Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!
Orí Kejìdínlọ́gbọ̀n
Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!
1. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi máa ń fúnni nírètí pé èèyàn yóò lọ gbé nínú Párádísè?
“NÍNÚ ohun tí ọkàn ọmọ ènìyàn máa ń fà sí lemọ́lemọ́ jù lọ láyé yìí, dídé Párádísè jẹ́ ọ̀kan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun gan-an ló ń gbani lọ́kàn pẹ́ títí jù lọ. Gbogbo ẹ̀ka ìgbòkègbodò inú ẹ̀sìn ni ọ̀ràn fífẹ́ láti dé Párádísè ti fara hàn lọ́nà kan ṣá.” Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion wí nìyẹn. Bó sì ṣe yẹ kí ọkàn ibẹ̀ máa fani nìyẹn o, nítorí Bíbélì sọ fún wa pé inú Párádísè, ìyẹn ọgbà ẹlẹ́wà kan tí kò ti sí àìsàn àti ikú rárá, ni ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8-15) Abájọ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn inú ayé yìí fi máa ń fúnni nírètí pé inú irú párádísè tibí tàbí tọ̀hún lèèyàn yóò lọ gbé lọ́jọ́ iwájú.
2. Ibo la ti lè rí ìrètí tòótọ́ nípa Párádísè ọjọ́ iwájú?
2 Ọ̀pọ̀ ibi nínú Bíbélì la ti lè kà nípa ìrètí tòótọ́ nípa Párádísè ọjọ́ iwájú. (Aísáyà 51:3) Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó wà ní orí karùndínlógójì, ṣàpèjúwe bí àwọn ilẹ̀ aginjù yóò ṣe yí padà di ibi tó rí bí ọgbà ìtura tó lẹ́wà àti àwọn oko eléso. Ó ṣàlàyé pé afọ́jú á ríran, odi á sọ̀rọ̀, adití á sì gbọ́ràn. Nínú Párádísè tó ṣèlérí yìí, kò ní sí ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìmí ẹ̀dùn mọ́, tó túmọ̀ sí pé ikú pàápàá ò ní sí mọ́. Áà, ìlérí yìí mà dára o! Kí ló yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí? Ǹjẹ́ wọ́n mú ká ní ìrètí kankan lóde òní bí? Àgbéyẹ̀wò orí Aísáyà yìí yóò jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí.
Ilẹ̀ Ahoro Ń Yọ Ayọ̀
3. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àyípadà wo ló máa bá ilẹ̀ yẹn?
3 Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí tí Aísáyà sọ nípa Párádísè táa Aísáyà 35:1, 2.
mú padà bọ̀ sípò, lọ báyìí pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. Láìkùnà, yóò yọ ìtànná, ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Ògo Lẹ́bánónì pàápàá ni a ó fi fún un, ọlá ńlá Kámẹ́lì àti ti Ṣárónì. Àwọn kan yóò wà tí yóò rí ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run wa.”—4. Ìgbà wo ni ìlú ìbílẹ̀ àwọn Júù dà bí aginjù, báwo ló sì ṣe dà bẹ́ẹ̀?
4 Nǹkan bí ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Aísáyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ní nǹkan bí ọdún márùnlélọ́gọ́fà lẹ́yìn náà, àwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn ará Júdà sì dèrò ìgbèkùn. Ìlú ìbílẹ̀ wọn wá di ahoro tó dá páropáro. (2 Àwọn Ọba 25:8-11, 21-26) Bí ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pé bí wọ́n bá di aláìṣòótọ́ wọn yóò dèrò ìgbèkùn ṣe ṣẹ nìyẹn o. (Diutarónómì 28:15, 36, 37; 1 Àwọn Ọba 9:6-8) Nígbà tí àwọn ará Hébérù dèrò ìgbèkùn ní ilẹ̀ òkèèrè, àwọn oko àti ọgbà eléso wọn tí wọ́n ń bomi rin dáadáa kò rí àbójútó fún àádọ́rin ọdún, ó wá dà bí aginjù.—Aísáyà 64:10; Jeremáyà 4:23-27; 9:10-12.
5. (a) Báwo ni ilẹ̀ náà ṣe padà bọ̀ sípò tó wá dà bíi Párádísè? (b) Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà “rí ògo Jèhófà”?
