Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dá Àwọn Èèyàn Lóró Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì?

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dá Àwọn Èèyàn Lóró Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì?

INÚ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Kọ́lá lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Olú.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Dá Àwọn Èèyàn Burúkú Lóró?

Kọ́lá: Ọ̀gbẹ́ni Olú, ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ṣé dáadáa ni?

Olú: A dúpẹ́ o. Ẹ káàbọ̀.

Kọ́lá: Lọ́jọ́ sí tá a jọ sọ̀rọ̀, ẹ sọ ohun kan, mo sì ronú gan-an lórí rẹ̀.

Olú: Kí nìyẹn?

Kọ́lá: Ẹ ní ó yà yín lẹ́nu nígbà tí ẹ gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbà gbọ́ pé iná ọ̀run àpáàdì wà.

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni o, ó yà mí lẹ́nu gan-an. Ká má purọ́, ó ṣòro fún mi láti gbà pé ẹ ò gbà gbọ́ pé iná ọ̀run àpáàdì wà.

Kọ́lá: Inú mi dùn bí ẹ ṣe sọ èrò yín fún mi. Mo máa ń fẹ́ gbọ́ èrò àwọn ẹlòmíì. Àmọ́, èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn èèyàn ní nípa iná ọ̀run àpáàdì. Ẹ jọ̀ọ́, ǹjẹ́ ẹ lè sọ ohun tí ẹ̀yin gbà gbọ́ nípa rẹ̀?

Olú: Ìgbàgbọ́ mi ni pé, tí àwọn èèyàn búburú bá kú inú iná ọ̀run àpáàdì ni wọ́n ń lọ, tí wọn yóò máa joró níbẹ̀ títí láé.

Kọ́lá: Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn náà ní nìyẹn. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n bi yín ní ìbéèrè kan. Ǹjẹ́ ohun kan tí inú yín kò dùn sí ti ṣẹlẹ̀ sí yín rí?

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹnì kan pa ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn.

Kọ́lá: Áà, ó mà ṣe o, ẹ pẹ̀lẹ́. Ó dájú pé ó máa dùn yín gan-an.

Olú: Ó dùn mí gan-an ni. Ojoojúmọ́ ni mo ń rántí ẹ̀gbọ́n mi.

Kọ́lá: Mo rí i pé ohun tí àwọn èèyàn burúkú ti fi ojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí ló mú kí wọ́n gbà pé iná ọ̀run àpáàdì gbọ́dọ̀ wà. Àwọn tí ẹni ibi ti hàn léèmọ̀ ṣáà máa fẹ́ kí àwọn òṣìkà jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àbí?

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni o! Mo fẹ́ kí ọkùnrin tó pa ẹ̀gbọ́n mi jìyà oró ńlá tó dá ìdílé wa.

Kọ́lá: Kò burú rárá láti ronú pé ó yẹ kí ìkà èèyàn jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé inú máa ń bí Ọlọ́run tí wọ́n bá ń hùwà ìkà sí àwọn aláìṣẹ̀. Ó sì ṣèlérí pé òun máa fi ìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú. Wo ohun tó wà nínú Aísáyà 3:11. Ó ní: “Ègbé ni fun eniyan buburu! yoo buru fun un: nitori èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni a o fi fun un.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Torí náà, ó dájú pé Ọlọ́run kò ní ṣàì fìyà jẹ àwọn ẹni burúkú.

Olú: Ó dáa, báwo ló ṣe máa wá fìyà jẹ wọ́n tí kò bá sí iná ọ̀run àpáàdì lóòótọ́?

Kọ́lá: Ìbéèrè yẹn dáa. Ní kúkúrú, ìdáhùn ni pé ìparun ayérayé ni ìyà tí Ọlọ́run yóò fi jẹ àwọn èèyàn burúkú. Ẹ wo ohun tí Bíbélì sọ níbí, nínú 2 Tẹsalóníkà 1:9. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kà á.

Olú: Ó dáa. Ó ní: “Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun láti iwájú Olúwa.”

Kọ́lá: Ẹ ò rí i báyìí pé, kò sí ìrètí kankan fún àwọn èèyàn burúkú, torí pé Ọlọ́run yóò fi ìyà tó jẹ́ ikú ayérayé jẹ wọ́n. Wọn ò sì ní ìrètí kankan pé wọ́n tún máa wà láàyè mọ́ títí láé.

Olú: Ohun tí ẹsẹ yẹn sọ yé mi o, àmọ́ ìyẹn kò dáa tó. Ṣebí gbogbo èèyàn náà ló ń kú. Ṣé kò wá yẹ kí Ọlọ́run fi ìyà tó le jù bẹ́ẹ̀ lọ jẹ àwọn èèyàn burúkú ni?

