Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orúkọ Ọlọ́run àti Ìsapá Alfonso de Zamora Láti Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Péye

Orúkọ Ọlọ́run àti Ìsapá Alfonso de Zamora Láti Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Péye

Orúkọ Ọlọ́run àti Ìsapá Alfonso de Zamora Láti Túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Péye

NÍ ỌDÚN 1492, Ferdinand tó jẹ́ ọba orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Isabella tó jẹ́ ọbabìnrin orílẹ̀-èdè Sípéènì pàṣẹ pé: “Kí gbogbo Júù lọ́kùnrin àti lóbìnrin . . . kúrò ní àwọn ìlú tí à ń ṣàkóso tó bá fi máa di ìparí oṣù July ọdún yìí, pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn àti àwọn ẹrúkùnrin àti àwọn ẹrúbìnrin wọn láìṣẹ́ ku ẹnì kan, títí kan ẹni ńlá àti kékeré, láìka ọjọ́ orí sí, wọn kò sì gbọ́dọ̀ pa dà wá mọ́.”

Àmọ́ ṣá o, nínú àṣẹ yẹn, wọ́n tún fún àwọn Júù tó ń gbé orílẹ̀-èdè Sípéènì ní àǹfààní láti pinnu láti kúrò ní ìlú tàbí láti yìí ẹ̀sìn wọn pa dà. Rábì kan tó ń jẹ́ Juan de Zamora lè ti da ọ̀rọ̀ náà rò pé, ó máa dára kí òun yí ẹ̀sìn òun pa dà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì kí òun sì dúró sí orílẹ̀-èdè Sípéènì, níbi tí àwọn baba ńlá òun ti ń gbé látọjọ́ pípẹ́. Nítorí pé ọkùnrin yìí jẹ́ Júù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ tó lókìkí tí wọ́n ti ń kọ́ èdè Hébérù ní ìlú kan tó ń jẹ́ Zamora ni ọkùnrin yìí rán ọmọkùnrin rẹ̀ tó ń jẹ́ Alfonso lọ. Nígbà tó yá, Alfonso di ògbóǹkangí nínú èdè Látìn, Gíríìkì àti èdè Árámáíkì. Nígbà tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èdè Hébérù ní Yunifásítì tó wà ní ìlú Salamanca. Nígbà tó yá, àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì tí wọ́n ń gbé káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù jàǹfààní ìmọ̀ èdè tí ọ̀gbẹ́ni yìí ní.

Ní ọdún 1512, Yunifásítì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ìlú Alcalá de Henares yan ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora sípò ọ̀gá àgbà ẹ̀kọ́ èdè Hébérù. Nítorí pé ọ̀gbẹ́ni Zamora jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé tó jẹ́ òléwájú nígbà ayé rẹ̀, Kádínà Jiménez de Cisneros, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ yunifásítì náà, sọ pé kí ó wá ṣèrànwọ́ láti ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta lórí Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ń jẹ́ Complutensian Polyglot. Bíbélì onídìpọ̀ mẹ́fà yìí jẹ́ Ìwé Mímọ́ ní èdè Hébérù, Gíríìkì, Látìn àti apá kan ní èdè Árámáíkì. *

Ọ̀gbẹ́ni Mariano Revilla Rico tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ yìí pé: “Nínú àwọn Júù mẹ́ta tí wọ́n yí ẹ̀sìn wọn pa dà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Kádínà [Cisneros], ẹni tó lókìkí jù lọ lára wọn ni ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora, yàtọ̀ sí pé ọ̀gbẹ́ni yìí jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú èdè Látìn, Gíríìkì, Hébérù àti Árámáíkì, ó tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú ìlò èdè, nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti nínú ìmọ̀ ìwé Támọ́dì.” Látinú àwọn ìwádìí tí ọ̀gbẹ́ni Zamora ṣe, ó rí i pé, kéèyàn tó lè túmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó péye, èèyàn ní láti ní òye tó jinlẹ̀ nípa àwọn èdè àtijọ́ tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Kódà, ọ̀gbẹ́ni yìí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn alátìlẹyìn fún ìmọ̀ Bíbélì èyí tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún.

Àmọ́, àkókò tó nira láti gbé ìmọ̀ Bíbélì lárugẹ àti ibi tó léwu láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ọ̀gbẹ́ni Zamora ń gbé. Lákòókò yẹn, Ìgbìmọ̀ Tó Ǹ Gbógun Ti Àdámọ̀ Nílẹ̀ Sípéènì ń ṣọ́ ohun gbogbo tọ́wọ́ tẹsẹ̀, bákan náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì “pàṣẹ” pé, Bíbélì Vulgate lédè Látìn nìkan ni Bíbélì tí àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa lò. Àmọ́, láti Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú ni àwọn ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì ti kíyè sí i pé, Bíbélì Vulgate lédè Látìn kò péye. Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora àti àwọn kan fẹ́ ṣe nǹkan kan sí ọ̀ràn náà.

‘Kí Ìgbàlà Tó Ṣeé Ṣe, A Nílò Ìtumọ̀ Èdè’

Kò sí àní-àní pé, lára iṣẹ́ tí ọ̀gbẹ́ni Zamora ṣe tó gbawájú jù lọ ni àtúnṣe tó ṣe sí apá Bíbélì tí wọ́n kọ lédè Hébérù, èyí tí àwọn èèyàn ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé” àti ìtúmọ̀ rẹ̀ lédè Látìn. Ó ṣeé ṣe kó ní in lọ́kàn láti lo àtúnṣe yìí fún Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ń jẹ́ Complutensian Polyglot tí wọ́n fẹ́ ṣe. Ọ̀kan lára àwọn ìwé àfọwọ́kọ rẹ̀ wà ní Ilé Ìkówèésí ti El Escorial tó wà ní ìtòsí ìlú Madrid, lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ohun tí wọ́n kọ sí ibi tí wọ́n kó o sí ni G-I-4, ó ní gbogbo ìwé Jẹ́nẹ́sísì ní èdè Hébérù, bákan náà, ó ní ìtumọ̀ ti èdè Látìn, ìtumọ̀ yẹn sì jẹ́, ọ̀rọ̀ Hébérù kan fún ọ̀rọ̀ Látìn kan.

Ọ̀rọ̀ kan wà lára ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú rẹ̀ tó sọ pé: “Kí àwọn orílẹ̀-èdè tó lè rí ìgbàlà, a ní láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí àwọn èdè míì. . . . A ti gbé e yẹ̀ wò . . . ó pọn dandan pé kí àwọn olóòótọ́ ní Bíbélì tí a túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, tí a ṣe lọ́nà tó jẹ́ pé, a túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù kan sí ọ̀rọ̀ Látìn kan.” Ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora kúnjú ìwọ̀n láti túmọ̀ Bíbélì láti èdè Hébérù sí Látìn lákọ̀tun, torí pé àwọn èèyàn gbà pé ọ̀mọ̀wé nípa èdè Hébérù ni.

‘Ọkàn Mi Kò Balẹ̀ Rárá’

Lọ́nà kan, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, orílẹ̀-èdè Sípéènì ni ibi tó dára jù lọ fún àwọn ọ̀mọ̀wé bí ọ̀gbẹ́ni Zamora láti ṣe iṣẹ́ wọn. Ní Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú, orílẹ̀-èdè Sípéènì ti di ibi tí àṣà àwọn Júù ti gbilẹ̀ gan-an. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopae Britannica sọ pé: “Nítorí pé àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Júù pọ̀ níbẹ̀, orílẹ̀-èdè Sípéènì nìkan ni orílẹ̀-èdè tó ní oríṣiríṣi àṣà àti ẹ̀sìn ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù, àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sì fi kún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Sípéènì nínú ẹ̀sìn, ìwé, iṣẹ́ ọnà àti yíya àwòrán ilé ní apá tó gbẹ̀yìn Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú.”

Nítorí pé àwọn Júù pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì, ẹ̀dà Bíbélì èdè Hébérù tí wọ́n fọwọ́ kọ wọ́pọ̀ gan-an níbẹ̀. Àwọn Júù tó jẹ́ akọ̀wé tó wà lápá ibi púpọ̀ lórílẹ̀-èdè Sípéènì ti ṣakitiyan láti fi ọwọ́ kọ àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ fún kíkà nínú Sínágọ́gù. Ọ̀gbẹ́ni L. Goldschmidt, sọ nínú ìwé The Earliest Editions of the Hebrew Bible, tó kọ, ó ní, “kì í ṣe ìwé Bíbélì márùn-ún àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ lédè Sípáníìṣì àti Potogí nìkan làwọn Ọ̀mọ̀wé Júù gbà pé ó péye, wọ́n tún gbà pé àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n fi ṣe wọ́n àti èyí tí wọ́n fi ṣe Bíbélì Elédè Púpọ̀ náà péye.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Sípéènì ṣí àǹfààní tó pọ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ yìí, síbẹ̀ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko àwọn tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì náà. Ní ọdún 1492, àwọn ọmọ ogun Kátólíìkì tí wọ́n ń jà fún Ọba Ferdinand àti Ọbabìnrin Isabella ṣẹ́gun àgbègbè tó kẹ́yìn níbi tí àwọn Mùsùlùmí ń gbé ní orílẹ̀-èdè Sípéènì. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, ọdún yẹn ni àwọn ọba yìí pàṣẹ pé kí àwọn tó bá ń ṣe ẹ̀sìn Júù kúrò ní orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n pa irú àṣẹ yìí fún àwọn Mùsùlùmí. Láti ìgbà yẹn, Kátólíìkì ni ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè Sípéènì, wọn kò sì fàyè gba àwọn ẹ̀sìn míì mọ́.

Ipa wo ni àìfàyè gba àwọn ẹ̀sìn míì yìí lè ní lórí ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n fẹ́ ṣe? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora jẹ́ àpẹẹrẹ ipa tí ọ̀ràn náà ní lórí ìtumọ̀ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé tó jẹ́ Júù yìí ti yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà sí Kátólíìkì, síbẹ̀ àwọn aláṣẹ Sípéènì kò fara mọ́ ọn torí pé ọmọ Júù ni. Àwọn alátakò kan tiẹ̀ ta ko Kádínà Cisneros torí pé ó lo àwọn ọmọ Júù tó di Kátólíìkì láti ṣe iṣẹ́ Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó fẹ́ ṣe. Àtakò yìí kó wàhálà tó pọ̀ bá ọ̀gbẹ́ni Zamora. Nínú ìwé àfọwọ́kọ kan tó wà ní Yunifásítì ìlú Madrid, ọ̀gbẹ́ni Zamora kédàárò pé: “Èmi, . . . gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi pa mí tì, wọ́n sì kórìíra mi, ìyẹn àwọn tó ti wá di ọ̀tá mi, ọkàn mi kò balẹ̀ rárá.”

Ọ̀kan lára àwọn olórí ọ̀tá ọ̀gbẹ́ni Zamora ni ọ̀gbẹ́ni Juan Tavera tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà Toledo tó wá di ọ̀gá àgbà Ìgbìmọ̀ Tó Ǹ Gbógun Ti Àdámọ̀ Nílẹ̀ Sípéènì. Àtakò ọ̀gbẹ́ni Tavera kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ̀gbẹ́ni Zamora débi pé, ó ké gbàjarè sí póòpù. Apá kan lẹ́tà tó kọ sọ pé: “A bẹ̀bẹ̀ pé kí o ràn wá lọ́wọ́ Ẹni Mímọ́ . . . kí o sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀tá wa, ìyẹn ọ̀gbẹ́ni Don Juan Tavera tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Toledo. Ojoojúmọ́ ló máa ń fa ọ̀pọ̀ ìnira fún wa. . . . A wà nínú ìnira tó gá, torí pé lójú rẹ̀, ńṣe la dàbí ẹranko tí wọ́n ń mú lọ pa. . . . Bí ìwọ Ẹni Mímọ́ bá fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀bẹ̀ wa yìí, ‘Yáwè yóò dáàbò bò ẹ́, kì yóò sì jẹ́ kí wọ́n gba ẹsẹ̀ rẹ mú.’ (Òwe 3:23)” *

Ogún Tí Alfonso de Zamora Fi Sílẹ̀

Láìka àtakò yìí sí, ọ̀gbẹ́ni Zamora ń bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó, ó sì ṣe é láṣeyọrí fún àǹfààní ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí àwọn èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ nígbà ayé rẹ̀, àmọ́ ó ṣe ìrànlọ́wọ́ tó ṣeyebíye fún àwọn atúmọ̀ èdè míì. Kí á lè lóye ipa tí ọ̀gbẹ́ni yìí kó, ó yẹ ká rántí pé iṣẹ́ àwùjọ ọ̀mọ̀wé méjì ṣe pàtàkì kí Bíbélì tó lè ṣeé túmọ̀ sí èdè míì. Àkọ́kọ́, a nílò àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ èdè Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì tó jẹ́ èdè tí wọ́n fi kọ àwọn Ìwé Mímọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ síyẹn, tí wọ́n á tún lè ṣe àtúnṣe tó péye sáwọn èdè yìí. Èkejì ni pé, a nílò atúmọ̀ èdè tó máa wá lo iṣẹ́ yìí láti fi ṣe ìtumọ̀ sí èdè ìbílẹ̀ míì.

Ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora jẹ́ òléwájú nínú àwọn ọ̀mọ̀wé tó ṣàtúnṣe àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ lédè Hébérù tí wọ́n wá tẹ̀ jáde nínú Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ń jẹ́ Complutensian Polyglot lọ́dún 1522. (Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti Látìn tó lò àti gírámà Hébérù tó lò nínú ìwé yìí tún mú kí iṣẹ́ àwọn atúmọ̀ èdè rọrùn.) Ọ̀gbẹ́ni Erasmus tí òun náà gbé láyé lákòókò ọ̀gbẹ́ni Zamora, náà ṣe ohun tó jọ ìyẹn lórí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, èyí tí àwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Bí àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí Ìwé Mímọ́ ní èdè Hébérù àti Gíríìkì yìí ti wà nílẹ̀, èyí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn atúmọ̀ èdè láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bàǹtàbanta láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè tí àwọn èèyàn ń sọ. Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni William Tyndale túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó jẹ́ ọ̀kan lára atúmọ̀ èdè tó kọ́kọ́ lo apá tí wọ́n kọ lédè Hébérù nínú Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ń jẹ́ Complutensian Polyglot.

Akitiyan àwọn èèyàn bí ọ̀gbẹ́ni Zamora ló mú kí Bíbélì di èyí tó wà káàkiri lóde òní, àwọn èèyàn yìí fi ìgbésí ayé wọn ṣe iṣẹ́ tó mú kí òye wa nípa Ìwé Mímọ́ túbọ̀ pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Zamora ti sọ, kí àwọn èèyàn tó lè rí ìgbàlà, wọ́n ní láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa fi í sílò. (Jòhánù 17:3) Ìyẹn sì gba pé kí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí èdè tí àwọn èèyàn lóye, torí ìgbà yẹn nìkan ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tó lè wọ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́kàn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí bí Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ń jẹ́ Complutensian Polyglot ti ṣe pàtàkì tó, ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2004, ojú ìwé 28 sí 31.

^ Ó dùn mọ́ni pé ọ̀gbẹ́ni Zamora lo orúkọ Ọlọ́run gangan dípò orúkọ oyè rẹ̀ nínú lẹ́tà ẹ̀bẹ̀ tó kọ sí póòpù ilẹ̀ Róòmù. “Yáwè” ni wọ́n pe orúkọ Ọlọ́run nínú lẹ́tà ẹ̀bẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Zamora tí wọ́n tú sí èdè Sípáníìṣì. A kò lè sọ bí wọ́n ṣe kọ ọ́ ní èdè Látìn tí wọ́n fi kọ lẹ́tà náà. Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí iṣẹ́ ìtumọ̀ tí ọ̀gbẹ́ni Zamora ṣe àti bó ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, wo àpótí náà, “Títúmọ̀ Orúkọ Ọlọ́run” lójú ìwé 19.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Títúmọ̀ Orúkọ Ọlọ́run

Ó dùn mọ́ni láti mọ bí ọ̀gbẹ́ni Alfonso de Zamora, ọ̀mọ̀wé tó jẹ́ Hébérù ṣe túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán tó wà lójú ìwé yìí, nínú àlàyé etí ìwé tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tí ọ̀gbẹ́ni yìí túmọ̀ láti èdè Hébérù sí Látìn, orúkọ Ọlọ́run fara hàn gẹ́gẹ́ bíi “jehovah.”

Kò sí àní-àní pé ọ̀gbẹ́ni Zamora gbà pé ó dára láti túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run lọ́nà yìí sí èdè Látìn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, nígbà tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè tó gbawájú nínú èdè ilẹ̀ Yúróòpù, ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè míì lo sípẹ́lì yìí tàbí òmíràn tó sún mọ́ ọn, títí kan ọ̀gbẹ́ni William Tyndale (tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ọdún 1530), Sebastian Münster (tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn, ọdún 1534), Pierre-Robert Olivétan (tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé, ọdún 1535) àti Casiodoro de Reina (tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Sípáníìṣì, ọdún 1569).

Nítorí náà, ọ̀gbẹ́ni Zamora jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún tó kọ́kọ́ ṣèrànwọ́ kí àwọn èèyàn lè lóye orúkọ Ọlọ́run. Ìgbà tí àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Ọlọ́run ló mú kí àwọn èèyàn má mọ orúkọ Ọlọ́run. Àṣà àwọn Júù yìí ló mú kí àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì tó túmọ̀ Bíbélì fi “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” tó jẹ́ orúkọ òye rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, àpẹẹrẹ kan ni ọ̀gbẹ́ni Jerome tó túmọ̀ Bíbélì Vulgate, ní èdè Látìn.

[Àwòrán]

Àwòrán lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tí ọ̀gbẹ́ni Zamora túmọ̀ sí “jèhófà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ÀṢẸ ỌBA ÀTI ỌBABÌNRIN ORÍLẸ̀-ÈDÈ SÍPÉÈNÌ, ỌDÚN 1492

[Credit Line]

Decree: Courtesy of the Archivo Histórico Provincial, Ávila, Spain

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Yunifásítì ìlú Alcalá de Henares

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwòrán abala àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tí ọ̀gbẹ́ni Zamora ṣe