pé tá a bá fi tèmi wé tí àwọn òbí mi, mo máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù jù wọ́n lọ. Àmọ́ kò tiẹ̀ yẹ ká fi ọ̀rọ̀ tèmi wé tiwọn rárá, ọmọ ogójì [40] ọdún làwọn, èmi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15].”—Alan.
Ṣé àwọn òbí rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti sọ fún ẹ pé o máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti dín bó o ṣe ń lò ó kù ni àbí kò tiẹ̀ wù ẹ́ láti dín in kù rárá?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Àkóbá tó lè ṣe. “Àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀. Ẹ ò rí i pé ìyẹn léwu!”—Julie.
“Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ra fóònù, gbogbo ìgbà ni mo máa ń rẹ́ni pè tàbí fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí. Bí mo sì ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn. Ó ba àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ará ilé jẹ́, ó sì tún ba àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi jẹ́. Ní báyìí mo wá kíyè sí i pé, nígbà tí mo bá jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi tàbí tá a jọ
ń sọ̀rọ̀, wọ́n sábà máa ń dá ọ̀rọ̀ wa dúró, tí wọ́n á sọ pé: ‘Jọ̀ọ́ dúró ná. Mo fẹ́ fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù mi.’ Ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí èmi àti àwọn yẹn jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.”—Shirley.Ǹjẹ́ o ti ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù tàbí kó o kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ò ń wa ọkọ̀ tàbí tó o wà nínú kíláàsì tàbí tó o wà nínú ìpàdé ìjọ rí?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Tó o bá ń bá àwọn ará ilé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, ṣé o máa ń dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu kó o lè fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí kọ̀ǹpútà tàbí kó o lè dáhùn ìpè tàbí kó o ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ṣé lílò tó ò ń lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde kì í jẹ́ kó o ráyè sùn tó, tàbí kì í jẹ́ kó o lè fọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àyípadà kan? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wo àwọn àbá tá a dá yìí.
Bó O Ṣe Lè Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Tó o bá ń lo ohun èlò èyíkéyìí tó ń gbé ìsọfúnni jáde, yálà kọ̀ǹpútà, fóònù alágbèéká tàbí ohun èlò míì, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè mẹ́rin tó wà nísàlẹ̀ yìí. Tó o bá fi àwọn ìmọ̀ràn tá a gbé karí Bíbélì tó wà níbẹ̀ sílò, tó o sì tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà níbẹ̀, o ò ní kó ara rẹ sí wàhálà, o ò sì ní sọ àwọn ohun èlò náà di bárakú.
● Kí ló dá lé lórí? “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
✔ Máa bá àwọn tó wà nínú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ sọ̀rọ̀, kó o sì máa sọ ohun tó ń gbéni ró.—X Má ṣe máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa, má ṣe fi ọ̀rọ̀ oníṣekúṣe tàbí àwòrán tó ń múni nífẹ̀ẹ́ sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́, má sì ṣe wo fídíò tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n èyí tí kò bójú mu.—Kólósè 3:5; 1 Pétérù 4:15.
● Ìgbà wo ni mo máa ń lò ó? “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”—Oníwàásù 3:1.
✔ Máa fi ìwọ̀n sí iye àkókò tó o máa lò lórí pípe àwọn èèyàn tàbí gbígba ìpè àti fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, wíwo ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí gbígbá géèmù orí kọ̀ǹpútà.
X Má ṣe jẹ́ kí lílò tí ò ń lo àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde gba àkókò tó o ti yà sọ́tọ̀ láti lò pẹ̀lú àwọn ará ilé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àkókò tó yẹ kó o fi kẹ́kọ̀ọ́ tàbí èyí tó yẹ kó o fi ṣe àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.—Éfésù 5:15-17; Fílípì 2:4.
● Àwọn wo ni mò ń bá kẹ́gbẹ́? “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—✔ Máa lo àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde lọ́nà tí wàá fi lè sún mọ́ àwọn tí wọ́n máa jẹ́ kó o lè máa ṣe ohun tó tọ́.—Òwe 22:17.
X Má ṣe tan ara rẹ jẹ, kò sí bó ò ṣe ní kọ́ àṣà, èdè àti ìrònú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra yín lórí kọ̀ǹpútà àti lórí fóònù, àwọn èèyàn tó ò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Òwe 13:20.
● Báwo ni mo ṣe ń pẹ́ tó nídìí rẹ̀? “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
✔ Máa kọ iye àkókò tó ò ń lò nídìí àwọn ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde sílẹ̀.
X Má ṣe kọ etí dídi sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bí wọ́n bá sọ fún ẹ pé o ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde, má sì kọ etí dídi sí ìtọ́sọ́nà tí àwọn òbí ẹ bá fún ẹ nípa rẹ̀.—Òwe 26:12.
Nígbà tí Andrew tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè lo ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó dáa, ó ní: “Àwọn ohun èlò wọ̀nyí máa ń múni lórí yá, àmọ́ fún ìgbà díẹ̀ ni. Mo ti mọ bí mi ò ṣe ní jẹ́ kí àwọn ohun èlò wọ̀nyí dí mi lọ́wọ́, tí mi ò fi ní máa ráyè fún àwọn ará ilé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi.”
KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 30 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ
Báwo lo ṣe lè fi àwọn òbí rẹ lọ́kàn balẹ̀ tí wọ́n á fi lè gbà ẹ́ láyè pé kó o lọ gbádùn ara rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 261]
“Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ. Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yí padà kúrò nínú ohun búburú.”—Òwe 3:7.
ÌMỌ̀RÀN
Ohun tó o lè ṣe kó o má bàa sọ fóònù di bárakú ni pé, kó o jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wàá máa yára dáhùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí fóònù tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kì í sì í ṣe gbogbo ìgbà ni wàá lè máa gbé ìpè wọn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tó o bá gbé fọ́tò ara rẹ tàbí àlàyé èyíkéyìí nípa àwọn ohun tó o máa ń ṣe sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lónìí, àwọn agbanisíṣẹ́ àtàwọn míì ṣì lè rí i lò kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Tó bá ṣòro fún mi láti ṣèkáwọ́ ara mi lórí bí mo ṣe ń lo ․․․․․, màá pinnu pé mi ò ní máa lò ju ․․․․․ péré lọ́sẹ̀ láti fi lo ohun èlò yìí.
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tíwọ fúnra rẹ fi lè má mọ̀ pé o ti sọ ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde di bárakú?
● Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó o bá sọ ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde di bárakú?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 262]
“Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi lè bọ́ lọ́wọ́ bí mo ṣe sọ tẹlifíṣọ̀n di bárakú. Mo ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ara mi láti máa dín àkókò tí mò ń lò nídìí rẹ̀ kù. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń sọ nípa ìṣòro mi yìí fún mọ́mì mi. Mo sì tún gba àdúrà gidigidi.”—Kathleen
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 263]
Ṣé ìwọ lò ń darí ohun tó ń gbé ìsọfúnni jáde tó o ní, àbí òun ló ń darí rẹ?