Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Kọjú Ìjà Sí Àwọn Ọmọ Kénáánì?
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Kọjú Ìjà Sí Àwọn Ọmọ Kénáánì?
“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kùnà láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ.”—DIUTARÓNÓMÌ 20:17.
“Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—RÓÒMÙ 12:18.
ǸJẸ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kò ta kora wọn lójú rẹ? Ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti rí ìbáramu tó wà nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa nínú Bíbélì pé kí wọ́n pa àwọn ọmọ Kénáánì run àti èyí tó sọ pé ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. a (Aísáyà 2:4; 2 Kọ́ríńtì 13:11) Lójú wọn, ó jọ pé àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run yìí kò dúró sójú kan.
Tó o bá ní àǹfààní láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, kí lo máa bi í? Gbé àwọn ìbéèrè márùn-ún táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè yìí yẹ̀ wò àti ìdáhùn Bíbélì nípa wọn.
1. Kí nìdí tí wọ́n fi gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì? Tá a bá ní ká wò ó, orí ilẹ̀ táwọn ọmọ Kénáánì ń gbé kì í ṣe tiwọn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ní nǹkan bí irinwó [400] ọdún ṣáájú, Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù olóòótọ́ pé àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló máa ni ilẹ̀ Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 15:18) Ọlọ́run mú ìlérí yẹn ṣẹ nígbà tó ní kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù gba àgbègbè náà. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè sọ pé àwọn ọmọ Kénáánì ti ń gbébẹ̀ ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà, àwọn ọmọ Kénáánì ló lẹ́tọ̀ọ́ sí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ló ni gbogbo ẹ̀tọ́ láti pinnu ibi tó yẹ kí ẹnì kan gbé.—Ìṣe 17:26; 1 Kọ́ríńtì 10:26.
2. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ máa gbé? Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn ọmọ Kénáánì pé: “Kí wọ́n má ṣe gbé ní ilẹ̀ rẹ, kí wọ́n má bàa mú ọ ṣẹ̀ sí mi. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o sin àwọn ọlọ́run wọn, yóò di ìdẹkùn fún ọ.” (Ẹ́kísódù 23:33) Nígbà tó yá, wòlíì Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní tìtorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi lé wọn kúrò níwájú rẹ.” (Diutarónómì 9:5) Báwo ni ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè náà ti pọ̀ tó?
Ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà àti fífi ọmọ rúbọ pọ̀ káàkiri ilẹ̀ Kénáánì. Òpìtàn nípa Bíbélì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Henry H. Halley sọ pé àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n walẹ̀ àgbègbè náà “rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìkòkò ńlá tó ní egungun àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n ti fi rúbọ sí Báálì [ìyẹn òrìṣà pàtàkì kan nílẹ̀ Kénáánì].” Ó tún sọ pé: “Gbogbo àgbègbè náà jẹ́ sàréè àwọn ọmọ jòjòló. . . . Àwọn ọmọ Kénáánì máa ń bára wọn lò pọ̀ níwájú àwọn òrìṣà wọn, wọ́n ń fi ìbálòpọ̀ ṣe ààtò ẹ̀sìn fún àwọn òrìṣà náà, wọ́n sì tún máa ń pa
àwọn àkọ́bí wọn láti fi rúbọ sí àwọn òrìṣà náà. Dé ìwọ̀n tó bùáyà, ó jọ pé gbogbo ilẹ̀ Kénáánì ti di Sódómù àti Gòmórà. . . . . Àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n walẹ̀ níbi òkìtì àlàpà àwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Kénáánì ṣe kàyéfì pé kí ló dé tí Ọlọ́run kò fi tètè pa wọ́n run ṣáájú ìgbà yẹn.”3. Ṣebí àwọn aṣebi míì náà wà nígbà yẹn, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ọmọ Kénáánì ni Ọlọ́run dájú sọ? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Ọlọ́run ti pa àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ run. Nígbà tí “ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá” lọ́jọ́ Nóà, Ọlọ́run fi àkúnya omi pa gbogbo àwọn èèyàn náà run, ìdílé Nóà nìkan ló ṣẹ́ kù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11; 2 Pétérù 2:5) Ọlọ́run pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ “rinlẹ̀ gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20; 2 Pétérù 2:6) Ọlọ́run tún kéde ìdájọ́ ikú fún Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríyà tí í ṣe “ìlú ẹ̀jẹ̀,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá ìlú yẹn sí nígbà táwọn olùgbé ibẹ̀ yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn. (Náhúmù 3:1; Jónà 1:1, 2; 3:2, 5-10) Ní tàwọn ọmọ Kénáánì, Ọlọ́run pa wọ́n run kó bàa lè dáàbò bo Ísírẹ́lì tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó máa mú Mèsáyà wá nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Sáàmù 132:11, 12.
4. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa àwọn ọmọ Kénáánì run bá jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ mu? Tí èèyàn ò bá ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, ó lè kọ́kọ́ dà bíi pé bí Ọlọ́run ṣe pa àwọn ọmọ Kénáánì run kò bá jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ mu. (1 Jòhánù 4:8) Àmọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run máa túbọ̀ ṣe kedere tá a bá wo ọ̀ràn náà dáadáa.
Ọlọ́run ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé àwọn olùgbé ilẹ̀ Kénáánì ti ṣìnà. Síbẹ̀, dípò kó pa wọ́n rẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ńṣe ló fi sùúrù gbà kí irinwó [400] ọdún kọjá, torí pé ìṣìnà wọn “kò ti ikun.”—Genesisi 15:16, Bibeli Mimọ.