5 Àmọ́ o, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti sọ ọ́ ṣáájú pé ilẹ̀ yẹn ò ní wà láhoro títí ayé. Yóò ṣì padà di Párádísè ní ti gidi. Yóò gba “ògo Lẹ́bánónì” àti “ọlá ńlá Kámẹ́lì àti ti Ṣárónì.” * Lọ́nà wo? Bí àwọn Júù ṣe padà dé láti ìgbèkùn, àyè ṣí sílẹ̀ fún wọn láti tún bẹ̀rẹ̀ sí dá oko wọn, kí wọ́n sì máa bomi rin ín, ilẹ̀ wọn sì wá padà di ibi eléso wọ̀ǹtìwọnti bíi ti tẹ́lẹ̀ rí. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà nìyẹn sì fi wáyé. Fífẹ́ tó fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìtìlẹyìn àti ìbùkún rẹ̀, làwọn Júù fi lè wà nínú irú ipò tó dà bíi Párádísè bẹ́ẹ̀. Ó wá ṣeé ṣe fáwọn èèyàn yẹn láti rí “ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run” wọn nígbà tí wọ́n gbà pé Jèhófà lọ́wọ́ sí àyípadà tó bá ilẹ̀ àwọn.
6. Ọ̀nà pàtàkì wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà gbà ṣẹ?
6 Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ lọ́nà kan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ìwọ̀nyí lọ nínú ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó padà bọ̀ sípò. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ibi gbígbẹ tó dà bí aṣálẹ̀ ni Ísírẹ́lì jẹ́ nípa tẹ̀mí. Lásìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn ní Bábílónì, ó ṣòro gidigidi láti ṣe ìsìn mímọ́ gaara. Kò sí tẹ́ńpìlì, kò sí pẹpẹ, kò sì sí ìṣètò ẹgbẹ́ àlùfáà. Ẹbọ ojoojúmọ́ dáwọ́ dúró. Wàyí o, Aísáyà wá ń sọ tẹ́lẹ̀ pé nǹkan máa yí padà. Lábẹ́ ìdarí àwọn èèyàn bíi Serubábélì, Ẹ́sírà àti Nehemáyà, àwọn aṣojú látinú ẹ̀yà méjèèjìlá Ísírẹ́lì padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́, wọ́n sì ń sin Jèhófà ní fàlàlà. (Ẹ́sírà 2:1, 2) Párádísè nípa tẹ̀mí ló dé yìí o!
Kí Iná Ẹ̀mí Máa Jó
7, 8. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn mikàn, báwo sì ni ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe fún wọn níṣìírí?
7 Ọ̀rọ̀ ayọ̀ ló kún inú Aísáyà orí karùndínlógójì. Ọjọ́ ọ̀la alárinrin ni wòlíì yìí ń kéde fún orílẹ̀-èdè tó ronú pìwà dà yẹn. Àní ọ̀rọ̀ tó ń sọ dá a lójú gan-an ni, pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa fún wọn. Nígbà tí ìmúbọ̀sípò àwọn Júù tó wà nígbèkùn sì wá kù fẹ́ẹ́fẹ́ ní ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn náà, ó ń béèrè pé kí wọ́n ní irú ìdánilójú kan náà, pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa. Jèhófà wá gbẹnu Aísáyà gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun, ẹ sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí. Ẹ sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má fòyà. Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín yóò wá tòun ti ẹ̀san, Ọlọ́run yóò wá, àní tòun ti ìsanpadà. Òun fúnra rẹ̀ yóò wá, yóò sì gbà yín là.’”—Aísáyà 35:3, 4.
8 Nígbà tí ìgbèkùn wọn ọlọ́jọ́ gbọọrọ dópin, àkókò wá tó 2 Kíróníkà 36:22, 23) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé àwọn Hébérù ló ní láti gbára dì láti rin ìrìn àjò eléwu yẹn láti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n bá débẹ̀, wọ́n ní láti kọ́ àwọn ibùgbé tí ó tó, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ bàǹtàbanta ti títún tẹ́ńpìlì àti ìlú yẹn kọ́. Gbogbo èyí sì lè ka òmíràn nínú àwọn Júù tó wà ní Bábílónì láyà. Àmọ́, àkókò ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìfòyà kọ́ nìyẹn. Àwọn Júù ní láti ki ara wọn láyà, kí wọ́n sì gbọ́kàn lé Jèhófà. Ó sì mú un dá wọn lójú pé òun yóò gbà wọ́n là.
fún iṣẹ́ pẹrẹu. Kírúsì Ọba Páṣíà, tí Jèhófà lò láti gbẹ̀san lára Bábílónì, kéde pé kí wọ́n mú ìjọsìn Jèhófà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù. (9. Ìlérí àgbàyanu wo ni Jèhófà ṣe fáwọn Júù tó ń padà bọ̀ wálé?
