Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ogun?

Ǹjẹ́ O Fara Mọ́ Ọwọ́ Tí Ẹ̀sìn Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ogun?

Ó tó nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alberto fi ṣiṣẹ́ ológun. Ó sọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí wọ́n fẹ́ lọ sójú ogun, ó ní: “Àlùfáà wa gbàdúrà fún wa pé, ‘kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.’ Àmọ́ mo wá ń rò ó pé, ‘Mò ń lọ pààyàn, bẹ́ẹ̀ Bíbélì sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn.”’”

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ray wà lára àwọn ọmọ ogun ojú omi. Lọ́jọ́ kan, ó béèrè lọ́wọ́ àlùfáà pé: “Ṣé kì í ṣe bí ẹ ṣe máa ń wá gbàdúrà fún wa ká lè ṣẹ́gun náà ni àwọn tí à ń lọ bá jà máa ń gbàdúrà pé kí àwọn náà ṣẹ́gun?” Àlùfáà fún un lésì pé àwámáàrídìí niṣẹ́ Olúwa.

Tí ohun tí àlùfáà yẹn sọ kò bá tẹ́ ọ lọ́rùn, ìwọ nìkan kọ́ ni kò tẹ́ lọ́rùn.

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

Jésù sọ pé ọ̀kan lára àwọn àṣẹ Ọlọ́run tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Máàkù 12:31) Ǹjẹ́ Jésù sọ pé ibi tí àwọn aládùúgbò wa ń gbé tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá ló máa pinnu bí a ṣe máa nífẹ̀ẹ́ wọn tó? Rárá o. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Ìfẹ́ tí wọ́n máa ní láàárín ara wọn máa dá yàtọ̀ débi pé òun ni àwọn èèyàn máa fi dá wọn mọ̀. Wọn kò ní gba ẹ̀mí ọmọnìkejì wọn láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe tán láti kú nítorí àwọn míì.

Ohun tí Jésù sọ ni àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ṣe. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Àwọn tí wọ́n jẹ́ bàbá ìjọ nígbà àtijọ́, irú bíi Tertullian àti Origen sọ gbangba pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí èèyàn, ìlànà yìí ni kò jẹ́ kí wọ́n wọnú ẹgbẹ́ ológun ti ilẹ̀ Róòmù.”

ṢÉ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

Ṣàṣà ni orílẹ̀-èdè tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò sí, kódà tí àwọn orílẹ̀-èdè kan bá ń bá ara wọn jagun, a máa ń rí lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè yẹn. Síbẹ̀, gbogbo ohun tó bá gbà ni wọ́n máa ń ṣe láti rí i pé ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín wọn ṣì wà bó ṣe wà.

Ǹjẹ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn èèyàn láti ní ìfẹ́ tòótọ́ tó yẹ kó wà láàárín àwọn Kristẹni?

Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1994 nígbà tí ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà wáyé láàárín ẹ̀yà Hutu àti ẹ̀yà Tutsi ní orílẹ̀-èdè Rùwáńdà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ kò bá wọn dá sí ìjà yẹn rárá. Àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láàárín àwọn ẹ̀yà méjèèjì yìí gbà káwọn Ẹlẹ́rìí míì sá pa mọ́ sílé wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè pa wọ́n torí ohun tí wọ́n ṣe yìí. Nígbà tí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Interahamwe militia ti ẹ̀yà Hutu tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kan tó fi àwọn Ẹlẹ́rìí míì láti ẹ̀yà Tutsi pa mọ́, àwọn ọmọ ogun yẹn sọ pé: Ńṣe la máa pa yín torí pé ẹ jẹ́ kí àwọn ará Tutsi sá lọ.” Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n pa àwọn Ẹlẹ́rìí méjèèjì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Hutu yẹn.—Jòhánù 15:13.

Kí lo rò? Ṣé irú ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní?