Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Lè Lọ Dá Gbé?
ORÍ 7
Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Lè Lọ Dá Gbé?
“Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn ń fojú ọmọdé wò mí torí èmi ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Ó máa ń dà bíi pé mi ò ní dẹni tó lè tójú bọ́ tí mi ò bá kúrò lọ́dọ̀ wọn.”—Katie.
“Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún [20] ọdún, síbẹ̀ àwọn òbí mi ló máa ń fẹ́ sọ gbogbo ohun tí màá ṣe fún mi, ìyẹn sì ń dùn mí gan-an. Bí màá ṣe lọ dá gbé ni mò ń rò báyìí.”—Fiona.
Ó LÈ ti pẹ́ tó ti ń wù ẹ́ pé kó o wà láyè ara ẹ kó tiẹ̀ tó di pé o dàgbà tó láti kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Nítorí pé, bá a ṣe sọ ní Orí 3 nínú ìwé yìí, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn látilẹ̀ wá fún àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n di àgbà, nígbà tó bá sì yá, kí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ bàbá àti ìyá wọn láti lọ dá ìdílé tiwọn sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:23, 24; Máàkù 10:7, 8) Àmọ́, báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó lè lọ máa dá gbé? Ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta kan wà tó yẹ kó o wá ìdáhùn sí. Àkọ́kọ́ ni . . .
Kí Nìdí Tí Mo Fi Fẹ́ Lọ Dá Gbé?
Wo àwọn ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí. Kọ nọ́ńbà sẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tó jẹ́ ìdí tó fi ń wù ẹ́ pé kó o lọ máa dá gbé, kó o bẹ̀rẹ̀ látorí ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ.
․․․․․ Mo fẹ́ sá fún wàhálà inú ilé wa
․․․․․ Mo fẹ́ lómìnira sí i
․․․․․ Mo fẹ́ túbọ̀ níyì lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi
․․․․․ Mo fẹ́ lọ máa gbé pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi tó ń wá ẹni tó máa bá a gbé
․․․․․ Mo fẹ́ yọ̀ǹda ara mi láti lọ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run
․․․․․ Kí n lè kọ́ bí màá ṣe máa gbọ́ bùkátà ara mi
․․․․․ Mo fẹ́ dín ìnáwó àwọn òbí mi kù
․․․․․ ǹkan míì ․․․․․
Kì í kúkú ṣe pé àwọn ohun tá a sọ yìí burú o. Àmọ́, ìbéèrè pàtàkì tó yẹ kó o ronú lé ni pé, Kí nìdí tó o fi fẹ́ lọ máa dá gbé? Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ torí pé àwọn òbí rẹ kì í gbà ẹ́ láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan lo ṣe fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ibi tó o fojú sí ọ̀nà lè má gbabẹ̀ o!
Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Danielle, tó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ fúngbà díẹ̀ nígbà tó wà ní ọmọ ogún [20] ọdún, kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ látinú ohun tí ojú rẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Kò sí béèyàn ṣe lè wà táá lè máa ṣe gbogbo ohun tó bá wù ú. Tó o bá ti ń dá gbé, iṣẹ́ tó ò ń ṣe tàbí owó tí kò pọ̀ tó kò ní jẹ́ kó o lè ṣe gbogbo ohun tó bá wù ẹ́.” Carmen, tó lọ gbé ilẹ̀ òkèèrè fún oṣù mẹ́fà sọ pé: “Mo gbádùn ibẹ̀ gan-an, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń dà bíi pé ọwọ́ mi ti dí jù. Ó máa ń di dandan pé kí n ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, irú bíi ṣíṣe ìmọ́tótó ilé, títún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe, ríro oko àyíká ilé, fífọ aṣọ, fífọ ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Má ṣe jẹ́ káwọn ẹlòmíì tì ẹ́ ṣe ìpinnu láìronú jinlẹ̀. (Òwe 29:20) Bó o bá tiẹ̀ ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó o fi fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, ohun míì wà tó tún ṣe pàtàkì gan-an. O gbọ́dọ̀ mọ bó o ṣe máa bójú tó ara rẹ. Èyí ló máa gbé wa dé orí ìbéèrè kejì, ìyẹn . . .
Ǹjẹ́ Mo Ti Lè Dá Gbé Lóòótọ́?
Tó o bá fẹ́ lọ máa dá gbé, ṣe ló dà bí ìgbà tó o fẹ́ rìnrìn àjò ọjọ́ mélòó kan nínú aginjù. Ṣé wàá fẹ́ rin irú ìrìn yìí láìmọ bó o ṣe máa pàgọ́, bó o ṣe máa dáná, bó o ṣe máa se oúnjẹ àti bó o ṣe máa mọ̀nà pa dà sílé? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ rin irú ìrìn bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn láìfi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àbójútó ilé.
