Ṣíṣe Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Aláìní
“Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú ni a ó bù kún, nítorí ó ti fún ẹni rírẹlẹ̀ lára oúnjẹ rẹ̀.”—ÒWE 22:9.
Ìdí tí àwọn kan fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì.
Jésù ṣoore fún àwọn aláìní, àwọn aláìsàn àtàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, àwọn kan sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọ́n ronú pé àkókò Kérésì nìgbà tó dáa jù láti fúnni lẹ́bùn, torí àsìkò yìí ni àwọn ẹgbẹ́ aláàánú máa ń káràmáásìkí bí wọ́n ṣe máa rí ọrẹ gbà fún àwọn aláìní.
Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn?
Nígbà ọdún, akitiyan lórí ọjà rírà, dídá àwọn èèyàn lára yá àti lílọ máa kí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ló máa ń gba àkókò àwọn èèyàn. Gbogbo lílọ sókè sódò yìí kì í jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ ráyè, tàbí ní owó tó pọ̀ tó láti fi gbọ́ ti àwọn tálákà àti aláìní. Wọ́n kàn lè fi ọrẹ àánú sí àpò ẹgbẹ́ aláàánú, ìyẹn tó bá ṣeé ṣe.
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè tọ́ni sọ́nà?
“Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Ìgbà ọdún Kérésì nìkan kọ́ ni ìyà ń jẹ àwọn tálákà, àwọn tí ebi ń pa àti àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Tí o bá kíyè sí i pé ẹnì kan nílò ìrànlọ́wọ́, tí o sì ní ‘agbára láti ṣe é,’ ǹjẹ́ ó yẹ kí o ṣẹ̀ṣẹ̀ dúró di ìgbà ọdún kí o tó ṣe é? Ọlọ́run yóò san ẹ́ lẹ́san oore àti àánú tí o bá ṣe.
“Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí.” (1 Kọ́ríńtì 16:2) Ìmọ̀ràn yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tí ó ń fẹ́ láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè máa ‘ya iye kan sọ́tọ̀’ déédéé tí o lè máa fún àwọn èèyàn kan tàbí àjọ kan tí wọ́n máa ń lo owó tí wọ́n bá rí gbà lọ́nà tó dára? Tí o bá ń ṣe èyí wàá máa bójú tó àwọn aláìní láìṣe ju agbára rẹ lọ.
“Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Kíyè sí i pé, yàtọ̀ sí “ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn,” a ò gbọ́dọ̀ “gbàgbé rere ṣíṣe” tàbí ríran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí àwọn òbí kọ́ ọmọ wọn ní bó ṣe máa ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́, bó ṣe lè lọ máa kí àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí kó pè wọ́n lórí fóònù láti béèrè àlàáfíà wọn. Kí wọ́n tún kọ́ ọmọ wọn pé kó máa ṣàánú tàbí ṣoore fún àwọn ọmọ tó jẹ́ aláìní àti àwọn aláàbọ̀ ara. Èyí á jẹ́ kó mọ́ ọmọ wọn lára láti máa ṣoore kó sì jẹ́ ọ̀làwọ́ ní gbogbo ìgbà, láìfi mọ sígbà ọdún.
Ó yẹ kí àwọn òbí kọ́ ọmọ wọn ní bó ṣe lè máa ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn àgbàlagbà, àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn ọmọ aláìní àti àwọn aláàbọ̀ ara. Á lè mọ́ ọmọ wọn lára láti máa ṣoore kó sì jẹ́ ọ̀làwọ́ ní gbogbo ìgbà, láìfi mọ sígbà ọdún