Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàyé Nípa Oríṣiríṣi Àwọ̀ àti Aṣọ Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Àlàyé Nípa Oríṣiríṣi Àwọ̀ àti Aṣọ Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Àlàyé Nípa Oríṣiríṣi Àwọ̀ àti Aṣọ Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

BÍBÉLÌ sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn aṣọ tí àwọn èèyàn ayé àtijọ́ máa ń wọ̀, àwọ̀ àwọn aṣọ náà àti ohun tí wọ́n fi ṣe wọ́n.

Lóòótọ́ Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra àwọn èèyàn. Síbẹ̀ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ìtàn inú Bíbélì mẹ́nu kàn máa ń jẹ́ kí ẹni tó bá ń kà á lè fojú inú yàwòrán ohun tó ń kà.

Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ ohun tí Ádámù àti Éfà ta mọ́ra bíi bàǹtẹ́ láti fi bo ìhòòhò ara wọn, ìyẹn ewé ọ̀pọ̀tọ́ tí wọ́n gán pọ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, Ọlọ́run pèsè ‘ẹ̀wù awọ gígùn’ tó lálòpẹ́ fún wọn kí wọ́n fi rọ́pò ewé yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 21.

Ìwé Ẹ́kísódù orí 28 àti 39 ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa aṣọ tí olórí àlùfáà máa ń wọ̀ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lára rẹ̀ ni ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe, aṣọ funfun, ìgbàjá tí wọ́n hun, aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá aláwọ̀ búlúù, éfódì àti ìgbàyà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí àti láwàní tó ní àwo wúrà tó ń tàn yinrin. Téèyàn bá ń ka àlàyé nípa bí wọ́n ṣe lo onírúurú ohun èlò tó ṣeyebíye láti fi ṣe aṣọ yìí, ó lè jẹ́ kéèyàn mọ bí aṣọ yìí ṣe máa dùn-ún wò tó.—Ẹ́kísódù 39:1-5, 22-29.

Aṣọ wòlíì Èlíjà ṣàrà ọ̀tọ̀ débi pé ìrísí rẹ̀ tí ẹnì kan ṣàpèjúwe lásán làwọn èèyàn fi mọ̀ kíákíá pé òun ni. Ohun tí ẹni náà sọ ni pé: “Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀wù tí a fi irun ṣe, tí ó sì fi ìgbànú awọ di abẹ́nú rẹ̀ lámùrè ni.” Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn kan rò pé Jòhánù Oníbatisí ni Èlíjà, bóyá torí pé aṣọ wọn jọra.—2 Àwọn Ọba 1:8; Mátíù 3:4; Jòhánù1:21.

Onírúurú Aṣọ àti Àwọ̀ Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa irú àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣe aṣọ, onírúurú àwọ̀ àti èròjà tí wọ́n fi ń pa aṣọ láró, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ríran òwú, híhun aṣọ àti rírán aṣọ. * Àwọn aṣọ tí Bíbélì mẹ́nu kàn sábà máa ń jẹ́ aṣọ onírun, èyí tí wọ́n máa ń rí lára ẹran ọ̀sìn tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ń fi ewéko ọ̀gbọ̀ ṣe. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé Ébẹ́lì jẹ́ “ẹni tí ń da àgùntàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:2) Bóyá ńṣe ni Ébẹ́lì ń sin àwọn àgùntàn nítorí kó lè rí irun wọn tí yóò fi ṣe òwú ni o, Bíbélì kò sọ. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kan aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà ni ìgbà tó sọ̀rọ̀ nípa aṣọ tí Fáráò fi wọ Jósẹ́fù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jẹ́nẹ́sísì 41:42) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí Bíbélì ti sọ ọ̀rọ̀ pé àwọn Júù wọ aṣọ tí wọ́n fi fọ́nrán òwú láti ara èso òwú ṣe, àmọ́ àwọn ará Àárín Ìlà-oòrùn máa ń lo irú aṣọ yẹn láyé àtijọ́.

Wọ́n máa ń rí fọ́nrán tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ lára pòròpórò ọ̀gbọ̀ àti lára irun ẹran, èyí tí wọ́n máa ń ran láti fi ṣe fọ́nrán òwú lóríṣiríṣi. Àwọn fọ́nrán òwú yìí ni wọ́n máa fi ń hun aṣọ. Wọ́n máa ń pa fọ́nrán òwú yẹn àti aṣọ tí wọ́n hun ní aró onírúurú àwọ̀ tó bá wù wọ́n. Lẹ́yìn ìyẹn, wọn á wá gé aṣọ yẹn lọ́nà tó máa bá ẹni tó fẹ́ lò ó mu. Wọ́n sábà máa ń fi àwọn fọ́nrán òwú tó ní àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kó iṣẹ́ sí ara aṣọ, èyí sí máa ń mú kí àwọn aṣọ náà lẹ́wà kí ó sì jojú ní gbèsè.—Àwọn Onídàájọ́ 5:30.

