Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÍ O MÁA GBÀDÚRÀ?

Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fí Máa Ń Gbàdúrà?

Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fí Máa Ń Gbàdúrà?

Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà déédéé? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kì í gbàdúrà, àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà gan-an ń gbàdúrà. Àmọ́, kí nìdí tí àwọn èèyàn fi ń gbàdúrà? Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Faransé jẹ́ ká mọ̀ pé ìdajì àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé máa ń gbàdúrà tàbí kí wọ́n ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ wọn kò ka àwọn nǹkan wọ̀nyí sí apá kan ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n kàn máa ń gbàdúrà kí “ara lè tù wọ́n lásán.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn ní ilẹ̀ Yúróòpù nìyẹn. Ó wá dà bíi pé wọ́n ti sọ àdúrà di “oògùn amáratuni.” Kódà, ọ̀rọ̀ náà kò yọ àwọn onígbàgbọ́ sílẹ̀, ìgbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa ń gbàdúrà. Wọ́n á wá máa retí ìdáhùn ojú ẹsẹ̀.—Aísáyà 26:16.

Kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ àdúrà kàn dà bí ohun tí èèyàn fi ń pa ìrònú rẹ́? Ṣé ò ń rí iṣẹ́ àdúrà ní ìgbésí ayé rẹ? Àbí ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà rẹ? Bíbélì á jẹ́ kó o mọ̀ pé àdúrà kì í ṣe oògùn ajẹ́bíidán tó kàn ń jẹ́ kára yá gágá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí èèyàn lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run.