9 Ṣe ni ìdùnnú yóò ṣubú layọ̀ fáwọn tó rí ìdáǹdè gbà kúrò nígbèkùn ní Bábílónì, torí pé ohun àgbàyanu ń bẹ níwájú Aísáyà 35:5, 6a.
fún wọn bí wọ́n bá padà dé Jerúsálẹ́mù. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—10, 11. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé ìtumọ̀ tẹ̀mí ni ọ̀rọ̀ Aísáyà yóò ní fún àwọn Júù tó padà wálé, kí ni wọ́n sì túmọ̀ sí?
10 Dájúdájú, ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ ni Jèhófà ní lọ́kàn. Ìpẹ̀yìndà wọn ìṣáájú ló jẹ́ kí Jèhófà rán wọn nígbèkùn àádọ́rin ọdún láti fi jẹ wọ́n níyà. Síbẹ̀ náà, nígbà tí Jèhófà jẹ wọ́n níyà, kò sọ wọ́n di afọ́jú, kò sọ wọ́n di adití, kò sọ wọ́n di arọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ wọ́n di odi. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn wíwo àbùkù ara-ìyára sàn nínú mímú tó fẹ́ mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bọ̀ sípò. Ohun tí wọ́n pàdánù ni Jèhófà dá padà fún wọn, ìyẹn ni, ìlera wọn nípa tẹ̀mí.
11 Àwọn Júù tó ronú pìwà dà gba ìwòsàn ní ti pé òye wọn nípa tẹ̀mí sọjí, ìyẹn agbára ìríran wọn nípa tẹ̀mí àti gbígbọ́ tí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, kí wọ́n ṣègbọràn, kí wọ́n sì máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n wá mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn fà mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. Bí wọ́n sì ṣe ń hùwà rere, ńṣe ni wọ́n ń fi ayọ̀ “ké jáde” láti bùyìn fún Ọlọ́run wọn. Ẹni tó ti “yarọ” nígbà kan rí wá di onítara àti alákitiyan lẹ́nu ìjọsìn Jèhófà. Lọ́nà àpèjúwe, yóò “gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.”
Jèhófà Tu Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lára
12. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe fi omi jíǹkí ilẹ̀ náà tó?
12 Kò sẹ́ni tó lè máa ronú pé párádísè kan lè wà kó má sì ní omi. Omi púpọ̀ wà nínú Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14) Bákan náà, ilẹ̀ tí wọ́n fún Ísírẹ́lì jẹ́ “ilẹ̀ tí ó ní àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní omi, tí àwọn ìsun àti àwọn ibú omi [ti] ń jáde wá.” (Diutarónómì 8:7) Nítorí náà, ó bá a mu pé Aísáyà ṣèlérí atunilára yìí, pé: “Omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi. Ibi gbígbé àwọn akátá, ibi ìsinmi wọn, ni koríko tútù yóò wà pẹ̀lú esùsú àti òrépèté.” (Aísáyà 35:6b, 7) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò bá tún bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú ilẹ̀ náà, ewéko tútù yọ̀yọ̀, tó ṣe gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́, ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ ahoro tí àwọn akátá tí ń jẹ̀ kiri nígbà kan rí. Ilẹ̀ gbígbẹ táútáú tí eruku bò yóò yí padà di “ibi irà” tí òrépèté àti àwọn esùsú ẹ̀bádò yòókù ti lè hù.—Jóòbù 8:11.
13. Ọ̀pọ̀ yanturu omi tẹ̀mí wo ni yóò wà fún orílẹ̀-èdè tó padà bọ̀ sípò yẹn?