Bíbélì sábà máa ń sọ ọ́ pé wọ́n fi àwọ̀ búlúù, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pípọ́n dòdò pa aṣọ tàbí fọ́nrán òwú láró. Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fi “okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè ìṣẹ́tí apá gbígbárìyẹ̀” lára aṣọ wọn, kí èyí lè máa rán wọn létí pé wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ kan pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run wọn. (Númérì 15:38-40) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tekhelet, ìyẹn oríṣi àwọ̀ búlúù kan àti ọ̀rọ̀ náà argaman, èyí tí wọ́n sábà máa túmọ̀ sí “àwọ̀ àlùkò,” ni àwọ̀ tí wọ́n sábà máa ń sọ pé aṣọ àlùfáà àgbà ní àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú àgọ́ ìjọsìn àti ti tẹ́ńpìlì.

Àgọ́ Ìjọsìn Àtàwọn Ohun Ọ̀ṣọ́ Tẹ́ńpìlì Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn, àmọ́ tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn ní Jerúsálẹ́mù. Abájọ tó fi jẹ́ pé Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe àwọn nǹkan èlò àgọ́ ìjọsìn àti ti tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́, àti bí wọ́n ṣe máa gbé e kalẹ̀. Yàtọ̀ sí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí a rí nípa àwọn nǹkan tí wọ́n máa fi ṣe aṣọ ìkélé àti aṣọ tí wọ́n máa fi bo àgọ́ ìjọsìn àti àwọ̀ wọn, a tún rí àlàyé nípa bí wọ́n ṣe máa hun àwọn aṣọ náà, bí wọ́n ṣe máa pa á láró, bí wọ́n ṣe máa rán an àti bí wọ́n ṣe máa kó iṣẹ́ sí i lára.

Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, àwọn àgbà oníṣẹ́ ọ̀nà kan, ìyẹn Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù àti àwọn míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ bàǹtàbanta kan, ìyẹn kíkọ́ àgọ́ kan tí wọ́n lè máa lò fún ìjọsìn Jèhófà. (Ẹ́kísódù 35:30-35) A rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nínú ìwé Ẹ́kísódù orí 26 nípa àwọn ohun èlò tí wọ́n lò àti bí wọ́n ṣe kọ́ àgọ́ ìjọsìn náà látòkè délẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, “aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà lílọ́ àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì” ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ àgọ́ ìjọsìn tó rí gbàràmù-gbaramu tó sì láwọ̀ mèremère. Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan èlò yìí ló jẹ́ èyí tí wọ́n kó wá láti Íjíbítì nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè yẹn. Ọ̀nà àrà-ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbà ṣe aṣọ ìkélé aláwọ̀ mèremère tó nípọn, tí wọ́n ṣe àwòrán àwọn kérúbù sí lára, èyí tí wọ́n fi pààlà “Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ” nínú àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kísódù 26:1, 31-33) Gbogbo irú kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí náà ni wọ́n sọ fún àwọn tó ṣe àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣe tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́, lábẹ́ ìdarí Sólómọ́nì Ọba.—2 Kíróníkà 2:1, 7.

Látinú àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tí a rí nínú Bíbélì, ó hàn kedere pé àwọn Hébérù ìgbàanì lo ìdánúṣe àti ọgbọ́n orí tó ga láti fi lo àwọn ohun èlò tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn dáadáa. Èyí jẹ́ ká rí i pé wọ́n kì í kàn ṣe àwùjọ èèyàn kan tó ń ráágó kiri nínú aṣọ àkísà aláwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀ kan. Àmọ́ wọ́n jẹ́ àwùjọ èèyàn tó gbọ́ fáàrí, tí wọ́n ń wọ aṣọ onírúurú ọnà àti àwọ̀ tó gbayì, èyí tí wọ́n ń lò fún onírúurú ìgbà àti àsìkò, bí ojú ọjọ́ bá ṣe rí àti ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí agbára wọn bá ká.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ilẹ̀ dáradára, “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin” kí wọ́n máa gbé ibẹ̀. (Ẹ́kísódù 3:8; Diutarónómì 26:9, 15) Bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà, ó ń bù kún wọn. Gbogbo nǹkan ń rọ̀ṣọ̀mù fún wọn, wọ́n ń láyọ̀, ọkàn wọn sì balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé: “Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì [Ọba].”—1 Àwọn Ọba 4:25.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé sí i lórí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Irun Ẹran Ọ̀sìn àti Ọ̀gbọ̀

Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé torí wàrà àti irun àgùntàn tí wọ́n máa rí lára àgùntàn, ni wọ́n ṣe ń sìn ín. Àgbẹ̀ máa ń rí irun àgùntàn tó pọ̀ tó láti fi ṣe aṣọ fún gbogbo ìdílé rẹ̀ láti ara àgùntàn mélòó kan péré. Tí àgbẹ̀ kan bá sì ní àgùntàn tó pọ̀, ó lè ta ìyókù nínú irun àgùntàn rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe aṣọ ládùúgbò rẹ̀. Àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé míì tiẹ̀ máa ń ní ẹgbẹ́ àwọn aláṣọ. Látayébáyé ni rírẹ́ irun àgùntàn sì ti di ara iṣẹ́ tí àwọn èèyàn yẹn sábà máa ń ṣe lọ́dọọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 31:19; 38:13; 1 Sámúẹ́lì 25:4, 11.

Fọ́nrán òwú tí wọ́n máa ń rí lára pòròpórò ọ̀gbọ̀ ni wọ́n fi ń ṣe aṣọ ọ̀gbọ̀. (Ẹ́kísódù 9:31) Tí koríko ọ̀gbọ̀ bá ti gbó ni wọ́n máa ń gé pòròpórò rẹ̀. Wọ́n á wá sá a sóòrùn kó lè gbẹ, wọ́n á sì kó o sínú omi kí ibi tó bá le lára rẹ̀ lè rọ̀ dáadáa. Tó bá ti gbẹ́, wọ́n á fi nǹkan lù ú, wọ́n á wá yọ àwọn fọ́nrán ara rẹ̀, wọ́n á ran án láti fi ṣe fọ́nrán òwú tí wọ́n máa fi hun aṣọ. Àwọn ọmọ aládé àti àwọn aláṣẹ onípò gíga sábà máa ń fẹ́ láti máa lo aṣọ tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.

[Àwòrán]

Ọ̀gbọ̀ tó ti gbẹ rèé kí wọ́n tó rẹ ẹ́ sómi

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ríran Òwú

Fọ́nrán okùn ọ̀gbọ̀ kan, fọ́nrán irun àgùntàn kan tàbí ti ewúrẹ́ ti kéré jù, ó sì tín-ínrín jù láti lò. Torí náà, ọ̀pọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ní láti lọ́ pọ̀ mọ́ra, ìyẹn ni pé wọ́n á ran án láti fi ṣe fọ́nrán òwú tó máa nípọn tó sì máa gùn tó béèyàn ṣe fẹ́. Bíbélì sọ nípa “aya tí ó dáńgájíá” pé: “Ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀pá ìrànwú, ọwọ́ tirẹ̀ sì di ìrànwú mú.” (Òwe 31:10, 19) Èyí jẹ́ àpèjúwe bí wọ́n ṣe máa ń lo igi tẹ́ẹ́rẹ́ méjì, ìyẹn ọ̀pá ìrànwú àti ìrànwú láti fi ran òwú.

Tí obìnrin kan bá fẹ́ rànwú, yóò fi ọwọ́ kan di ọ̀pá ìrànwú mú, èyí tí òwú tó fẹ́ ran wà lára rẹ̀. Yóò wá máa fi ọwọ́ kejì fa òwú tí ó bá fẹ́ ran, yóò lọ́ ọ pọ̀ sí fọ́nrán òwú, yóò wá fi kọ́ ara ìrànwú lápá ìsàlẹ̀ kó lè lọ́ mọ́ ọn. Yóò kan igi pẹlẹbẹ kan tó ṣe róbótó mọ́ orí ìrànwú náà, kó fi lè máa yí bírí. Yóò di fọ́nrán òwú tó wà lára ìrànwú mú, yóò sì wá ta ìrànwú náà bí òkòtó. Jíjó tó ń jó ran-in ni yóò máa ran òwú náà sí bó ṣe fẹ́ kó nípọn tó. Fọ́nrán òwú náà yóò sì máa wé mọ́ ara ìrànwú náà. Bí obìnrin náà yóò ṣe máa ṣe nìyẹn títí yóò fi ran gbogbo òwú ara ọ̀pá ìrànwú di fọ́nrán òwú gígùn, tí wọ́n máa pa láró tàbí tí wọ́n á fi hun aṣọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Pípa Òwú àti Aṣọ Láró

Lẹ́yìn tí wọ́n bá ran òwú tán, tí wọ́n sì fọ̀ ọ́, wọ́n á wá rẹ fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ àti ti irun ẹran náà, tàbí aṣọ tí wọ́n fi hun, sínú aró tó ní àwọ̀ tí wọ́n bá fẹ́. Bí wọ́n bá ṣe rẹ ẹ́ sínú aró púpọ̀ tó, ló ṣe máa gbé àwọ̀ náà yọ dáadáa tó. Nítorí pé aró wọ́n gan-an, tí wọ́n bá ti kó aṣọ tàbí òwú jáde nínú ibi tí wọ́n ti ń pa á láró, wọ́n máa ń fún un dáadáa kí wọ́n lè tún aró tí wọ́n fún jáde lára rẹ̀ ló nígbà míì. Lẹ́yìn èyí, wọ́n á wá sá aṣọ náà kó lè gbẹ.

