Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa ṣe ìdájọ́ òdodo?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni
Bẹ́ẹ̀ kọ́
Kò dá mi lójú
Ohun tí Bíbélì sọ
“Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.” (Sáàmù 140:12) Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà láyé.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
Ọlọ́run ń rí bí ìdájọ́ òdodo ò ṣe sí láyé mọ́, ó sì máa ṣe àtúnṣe sí i.
—Oníwàásù 5:8. Tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ òdodo wá, àlàáfíà àti ààbò máa wà láyé.
—Aísáyà 32:16-18.
Ṣé Ọlọ́run ka àwọn èèyàn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ?
Èrò àwọn kan ni pé Ọlọ́run bù kún àwùjọ àwọn èèyàn pàtó kan, ó sì ti gégùn-ún fún àwọn kan. Àwọn míì sì gbà pé bákan náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bákàn náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
“Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ni “ìhìn rere” tàbí ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì wà fún.
—Ìṣípayá 14:6.