13 Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni omi tẹ̀mí, ìyẹn òtítọ́, tí àwọn Júù tí wọ́n padà wálé yóò rí gbà lọ́pọ̀ yanturu. Jèhófà yóò fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pèsè ìmọ̀, ìṣírí, àti ìtùnú. Ẹ̀wẹ̀, àwọn àgbà ọkùnrin àtàwọn ọmọ aládé olóòótọ́ yóò dà “bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi.” (Aísáyà 32:1, 2) Ìgbésí ayé àwọn bíi Ẹ́sírà, Hágáì, Jéṣúà, Nehemáyà, Sekaráyà àti Serubábélì tó gbé ìsìn mímọ́ gaara lárugẹ, yóò jẹ́ ẹ̀rí pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ.—Ẹ́sírà 5:1, 2; 7:6, 10; Nehemáyà 12:47.
“Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”
14. Ṣàpèjúwe bí ìrìn àjò láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù ṣe rí.
14 Ṣùgbọ́n, kí ọwọ́ àwọn Júù tí ń bẹ nígbèkùn tó lè tẹ irú ipò inú Párádísè nípa ti ara àti tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn réré, tó léwu, láti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n bá fẹ́ gba ọ̀nà tó lọ tààrà, wọn yóò ní láti gba inú ilẹ̀ págunpàgun tó gbẹ táútáú tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà, kọjá. Bí wọ́n bá sì fẹ́ gba ọ̀nà mìíràn tó tún fi díẹ̀ rọrùn ju ọ̀nà yẹn lọ, ìrìn ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà ni wọn yóò rìn. Ọ̀nà tó wù kí wọ́n gbà nínú méjèèjì, yóò gbà wọ́n ní ìrìn ọ̀pọ̀ oṣù, nínú òtútù, nínú ooru, nínú oòrùn, bẹ́ẹ̀, wọ́n sì lè pàdé àwọn ẹhànnà ẹranko àti ẹhànnà èèyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tó gba asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà gbọ́ kò ṣàníyàn jù. Èé ṣe?
15, 16. (a) Irú ààbò wo ni Jèhófà fi bo àwọn Júù olóòótọ́ nígbà tí wọ́n ń padà lọ sílé? (b) Ọ̀nà mìíràn wo ni Jèhófà fi pèsè òpópónà aláìléwu fún àwọn Júù?
15 Jèhófà gbẹnu Aísáyà ṣèlérí pé: “Dájúdájú, òpópó kan yóò sì wá wà níbẹ̀, àní ọ̀nà kan; Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ sì ni a ó máa pè é. Aláìmọ́ kì yóò gbà á kọjá. Yóò sì wà fún ẹni tí ń rìn lójú ọ̀nà, òmùgọ̀ kankan kì yóò sì rìn káàkiri lórí rẹ̀. Kìnnìún kankan kì yóò sí níbẹ̀, irú apẹranjẹ ẹranko ẹhànnà kankan kì yóò sì wá sórí rẹ̀. Ìkankan kì yóò sí níbẹ̀; àwọn tí a tún rà sì ni yóò máa rìn níbẹ̀.” (Aísáyà 35:8, 9) Jèhófà ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ padà! Àwọn ni èèyàn rẹ̀ tó “tún rà,” ó sì mú un dá wọn lójú pé òun óò mú wọn délé gbẹẹrẹgbẹ láìséwu. Ṣé ọ̀nà gíga kankan wà láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù ni, tí wọ́n fi òkúta tẹ́, tí wọ́n sì sọgbà yí ká? Rárá o, ṣùgbọ́n, ààbò Jèhófà lórí àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ìrìn àjò wọn dájú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tó fi dà bíi pé irú òpópónà yẹn ni wọ́n gbà.—Fi wé Sáàmù 91:1-16.
16 Ààbò kúrò lọ́wọ́ ewu tẹ̀mí tún wà fáwọn Júù pẹ̀lú. “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” ni ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ yẹn. Àwọn tó bá fojú tín-ínrín àwọn ohun ọlọ́wọ̀ tàbí tó bá jẹ́ aláìmọ́ nípa tẹ̀mí kò tóótun láti gba ibẹ̀. Wọn kò fẹ́ irú wọn ní ilẹ̀ tó padà bọ̀ sípò yẹn. Ẹ̀mí tó tọ́ làwọn táa gbà láyè ní. Kì í ṣe torí ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tàbí ìfẹ́ láti wá ire tara ẹni ni wọ́n ṣe ń padà lọ sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Àwọn Júù tí ohun tẹ̀mí jẹ lọ́kàn mọ̀ pé ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń padà lọ ni láti lọ fìdí ìsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà múlẹ̀ padà ní ilẹ̀ yẹn.—Àwọn Èèyàn Jèhófà Ń Yọ̀
17. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti ṣe tu àwọn Júù olóòótọ́ nínú lásìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn ọlọ́jọ́ gbọọrọ?