Torí pé àwọn ọ̀nà àgbélẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé onírúurú àwọ̀ jáde lòde òní kò tíì sí láyé àtijọ́, ńṣe làwọn èèyàn yẹn máa ń dá ọgbọ́n tí wọ́n fi ń rí aró ní onírúurú àwọ̀ láti ara àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí àti ewéko. Wọ́n máa ń rí àwọ̀ yẹ́lò láti ara ewé álímọ́ńdì tàbí láti ara èèpo èso pómégíránétì tí wọ́n lọ̀, wọ́n sì máa ń rí aró aláwọ̀ dúdú láti ara èèpo igi pómégíránétì. Wọ́n máa ń rí aró pupa láti ara gbòǹgbò igi madder tàbí láti ara kòkòrò kókọ́sì. Wọ́n sì máa ń rí aró aláwọ̀ búlúù láti ara òdòdó ẹ̀lú. Ara irú àwọn ìṣáwùrú òkun kan ni wọ́n ti ń rí oríṣiríṣi aró bí aró aláwọ̀ àlùkò, aláwọ̀ búlúù àti aláwọ̀ pípọ́n dòdò.

Ìṣáwùrú òkun mélòó ni wọ́n máa nílò kí wọ́n tó lè rí aró tó máa tó ṣe aṣọ kan ṣoṣo? Ẹ̀kán omi aró tín-ń-tín ni wọ́n máa ń rí nínú ìṣáwùrú kọ̀ọ̀kan. Ìwádìí sì fi hàn pé, wọ́n máa nílò nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ìṣáwùrú kí wọ́n tó lè rí omi aró tó máa tó láti pa ẹ̀wù kan tàbí aṣọ kan láró tó fi máa di aṣọ aláwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa tí àwọn ọmọ aládé sábà máa ń lò. Nígbà ìjọba Nábónídọ́sì ọba Bábílónì, owó aṣọ tí wọ́n bá fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró máa ń fi ìlọ́po ogójì ju èyí tí wọ́n kàn fi àwọ̀ míì pa láró lọ. Bó ṣe jẹ́ pé ìlú Tírè ìgbàanì gbajúmọ̀ nídìí ṣíṣe òwò aró olówó gọbọi yìí, àwọ̀ àlùkò di èyí tí wọ́n wá ń pè ní àwọ̀ àlùkò ìlú Tírè.

[Àwòrán]

Ìkarawun ìṣáwùrú òkun

Ibi tí wọ́n tí ń ṣe aró aláwọ̀ àlùkò ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìkẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tí wọ́n rí nílùú Dórì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì

[Credit Line]

The Tel Dor Project

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Híhun Aṣọ

Òfì ni wọ́n sábà máa fi ń hun fọ́nrán òwú títí yóò fi di aṣọ. Aṣọ yẹn máa ń fẹ̀ tó èyí tí wọ́n lè fi ṣe ẹ̀wù tàbí nǹkan míì. Tí wọ́n bá fẹ́ hun aṣọ, wọ́n máa ń ta fọ́nrán òwú wọ inú apásá tó ní ihò kéékèèké, yóò sì wà ní ìdúró gbọọrọ. Wọ́n á wá máa fi ohun tí a ń pè ní ọ̀kọ̀ fa oríṣi òwú míì kọjá sọ́tùn-ún-sósì gba àárín òwú apásá títí wọ́n fi máa hun aṣọ náà tán.

Òfì tí wọ́n ń lò láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì sábà máa ń jẹ́ igi gbọọrọ tí wọ́n gbé sílẹ̀ tàbí èyí tí wọ́n gbé dúró lóròó. Nígbà míì wọ́n máa ń gbé nǹkan tó wúwo sórí òkùkù tí wọ́n so àwọn fọ́nrán òwú apásá mọ́. Àwọn ibi tó pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti rí ohun tí àwọn olófì ayé àtijọ́ máa ń gbé sórí òkùkù wọn.

Aṣọ híhun sábà máa ń jẹ́ ara iṣẹ́ ilé kọ̀ọ̀kan, àmọ́ láwọn ibòmíì, gbogbo abúlé ló jọ máa ń ṣeé pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé 1 Kíróníkà 4:21, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa “ilé àwọn oníṣẹ́ aṣọ híhun àtàtà,” èyí ti ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

“Òwú aláwọ̀ búlúù àti irún àgùntàn ti a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.”—Ẹ́kísódù 26:1