Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Bíbélì fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe nígbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn Báálì ọlọ́run èké?

Òrìṣà àwọn ará Kénáánì, ìyẹn Báálì ni wọ́n kà sí òrìṣà ìbímọlémọ. Àwọn olùjọsìn rẹ̀ gbà gbọ́ pé Báálì ló máa ń jẹ́ kí irè oko wọn dára, tó sì ń mú kí agbo ẹran wọn máa pọ̀ sí i. Ìdí nìyẹn tí ìwé Manners and Customs in the Bible, tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ fi sọ pé, “wọ́n dìídì ń ṣe ìṣekúṣe ní àwọn ojúbọ wọn torí kí irúgbìn àti agbo ẹran wọn lè máa pọ̀ sí i, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ kí òrìṣà Báálì, tí wọ́n gbà pé òun ló máa ń rọ òjò, àti ìkejì rẹ̀, ìyẹn Áṣérà máa ní ìbálòpọ̀ mímọ́, kí irè oko àti agbo ẹran wọn lè máa pọ̀ sí i.”

Àwọn ará Kénáánì gbà gbọ́ pé Báálì máa ń lọ sí ìsàlẹ̀ lábẹ́ ilẹ̀ nígbà ẹ̀rùn, ìyẹn nígbà tí Mot, ọlọ́run ọ̀gbẹlẹ̀ àti ikú bá ṣẹ́gun rẹ̀. Ìgbàgbọ́ wọn sì ni pé tí òjò àkọ́kọ́ bá ti rọ̀, Báálì ti gba agbára nìyẹn, èyí á sì mú kí irúgbìn àti agbo ẹran wọn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Àwọn ará Kénáánì máa ń ṣe àjọyọ̀ àkókò yìí pẹ̀lú ìṣekúṣe tí kò ní ààlà. Èyí jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń ní “ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù” nígbà tí wọ́n lọ sídìí òrìṣà Báálì ti Péórù.—Númérì 25:1-3.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí dà bí “àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun”?

Jésù sọ fáyé gbọ́ pé alágàbàgebè ni àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun, tí wọ́n fara hàn lóde bí ẹlẹ́wà ní tòótọ́ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn àti gbogbo onírúurú ohun àìmọ́.” (Mátíù 23:27) Àṣà àwọn Júù ni láti máa fi ẹfun kun sàréè lẹ́yìn tí àsìkò òjò bá ti kásẹ̀ nílẹ̀, ìyẹn tí Àjọyọ̀ Ìrékọjá bá ti ku oṣù kan, ó sì máa ń bọ́ sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù Ádárì. Àmọ́ tó bá ti di ìgbà òjò, òjò máa ń fọ gbogbo ẹfun náà dà nù.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Jewish Encyclopedia ṣe sọ, ìdí tí wọ́n fi ń kun àwọn sàréè ní ẹfun ni pé kí “onírúurú àwọn àlejò tó máa ń rìnrìn àjò wá síbi àjọyọ̀ Ìrékọjá” má bàa fara kan àwọn sàréè náà kí wọ́n sì di ẹlẹ́gbin. Òfin tó wà nínú Ìwé Númérì 19:16 sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú, egungun èèyàn tàbí sàréè máa di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. Ọmọ Ísírẹ́lì tó bá jẹ́ aláìmọ́ kò ní lè ṣe ìjọsìn mímọ́, bí kò bá sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, kíkú ló máa kú. (Léfítíkù 15:31) Jésù lo àpèjúwe yìí nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ kí wọ́n ṣe Ìrékọjá, torí náà, àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì máa rántí bí wọ́n ṣe máa ń kun sàréè lẹ́fun ní ọdọọdún. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé kì í ṣe bí àwọn tó ń ta kò ó yìí ṣe rí ní òde ara ni wọ́n rí ní inú àti pé ìjọsìn èèyàn lè di ẹlẹ́gbin tó bá ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú wọn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Òkúta ẹfun ti báálì ọlọ́run ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìnlá sí ìkẹtàlá ṣáájú sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

Musée du Louvre, ìlú Paris