Ṣé Àwọn Ìràwọ̀ Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
Ṣé Àwọn Ìràwọ̀ Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
TÓ O bá wo ojú ọ̀run ní alẹ́ nígbà tí kò sí ìmọ́lẹ̀ láyìíká rẹ, wàá rí i tí ojú ọ̀run dúdú, wàá sì tún rí ẹgbàágbèje ìràwọ̀ tí wọ́n rí bíi dáyámọ́ńdì tíntìntín lójú sánmà tó lọ salalu. Àádọ́ta lé ní ọ̀ọ́dúnrún [350] ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mọ bí àwọn ìràwọ̀ ṣe tóbi tó àti bí wọ́n ṣe jìnnà sí wa tó. A ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lóye agbára tó gadabú tó ń darí àgbá ńlá ayé wa yìí ni.
Láti ìgbà ìjímìjí làwọn èèyàn ti ń kíyè sí bí àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà ṣe ń ṣí kiri létòlétò lálaalẹ́, tí wọ́n sì tún kíyè sí bí wọ́n ṣe ní àsìkò tí wọ́n máa ń ṣí kiri. (Jẹ́nẹ́sísì 1:14) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti sọ èrò wọn bíi ti Dáfídì ọba Ísírẹ́lì tó kọ̀wé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn?”—Sáàmù 8:3, 4.
Àmọ́ ṣá o, bóyá a mọ̀ tàbí a kò mọ̀, àwọn nǹkan ojú sánmà àti ìṣíkiri wọn ń nípa lórí ìgbésí ayé wa gan-an. Oòrùn tó jẹ́ ìràwọ̀ tí ayé wa ń yí po la fi ń díwọ̀n àkókò wa, ìyẹn gígùn ọjọ́ àti ọdún. Òṣùpá wà “fún àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀,” tàbí láti sọ ìgbà fún wa. (Sáàmù 104:19) Àwọn ìràwọ̀ tún máa ń ṣe atọ́nà fún àwọn awakọ̀ òkun, kódà wọ́n máa ń tọ́ àwọn arìnrìn àjò tó gbé ọkọ̀ òfuurufú lọ sínú sánmà sọ́nà. Nítorí gbogbo nǹkan tí àwọn ìràwọ̀ ń ṣe yìí, àwọn kan ń rò pé wọ́n lè ṣe ju sísọ àkókò àti ìgbà lọ, wọ́n sì lè ṣe ju jíjẹ́ ká túbọ̀ mọrírì iṣẹ́ Ọlọ́run lọ. Ṣé wọ́n lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ ọ̀la tàbí kìlọ̀ fún wa nípa àwọn àjálù tó ń bọ̀?
Bí Ìwòràwọ̀ Ṣe Bẹ̀rẹ̀ àti Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe É
Ìlú Mesopotámíà àtijọ́ ni wíwo ojú ọ̀run láti rí àmì táá máa darí ìgbésí ayé àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn awòràwọ̀ ìjímìjí máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ojú ọ̀run. Ìmọ̀ nípa sánmà bẹ̀rẹ̀ látinú akitiyan wọn láti mọ ipa ọ̀nà tí àwọn nǹkan ojú ọ̀run ń tọ̀, ibi táwọn ìràwọ̀ ń dúró sí, bí wọ́n ṣe ṣe onírúurú kàlẹ́ńdà àti bí wọ́n ṣe mọ̀ nípa ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá máa ń pàdé. Ṣùgbọ́n wíwo ìràwọ̀ tún lọ kọjá wíwo bí oòrùn àti òṣùpá ṣe ń nípa lórí àyíká wa. Wọ́n sọ pé kì í ṣe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì inú ayé nìkan ni oòrùn, òṣùpá, pílánẹ́ẹ̀tì, ìràwọ̀ àti ibí tí àgbájọ ìràwọ̀ dúró sí ń nípa lé lórí, wọ́n ní ó tún ń darí ìgbésí ayé èèyàn kọ̀ọ̀kan. Láwọn ọ̀nà wo?
Àwọn kan lára àwọn onímọ̀ sánmà máa ń wo àwọn nǹkan ojú ọ̀run láti gbé àmì tàbí ìkìlọ̀ kan jáde nípa ọjọ́ ọ̀la, èyí táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lè lò ní oríṣiríṣi ọ̀nà tó sì máa ń wúlò. Èrò àwọn míì ni pé wíwo ìràwọ̀ máa ń fi kádàrá wa hàn tàbí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àkókò tá a lè ṣàṣeyọrí ohun tá a fẹ́ dáwọ́ lé tàbí àkókò tó yẹ ká ṣe ohun kan pàtó. Wọ́n sọ pé èèyàn lè rí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ gbà téèyàn bá kíyè sí bí àwọn nǹkan pàtàkì lójú ọ̀run ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn, téèyàn sì ṣírò bí wọ́n ṣe jìnnà sí ayé tó. Bí àwọn nǹkan ojú ọ̀run yìí ṣe máa darí ìgbésí ayé ẹnì kan sinmi lórí bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn nígbà tí wọ́n bí ẹni náà.
