Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
BÍBÉLÌ sọ pé: ‘Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run; nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.’ (1 Jòhánù 4:8, Bibeli Mimọ) Nítorí náà, ó yẹ kí ìsìn tòótọ́ máa kọ́ni láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń ṣe dáadáa nínú bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn aláìlera, àwọn àgbàlagbà àtàwọn òtòṣì. Wọ́n máa ń rọ àwọn ọmọ ìjọ wọn láti máa fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Jòhánù sílò, ó ní: ‘Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ní ohun ìní ayé, tó sì rí arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ní ìṣe 1 Jòhánù 3:17, 18, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
àti ní òtítọ́.’—Àmọ́, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá lọ jagun? Ṣé ìgbà tí àlàáfíà bá wà nìkan ló yẹ ká pa òfin Ọlọ́run tó sọ pé ‘fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ’ mọ́, ká sì wá tẹ̀ ẹ́ lójú nígbà tí olóṣèlú tàbí ọba kan bá fẹ́ bá orílẹ̀-èdè míì jà?—Mátíù 22:39, Bibeli Mimọ.
Jésù sọ pé: ‘Nípa èyí ni gbogbo èèyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, nígbà tí ẹ̀yín bá ní ìfẹ́ ọmọnìkejì yín.’ (Jòhánù 13:35, Bibeli Mimọ) Bó o ṣe ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí, bi ara rẹ pé, ‘Ṣáwọn ọmọ ìjọ tó o mọ̀ yìí máa ń fi hàn nígbà gbogbo nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà wọn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn?’
ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ogun.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ ṣoore fáwọn tó kórìíra yín.’—Mátíù 5:44, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Nígbà táwọn ọmọ ogun wá mú Jésù, àpọ́sítélì Pétérù fa idà yọ láti fi gbèjà rẹ̀. Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: ‘Fi idà rẹ sí ipò rẹ̀. Nítorí pé gbogbo àwọn tí ó mú idà ni yóò ti ipa idà ṣègbé.’—Mátíù 26:52, Bibeli Mimọ.
Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: ‘Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọ́run yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù ni yìí; gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sí fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí a fẹ́ràn ara wa. Kí a má ṣe dà bí Kéènì tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arákùnrin rẹ̀.’—1 Jòhánù 3:10-12, Ìròhìn Ayọ̀.
ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń fáwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n máa jagun?
ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ìṣèlú.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Lẹ́yìn táwọn kan ti rí agbára tí Jésù ní láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, wọ́n fẹ́ kó wá di olóṣèlú. Kí ni Jésù ṣe? Bíbélì sọ pé: ‘Nígbà tí Jésù sì wòye pé, wọ́n ń fẹ́ wá fagbára mú òun láti lọ fi jọba, ó tún pa dà lọ sórí òkè lóun nìkan.’—Jòhánù 6:15, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú Jésù tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ń mú káwọn èèyàn máa ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, ó dá wọn lóhùn pé: ‘Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí; ìbáṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá jà, kí a máa bàa fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́; ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.’—Jòhánù 18:36, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: ‘Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé.’—Jòhánù 17:14, Bibeli Ajuwe.
ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tí wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, kódà tí ìyẹn bá máa yọrí sí pé káwọn olóṣèlú kan kórìíra àwọn ọmọ ìjọ náà?
ÀKÒRÍ Ọ̀RỌ̀: Ẹ̀tanú.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni lára àwọn tí kì í ṣe Júù pé: ‘Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú èèyàn; ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.’—Ìṣe 10:34, 35, Bibeli Mimọ.
Nígbà tí Jákọ́bù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ó sọ pé: ‘Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa, Jésù Kristi, Olúwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojúsàájú. Fún àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá wọ àwùjọ yín tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tó ń dán, tí tálákà kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí; ẹ máa ń fi ojú rere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ ń sọ fún un pé, ‘Wá jókòó níbi dáradára yìí.’ Ṣùgbọ́n ẹ wá sọ fún tálákà pé, ‘Dúró níbẹ̀ tàbí wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn.’ Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàárín ara yín, ẹ kò sì ń ṣe ìdájọ́ nípa ìwò ojú?’—Jákọ́bù 2:1-4, Ìròhìn Ayọ̀.
ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń kọ́ni pé bákan náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run àti pé àwọn ọmọ ìjọ ò gbọ́dọ̀ máa ka ara wọn sí pàtàkì ju àwọn tó kù lọ torí ẹ̀yà wọn tó yàtọ̀ tàbí torí pé wọ́n rí tajé ṣe?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Ìsìn wo ló ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, ẹ̀yà àti owó jẹ́ kí wọ́n máa rò pé àwọn sàn ju àwọ́n míì lọ?