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì ti dé orí pé wọn ò lè ṣàtúnṣe mọ́, Jèhófà mú òpin dé bá wọn. Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò pa gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì run. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ gbogbo wọn kọ́ ló kọjá àtúnṣe. Ọlọ́run fi àánú hàn sáwọn kan tí wọ́n fẹ́ ṣe àtúnṣe, irú bíi Ráhábù àtàwọn ará Gíbéónì.—Jóṣúà 9:3-11, 16-27; Hébérù 11:31.
5. Kí nìdí tí Ọlọ́run ìfẹ́ fi ní láti pa ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí run? Ìdí tí ìbéèrè yìí fi wáyé ni pé kì í dùn mọ́ni nínú láti máa ronú nípa pípa àwọn èèyàn run. Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ló mú kó pa àwọn aṣebi náà run. A lè ṣàpèjúwé
rẹ lọ́nà yìí: Bí aláìsàn kan bá ní egbò kíkẹ̀, kò sóhun tí dókítà lè ṣe ju pé kó gé ibi tí egbò náà wà kúrò. Ṣàṣà dókítà ló máa fẹ́ ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ àwọn dókítà tó mọṣẹ́ mọ̀ pé ewu ńlá ló jẹ́ tí egbò náà bá kẹ̀ kọjá ibi tó wà. Nítorí pé ìlera aláìsàn náà jẹ dókítà lógún, ó máa ṣe iṣẹ́ tí kò rọrùn yìí fún àǹfààní aláìsàn náà.Bákan náà, kò dùn mọ́ Jèhófà nínú láti pa àwọn ọmọ Kénáánì run. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú.” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ní in lọ́kàn pé inú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Mèsáyà ti máa wá, òun ló máa ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́. (Jòhánù 3:16) Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run kò ní gbà kí ìwà ìbàjẹ́ àwọn ọmọ Kénáánì ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ọmọ Kénáánì run kúrò lórí ilẹ̀ náà. Ohun tí Ọlọ́run ṣe yìí fi ìfẹ́ rẹ̀ títayọ hàn, ìyẹn ìfẹ́ tó mú kó pa àwọn aṣebi run fún àǹfààní àwọn olóòótọ́ tí wọ́n ń jọ́sìn rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣohun tó dùn mọ́ ọn nínú láti pa wọ́n run.
Àǹfààní Tó Wà Níbẹ̀
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ìparun àwọn ọmọ Kénáánì ṣe wá láǹfààní lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ìwé Róòmù 15:4 sọ pé: “Nítorí gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Kénáánì ṣe fún wa ní ìtọ́ni àti ìrètí?
Àwọn ìtàn yẹn kọ́ wa lóhun tó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run fi àánú dá Ráhábù àti àwọn ará Gíbéónì sí nígbà tí ìgbàgbọ́ wọn mú kí wọ́n gbà láti sìn ín. Èyí rán wa létí pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wu Ọlọ́run ní tòótọ́ lè wù ú láìka ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá tàbí ibi tó ti wá sí.—Ìṣe 17:30.
Ìtàn tó dá lórí ìparun ilẹ̀ Kénáánì tún fún wa ní ìrètí nípa bó ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà. Ó mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ibi borí ire. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì mú un dá wa lójú pé ó máa pa gbogbo àwọn aṣebi run láìpẹ́, tí yóò sì dá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nídè bọ́ sínú ayé tuntun òdodo. (2 Pétérù 2:9; Ìṣípayá 21:3, 4) Ní àkókò yẹn, ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yìí yóò ṣẹ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.”—Sáàmù 37:34.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀rọ̀ náà “ọmọ Kénáánì” túmọ̀ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Ṣé Bíbélì Fọwọ́ sí Ogun Jíjà?
Ṣé àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àwọn ọmọ Kénáánì run fi hàn pé ó yẹ káwa èèyàn máa jagun lónìí? Rárá o, ó kéré tán ìdí mẹ́ta wà tí a kò gbọ́dọ̀ fi máa jagun:
▪ Kò sí orílẹ̀-èdè kankan lónìí tí Ọlọ́run fi ojú rere tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn sí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, wọn kò ṣojú fún Ọlọ́run mọ́ nínú ohunkóhun, títí kan ṣíṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè míì. (Mátíù 21:42, 43) Irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ló fi ń wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà. (Léfítíkù 18:24-28) Látìgbà yẹn, kò sí orílẹ̀-èdè kankan lórí ilẹ̀ ayé tó lè sọ pé Ọlọ́run ń ti òun lẹ́yìn nínú ogun.
▪ Jèhófà kò yan àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti máa gbé ní ilẹ̀ kan pàtó tàbí ní àgbègbè kan mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà” tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9; Ìṣe 10:34, 35.
▪ Jésù sọ kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní jagun. Nígbà tó ń kìlọ̀ nípa àjálù tó máa dé bá Jerúsálẹ́mù, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n kúrò nínú ìlú yẹn, wọn kò sì gbọ́dọ̀ jà, kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sá jáde, ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn. (Mátíù 24:15, 16) Dípò tí wọ́n á fi gbé ohun ìjà ogun, Ìjọba Ọlọ́run làwọn Kristẹni tòótọ́ gbẹ́kẹ̀ lé, èyí tó máa tó mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé.—Dáníẹ́lì 2:44; Jòhánù 18:36.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àpẹẹrẹ Ráhábù fi hàn pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti wu Ọlọ́run ní tòótọ́ lè wù ú