Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn

Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn

Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn

ÒǸKỌ̀WÉ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún ọmọ ilẹ̀ Sípéènì náà, Miguel de Cervantes kọ ìtàn àròkọ kan tó dá lórí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Don Quixote. Ìtàn ọkùnrin yìí gbajúmọ̀ gan-an. Nínú ìwé náà, Don Quixote bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa akọni inú ìtàn àròsọ kan tó wọ ìhámọ́ra tó fẹ́ lọ gba omidan kan tó wà nínú ewu sílẹ̀. Nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbà pé akọni lòun náà. Apá kan nínú ìwé náà táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa sọ nípa ìgbà kan tí Don Quixote lọ kọ lu àwọn ẹ̀rọ tí ẹ̀fúùfù ń yí tó kà sí àwọn òmìrán eléwu. Èrò rẹ̀ ni pé, ìfẹ́ Ọlọ́run lòun ń ṣe bí òun ṣe pa àwọn òmìrán náà, àmọ́, ó tẹ́ nítorí ohun tó ṣe yìí.

Lóòótọ́, ìtàn àròkọ lásán lọ̀rọ̀ Don Quixote, àmọ́ títannijẹ kì í ṣọ̀rọ̀ àwàdà. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀mùtí kan tó gbà pé òun lè mu ìwọ̀n ọtí tí òun fẹ́, àmọ́ àbájáde ohun tó ṣe yìí ni pé, ó ba ìlera ara rẹ̀ jẹ́, ìdílé rẹ̀ sì dàrú. Tàbí, ronú nípa obìnrin kan tí kò jẹunre kánú nítorí pé kò fẹ́ tóbi, tó wá ronú pé òun ń jẹun bó ṣe yẹ àti pé ara òun le, àmọ́ àbájáde rẹ̀ ni pé, ńṣe ló ń pa ara rẹ̀ díẹ̀díẹ̀.

Ṣé àwa náà lè di ẹni tí wọ́n tàn jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo wa pátá la lè bọ́ sínú ewu yẹn. A tún lè dẹni tí wọ́n tàn tó bá dọ̀rọ̀ ohun tá a gbà gbọ́, èyí tó sì lè yọrí sí àgbákò. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Báwo ni o kò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ?

Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Dídi Ẹni Tí Wọ́n Tàn Jẹ

Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ẹ̀tàn ni, “mímú kí ẹnì kan gbà pé ohun tí kì í ṣe òótọ́ tàbí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ jẹ́ òótọ́ tàbí pé ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Ó tún kan “mímú kí ẹnì kan gbà gbọ́ nínú irọ́ tàbí èrò tó ń sọni di aláìmọ̀kan.” Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí àtàwọn míì bí “ìṣìnà” túmọ̀ sí ni fífi màgòmágó sún ẹnì kan kúrò nídìí ohun tó tọ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ẹni tí kò mọ̀ pé ohun tí wọ́n sọ fún òun ti sọ òun di “aláìmọ̀kan” wà nínú ewu ńlá.

Ohun tó máa ń bani nínú jẹ́ ni pé, àwọn tí wọ́n ti tàn kì í fẹ́ fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sílẹ̀ láìka ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ sí, ìyẹn ẹ̀rí tó fi hàn pé irọ́ ni nǹkan náà. Bóyá nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yẹn gan-an ló mú kí wọ́n kọ etí dídi sí ẹ̀rí èyíkéyìí tó fi hàn pé kò tọ̀nà.

Ṣé A Wà Nínú Ewu?

O lè béèrè pé, ‘Ṣé àbùmọ́ kọ́ ni pé gbogbo wa pátá wà nínú ewu dídi ẹni tí wọ́n tàn jẹ tó bá dọ̀rọ̀ ohun tá a gbà gbọ́?’ Rárá, kì í ṣe àbùmọ́. Ìdí ni pé ìfẹ́ ọkàn Sátánì Èṣù, ẹni tí Jésù pè ní “baba irọ́,” ni láti tan gbogbo wa jẹ àti láti ṣì wá lọ́nà. (Jòhánù 8:44) Bíbélì tún pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” Ìtàn fi hàn pé, ó ti “fọ́ èrò inú” ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn “lójú.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ní báyìí pàápàá, ó “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9.

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni Sátánì ti ń tanni jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó tan Éfà láti gbà pé kò pọn dandan kó pa òfin Ẹlẹ́dàá rẹ̀ mọ́ àti pé, ó máa “dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú,” ìyẹn ni pé, á máa fúnra rẹ̀ pinnu pé ohun kan dára tàbí kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ẹ̀tàn ńlá gbáà ni téèyàn bá rò pé nítorí pé èèyàn lómìnira láti ṣe ohun tó bá wù ú, ó láṣẹ láti fúnra rẹ̀ pinnu pé ohun kan dára tàbí kò dára. Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, nìkan ló ní àṣẹ láti pinnu pé ohun kan dára tàbí kò dára. (Jeremáyà 10:23; Ìṣípayá 4:11) À bẹ́ ò rí i pé, ẹ̀tàn gbáà ló máa jẹ́ téèyàn bá rò pé nítorí pé èèyàn lè ṣe ohun tó wù ú, ó ti láṣẹ láti pinnu pé ohun kan dára tàbí pé kò dára nìyẹn! Ìyẹn sì jẹ́ ìdẹkùn tí èèyàn aláìpé máa ń tètè kó sí.