Báwo Ni Ìdájọ́ Òdodo Ṣe Máa Wáyé?

Kọ́lá: Mo rí i pé ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo jẹ yín lógún gan-an.

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni, mi ò fi ṣeré rárá.

Kọ́lá: Ìyẹn dáa gan-an ni. Àmọ́ ká sòótọ́, ohun tó jẹ́ ká lè ní òye ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ ni pé Ọlọ́run dá òye yẹn mọ́ wa. Torí náà, ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo jẹ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lógún gan-an. Àmọ́ nígbà tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn bá ń kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run máa ń sọ àwọn èèyàn sínú iná ọ̀run àpáàdì, ṣe ni wọ́n ń fi Ọlọ́run hàn bí ẹni tí kò ṣe ìdájọ́ òdodo rárá.

Olú: Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Kọ́lá: Ó dáa, ẹ jẹ́ kí n fi àpẹẹrẹ kan hàn yín. Ṣé ẹ mọ ìtàn Ádámù àti Éfà tó wà nínú Bíbélì?

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi kan, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn wọn lọ jẹ ẹ́.

Kọ́lá: Òótọ́ ni. Ẹ jẹ́ ká jọ wo ìtàn yẹn nínú Bíbélì. Ó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17. Ó ní: “Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: ‘Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.’” Kí ni Ọlọ́run sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ tí Ádámù bá jẹ èso tí òun ní kò gbọ́dọ̀ jẹ?

Olú: Ó ní Ádámù máa kú.

Kọ́lá: Ẹ gbà á. Ẹ wá rò ó wò ná: Ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù ṣẹ̀ yìí ló fi sọ gbogbo ìran ènìyàn pátá di ẹni tí a bí ní ẹlẹ́ṣẹ̀. * Ṣùgbọ́n bó tiẹ̀ ṣe jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó yìí, ǹjẹ́ Ọlọ́run sọ pé yóò lọ jìyà nínú iná ọ̀run àpáàdì?

Olú: Rárá.

Kọ́lá: Tó bá jẹ́ pé ṣe ni Ádámù àti Éfà yóò máa joró títí láé, ǹjẹ́ ẹ kò rò pé Ọlọ́run máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ṣé ohun tí ẹni tó bá jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti onífẹ̀ẹ́ máa ṣe kọ́ nìyẹn?

Olú: Ohun tí mo rò pé ó yẹ kó ṣe nìyẹn.

Kọ́lá: Ẹ tún ronú nípa ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà lẹ́yìn tí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

Olú: Ó kà pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”

Kọ́lá: Ẹ ṣeun. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ, ibo ni Ádámù ń lọ tó bá ti kú?

Olú: Ó sọ pé Ádámù máa pa dà sí ekuru inú ilẹ̀.

Kọ́lá: Bó ṣe rí gan-an nìyẹn. Ẹ máa gbà pẹ̀lú mi pé kí ẹnì kan tó pa dà sí ibì kan, ó ní láti jẹ́ pé ó ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni.

Kọ́lá: Ibo ni Ádámù wà ṣáájú kí Ọlọ́run tó dá a?

Olú: Ádámù kò tíì sí rárá.

Kọ́lá: Òótọ́ ni. Ẹ sì tún kíyè sí i pé Ọlọ́run ò mẹ́nu kan iná ọ̀run àpáàdì nínú ìdájọ́ rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé inú iná ọ̀run àpáàdì ni Ádámù ń lọ, àmọ́ tí Ọlọ́run wá sọ fún un pé ó máa pa dà sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ ẹ rò pé ó dáa bẹ́ẹ̀?

Olú: Rárá, kò ní dáa bẹ́ẹ̀.

Ṣé Èṣù Máa Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Ni?

Kọ́lá: Ohun mìíràn tún wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì.

Olú: Kí nìyẹn?

Kọ́lá: Ó dáa, ta ni àwọn èèyàn máa ń sọ pé ó ń “ṣàkóso” ọ̀run àpáàdì? Ta tiẹ̀ ni wọ́n ní ó máa ń fi ìyà jẹ àwọn èèyàn ní ọ̀run àpáàdì?

Olú: Èṣù ni.

Kọ́lá: Síbẹ̀, Èṣù ni olórí ọ̀tá Ọlọ́run. Tí Ọlọ́run bá ń fi àwọn èèyàn sínú iná ọ̀run àpáàdì pé kí Èṣù máa dá wọn lóró níbẹ̀, ǹjẹ́ èyí ò ní fi hàn pé Ọlọ́run àti Èṣù jọ ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀?

