Ọ̀RỌ̀ ỌGBỌ́N TÓ WÚLÒ LÓDE ÒNÍ
Máa Dárí Jini Látọkànwá
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ . . . máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.
Ohun tó túmọ̀ sí Bíbélì fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè, ó sì fi ìdáríjì wé fífa igi lé gbèsè tẹ́nì kan jẹ. (Lúùkù 11:4) Ìwé kan tá a ṣe ìwádìí nínú rẹ̀ sọ pé nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìdáríjì” túmọ̀ sí “yíyọ̀ǹda gbèsè tẹ́nì kan jẹ,” kéèyàn má sì tún béèrè mọ́. Torí náà, tá a bá yàn láti darí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, a ò tún ní ronú pé a máa gbẹ̀san. Bá a ṣe dárí ji ẹni náà kò túmọ̀ sí pé a fara mọ́ ohun tí ẹni náà ṣe tàbí pé ohun tó ṣe kò dùn wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la dìídì pinnu láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹni náà ṣe dùn wá.
Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa dárí jini? Gbogbo èèyàn ló máa ń dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 3:23) Torí náà, ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá. Ìdí ni pé bópẹ́ bóyá, àwa náà máa ṣẹ ẹlòmíì, a sì máa fẹ́ kónítọ̀hún dárí jì wá. Bákan náà, tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, èrè wà níbẹ̀ fún wa. Lọ́nà wo?
Tá a bá di ẹni tó ṣẹ̀ wá sínú, tí a kò sì dárí jì í, ó máa ṣe ìpalára fún wa. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká láyọ̀, ara wa kò ní yá gágá, á sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì lè ṣàkóbá fún ìlera wa. Ìròyìn kan tó wà nínú Journal of the American College of Cardiology, tó dá lórí ìwádìí tí dókítà Yoichi Chida àti ọ̀jọ̀gbọ́n Andrew Steptoe ṣe, sọ pé: “Ìwádìí tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé téèyàn bá ń bínú tàbí tó di èèyàn sínú, àrùn ọkàn tí wọ́n ń pè ní coronary heart disease, kò ní jìnnà sírú ẹni bẹ́ẹ̀.”
Àmọ́ ṣá o, àǹfààní wà nínú kéèyàn máa dárí jini. Tá a bá ń dárí jini, a máa mú kí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà gbilẹ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì kò sì ní bà jẹ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé tá a bá ń dárí jini, ńṣe là ń fìwà jọ Ọlọ́run torí pé ó máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, ó sì fẹ́ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Máàkù 11:25; Éfésù 4:32; 5:1.