Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́?
Ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ ni wàá retí pé kí Bíbélì jẹ́, bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dà rẹ̀ ni a ti tẹ̀ jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lágbára láti tún ayé àwọn èèyàn ṣe.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Tímótì 3:16.
A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá torí pé ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ìwé Aísáyà tó wà nínú Bíbélì. Wọ́n kọ ẹ̀dà rẹ̀ kan ní nǹkan bí ọgọ́rùn ún ọdún kan ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù. Wọ́n sì rí ẹ̀dà yìí nínú ihò àpáta lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Òkú. Àsọtẹ́lẹ̀ ti wà nínú ìwé Aísáyà pé, kò sẹ́ni tó máa gbé ìlú Bábílónì mọ́. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Aísáyà 13:19, 20; 2 Pétérù 1:20, 21.
Báwo ni wọ́n ṣe kọ Bíbélì?
Ó lé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn ogójì [40] ọkùnrin tó kọ ọ́. Ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni gbogbo ohun tí wọ́n kọ dá lé, ọ̀rọ̀ wọn kò sì ta kora. Kí ló mú kí ìyẹn ṣeé ṣe? Ohun tó jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ló darí gbogbo ohun tí wọ́n kọ.—Ka 2 Sámúẹ́lì 23:2.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́run gbà bá àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀, nígbà míì, ó lè rán áńgẹ́lì sí wọn, ó sì lè bá wọn sọ̀rọ̀ lójú ìran tàbí lójú àlá. Ọlọ́run sábà máa ń fi èrò rẹ̀ sí ọkàn òǹkọ̀wé náà, á wá jẹ́ kí ẹni náà yan ọ̀rọ̀ tó máa fi jẹ́ iṣẹ́ tí òun rán an.—Ka Ìṣípayá 1:1; 21:3-5.