Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Mo Ṣe Mọ̀ Pé Ọlọ́run Jẹ́—“Olùṣe Àwọn Ohun Ńlá”

Bí Mo Ṣe Mọ̀ Pé Ọlọ́run Jẹ́—“Olùṣe Àwọn Ohun Ńlá”

Bí Mo Ṣe Mọ̀ Pé Ọlọ́run Jẹ́—“Olùṣe Àwọn Ohun Ńlá”

Gẹ́gẹ́ bí Maurice Raj ṣe sọ ọ́

Èmi àtàwọn tó wà nínú ìdílé wa pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àjèjì míì sá lọ nítorí ọ̀kan lára ìpakúpa tó tíì burú jù lọ, èyí tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ la fi ń rìn káàkiri nínu igbó kìjikìji lórílẹ̀-èdè Burma, tí a sì ń sùn lábẹ́ igi lálaalẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí nígbà yẹn. Inú àpò kékeré kan tí mo so mọ́ ẹ̀yìn mi ni gbogbo ohun ìní mi wà. Àmọ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.

ỌDÚN 1942 ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé. Ogun ń lọ lọ́wọ́ nínú ayé, a sì ń sá lọ fún àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Japan tí wọ́n ń bọ̀. Wọ́n ti ya wọ orílẹ̀-èdè Burma, tí wọ́n ń pè ní Myanmar nísinsìnyí, wọ́n ti gba ibi tí wọ́n ti ń wa epo ní ìlú Yenangyaung. Ká tó dé ẹnu ààlà orílẹ̀-èdè Íńdíà, àwọn ọmọ ogun Japan lé wa bá, wọ́n sì fipá mú wa láti pa dà sílé.

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìlú Yenangyaung là ń gbé, níbi tí bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́ fún Ilé Iṣẹ́ Epo Burmah. Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Japan ti ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Burma, àwọn ọkọ̀ ogun òfuurufú ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá ń yin bọ́ǹbù lu apá ibi tí epo pọ̀ sí nílùú Yenangyaung. Nígbà kan, ìdílé wa sá pa mọ́ sínú kòtò fún ọjọ́ mẹ́ta bí bọ́ǹbù ṣe ń dún láyìíká wa. Níkẹyìn, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan, a sì sá lọ síìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Sale, tó wà lórí Odò Ayeyarwady, tàbí Odò Irrawaddy. A dúpẹ́ gan-an pé a wà láàyè, ibẹ̀ la wà títí ogun fi parí.

Àjálù Mú Kí N Rí Òtítọ́

Ọdún 1945 tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ni wọ́n bí àbúrò mi ọkùnrin. Inú bàbá mi dùn gan-an láti ní ọmọ kan lọ́jọ́ ogbó rẹ̀. Àmọ́ ayọ̀ rẹ̀ kò tọ́jọ́. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, àbúrò mi kú. Kété lẹ́yìn náà, ìbànújẹ́ pa bàbá mi.

Àwọn ọ̀rẹ́ wa gbìyànjú láti tù mí nínú nípa sísọ pé Ọlọ́run ti mú bàbá mi àti àbúrò mi lọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lọ́run. Ó wù mí gan-an láti wà pẹ̀lú wọn! Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni ìdílé wa ń lọ, ibẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn. Wọ́n ti kọ́ mi pé ọ̀run ni àwọn àlùfáà àti àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ nítorí ẹ̀sìn máa ń lọ ní tààràtà tí wọ́n bá ti kú, àmọ́ àwọn yòókù ní láti lo àkókò díẹ̀ ní pọ́gátórì, ìyẹn ibi tí wọ́n ti n dá àwọn èèyàn lóró fúngbà díẹ̀ kí wọ́n bàa lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Mo pinnu pé màá fẹ́ láti wà pẹ̀lú bàbá mi àti àbúrò mi lọ́run, nítorí náà, mò ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tó wà nílùú Maymyo déédéé, èyí tí wọ́n ń pè ní Pyin Oo Lwin báyìí, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí igba ó lé mẹ́wàá [210] kìlómítà sí ibi tí à ń gbé.

Kí ẹnì kan tó lè wọ ilé ẹ̀kọ́ ìsìn náà, ó ní láti jẹ́ ẹni tó mọ̀wé dáadáa. Àjèjì ni mí, ọdún méjì péré ni mo lò nílé ìwé. Wọ́n ti gbogbo ilé ìwé pa nígbà ogun yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣí àwọn ilé ìwé náà pa dà, àmọ́ nǹkan kò ṣẹnuure fún ìdílé wa ní ti ọ̀ràn ìṣúnná owó. Yàtọ̀ sí èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì, màmá mi tún ń bójú tó àwọn ọmọ mẹ́ta tó jẹ́ àwọn ọmọ àbúrò rẹ̀ tó ti ṣaláìsí. Nítorí náà, màmá mi kò lè rán àwa tá a jẹ́ ọkùnrin lọ sílé ìwé mọ́.