Ṣé Ó Lè Ṣẹlẹ̀ sí Ìwọ Náà?

Ó lè jẹ́ pé láti ọdúnmọ́dún ni ohun tó o gbà gbọ́ ti wà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọwọ́ àwọn èèyàn rẹ lo ti bá a. Àmọ́, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé òótọ́ lohun náà. Kí nìdí? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Kristi, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ń tanni jẹ dìde nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n sì ń kọ́ni ní “àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Ọ̀jáfáfá ni wọ́n nínú fífi “àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà” ṣini lọ́nà, bákan náà, wọ́n tún lo “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.”—Kólósè 2:4, 8.

Ṣé àwọn nǹkan ti yàtọ̀ lákòókò tiwa yìí? Rárá, nítorí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé nǹkan túbọ̀ máa burú sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tá a wà yìí. Ó sọ pé, “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà [tàbí, ‘wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ,’ Ìròyìn Ayọ̀].”—2 Tímótì 3:1, 13.

Nítorí náà, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti túbọ̀ fi ìkìlọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, ó ní: “Nítorí náà, kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:12) Àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kódà, ẹ̀tàn ńlá ló jẹ́ téèyàn bá rò pé Sátánì kò lè ṣi òun lọ́nà láé. Kókó ibẹ̀ ni pé, kò sí ẹni tí Sátánì kò lè fi “àwọn ètekéte” rẹ̀ mú. (Éfésù 6:11) Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì yìí sọ ohun tó ń bà á lẹ́rù nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé, “lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.”—2 Kọ́ríńtì 11:3.

Báwo Lo Ṣe Máa Ṣe É Tó Ò Fi Ní Dẹni Tí Wọ́n Tàn Jẹ?

Báwo lo ṣe lè ṣe é tó ò fi ní dẹni tí Sátánì tàn jẹ? Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé ò ń “jọ́sìn [Ọlọ́run] ní ẹ̀mí àti òtítọ́”? (Jòhánù 4:24) Lo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fún ẹ. Àkọ́kọ́ ni pé, ó ti fún ẹ ní “agbára ìmòye” kó o lè mọ ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ àti irọ́. (1 Jòhánù 5:20) Ó tún ti jẹ́ kó o mọ àwọn ọgbọ́n àrékérekè Sátánì. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Kódà, ó ti fún ẹ ní gbogbo nǹkan tó o nílò tí Sátánì kò fi ní ṣì ẹ́ lọ́nà.—Òwe 3:1-6; Éfésù 6:10-18.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Ọlọ́run ti fún ẹ ní ohun kan tó péye tó o lè fi dáàbò bo ara rẹ. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Nǹkan náà ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kó fi ṣe ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ìkìlọ̀ nípa “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà,” ó sọ fún Tímótì pé kó má ṣe fàyè gbà wọ́n, kó rí i dájú pé “ìwé mímọ́” ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi ṣe ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan tó bá gbà gbọ́.—2 Tímótì 3:15.

Àmọ́ àwọn kan lè sọ pé, ẹnikẹ́ni tó bá gba Ọlọ́run gbọ́, tó sì gbà pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ṣì lọ́nà. Ṣùgbọ́n, àwọn tó dìídì ta ko gbogbo ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà àti pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ṣì lọ́nà. aRóòmù 1:18-25; 2 Tímótì 3:16, 17; 2 Pétérù 1:19-21.

Dípò tí wàá fi jẹ́ kí wọ́n fi “ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀,’” tàn ẹ́ jẹ, lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti wádìí òtítọ́. (1 Tímótì 6:20, 21) Ṣe bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní ọkàn títọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù fún ní ìlú Bèróà. Wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú.” Yàtọ̀ sí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn gba ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ wọn gbọ́, wọ́n tún “ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

Kò sí ìdí tó fi yẹ kó o bẹ̀rù láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀sìn rẹ lọ́nà kan náà. Kódà, Bíbélì pàápàá gbà ẹ́ níyànjú pé kó o “wádìí ohun gbogbo dájú” kó o tó gbà pé òótọ́ ni. (1 Tẹsalóníkà 5:21) Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ń parí lọ, àpọ́sítélì Jòhánù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Bẹ́ẹ̀ ni, bí ẹ̀kọ́ ìsìn kan bá tiẹ̀ jọ pé ó “ní ìmísí Ọlọ́run” tàbí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ láti rí i dájú pé ó jóòótọ́ ká tó gbà á gbọ́.—Jòhánù 8:31, 32.

