Ìhìn Rere Ní Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Èdè
Ìhìn Rere Ní Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Èdè
NÍ ÀKÓKÒ tí ogun abẹ́lé ṣì ń gbóná girigiri lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà, àwọn atúmọ̀ èdè mélòó kan fi ohun ìní wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ. Àmọ́, wọ́n gbìyànjú láti gbé àwọn kọ̀ǹpútà alágbèéká wọn dání lọ sí ibùdó àwọn tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè wọn. Kí nìdí? Kí wọ́n bàa lè máa bá iṣẹ́ ìtumọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí èdè Kinyarwanda nìṣó.
Obìnrin kan ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà ń fi kọ̀ǹpútà rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè títí ilẹ̀ fi ṣú, ó ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu, ooru ń mú un, iná mànàmáná tí wọ́n sì ń mú-lọ-mú-bọ̀ kò jẹ́ kó gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe. Kí nìdí tó fi tẹra mọ́ iṣẹ́ náà? Ó fẹ́ tètè ṣe tán ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa tẹ ìwé náà.
Àwọn atúmọ̀ èdè yìí wà lára nǹkan bí egbèjìlá-ó-dín-ọgọ́rùn-ún [2,300] àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi tó lé ní igba-ó-dín-mẹ́wàá [190] káàkiri ayé. Ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogún [20] ọdún sí nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] ọdún, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kárakára kí àwọn èèyàn lè rí ìtùnú gbà látinú Bíbélì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èdè.—Ìṣípayá 7:9.
Mímú Ìhìn Rere Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Ń Sọ Onírúurú Èdè
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1985, ìgbà kan náà ni Ilé Ìṣọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè mẹ́tàlélógún [23] míì ń jáde, ìyẹn sì ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà yẹn. Àmọ́ ní báyìí, ọgọ́sàn-án-dín-mẹ́rin [176] èdè la fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde, gbogbo rẹ̀ ló sì ń jáde nígbà kan náà pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì kí àwọn òǹkàwé káàkiri ayé bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan náà nígbà kan náà.
Ilé Ìṣọ́ nìkan ni ìwé ìròyìn tí wọ́n máa ń tẹ̀ jáde déédéé ní èdè tó tó nǹkan bí àádọ́ta [50]. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ilé iṣẹ́ tó ń tẹ ìwé kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí títẹ ìwé tí wọ́n fi èdè ìbílẹ̀ kọ. Àmọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń fi tinútinú ṣètìlẹ́yìn kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì bàa lè wà níbikíbi tí kò bá ti rọrùn láti ṣe wọ́n jáde.—2 Kọ́ríńtì 8:14.
Àwọn èèyàn máa ń mọyì rẹ̀ gan-an tí wọ́n bá rí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ṣe àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde lédè Miskito, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] èèyàn ló ń sọ èdè yìí lórílẹ̀-èdè Nicaragua. Obìnrin kan béèrè fún Ìwé Ìtàn Bíbélì a ní èdè Miskito, pásítọ̀ kan lágbègbè náà sì wà níbẹ̀ nígbà tí obìnrin náà rí ìwé yìí gbà. Nígbà tí pásítọ̀ náà rí ìwé tó fani mọ́ra yìí, ó fẹ́ kó di tòun. Obìnrin yẹn kò fún un, pásítọ̀ náà tiẹ̀ fi ogún [20] gíráàmù èso kọfí lọ obìnrin yìí kó lè fún un ní ìwé náà, àmọ́ obìnrin náà kò gbà!
Láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, a ti túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀ tó ju méjìlá lọ tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, lára wọn ni èdè Maya, Nahuatl àti èdè Tzotzil. Ní ohun tí kò tó ọdún mẹ́wàá, ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ àti èdè àwọn adití lórílẹ̀-èdè náà ti gbèrú láti àádọ́rin-ó-lé-méjì [72] sí ohun tó ju ẹgbẹ̀fà [1,200] èdè lọ. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè gbin òtítọ́ sí ọkàn àwọn èèyàn, àmọ́ ojú Ọlọ́run là ń wò pé kó dàgbà.—1 Kọ́ríńtì 3:5-7.
Bíbélì Tí Wọ́n Tú Sí Ọgọ́rin Èdè Lóde Òní
Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣiṣẹ́ kárakára láti gbé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní ọgọ́rin [80] èdè. Kí sì ni àbájáde rẹ̀? Ọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè South Áfíríkà sọ nípa Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Tswana pé: “Irinṣẹ́ tó ṣeyebíye lèyí jẹ́. Ó máa jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò rọrùn láti kà, wọ́n sì gbádùn mọ́ni.” Ọkùnrin kan tó máa ń ka èdè Tsongan ní orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì kọ̀wé pé: “Téèyàn bá ní gbogbo àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, àmọ́ tí kò sí Bíbélì, ńṣe ló dà bí ìgbà tí ààrá sán, tí ìmọ́lẹ̀ bù yẹ̀rì àmọ́ tí òjò kò rọ̀! Òjò gan-an ló rọ̀ yìí bí wọ́n ṣe gbé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Tsonga.”
Ńṣe ni àwọn tó ń túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àti àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì ń mú àsọtẹ́lẹ̀ tó ti pẹ́ kan ṣẹ. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ló sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Graph tó wà ní ojú ìwé 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÌTUMỌ̀ AYÉ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE
TUNTUN MÍÌ
Èyí tó wà lódindi
tàbí lápá kan
80 2010 500 2010
36 2000
13 1990 200 1990
190 1980
7 1970 165 1970
125 1960
1 1950 88 1950
IYE ÈDÈ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó tó nǹkan bí egbèjìlá-ó-dín-ọgọ́rùn-ún ló ń túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èdè
BENIN
SLOVENIA
ETIÓPÍÀ
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