Àwọn awòràwọ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rò pé àárín àgbáyé ni ayé wa yìí wà àti pé àwọn pílánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ìràwọ̀ tò tẹ̀ lé ara wọn ń yí ayé po. Wọ́n tún rò pé oòrùn ń lọ lójú sánmà láàárín àwọn ìràwọ̀ àti àgbájọ ìràwọ̀ ní ipa ọ̀nà kan lọ́dọọdún. Wọ́n pe ipa ọ̀nà tí oòrùn ń tọ̀ ní àgbá, wọ́n sì pín in sí ọ̀nà méjìlá. Orúkọ àgbájọ ìràwọ̀ tí oòrùn ń gba inú wọ́n kọjá ni wọ́n fi ń pe ọ̀nà kọ̀ọ̀kan. Bí sódíákì méjìlá ṣe wáyé nìyẹn. Àwọn ọ̀nà yìí, tàbí ibi tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ àwọn ilé ọ̀run ni wọ́n pè ní ibùgbé àwọn ọlọ́run àjúbàfún kan. Àmọ́ ṣá o, nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wá mọ̀ pé oòrùn kò yí ayé po, àmọ́ ayé ló ń yí oòrùn po. Àwárí yìí ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn awòràwọ̀ kì í ṣe onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Látìgbà tí ìwòràwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Mesopotámíà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ayé ló tàn kálẹ̀ dé, ó sì wà ní onírúurú ọ̀nà ní àwùjọ èèyàn tó gbajúmọ̀ jù lọ. Lẹ́yìn tí àwọn ará Páṣíà ṣẹ́gun àwọn ará Bábílónì, wíwo ìràwọ̀ tàn dé Íjíbítì, Gíríìsì àti Íńdíà. Àwọn míṣọ́nnárì ìsìn Búdà ló gbé wíwo ìràwọ̀ lọ sí àárín gbùngbùn Éṣíà, Ṣáínà, Tibet, Japan àti Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ bí wíwo ìràwọ̀ ṣe dé ọ̀dọ̀ àwọn Maya, àwọn èèyàn yìí lo ìwòràwọ̀ lọ́nà tó gbòòrò gan-an bíi ti àwọn ará Bábílónì. Ìwòràwọ̀ ti “òde òní” wá látọ̀dọ̀ àwọn ará Íjíbítì tó wà lábẹ́ ìjọba Gíríìsì, ó sì ní ipa tó pọ̀ lórí ìrònú àwọn onísìn Júù, àwọn Mùsùlùmí àti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.
Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàápàá kò bọ́ lọ́wọ́ ìwòràwọ̀, àní kí wọ́n tó lọ sí ìgbèkùn Bábílónì ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bíbélì sọ nípa ipa tí Jòsáyà ọba olóòótọ́ sà láti ṣe àmúkúrò gbogbo ọrẹ ẹbọ “sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ 2 Àwọn Ọba 23:5.
ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run.”—Ọ̀dọ̀ Ẹni Tí Ìwòràwọ̀ Ti Wá
Wíwo ìràwọ̀ wá látinú ìsọfúnni tí kò tọ̀nà tí wọ́n rí nínú ìrísí àwọn nǹkan ojú ọ̀run àti bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn. Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ìwòràwọ̀ kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Inú irọ́ ni wíwo ìràwọ̀ tí wá, nítorí náà, kò lè sọ òtítọ́ nípa ọjọ́ ọ̀la. A ti wá rí i pé ìwòràwọ̀ kò ṣeé gbára lé gẹ́gẹ́ bí ìtàn méjì kan tó gbàfiyèsí yìí ṣe fi hàn.
Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń ṣàkóso, àwọn àlùfáà àtàwọn awòràwọ̀ kò lè túmọ̀ àlá tí ọba náà lá. Dáníẹ́lì tó jẹ́ wòlíì Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ sọ ohun tó fa ìṣòro náà, ó ní: “Àṣírí tí ọba ń béèrè, ni àwọn ọlọ́gbọ́n, àwọn alálùpàyídà, àwọn àlùfáà pidánpidán àti àwọn awòràwọ̀ pàápàá kò lè fi han ọba. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀ fún Ọba Nebukadinésárì.” (Dáníẹ́lì 2:27, 28) Ojú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “Olùṣí àwọn àṣírí payá,” ni Dáníẹ́lì wò, kò wo oòrùn, òṣùpá tàbí àwọn ìràwọ̀, ó sì sọ ìtumọ̀ tó tọ̀nà fún ọba.—Dáníẹ́lì 2:36-45.