Ẹ̀gbọ́n mi tí mo tẹ̀ lé máa ń lọ ṣiṣẹ́, nígbà yẹn ọmọ ọdún mẹ́tàlá péré ni mí, mi ò sì lè fi bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó pọ̀. Àbúrò bàbá mi tó ń jẹ́ Manuel Nathan, ń gbé ní Chauk, ìlú kan nítòsí ìlú Sale. Mo ronú pé, ‘Tí mo bá kúrò nílé, iye àwọn tí wọ́n á máa bọ́ dín kù nìyẹn.’ Nítorí náà, mo lọ sí Chauk láti máa gbé lọ́dọ̀ àbúrò bàbá mi yìí.

Mi ò mọ̀ pé àbúrò bàbá mi yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé ni, ó sì ń fẹ́ láti sọ ohun tuntun tó kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn ẹlòmíì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi díẹ̀díẹ̀ látorí ìtumọ̀ àdúrà Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run. Ó kà báyìí pé: “Baba wa ti mbẹ li ọrun; ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.”—Mátíù 6:9, 10, Bibeli Mimọ.

Àbúrò bàbá mi yìí sọ fún mi pé, “Ṣó o rí i pé Ọlọ́run ní orúkọ, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó fi orúkọ Ọlọ́run hàn mí nínú Bíbélì. Mo fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i. Àmọ́, mi ò mọ̀wé kà dáadáa, kódà mi ò lè ka èdè Tamil tó jẹ́ èdè ìlú mi dáadáa. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà lọ́wọ́ àbúrò bàbá mi, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ lóye èdè yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé tí mo kà kò tó nǹkan, díẹ̀díẹ̀ ni mo wá lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì. (Mátíù 11:25, 26) Ojú mi là pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ mi tẹ́lẹ̀ ni kò bá Bíbélì mu. Mo sọ fún àbúrò bàbá mi pé, “Òtítọ́ gan-an nìyí!”

Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí mo kọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] ló wà ní orílẹ̀-èdè Myanmar nígbà yẹn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, míṣọ́nnárì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robert Kirk tó wá láti Rangoon tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, èyí tó ń jẹ́ Yangon nísinsìnyí, wá sọ́dọ̀ àbúrò bàbá mi nílùú Chauk. Mo sọ fún Robert pé mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Nítorí náà, ní December 24, ọdún 1949, mo ṣe ìrìbọmi nínú Odò Ayeyarwady, láti fẹ̀rí hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

Bí Mo Ṣe Borí Àwọn Ìdènà

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo kó lọ sí ìlú Mandalay láti lọ wá iṣẹ́ tó dáa. Ohun tí mò ń lé ni láti di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Lọ́jọ́ kan tí mò ń wo eré bọ́ọ̀lù, gìrì gbé mi. Mo ti ní àrùn wárápá, mo sì ní láti pa dà sọ́dọ̀ màmá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi kí wọ́n lè tọ́jú mi.

Ọdún mẹ́jọ gbáko ni wárápá náà fi ṣe mí, tó ń wá tó sì ń lọ. Nígbà tí ara mi le díẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ kan láti wá oúnjẹ òòjọ́. Àmọ́ nítorí àìlera mi, màmá mi kò fẹ́ kí n ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn iṣẹ́ fífi àkókò púpọ̀ wàásù, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan mo sọ fún un pé: “Mi ò lè dúró mọ́, mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà. Jèhófà á bójú tó mi!”

Lọ́dún 1957, mo kó lọ sí Yangon, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé lẹ́yìn àádọ́ta ọdún [50], ìyẹn ọdún 2007 ni wárápá náà tún pa dà gbé mi. Àmọ́ ní báyìí, oògùn ni mò ń lò sí i. Lọ́dún 1958, wọ́n yàn mí láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, tí mò ń fi àádọ́jọ wákàtí [150] wàásù lóṣooṣù.

Ìlú Kyonsha ni wọ́n kọ́kọ́ yàn mí sí láti ṣiṣẹ́, ìyẹn sì tó àádọ́fà [110] kìlómítà sí àríwá ìwọ̀ oòrùn Yangon. Àwùjọ àwọn èèyàn kékeré kan wà níbẹ̀, wọ́n ti ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, wọ́n sì fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Nígbà tí èmi àti Robert dé ibẹ̀, àwọn èèyàn rẹpẹtẹ kóra jọ láti gbọ́ wa. A dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí wọ́n ní nínú Bíbélì, a sì fi bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn ìpàdé tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n. Kò sì pẹ́ tí àwọn kan lára wọn fi dara pọ̀ mọ́ wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n ní kí n dúró sí abúlé náà. Láàárín oṣù díẹ̀, àwùjọ kékeré náà ti di ìjọ tó ń gbèrú. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé láàádọ́jọ [150] ló wà lágbègbè náà.

Lẹ́yìn náà, wọ́n yàn mí láti ṣe òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, wọ́n ní kí n máa ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó wà ní àdádó káàkiri orílẹ̀-èdè Myanmar. Bí mo ti ń rìnrìn àjò àìmọye kìlómítà lọ́nà eléruku, orí ẹrù nínú ọkọ̀ akẹ́rù ni mo máa ń jókòó sí, mò ń fẹsẹ̀ rìn gba inú igbó, mò ń wọ ọkọ̀ ojú omi, mo sì ń fẹsẹ̀ rìn kọjá lórí àwọn òkè ńlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara mi kò fi bẹ́ẹ̀ le dáadáa, àmọ́ Jèhófà fún mi ní agbára láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó.—Fílípì 4:13.

“Jèhófà Yóò Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́”

Nígbà tó di ọdún 1962, wọ́n ní kí n lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Yangon, ibẹ̀ ni Robert ti fún mi láwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan. Lójijì, àwọn aláṣẹ ìjọba pàṣẹ pé kí àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ àjèjì tó wà ní orílẹ̀-èdè Myanmar fi ibẹ̀ sílẹ̀, láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọ́n ti lọ. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n sọ pé èmi ni kí n máa bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì náà.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara mi pé, ‘Báwo ni mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ yìí? Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé, mi ò sì ní ìrírí.’ Nígbà tí àwọn àgbàlagbà kan rí àníyàn tí mò ń ṣe, wọ́n sọ fún mi pé: “Maurice, fọkàn rẹ balẹ̀. Jèhófà yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwa náà sì wà pẹ̀lú rẹ.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí fi mí lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo ní láti ṣàkójọ ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù tá a ṣe ní orílẹ̀-èdè Myanmar kí wọ́n lè fi sínú ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn 1967 Yearbook of Jehovah’s Witnesses. Ọdún méjìdínlógójì [38] tó tẹ̀ lé e ni mo fi ṣàkójọ irú ìròyìn yìí fún orílẹ̀-èdè náà. Látìgbàdégbà làwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń fi dá mi lójú pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo kọ́kọ́ béèrè pé kí wọ́n fún mi ní ìwé ọmọ onílẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Myanmar, mi ò ní 450 kyats a tí mo máa fi san owó ìwé náà, nítorí náà, mo fi sílẹ̀ dìgbà míì. Lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ kan tí mò ń kọjá ní ọ́fíìsì ilé iṣẹ́ tí mo bá ṣiṣẹ́ láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀gá mi tẹ́lẹ̀ rí mi, ló bá lọgun pè mí pé: “Raj, wá gba owó rẹ. O kò rántí gba owó ìfẹ̀yìntì rẹ kó o tó lọ.” Owó náà sì jẹ́ 450 kyats.

Nígbà tí mo kúrò ní ọ́fíìsì náà, mò ń ronú lórí ohun tí mo lè fi 450 kyats náà ṣe. Àmọ́, bó ti jẹ́ pé iye owó tí mo fẹ́ fi gba ìwé ọmọ onílẹ̀ gan-an lówó náà jẹ́, mo gbà pé ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí n fi owó náà gba ìwé náà. Ìpinnu tí mo ṣe yìí ló sì ṣàǹfààní jù lọ. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọmọ onílẹ̀, màá lè máa gbé ní orílẹ̀-èdè náà nìṣó, màá lè rìnrìn àjò káàkiri fàlàlà, màá lè máa kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé láti orílẹ̀-èdè míì, màá sì lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó máa mú kí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa tẹ̀ síwájú lórílẹ̀-èdè Myanmar.