17 Gbólóhùn ayọ̀ ló kásẹ̀ orí karùndínlógójì àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó ní: “Àní àwọn tí Jèhófà tún rà padà yóò sì padà dé, wọn yóò sì fi igbe ìdùnnú wá sí Síónì dájúdájú; ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin yóò sì wà ní orí wọn. Ọwọ́ wọn yóò sì tẹ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, ẹ̀dùn-ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.” (Aísáyà 35:10) Ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù, òǹdè, tó ti ń fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí tu ara wọn nínú, tí wọ́n sì fi ń fún ara wọn nírètí lásìkò ìgbèkùn wọn, ti máa ronú nípa bí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ. Bóyá wọ́n tiẹ̀ lè máà tíì lóye ọ̀pọ̀ ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Síbẹ̀ náà, ó hàn gbangba gbàǹgbà pé wọn yóò “padà dé, wọn yóò sì fi igbe ìdùnnú wá sí Síónì dájúdájú.”
18. Ọ̀nà wo ni ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ní ilẹ̀ wọn tó padà bọ̀ sípò gbà dípò ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn wọn ní Bábílónì?
18 Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] ọkùnrin (àti ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] ẹrú) pa pọ̀ mọ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọ kéékèèké, gbéra ìrìn àjò oṣù mẹ́rin tí wọ́n rìn padà lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Ẹ́sírà 2:64, 65) Oṣù mélòó kan péré lẹ́yìn náà ni wọ́n kọ́ pẹpẹ Jèhófà, wọ́n fi ìyẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì kọ́ lódindi. Nípa bẹ́ẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà ti sọ ní igba ọdún ṣáájú ìgbà yẹn wá ṣẹ. Ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ní ilẹ̀ wọn tó padà bọ̀ sípò wá dípò ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn tó bá orílẹ̀-èdè yẹn nígbà tí wọ́n wà ní Bábílónì. Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Párádísè, ìyẹn nípa ti ara àti tẹ̀mí, ti padà bọ̀ sípò!
Orílẹ̀-Èdè Tuntun Kan Wáyé
19. Èé ṣe táa fi ní láti sọ pé kìkì ìmúṣẹ tó mọ níwọ̀nba ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa?
19 Lóòótọ́ o, ìmúṣẹ tó mọ níwọ̀nba ni Aísáyà orí karùndínlógójì ní ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìgbà kúkúrú làwọn Júù tí wọ́n dá padà wálé fi gbádùn ipò tó dà bíi ti Párádísè. Kò pẹ́ tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké àti ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni fi ta àbààwọ́n sí ìsìn tòótọ́. Ni ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn nípa tẹ̀mí bá tún bo àwọn Júù. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà kọ̀ wọ́n pé wọn kì í ṣe ènìyàn òun mọ́. (Mátíù 21:43) Nítorí pé wọ́n tún gbé ẹ̀mí àìgbọ́ràn wọ̀, ayọ̀ wọn ò wà lọ títí. Gbogbo èyí wá ń fi hàn pé Aísáyà orí karùndínlógójì yóò ṣì tún ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ ga sí i.
20. Ísírẹ́lì tuntun wo ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
20 Nígbà tó tákòókò lójú Jèhófà, Ísírẹ́lì mìíràn, ìyẹn Ísírẹ́lì Gálátíà 6:16) Ìgbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ló ti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún dídé Ísírẹ́lì tuntun yìí. Jésù mú ìsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò, ẹ̀kọ́ tó sì ń kọ́ni mú kí omi òtítọ́ tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Ni igbe ayọ̀ bá tún ta bí pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń bá a lọ. Ọ̀sẹ̀ méje lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù táa ti ṣe lógo, ó dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ ni àwọn Júù àtàwọn yòókù tí ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀ rà padà, Ọlọ́run sì sọ wọ́n dọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n fi di àbúrò Jésù, táa sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n.—Ìṣe 2:1-4; Róòmù 8:16, 17; 1 Pétérù 1:18, 19.
tẹ̀mí, wáyé. (21. Ní ti ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo la lè kà sí ìmúṣẹ àwọn kan lára ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?
