Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo ni Aṣòdì sí Kristi?

Àwọn Wo ni Aṣòdì sí Kristi?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n gbé fíìmù kan tó ń dẹ́rù bani jáde, àkọlé rẹ̀ ni Antichrist, ìyẹn Aṣòdì sí Kristi.

Ẹgbẹ́ akọrin kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó pe àkọlé orin wọn kan ní Antichrist Superstar, ìyẹn gbajúmọ̀ aṣòdì sí Kristi.

Onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tó ń jẹ́ Friedrich Nietzsche tó gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún kọ ìwé kan tó pè ní Aṣòdì sí Kristi.

Àwọn ọba àti olú ọba láyé àtijọ́ máa ń pe àwọn alátakò wọn ní aṣòdì sí Kristi.

Martin Luther tó jẹ́ aṣáájú àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn nílẹ̀ Jámánì pe àwọn póòpù ìjọ Kátólíìkì ní Aṣòdì sí Kristi.

NÍ BÁYÌÍ a ti wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ náà “aṣòdì sí Kristi” fún. Wọ́n máa ń lò ó fún àwọn ọba, àwọn tó ń ṣe fíìmù náà sì máa ń lò ó. A wá lè bi ara wa pé: Àwọn wo ni aṣòdì sí Kristi náà? Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe kàn wá lónìí? Ó bọ́gbọ́n mu pé tá a bá fẹ́ mọ ibi tí aṣòdì sí Kristi ti ṣẹ̀ wá, a ní láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀, torí ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara hàn nínú Bíbélì.

BÍBÉLÌ SỌ ÀWỌN TÓ JẸ́ AṢÒDÌ SÍ KRISTI

Jòhánù nìkan ni òǹkọ̀wé Bíbélì tó lo ọ̀rọ̀ náà “aṣòdì sí Kristi.” Kí ló wá sọ nípa aṣòdì sí Kristi? Ó ṣàlàyé nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ tí a fi orúkọ rẹ̀ pè nínú Bíbélì, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí, àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀, nísinsìnyí pàápàá ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ni ó ti wà; láti inú òtítọ́ tí àwa ti jèrè ìmọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí. Wọ́n jáde lọ láti ọ̀dọ̀ wa, ṣùgbọ́n wọn kò sí ní ìsọ̀wọ́ wa . . . Ta ni òpùrọ́ bí kì í bá ṣe ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù ni Kristi? Èyí ni aṣòdì sí Kristi, ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.”—1 Jòhánù 2:18, 19, 22.

Àpọ́sítélì Jòhánù gbà pé gbogbo àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Jésù àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni aṣòdì sí Kristi

Kí la wá rí fà yọ nínú ọ̀rọ̀ yìí? Jòhánù mẹ́nu kan “ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi,” tó fi hàn pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni aṣòdì sí Kristi, àmọ́ wọ́n pọ̀, wọ́n sì wà lóríṣiríṣi. Àwọn èèyàn tàbí àwọn àjọ tó jẹ́ aṣòdì sí Kristi sábà máa ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Jésù. Wọ́n sọ pé Jésù kọ́ ni Kristi tàbí Mèsáyà àti pé Jésù kì í ṣe Ọmọ Ọlọ́run. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ dọ́gbọ́n bẹnu àtẹ́ lu àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Kristi. Àwọ̀n aṣòdì sí Kristi ni àwọn tó ń pe ara wọn ní Kristi tàbí tí wọ́n ń sọ pé aṣojú rẹ̀ làwọn. Àmọ́, “wọ́n jáde lọ láti ọ̀dọ̀ wa,” ìyẹn ni pé, wọ́n ti yà kúrò nínú kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Síwájú sí i, Jòhánù kọ lẹ́tà rẹ̀ ní “wákàtí ìkẹyìn” torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán nígbà yẹn, àmọ́ tí àwọn aṣòdì sí Kristi yìí wà láyé.