Àpéjọ Tá A Ṣe ní Àríwá

Nígbà tó fi máa di ọdún 1969, iṣẹ́ wa ń yára tẹ̀ síwájú ní ìlú Myitkyina tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Myanmar, nítorí náà, a pinnu láti ṣe àpéjọ kan ní ìlú yìí. Àmọ́, ìṣòro tó le jù tá a ní lákòókò náà ni, bá a ṣe máa kó gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé ní gúúsù wá sí ibi àpéjọ náà. Nítorí náà, a gbàdúrà, a sì béèrè wágọ̀nù mẹ́fà ọkọ̀ ojú irin lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ Rélùwéè orílẹ̀-èdè Myanmar. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé wọ́n gbà láti fún wa ní ohun tá a béèrè.

Nígbà tó yá, a múra ohun gbogbo sílẹ̀ fún àpéjọ wa. Lọ́jọ́ tí àwọn tó ń bọ̀ wá sí àpéjọ náà máa dé, a lọ sí ibùdókọ̀ ojú irin ní ọ̀sán, a retí pé ọkọ̀ ojú irin náà máa dé ní aago méjì ààbọ̀ ọ̀sán. Bí a ti ń retí wọn, ọ̀gá ibùdókọ̀ náà fún wa ní wáyà tó rí gbà, ohun tó wà nínú rẹ̀ kà pé: “A ti já wágọ̀nù mẹ́fà ọkọ̀ ojú irin ti Watch Tower Society sílẹ̀.” Ó sọ pé ọkọ̀ ojú irin náà kò lè wọ́ àwọn wágọ̀nù náà gùnkè.

Kí la máa ṣe? Ohun tá a kọ́kọ́ rò ni pé ká yí ọjọ́ àpéjọ náà pa dà. Àmọ́, ìyẹn túmọ̀ sí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ìwé àṣẹ míì nìyẹn, èyí tó máa gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ kó tó jáde! Bá a ṣe ń fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà lọ́wọ́ ni ọkọ̀ ojú irin náà dé sí ibùdókọ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa pé àwọn ará wa ló kún inú wágọ̀nù mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà! Wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń juwọ́. Nígbà tá a béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ọ̀kan lára wọn sọ pé, “Òótọ́ ni pé wọ́n já wágọ̀nù mẹ́fà sílẹ̀, àmọ́ kì í ṣe tiwa!”

Láàárín ọdún 1967 àti ọdún 1971, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Myanmar di ìlọ́po méjì, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ta [600] èèyàn. Lẹ́yìn náà, lọ́dún 1978, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣí lọ sí ilé alágbèékà kan. Ogún ọdún lẹ́yìn náà, iye àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ ti pọ̀ sí i, wọ́n sì lé ní ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,500]. A tún mú ẹ̀ka ọ́fíìsì náà gbòòrò síwájú sí i. Ní January 22, ọdún 2000, Arákùnrin John E. Barr, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì sọ ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ ọ́fíìsì tó jẹ́ alágbèékà méjì náà àti ilé gbígbé tá à ń lò títí dòní.

Àwọn Ìbùkún Tí Mo Rí Gbà

Lónìí, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni méjìléláàádọ́ta [52] ni wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Yangon níbí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún [3,500] Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń sìn ní ìjọ mẹ́rin lé láàádọ́rin [74] àtàwọn àwùjọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Mo láyọ̀ láti sọ pé ní ọdún 1969, kété ṣáájú kí ìyá mi ọ̀wọ́n tó kú, òun náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Òjíṣẹ́ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Doris Ba Aye, di atúmọ̀ èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní nǹkan bí ọdún 1965. Ó ti lọ sí kíláàsì kejìlélọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ọdún 1959, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń dá àwọn míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin yìí lẹ́wà, ó lọ́yàyà, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, gbogbo èyí ló mú kí ìfẹ́ rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1970. Títí dòní yìí, a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti sí ara wa.

Ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún báyìí tí mo ti ń rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lórílẹ̀-èdè yìí. Lóòótọ́, Ọlọ́run tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi. Òun ni “Olùṣe àwọn ohun ńlá,” àwọn ohun tí mo rí jálẹ̀ ìgbésí ayé mi ló mú kí n gbà bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 106:21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà yẹn, iye owó yẹn tó nǹkan bíi $95 owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà, owó náà sì pọ̀ díẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Mo wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nílùú Rangoon, lórílẹ̀-èdè Burma, ní nǹkan bí ọdún 1957

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Mò ń lọ sí àpéjọ kan nílùú Kalemyo, lórílẹ̀-èdè Burma, ní nǹkan bí ọdún 1979

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun tó lẹ́wà, tá a yà sí mímọ́ lọ́dún 2000

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Doris lónìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

À ń wàásù láti ilé dé ilé