Olú: Òótọ́ ni o. Mi ò tiẹ̀ ronú kan gbogbo ìyẹn rí.

Kọ́lá: Àpèjúwe kan nìyí: Ká ní bàbá dáadáa kan ní ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ọmọ náà wá ya ọmọ burúkú, ó ń hu àwọn ìwà àìdáa tó ń dun bàbá náà. Tó bá jẹ́ ẹ̀yin ni bàbá onífẹ̀ẹ́ yìí kí lẹ máa ṣe?

Olú: Màá bá a wí, màá sì tọ́ ọ sọ́nà.

Kọ́lá: Mo mọ̀ pé gbogbo ipá yín lẹ máa sà kí ọmọ náà lè yí pa dà.

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni o.

Kọ́lá: Ká wá sọ pé, pẹ̀lú gbogbo ìsapá yín, ọmọ náà lo agídí kò yí pa dà. Ẹ lè wá wò ó pé ó yẹ kí ọmọ náà jìyà, àbí?

Olú: Bẹ́ẹ̀ ni.

Kọ́lá: Tí ẹ bá wá rí i pé ìkà ọkùnrin kan ló ń kọ́ ọmọ náà ní gbogbo ìwà burúkú tó ń hù yẹn ńkọ́?

Olú: Màá bínú sí ọkùnrin náà gan-an ni.

Kọ́lá: Ẹ jọ̀ọ́ ẹ sọ fún mi: Bí ẹ ṣe wá mọ̀ pé, ìkà ọkùnrin, oníwà ìbàjẹ́ yẹn ló ń kọ́ ọmọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, ṣé ọkùnrin yẹn kan náà lẹ tún máa ní kó wá bá yín jẹ ọmọ náà níyà?

Olú: Ó tì o. Ìyẹn ò ní bọ́gbọ́n mu.

Kọ́lá: Ṣé ó máa wá bọ́gbọ́n mu nígbà náà, tí Ọlọ́run bá ní kí Sátánì Èṣù, tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ìwà búburú, tún máa wá dá àwọn èèyàn tó mú kó dẹ́ṣẹ̀ yẹn kan náà lóró?

Olú: Rárá, kò ní bọ́gbọ́n mu o.

Kọ́lá: Ká tiẹ̀ sọ pé Ọlọ́run fẹ́ fìyà jẹ àwọn ẹni burúkú, ṣé Èṣù tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run máa bá Ọlọ́run fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kó wá máa bá a dá àwọn ẹni burúkú lóró?

Olú: Òdodo ọ̀rọ̀ nìyẹn. Mi ò ro ọ̀rọ̀ yẹn bẹ́ẹ̀ rí!

Jèhófà Máa Fòpin sí Gbogbo Ìwà Búburú

Kọ́lá: Ṣùgbọ́n ohun kan dájú ṣá o. Ọlọ́run kò ní ṣàì dá àwọn aṣebi tí kò yí pa dà lẹ́jọ́. Ẹ jẹ́ ká jọ wo ẹsẹ Bíbélì kan péré sí i, èyí tó ti kókó yìí lẹ́yìn. Sáàmù 37:9 ni. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kà á.

Olú: Ó dáa. Ó ní: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.”

Kọ́lá: Ẹ ṣeun. Ǹjẹ́ ẹ kíyè sí ohun tí Ọlọ́run máa ṣe sí àwọn aṣebi?

Olú: Ẹsẹ yìí sọ pé, Ọlọ́run yóò ké wọn kúrò.

Kọ́lá: Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìyẹn ni pé, ó máa pa wọ́n run títí láé. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn èèyàn rere, ìyẹn “àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà,” wọn yóò máa gbádùn ẹ̀mí wọn títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ẹ ní àwọn ìbéèrè kan lórí èyí. Bí àpẹẹrẹ, kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi dá àwọn èèyàn dúró kí wọ́n má wulẹ̀ hùwà ibi rárá? Àti pé, tí Ọlọ́run bá fẹ́ dá àwọn èèyàn burúkú lẹ́jọ́ lóòótọ́, kí nìdí tí kò fi tíì dá wọn lẹ́jọ́ ọ̀hún títí di báyìí?

Olú: Òótọ́ ni. Àwọn ìbéèrè yẹn ṣe pàtàkì.

Kọ́lá: Bóyá tó bá di ìgbà míì, màá fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yẹn hàn yín. *

Olú: Ẹ ṣeun gan-an ni. Inú mi á dùn láti mọ ìdáhùn ìbéèrè wọ̀nyẹn.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.