Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn

Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ó Kọ́kọ́ Ṣàìgbọràn àmọ́ Nígbà Tó Yá Ó Ṣègbọràn

ǸJẸ́ o ti ṣàìgbọràn rí, tí o kò gbọ́ràn sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu? * Bóyá o wo eré kan lórí tẹlifíṣọ̀n tí ìyá rẹ tàbí bàbá rẹ sọ pé o kò gbọ́dọ̀ wò. Bóyá nígbà tí o wò ó tán, ó wá ń dùn ọ́ pé o ti ṣàìgbọràn. Ẹnì kan náà wà tí kò ṣègbọràn nígbà àkọ́kọ́. Náámánì ni orúkọ rẹ̀. Jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe ràn án lọ́wọ́ tó fi lè ṣègbọràn.

Ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni ọkùnrin tó ń jẹ́ Náámánì gbé láyé. Ó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Síríà. Torí ipò rẹ̀, òun ló máa ń sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ohun tí wọ́n máa ṣe, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é. Àmọ́ ṣá o, Náámánì ní àrùn burúkú kan tí wọ́n ń pè ní ẹ̀tẹ̀. Àrùn náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́ gan-an, ó sì tún lè máa dùn ún gan-an.

Ìyàwó Náámánì ní ìránṣẹ́bìnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin yìí sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Èlíṣà wà ní ìlú òun. Ó ní ọkùnrin náà lè wo Náámánì sàn. Nígbà tí Náámánì gbọ́ ohun tí ọmọbìnrin yìí sọ, kíákíá ló múra láti lọ sọ́dọ̀ Èlíṣà. Ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn dání, òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ó kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì láti lọ sọ ìdí tí òun fi wá síbẹ̀ fún un.

Nígbà tí Èlíṣà gbọ́, ó ránṣẹ́ pé kí ọba sọ fún Náámánì pé kó wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí Náámánì dé ilé Èlíṣà, ṣe ni Èlíṣà rán ìránṣẹ́ kan sí Náámánì pé kó sọ fún un pé kó lọ wẹ̀ ní ìgbà méje nínú Odò Jọ́dánì. Èlíṣà sọ pé tí Náámánì bá ti wẹ̀ bẹ́ẹ̀ tán, ara rẹ máa dá. Ǹjẹ́ o rò pé inú Náámánì dùn nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí?

Rárá o, ṣe ni Náámánì bínú. Torí náà, ó ṣàìgbọràn, ó sì kọ̀ láti ṣe ohun tí wòlíì Ọlọ́run sọ pé kó ṣe. Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé: ‘Àwọn odò tó dára ju odò Jọ́dánì lọ wà ní orílẹ̀-èdè wa tí mo lè lọ wẹ̀ níbẹ̀.’ Náámánì wá fẹ́ máa pa dà lọ sílé. Àmọ́, ṣé o mọ ohun tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún un?— Wọ́n sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ ohun ńlá kan ni wòlíì náà sọ pé kó o ṣe, ṣebí wàá ṣe é. Kí ló dé tí o kò fi ṣègbọràn kí o sì ṣe ohun kékeré tó ní kí o ṣe yìí?’

Náámánì gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ fún un, ó sì lọ wẹ̀ nínú odò náà. Ìgbà mẹ́fà ló bẹ́ sínú odò náà tó sì ń jáde. Nígbà tó máa jáde nínú odò ní ìgbà keje, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó ya Náámánì lẹ́nu. Àrùn ẹ̀tẹ̀ tó wà ní ara rẹ̀ ti kúrò pátápátá! Ara rẹ̀ sì ti yá! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rin ìrìn àjò nǹkan bí kìlómítà méjìdínláàádọ́ta [48] pa dà lọ sí ilé Èlíṣà, láti lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó fẹ́ fún Èlíṣà ní àwọn ẹ̀bùn tí owó rẹ̀ pọ̀ gan-an, àmọ́ wòlíì náà kò gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

Torí náà, Náámánì tọrọ ohun kan lọ́wọ́ Èlíṣà. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó tọrọ?— Ó ní: ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n bu erùpẹ̀ ilẹ̀ Ísírẹ́lì dání lọ sí ilé mi, kí ó pọ̀ tó ẹrù tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì máa gbé.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fẹ́ fi ṣe?— Náámánì sọ pé òun fẹ́ máa rú ọrẹ ẹbọ sí Ọlọ́run lórí ilẹ̀ tí òun bù láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Náámánì wá ṣe ìlérí pé òun kò ní sin òrìṣà kankan mọ́, pé Jèhófà ni òun yóò máa sìn! Kò ṣàìgbọràn mọ́, ó fẹ́ máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run tòótọ́.

Ṣé o mọ bí ìwọ náà ṣe lè ṣe bíi ti Náámánì?— Tí o bá ṣẹlẹ̀ pé o ṣàìgbọràn bíi ti Náámánì, ìwọ náà lè yí pa dà. O lè gba ìrànlọ́wọ́, kí o má sì ṣàìgbọràn mọ́.

Kà á nínú Bíbélì rẹ

2 Àwọn Ọba 5:1-19

Lúùkù 4:27

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.