Ohun míì wo ni Jòhánù tún sọ nípa àwọn aṣòdì sí Kristi? Nígbà tó ń sọ nípa àwọn wòlíì èké, ó kìlọ̀ pé: “Gbogbo àgbéjáde onímìísí tí ó bá jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n gbogbo àgbéjáde onímìísí tí kò bá jẹ́wọ́ Jésù kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síwájú sí i, èyí ni àgbéjáde onímìísí ti aṣòdì sí Kristi èyí tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, nísinsìnyí ó ti wà ní ayé ná.” (1 Jòhánù 4:2, 3) Jòhánù tún tẹnu mọ́ kókó yìí nínu lẹ́tà rẹ̀ kejì, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.” (2 Jòhánù 7) Ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Jésù àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Jòhánù pè ní aṣòdì sí Kristi.

“ÀWỌN WÒLÍÌ ÈKÉ” ÀTI “ỌKÙNRIN ONÍWÀ ÀÌLÓFIN”

Jésù ní ká ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí wọ́n da awọ àgùntàn bora, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n

Kí Jòhánù tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn onísìn afàwọ̀rajà yẹn ni Jésù ti gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.” (Mátíù 7:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan sún yín dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí, nítorí kì yóò dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà kọ́kọ́ dé, tí a sì ṣí ọkùnrin oníwà àìlófin payá, ọmọ ìparun.”—2 Tẹsalóníkà 2:3.

Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní làwọn wòlíì èké àtàwọn apẹ̀yìndà ti ń gbìyànjú láti ba àjọṣe tí ìjọ Kristẹni ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Gbogbo àwọn tó ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Jésù Kristi àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń fi ìsìn èké tan àwọn èèyàn jẹ ni Jòhánù pè ní “aṣòdì sí Kristi.” Ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n hàn kedere nígbà tí Pọ́ọ̀lù pè wọ́n ní “ọmọ ìparun.”

ṢỌ́RA FÚN ỌGBỌ́N ÀRÉKÉREKÈ TÍ ÀWỌN AṢÒDÌ SÍ KRISTI Ń LÒ LÓNÌÍ

Lónìí ńkọ́? Àwọn èèyàn àti àwọn àjọ tí wọ́n jẹ́ aṣòdì sí Kristi ṣì ń ta ko Kristi àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, kí àwọn èèyàn má báa mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ Rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì ká mọ irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀, ká sì yẹra fún wọn. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀wò.

Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń tan ẹ̀kọ́ nípa mẹ́talọ́kan kalẹ̀, wọ́n ń sọ pé Baba àti Ọmọ jẹ́ ọ̀kan náà. Nípa báyìí, àwọn aṣòdì sí Kristi wá sọ òtítọ́ nípa irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi jẹ́ di àdììtú. Bíbélì rọ̀ wá pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká sì tún sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, ẹ̀kọ́ àdììtú tí àwọn aṣòdì sí Kristi ń kọ́ àwọn èèyàn kò jẹ́ kí àwọn tó ní ọkàn rere lè ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 11:1; Jákọ́bù 4:8.

Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì náà wá dá kún ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí yíyọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run ìyẹn Jèhófà fara han nínu Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀, síbẹ̀ wọ́n ṣì yọ orúkọ náà kúrò. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Wọ́n túbọ̀ wá sọ Ọlọ́run di àdììtú sí i.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn ṣe mọ orúkọ Ọlọ́run ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Richard nìyẹn. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì sọ̀rọ̀, ó ní: “Wọ́n fi hàn mí nínú Bíbélì pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́. Orí mi wú nígbà tí mo rí i pé Ọlọ́run ní orúkọ, èyí tí mi ò tíì gbọ́ rí.” Láti ọjọ́ náà, ó ṣe ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu, ó sì ń ṣé àwọn nǹkan tó ń múnú Jèhófà dùn. Richard parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí mo ṣe mọ orúkọ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.”

Ọjọ́ pẹ́ táwọn aṣòdì sí Kristi ti sọ àìlóǹkà èèyàn sínú òkùnkùn tó bá dọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run. Àmọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ irú ẹni tí aṣòdì sí Kristi jẹ́, ó sì ti jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ irọ́ àti ẹ̀tàn tí àwọn aṣòdì sí Kristi ń tàn kálẹ̀.—Jòhánù 17:17.