21 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Aísáyà orí karùndínlógójì, ẹsẹ kẹta nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ó ní: “Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán.” (Hébérù 12:12) A jẹ́ pé, ó dájú pé ọ̀rọ̀ Aísáyà orí karùndínlógójì ṣẹ lọ́nà kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi iṣẹ́ ìyanu lajú àwọn afọ́jú, wọ́n sì ṣí etí àwọn adití ní ti gidi. Wọ́n mú kí “àwọn arọ” rìn, wọ́n sì mú kí àwọn odi máa sọ̀rọ̀. (Mátíù 9:32; 11:5; Lúùkù 10:9) Ní pàtàkì jù lọ, àwọn olódodo bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké, wọ́n sì wá ń gbádùn párádísè tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni. (Aísáyà 52:11; 2 Kọ́ríńtì 6:17) Ọ̀ràn àwọn tó ń rí ọ̀nà àjàbọ́ yìí wá dà bíi tàwọn Júù tó padà wálé láti Bábílónì, wọ́n rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ní ẹ̀mí àìyẹhùn, ẹ̀mí ìgboyà.—Róòmù 12:11.
22. Báwo ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn tí ń wá òtítọ́ kiri lóde òní ṣe di òǹdè Bábílónì?
22 Ìgbà tiwa yìí wá ńkọ́? Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ mìíràn, tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́, tó sì kan ìjọ Kristẹni òde òní bí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, iye àwọn tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tòótọ́ dín kù gan-an ni, tí àwọn èké Kristẹni, ìyẹn “àwọn èpò,” sì gbilẹ̀ láyé. (Mátíù 13:36-43; Ìṣe 20:30; ) Kódà nígbà tí àwọn olóòótọ́ ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára Kirisẹ́ńdọ̀mù ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ìsìn mímọ́ gaara, àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ṣì nípa lórí bí wọ́n ṣe lóye Ìwé Mímọ́ sí. Lọ́dún 1914, Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba, ṣùgbọ́n kò pẹ́ sí ìgbà yẹn tí ipò nǹkan fi di ráuràu fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ń wá òtítọ́ kiri wọ̀nyí. Àsọtẹ́lẹ̀ wá ṣẹ ní ti pé, àwọn orílẹ̀-èdè ‘bá wọn jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn,’ gbogbo ìsapá táwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn yìí sì ṣe láti wàásù ìhìn rere ni wọ́n tẹ̀ rì. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n di òǹdè Bábílónì.— 2 Pétérù 2:1-3Ìṣípayá 11:7, 8.
23, 24. Àwọn ọ̀nà wo lọ̀rọ̀ Aísáyà ti gbà ṣẹ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run látọdún 1919?
23 Àmọ́, àwọn nǹkan yí padà lọ́dún 1919. Jèhófà kó àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nígbèkùn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ti jẹ́ àbààwọ́n nínú ìsìn wọn látẹ̀yìnwá sílẹ̀. Nítorí náà, wọ́n rí ìwòsàn gbà. Wọ́n dẹni tó wà nínú párádísè tẹ̀mí, tó ń bá a lọ láti gbilẹ̀ kárí ayé títí di òní pàápàá. Ni àwọn afọ́jú bá ń kọ́ láti ríran, táwọn adití sì ń kọ́ láti gbọ́ràn nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé, wọ́n dẹni tó wà lójúfò dáadáa sí ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń fìgbà gbogbo rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:6; 2 Tímótì 4:5) Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ti yadi mọ́, wọ́n ń hára gàgà láti “ké jáde,” láti polongo òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. (Róòmù 1:15) Àwọn tó ti jẹ́ aláìlera, tàbí “arọ” nípa tẹ̀mí, wá di onítara àti aláyọ̀ wàyí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n dẹni tó lè “gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.”