Àwọn Maya kò lè gba ìlú àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìparun ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án Sànmánì Kristẹni bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ ìràwọ̀ wò dáadáa. Kì í ṣe pé ìkùnà wọn fi hàn pé jìbìtì ló wà nídìí ìwòràwọ̀ nìkan ni, àmọ́, ó tún túdìí àṣírí ìdí tí ìwòràwọ̀ fi wà. Ìdí náà ni pé káwọn èèyàn má bàa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà nípa ọjọ́ ọ̀la.
Nítorí pé irọ́ ló wà nídìí ìwòràwọ̀, èyí jẹ́ ká mọ ọ̀dọ̀ ẹni tó ti wá. Jésù sọ nípa Èṣù pé: “Kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Sátánì máa ń díbọ́n pé òun jẹ́ “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” àwọn ẹ̀mí èṣù sì máa ń pa ara wọn dà di “òjíṣẹ́ òdodo.” Ní tòdodo, ẹlẹ́tàn ni wọ́n, wọ́n sì ti múra tán láti máa fẹ̀tàn mú àwọn èèyàn. (2 Kọ́ríńtì 11:14, 15) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tú àṣírí “iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́” pé ó jẹ́ “ìṣiṣẹ́ Sátánì.”—2 Tẹsalóníkà 2:9.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Yẹra fún Un
Inú irọ́ ni ìwòràwọ̀ ti wá, nítorí náà, ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́. (Sáàmù 31:5) Nítorí ìdí yìí, Bíbélì sọ kedere pé kò dára, ó sì rọ̀ wá pé ká ta kété sí i. Ní Diutarónómì 18:10-12, Ọlọ́run sọ kedere pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, . . . ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ló wà nídìí ìwòràwọ̀, téèyàn kan bá lọ́wọ́ Ámósì 5:15.
nínú rẹ̀, àwọn lá máa darí ẹni náà. Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá ń lo oògùn olóró, oògùn olóró náà lá máa darí onítọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn ẹni tó ń lọ́wọ́ nínú ìwòràwọ̀ ṣe rí, Sátánì, ọ̀gá àwọn ẹlẹ́tàn lá máa darí ẹni náà. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti òtítọ́ gbọ́dọ̀ sá fún wíwo ìràwọ̀, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.”—Nítorí pé àwọn èèyàn ń fẹ́ mọ ọjọ́ ọ̀la ni wọ́n ṣe máa ń lọ wo ìràwọ̀. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti mọ ọjọ́ ọ̀la? Tó bá ṣeé ṣe, báwo lèèyàn ṣe lè mọ̀ ọ́n? Bíbélì sọ fún wa pé a kò lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́la, lóṣù tó ń bọ̀, tàbí lọ́dún tó ń bọ̀. (Jákọ́bù 4:14) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ fún wa nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí aráyé lápapọ̀ láìpẹ́. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba tá à ń gbàdúrà fún nínú Àdúrà Olúwa yóò dé láìpẹ́. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Ó tún sọ fún wa pé ìyà tó ń jẹ aráyé yóò dópin láìpẹ́, kò sì ní sí ìpọ́njú mọ́. (Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:4) Kàkà kí Ọlọrun kádàrá ayé àwọn èèyàn, ńṣe ló ń pe gbogbo èèyàn níbi gbogbo láti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti ohun tí òun máa ṣe fún àǹfààní wọn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí “a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.
Ọ̀run tó lọ salalu yìí àti gbogbo nǹkan tó wà nínú rẹ̀ kò wà fún dídarí ìgbésí ayé wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi agbára Jèhófà àti jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run hàn wá. (Róòmù 1:20) Ohun tá a rí kọ́ lára wọn ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gba irọ́ gbọ́, ó ń jẹ́ ká máa wo ojú Ọlọ́run àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, fún ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé, tó máa mú kí ìgbésí ayé wa yọrí sí rere. Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ.”—Òwe 3:5, 6.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Àwọn Maya lo ìwòràwọ̀ lọ́nà tó gbòòrò gan-an
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
Àwọn Maya kò lè gba ìlú àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìparun bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ ìràwọ̀ wò dáadáa
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
“Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ibi tí wọ́n ti ń wojú ọ̀run ní el Caracol, Chichén Itzá, Yucatán, Mexico, ọdún 750 sí 900 Sànmánì Kristẹni
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Ojú ìwé 18 àti 19, látọwọ́ òsì sí ọ̀tún: Àwọn ìràwọ̀: NASA, ESA, àti A. Nota (STScI); Kàlẹ́ńdà àwọn Maya: © Lynx/Iconotec com/age fotostock; Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí wọ́n jẹ́ àwọn Maya: © Albert J. Copley/age fotostock; Ibi tí àwọn Maya ti ń wojú ọ̀run: El Caracol (The Great Conch) (fọ́tò), Àwọn Mayan/Chichen Itza, Yucatan, Mexico/Giraudon/The Bridgeman Art Library