Máa fi Ohun Tó O Kọ́ Sílò

Àmọ́, àwọn nǹkan míì wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe. Ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ.” (Jákọ́bù 1:22) Kó o mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni níkàn kò tó. O ní láti fi ohun tó o kọ́ sílò. Báwo? Ìyẹn ni pé, kó o máa ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ pé kó o ṣe, kó o sì yàgò fún ohun tí kò fẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, wo bí ìwà pálapàla ṣe gbilẹ̀ káàkiri. Ǹjẹ́ ìyẹn kò jẹ́ kó o rí i bí Sátánì ti ṣàṣeyọrí nínú títan àwọn èèyàn jẹ láti máa rò pé àwọn lè kọ ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà tó yẹ sílẹ̀ láìsí nǹkan tó máa tìdí rẹ̀ yọ? Nítorí ìdí èyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ní ìkìlọ̀ tó ṣe pàtó yìí pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7.

Má ṣe dà bí “òmùgọ̀ ọkùnrin,” tí Jésù ṣàlàyé pé ó “gbọ́” ọ̀rọ̀ òun tí kò sì “ṣe wọ́n.” Gẹ́gẹ́ bíi Don Quixote tó wà nínú àròkọ ọ̀gbẹ́ni Cervante ti jẹ́ kí àwọn èrò òun tan òun jẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkùnrin tí Jésù sọ yìí ṣe tan ara rẹ̀ jẹ tó rò pé òun lè kọ́ ilé tó dúró sán-ún sórí iyẹ̀pẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe bí ọkùnrin “tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” Jésù pe ọkùnrin yìí ní “olóye” nítorí pé ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù “ó sì ń ṣe wọ́n.”—Mátíù 7:24-27.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ka ìwé náà Is There a Creator Who Cares About You? àti The Bible—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Àwọn Nǹkan bí Wọ́n Ṣe Jẹ́ Gan-an?

Láwọn ọdún 1930 sí 1939, ayàwòrán tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Sweden kan, Oscar Reutersvärd ya ọ̀pọ̀ àwòrán tó ń tanni jẹ. Irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ ti òde oní ló wà lápá òsì yìí. Téèyàn bá wo àwọn àwòrán yìí gààràgà, ńṣe ni wọ́n fẹ́ kéèyàn gba àwọn nǹkan tí kò jóòótọ́ gbọ́. Àmọ́ téèyàn bá fara bálẹ̀ wò ó, èèyàn á wá rí i pé ńṣe lẹni tó ya àwòrán náà fẹ́ fi ṣi àwọn tó ń wò ó lọ́nà tàbí tàn wọ́n jẹ.

Àwọn àwòrán tó ń tanni jẹ nìkan kọ́ ló máa ń yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n jẹ́ téèyàn bá wò wọ́n. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.

Ohun tó mú kí ìkìlọ̀ yìí túbọ̀ lágbára ni pé, wọ́n ti tan ọkùnrin tó kọ ọ̀rọ̀ yìí jẹ rí. Èèyàn lè sọ pé ọkùnrin yìí kò sí lára àwọn tí wọ́n lè tàn jẹ, nítorí pé ọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ jù lọ nígbà ayé rẹ̀ ló ti kẹ́kọ̀ọ́, tó sì tún mọ àwọn èèyàn tó wà nípò gíga.—Ìṣe 22:3.

Wọ́n ti mú kí ọkùnrin tá à ń sọ yìí, ìyẹn Sọ́ọ̀lù ará Tásù gbà gbọ́ pé, ikú tọ́ sí ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìsìn tí òun ń ṣe, tí kò bá sì tẹ̀ lé àṣà àwọn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fún un láṣẹ, torí náà, ó kà á sí pé Ọlọ́run ló gbé iṣẹ́ lé òun lọ́wọ́ láti fi ẹ̀sùn kan ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni. Ó tiẹ̀ bá wọn lọ́wọ́ sí pípa ọkùnrin ará ìlú rẹ̀ kan tí wọ́n fi ẹ̀sùn èké kàn pé ó sọ̀rọ̀ òdì.—Ìṣe 22:4, 5, 20.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dára àti èyí tí kò dára, ohun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí àti èyí tí kò fọwọ́ sí. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ti lóye pé ohun tóun ń ṣe kò dára, ọkùnrin onítara yìí yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, ó sì wá di ẹni tá a mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tàn, ó sì wá rí ọ̀nà tòótọ́ tó yẹ kéèyàn gbà jọ́sìn.—Ìṣe 22:6-16; Róòmù 1:1.

Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn ni wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu ṣì lọ́nà, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè fi wé àwòrán tó ń tanni jẹ. (Òwe 14:12; Róòmù 10:2, 3) Nígbà tó yá, wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti ronú lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti èso tí ẹ̀sìn wọn ń so, kí wọ́n lè rí ohun tí ẹ̀sìn wọn jẹ́ gan-an. (Mátíù 7:15-20) Bí wọ́n ṣe ń ní ìmọ̀ tó péye látinú Bíbélì, wọ́n ṣe àtúnṣe ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn kí wọ́n bàa lè rí ojú rere Ọlọ́run.

Ṣé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kó o sì fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàyẹ̀wò ìgbàgbọ́ rẹ? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Doré ló ṣe àwòrán yìí