24 “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” làwọn Kristẹni tó ti padà bọ̀ sípò yìí wá ń rìn. Gbogbo olùsìn tó bá sáà ti jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí ló lè rìn ní “Ọ̀nà” tó tinú Bábílónì Ńlá wá sínú párádísè tẹ̀mí yìí. (1 Pétérù 1:13-16) Kí ó dá wọn lójú pé ààbò Jèhófà ń bẹ fún wọn digbídigbí, kí wọ́n sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé àtakò ẹhànnà tí Sátánì ń gbé wá láti fi pa ìsìn tòótọ́ rẹ́ kò ní kẹ́sẹ járí láéláé. (1 Pétérù 5:8) Àyè ò sí fún àwọn aláìgbọràn àti ẹnikẹ́ni tó bá ń hùwà bí ẹranko ẹhànnà láti kó ìwàkiwà ran àwọn tó wà lójú òpópónà ìwà mímọ́ ti Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 5:11) Nínú ibi ààbò yìí, ṣe ni àwọn ẹni tí Jèhófà ti rà padà wọ̀nyí, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn,” ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—Jòhánù 10:16.
25. Ǹjẹ́ Aísáyà orí karùndínlógójì yóò ní ìmúṣẹ nípa ti ara? Ṣàlàyé.
25 Lọ́jọ́ ọ̀la ńkọ́? Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yóò tiẹ̀ fìgbà kankan ṣẹ nípa ti ara bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ìwòsàn tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe lọ́nà ìyanu ní ọ̀rúndún kìíní fi hàn pé Jèhófà ń fẹ́ láti ṣe irú ìwòsàn wọ̀nyẹn lọ́nà tó gadabú lọ́jọ́ iwájú, àti pé ó lágbára láti ṣe é. Ìwé Sáàmù onímìísí sọ̀rọ̀ nípa ìwàláàyè títí láé nínú ipò àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9, 11, 29) Jésù ṣèlérí ìwàláàyè nínú Párádísè. (Lúùkù 23:43) Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí Bíbélì la ti ń kà nípa ọ̀rọ̀ tí ń múni retí pé Párádísè ń bọ̀ ní ti gidi. Ní ìgbà yẹn, afọ́jú, adití, arọ, àti odi yóò gba ìwòsàn ní ti gidi, tí yóò wà títí láé. Ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò fò lọ. Ayọ̀ yíyọ̀ yóò wá wà títí gbére, àní títí láé.—Ìṣípayá 7:9, 16, 17; 21:3, 4.
26. Báwo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe ń fún àwọn Kristẹni lókun lóde òní?
26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣì ń dúró de ìgbà tí Párádísè orí ilẹ̀ ayé máa padà bọ̀ sípò nípa ti ara, síbẹ̀ wọ́n ń gbádùn ìbùkún párádísè tẹ̀mí nísinsìnyí pàápàá. Ọkàn akin ni wọ́n fi ń kojú àwọn àdánwò àti ìpọ́njú tó bá bá wọn. Bí wọ́n sì ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìmikàn, wọ́n a máa gba ara wọn níyànjú, wọ́n ń tipa báyìí tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣítí náà, pé: “Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun, ẹ sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí. Ẹ sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má fòyà.’” Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n ní nínú ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn mú dá wọn lójú, ó ní: “Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín yóò wá tòun ti ẹ̀san, Ọlọ́run yóò wá, àní tòun ti ìsanpadà. Òun fúnra rẹ̀ yóò wá, yóò sì gbà yín là.”—Aísáyà 35:3, 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Lẹ́bánónì àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ eléso tó ní àwọn igbó tútù yọ̀yọ̀, tó sì ní àwọn igi kédárì ńláńlá, tó ṣeé fi wé Ọgbà Édẹ́nì. (Sáàmù 29:5; 72:16; Ìsíkíẹ́lì 28:11-13) Àwọn èèyàn mọ Ṣárónì gẹ́gẹ́ bí ibi tó ní àwọn odò àti igi óákù; òkìkí Kámẹ́lì sì kàn fún níní tó ní àwọn ọgbà àjàrà, ọgbà eléso, àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tí àwọn òdòdó bò lọ súà.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 370]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 370]
Àwọn aṣálẹ̀ yóò di ibi olómi púpọ̀ tó ní òrépèté àti àwọn esùsú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 378]
Jésù wo àwọn aláìsàn sàn, nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí