2 Ọlọ́run Kò Bìkítà—Ṣé Òótọ́ Ni?
2 Ọlọ́run Kò Bìkítà—Ṣé Òótọ́ Ni?
Ohun táwọn èèyàn ń sọ: “Bí Ọlọ́run bá bìkítà nípa aráyé lóòótọ́, ó yẹ kó ti mú ìwà ibi àti ìyà kúrò ní ayé yìí. Tó bá sì jẹ́ pé ó bìkítà nípa gbogbo èèyàn, kò bìkítà nípa èmi.”
Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Jèhófà Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn nǹkan búburú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. (Jákọ́bù 1:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè mú àwọn nǹkan búburú yìí kúrò ní ìgbàkugbà, ó fàyè gba ayé tó ti bà jẹ́ bàlùmọ̀ yìí láti máa wà nìṣó, kí ó bàa lè yanjú ọ̀ràn tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn aráyé. Níkẹyìn, yóò bójú tó ọ̀ràn aráyé yóò sì yanjú gbogbo ìṣòro táwọn tó ta ko ìṣàkóso rẹ̀ dá sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Aísáyà 65:17. *
Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run ń bìkítà fún gbogbo aráyé lápapọ̀, ó tún nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Mátíù 10:29-31 fi hàn pé ó ń ṣàkíyèsí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, tí àwa pàápàá kò mọ̀, ó ní: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”
Bí mímọ òtítọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: A sábà máa ń yẹra fún àwọn èèyàn tí wọ́n bá ń kanra tàbí tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tí kò bìkítà. Abájọ tí irọ́ tí wọ́n pa mọ́ Ọlọ́run pé kò bìkítà fúnni fi mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn má ṣe fẹ́ mọ Ọlọ́run tàbí kó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá sún kan ògiri nìkan ni wọ́n máa tó wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Mímọ̀ tó o mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run bìkítà lè mú kó o fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, kí o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, o lè ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, àmọ́ tí ò ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run gbọ́ tàbí bóyá yóò dá ọ lóhùn àdúrà náà. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé “Olùgbọ́ àdúrà” ṣe tán láti gbọ́ àwọn èèyàn tó bá fi gbogbo ọkàn wọn gbàdúrà sí òun nígbà gbogbo.—Sáàmù 65:2.
Ọlọ́run fẹ́ kí o “kó gbogbo àníyàn [rẹ lé òun], nítorí ó bìkítà fún [ọ].” (1 Pétérù 5:7) A lè gbára lé Ọlọ́run pé á bìkítà fún wa, pàápàá nígbà ìṣòro, nítorí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, ka orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kò bìkítà, kí nìdí tó fi ní ká máa gbàdúrà sí òun?