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé, “afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Kó o lè mọ̀ bóyá o ti lè lọ dá gbé lóòótọ́, ronú lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ mẹ́nu bà yìí. Fi àmì ✔ sí ẹ̀gbẹ́ èyí tó o lè ṣe, kó o sì fi àmì X sí ẹ̀gbẹ́ èyí tí o kò tíì mọ̀ ọ́n ṣe nínú wọn.
□ Béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná: Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Serena, sọ pé: “Mi ò tíì fi owó ara mi ra ohunkóhun rí, ṣe ni wọ́n máa ń ra gbogbo ẹ̀ fún mi. Ẹ̀rù ń bà mí láti lọ máa dá gbé, torí mi ò mọ bí màá ṣe máa ṣètò owó níná.” Báwo lo ṣe lè mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́wó ná?
Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” (Òwe 1:5) O ò ṣe béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ, iye tó máa ná ẹnì kan lóṣù láti san owó ilé, láti ra oúnjẹ, láti bójú tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí iye téèyàn máa fi wọ ọkọ̀? Kó o wá ní káwọn òbí rẹ kọ́ ẹ bó o ṣe lè ṣètò owó nǹkan wọ̀nyí àti bó o ṣe máa san án. *
□ Àwọn iṣẹ́ ilé: Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé ohun tó ń ba òun lẹ́rù jù nípa lílọ dá gbé ni bí òun á ṣe máa fọ àwọn aṣọ òun. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá o ti lè máa bójú tó ara rẹ? Àbá tí Aron, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún dá ni pé: “Gbìyànjú láti fi odindi ọ̀sẹ̀ kan jálẹ̀ ṣe bíi pé o ti ń dá gbé. Oúnjẹ tó o lọ fi owó ara rẹ rà, tó o sì sè fúnra rẹ ni kó o jẹ. Máa wọ àwọn aṣọ tó o fọ̀, tó o sì lọ̀ fúnra rẹ. Máa tún ilé ṣe fúnra rẹ. Máa lọ sáwọn ibi tó o bá fẹ́ lọ fúnra rẹ láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni mú ẹ lọ tàbí pé wọ́n fún ẹ lówó ọkọ̀.” Tó o bá tẹ̀ lé àbá yìí, àǹfààní méjì lo máa rí níbẹ̀: (1) Wàá lè mọ nǹkan wọ̀nyẹn ṣe, (2) wàá sì túbọ̀ mọyì iṣẹ́ táwọn obí rẹ ń ṣe.
□ Béèyàn ṣe ń wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì: Ṣé ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn òbí rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ máa ń wọ̀? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa rò pé nǹkan á túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ kan bá jọ ń gbé. Àmọ́, wo ohun tí ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Eve sọ, ó ní: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì kan wọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀, ìwà wọn kò bára mu rárá, ni wọ́n bá tú ká. Ọ̀kan jẹ́ afínjú, èkejì sì ya ọ̀bùn. Ọ̀kan fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, èkejì kò fi bẹ́ẹ̀ ka ìjọsìn Ọlọ́run sí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, wọ́n rí i pé àwọn ò lè jọ gbé!”
Kí lo wá lè ṣe? Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Erin sọ pé: “O lè kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa béèyàn ṣe ń wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì nígbà tó o ṣì wà nílé. Wàá kọ́ bó o ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro àti bó o ṣe lè fara mọ́ àwọn nǹkan kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn. Mo ti kíyè sí pé àwọn tó máa ń kúrò nílé nítorí awuyewuye tó ń wáyé láàárín àwọn àtàwọn òbí wọn kì í mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú èdè àìyedè, ńṣe ni wọ́n máa ń sá tó bá di pé kí wọ́n yanjú rẹ̀.”
□ Àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run: Ìdí táwọn ọ̀dọ́ kan fi ń lọ dá gbé ni pé, wọ́n fẹ́ sá fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn táwọn òbí wọn ń ṣe. Ohun tó wà lọ́kàn àwọn míì nígbà tí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ òbí wọn ni pé àwọn á máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, àwọn á sì máa jọ́sìn Ọlọ́run dáadáa, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n dẹni tí kò ṣe dáadáa mọ́. Kí lo lè ṣe tí ‘ọkọ̀ ìgbàgbọ́ rẹ kò fi ní rì’? *—1 Tímótì 1:19.
Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí òye àwọn ohun tá a gbà gbọ́ yé àwa fúnra wa dáadáa. (Róòmù 12:1, 2) Torí náà, ṣètò bí wàá ṣe máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bí wàá ṣe máa jọ́sìn Ọlọ́run déédéé, kó o sì máa tẹ̀ lé ètò tó o bá ṣe. O ò ṣe kọ ètò tó o ṣe yìí sórí kàlẹ́ńdà, kó o sì gbìyànjú láti tẹ̀ lé e fún oṣù kan láìjẹ́ pé àwọn òbí rẹ ń rán ẹ létí?
