Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run Fi Hàn Pé Ìkà Ni?

Ṣé Àwọn Ìdájọ́ Ọlọ́run Fi Hàn Pé Ìkà Ni?

KÁ LÈ rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì nínú àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe tó wà nínú Bíbélì. A máa wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà àti nígbà ìparun àwọn ará Kénáánì.

ÌKÚN-OMI ỌJỌ́ NÓÀ

OHUN TÍ ÀWỌN KAN SỌ: “Ìwà ìkà gbáà ni Ọlọ́run hù bó ṣe rọ òjò ńlá tó di alagbalúgbú omi tó fi pa gbogbo èèyàn run àyàfi Nóà àti ìdílé rẹ̀ tó yè é.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run sọ pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Nítorí náà, kì í ṣe nǹkan ayọ̀ fún Ọlọ́run bó ṣe pa àwọn èèyàn burúkú run nígbà ayé Nóà. Kí wá nìdí tó fi pa wọ́n run?

Ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ṣe ni Ọlọ́run ń fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀,” bó ṣe pa àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ run nígbà àtijọ́. (2 Pétérù 2:5, 6) Kí ni èyí fi hàn nípa Ọlọ́run?

Lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé, kì í ṣe ìdùnnú òun láti pa àwọn èèyàn run. Ó fi hàn pé òun ń rí àwọn ìkà èèyàn tó ń fìyà jẹ àwọn míì, òun sì máa mú kí wọ́n jìyà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà tó ń jẹ aráyé.

Ohun kejì ni pé, àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn kó tó ṣe ìdájọ́ wọn, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Nóà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára wọn kò fetí sí i. Bíbélì sọ pé: “Wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:39.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run yí bó ṣe ń ṣe nǹkan pa dà nígbà tó yá? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀ pé, tí wọ́n bá ń hùwà burúkú tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń hù, òun máa jẹ́ kí àwọn ọ̀tá gbógun jà wọ́n, wọ́n á pa Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn run, wọ́n á sì kó wọn lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, wọ́n tiẹ̀ tún fi ọmọ wọn rúbọ. Ǹjẹ́ Jèhófà ṣe ìdájọ́ tó yẹ fún àwọn èèyàn yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ ó kọ́kọ́ rán àwọn wòlíì pé kí wọ́n lọ kìlọ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ léraléra, kí wọ́n lè yí pa dà kó tó pẹ́ jù. Kódà Ọlọ́run sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.”—Ámósì 3:7.

BÍ Ó ṢE KÀN Ọ́: Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe ìdájọ́ jẹ́ ká ní ìrètí. Ọkàn wa balẹ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run máa tó dé sórí àwọn ìkà èèyàn tó ń ni àwọn ẹlòmíì lára. Bíbélì sọ pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11) Kí ni èrò rẹ nípa ìdájọ́ tó máa gba aráyé kúrò lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ìkà ni ẹni tó máa ṣe irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀, àbí aláàánú?

ÌPARUN ÀWỌN ARÁ KÉNÁÁNÌ

OHUN TÍ ÀWỌN KAN SỌ: “Ìpakúpa tó burú jáì ni Ọlọ́run pa àwọn ará Kénáánì, kódà o burú ju ìpẹ̀yàrun tó ń wáyé lóde òní.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Gbogbo ọ̀nà [Ọlọ́run] jẹ́ ìdájọ́ òdodo. [Ó jẹ́] Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) A ò lè fi ohun tí Ọlọ́run máa ṣe tó bá ń mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ wé ogun táwọn èèyàn ń jà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run yàtọ̀ sí àwa èèyàn, nítorí ó lè mọ èrò ọkàn wa, ìyẹn irú ẹni tí a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ ìlú Sódómù àti Gòmórà, tó sì pinnu pé òun máa pa wọ́n run, ọ̀rọ̀ yìí ká Ábúráhámù lára, ó sì fẹ́ mọ̀ bóyá ìpinnu tí Ọlọ́run ṣe yìí bá ìdájọ́ òdodo mu. Lójú tirẹ̀, ó ń wò ó pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo, torí náà, kò lè wá “gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú.” Ọlọ́run fi sùúrù ṣàlàyé fún un pé, bí òun bá lè rí àwọn mẹ́wàá péré tó jẹ́ olódodo ní ìlú Sódómù, òun kò ní pa ìlú náà run. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20-33) Èyí jẹ́ kó hàn kedere pé Ọlọ́run ti wo ọkàn àwọn èèyàn yẹn, ó sì ti rí bí ìwà ibi ṣe rinlẹ̀ tó lọ́kàn wọn.—1 Kíróníkà 28:9.

Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run rí ìwà ibi tí àwọn ará Kénáánì ń hù, ó sì sọ pé kí wọ́n pa wọ́n run. Àwọn ará Kénáánì ti jingíri sínú ìwà ìkà, ó le débi pé wọ́n máa ń sun àwọn ọmọ wọn lóòyẹ̀ nínú iná tí wọ́n fi ń rúbọ sí òrìṣà. * (2 Àwọn Ọba 16:3) Àwọn ará Kénáánì mọ̀ pé Jèhófà ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ wọn. Torí náà, bí àwọn ará Kénáánì tó ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ náà ṣe kọ̀ láti kúrò, kí wọ́n lè gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń ta kò wọ́n. Wọ́n tún tipa bẹ́ẹ̀ ta kò Jèhófà lẹ́yìn tó ti fi hàn kedere pé òun wà lẹ́yìn àwọn èèyàn òun.

Àmọ́ ṣá, Ọlọ́run ṣàánú àwọn ará Kénáánì tó yí pa dà kúrò nínú ìwà ibi, tí wọ́n sì wá ń pa àwọn ìlànà ìwà rere Jèhófà mọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run gba Ráhábù, obìnrin aṣẹ́wó kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kénáánì àti ìdílé rẹ̀ là. Bákan náà, nígbà tí àwọn tó ń gbé ìlú Gíbéónì bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàánú wọn, Ọlọ́run dá àwọn àti gbogbo ọmọ wọn sí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ilẹ̀ Kénáánì ni wọ́n.—Jóṣúà 6:25; 9:3, 24-26.

BÍ Ó ṢE KÀN Ọ́: A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan lára ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn ọmọ Kénáánì. A mọ̀ pé “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” ti ń yára sún mọ́lé gan-an. (2 Pétérù 3:7) Tí a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a máa jàǹfààní nígbà tó bá fi òpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé, tó sì mú gbogbo àwọn tó ń ta ko ìṣàkóso rẹ̀ kúrò.

Àwọn ará Kénáánì ti jingíri sínú ìwà ìkà, wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ta ko Ọlọ́run àti àwọn èèyàn rẹ̀

Jèhófà rán wa létí tìfẹ́tìfẹ́ pé, ìpinnu tí àwọn òbí bá ṣe máa ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Diutarónómì 30:19, 20) Ṣé a wá lè sọ pé ìkà ni Ọlọ́run tó sọ irú ọ̀rọ̀ yìí àbí Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, tó sì fẹ́ kí wọ́n máa ṣe ìpinnu tí ó tọ́?

^ ìpínrọ̀ 15 Àwọn awalẹ̀pìtàn hú àwọn nǹkan kan jáde nílẹ̀ Kénáánì tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n máa ń fi àwọn ọmọ jòjòló rúbọ tí wọ́n bá ń jọ́sìn òrìṣà.