KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?
Ọlọ́run Ń Tù Ẹ́ Nínú
“Ọlọ́run, ẹni tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú, tù wá nínú.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 7:6.
ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Nígbà míì tí àwọn èèyàn bá nílò ìtùnú lójú méjèèjì nítorí ìṣòro tó bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n lè máa rò pé àṣejù ni tí àwọn bá ń yọ Ọlọ́run lẹ́nu pé kó dá sí ìṣòro àwọn. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára obìnrin kan tó ń jẹ Raquel náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Tí mo bá wo bí ìṣòro ṣe kún inú ayé, tí mo sì rí nǹkan tí ẹlòmíì ń bá yí, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé ohun tó ń bá mi fínra kò tó nǹkan tó yẹ kí n máa da Ọlọ́run láàmù sí.”
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run ti ṣe ètò kan láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì tù wá nínú. Gbogbo èèyàn pátápátá ló ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, torí náà kò sí bá a ṣe lè sapá tó, a kò lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ délẹ̀délẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ [Jésù Kristi] jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 4:10) Ipasẹ̀ ikú ìrúbọ Jésù yìí ni a fi máa ń rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó tún ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn rere, a sì máa ní ìrètí láti gbé títí láé nínú ayé tuntun tí àlàáfíà ti máa jọba. * Àmọ́, ṣé Ọlọ́run kàn ṣe ètò yìí fún gbogbo ìran èèyàn lápapọ̀ ni àbí ó ṣeé torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
Wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ikú ìrúbọ Jésù wú Pọ́ọ̀lù lórí débi tó fi sọ pé: “Mo ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gálátíà 2:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti kú ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, síbẹ̀, ó rí ohun tí Jésù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì fún òun.
Ikú ìrúbọ Jésù jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì fún ìwọ náà. Ẹ̀bùn yìí fi hàn pé Ọlọ́run kà ẹ́ sí pàtàkì. Ẹ̀bùn yìí sì lè fún ẹ ní “ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí,” èyí á sì mú kí o ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.’—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn, ẹ̀rí wo la ní lónìí pé Ọlọ́run fẹ́ kí o sún mọ́ òun?
^ ìpínrọ̀ 5 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ikú ìrúbọ Jésù, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.