Ìbéèrè kẹta tó wá yẹ kó o bi ara rẹ ni pé . . .
Kí Ni Mo Fẹ́ Lọ Ṣe?
Ṣé torí kó o lè sá fún wàhálà lo ṣe fẹ́ kúrò nílé? Àbí torí pé o kò fẹ́ kí àwọn òbí rẹ máa darí rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ohun tó o
fẹ́ sá fún nìkan lò ń rò, o kò ronú nípa ibi tó ò ń lọ. Ńṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tó ò ń wa mọ́tò, àmọ́ tó jẹ́ pé dígí tí awakọ̀ fi ń wo ẹ̀yìn lo tẹjú mọ́. O ti jẹ́ kí àwọn ohun tó o fẹ́ fi sílẹ̀ sẹ́yìn gbà ẹ́ lọ́kàn débi pé o ò ní lè rí àwọn nǹkan tó wà ní iwájú rẹ. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa? Má kàn máa ronú ṣáá nípa bó o ṣe máa kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, ó yẹ kó o ní ohun pàtàkì kan tó o fọkàn sí pé o fẹ́ lọ ṣe.Àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn nítorí pé wọ́n fẹ́ lọ wàásù ní apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Àwọn míì kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn láti lọ ṣèrànwọ́ láwọn ibi tí wọ́n ti ń kọ́ ibi ìjọsìn tàbí kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ronú pé ó máa dáa káwọn dá gbé fúngbà díẹ̀ káwọn tó ṣègbéyàwó. *
Fara balẹ̀ ronú nípa ohun yòówù tó o bá ní lọ́kàn pé o fẹ́ lọ ṣe. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Fetí sí ìmọ̀ràn àwọn òbí rẹ. (Òwe 23:22) Gbàdúrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Tó o bá wá fẹ́ pinnu ohun tó o máa ṣe, kó o fi àwọn ìlànà Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí sọ́kàn.
Má kàn ṣáà máa bi ara rẹ pé, Ṣé mo ti tó ẹni tó lè lọ dá gbé? Ṣe ló yẹ kó o bi ara rẹ pé, Ǹjẹ́ mo ti ṣe tán láti máa dá gbọ́ bùkátà ara mi? Tó o bá ti lè dá gbọ́ bùkátà ara rẹ lóòótọ́, a jẹ́ pé o ti ń tó ẹni tó lè lọ dá gbé nìyẹn.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 23 Wo Orí 19 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ̀ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
^ ìpínrọ̀ 27 Wo Orí 34 àti 35 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
^ ìpínrọ̀ 32 Ní àwọn ìlú kan, àṣà wọn ni pé kí ọmọ wọn, pàápàá jù lọ ọmọbìnrin, máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí títí dìgbà tó máa ṣègbéyàwó. Bíbélì kò fún wa ní ìtọ́ni pàtó lórí ọ̀rọ̀ yìí.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.”—Mátíù 19:5.
ÌMỌ̀RÀN
Fún ìgbà díẹ̀ kan, máa fún àwọn òbí rẹ ní àròpọ̀ iye tí wọ́n ń ná lórí rẹ fún oúnjẹ, ilé àtàwọn ìnáwó míì. Tí o kò bá lè san owó yìí tàbí kò wù ẹ́ láti san án nígbà tó o ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, a jẹ́ pé o kò tíì tó ẹni tó lè máa dá gbé nìyẹn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ohun tó mú kó o kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ lè nípa lórí bó o ṣe máa láyọ̀ tó lẹ́yìn tó o bá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Ohun tí mo fẹ́ kí ọwọ́ mi tẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá kúrò nílé ni ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Bí nǹkan kò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ rọrùn nínú ìdílé yín, àǹfààní wo ló wà nínú kó o ṣì máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ fún ìgbà díẹ̀?
● Kí lo lè máa ṣe nígbà tó o ṣì wà nílé, tó máa ṣe ìdílé yín láǹfààní tó sì máa jẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà ìdílé tìẹ lọ́jọ́ iwájú?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 52]
“Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn fẹ́ wà láyè ara rẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé torí kó o lè sá fún àwọn òfin táwọn òbí ẹ ń fún ẹ lo ṣe fẹ́ kúrò nílé, a jẹ́ pé o ò tíì tó ẹni tó lè kúrò nílé nìyẹn.”—Aron
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 50, 51]
Tó o bá fẹ́ lọ máa dá gbé, bí ìgbà tó o fẹ́ rìnrìn àjò ọjọ́ mélòó kan nínú aginjù ni; ó yẹ kó o mọ bó o ṣe máa bójú tó ara rẹ lọ́hùn-ún kó o tó gbéra nílé