3. Jẹ́ Káwọn Ẹlòmíì Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Bó O Ṣe Lè Lóye Bíbélì
3. Jẹ́ Káwọn Ẹlòmíì Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Edward John Eyre, tó máa ń ṣàwárí nǹkan rìnrìn àjò lọ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Nullarbor, tó jẹ́ aṣálẹ̀, àwọn tó ti kọ́kọ́ tẹ ibẹ̀ dó kọ́ Ọ̀gbẹ́ni Eyre bí wọ́n ṣe máa ń rí omi nínú àwọn òkìtì yanrìn tí afẹ́fẹ́ gbá jọ àti nínú àwọn igi eucalyptus. Ọ̀gbẹ́ni Eyre gba ẹ̀mí ara ẹ̀ là torí pé ó gbà káwọn tó mọ àdúgbò yẹn ran òun lọ́wọ́.
ÌRÍRÍ ọ̀gbẹ́ni Eyre yìí fi hàn pé téèyàn bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ alágbára kan láṣeyọrí, àfi kéèyàn gbà pé kí ẹlòmíì tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ọ̀hún ran òun lọ́wọ́. Ohun tó yẹ kó o ṣe náà nìyẹn tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì.
Jésù ò retí pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣàdédé lóye Bíbélì láìjẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó “ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ.” (Lúùkù 24:45) Jésù mọ̀ pé àwọn tó ń ka Bíbélì nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́.
Ta Ló Máa Ràn Wọ́n Lọ́wọ́?
Jésù pàṣẹ fáwọn tó ń fi tọkàntọkàn tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé kí wọ́n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Kí Jésù tó gòkè lọ sọ́run, ó pàṣẹ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín Mátíù 28:19, 20) Olórí iṣẹ́ táwa Kristẹni gbà ni láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn sì gba pé ká máa ṣàlàyé fún wọn nípa bí wọ́n ṣe lè máa fàwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wọn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.
mọ́.” (Kò pẹ́ sígbà tí Jésù pa àṣẹ yìí fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó fani lọ́kàn mọ́ra fi wáyé. Bíbélì ròyìn nípa ìjòyè kan láti ilẹ̀ Etiópíà tó ń ka apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. Ìjòyè yẹn ka ibì kan níbẹ̀, àmọ́ kò lóye rẹ̀. Ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tó ń kà yẹn ni pé: “Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn, a mú un wá fún ìfikúpa, àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lè fọhùn níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun kò la ẹnu rẹ̀. Nígbà ìtẹ́lógo rẹ̀, a mú ìdájọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ta ni yóò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí a mú ìwàláàyè rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 8:32, 33; Aísáyà 53:7, 8.
Ìjòyè yẹn wá béèrè lọ́wọ́ Fílípì, tó jẹ́ Kristẹni tó lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa, pé: “Ta ni wòlíì náà sọ èyí nípa rẹ̀? Nípa ara rẹ̀ ni tàbí nípa ẹlòmíràn?” (Ìṣe 8:34) Ìjòyè, tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́, yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ́sìn tán ní Jerúsálẹ́mù ni, ó sì ṣeé ṣe kó ti gbàdúrà níbẹ̀ pé kí Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló ń fi tọkàntọkàn ka ìwé yẹn, ó sì ń fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i. Àmọ́, ìjòyè yìí ò lóye ohun tó ń kà. Ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bẹ Fílípì pé kó ran òun lọ́wọ́. Àwọn àlàyé tí Fílípì ṣe wọ ìjòyè yẹn lọ́kàn gan-an, inú ẹ̀ sì dùn débi pé ó pinnu láti di Kristẹni.—Ìṣe 8:35-39.
Iṣẹ́ tí Fílípì àtàwọn yòókù tí wọ́n jọ bẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni ṣe làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń ṣe nìṣó lóde òní. À ń yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì láwọn orílẹ̀-èdè tó ju igba àti márùnlélọ́gbọ̀n [235] lọ. Onírúurú kókó ọ̀rọ̀ tó dá lórí Ìwé Mímọ́ la máa ń jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bá ṣe ń tẹ̀ síwájú, a máa ń ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. a—Wo àpótí tá a pe àkọlé ẹ̀ ní: “Àwọn Ìdáhùn Tó Tẹ́ni Lọ́rùn Látinú Bíbélì.”
‘Ó Dáhùn Gbogbo Ìbéèrè Mi’
Ọ̀gbẹ́ni Steven, Valvanera àti Jo-Anne, tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ yẹn, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Steven sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé mo lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi nípa fífi àwọn ìlànà tàbí àwọn ìtàn kan wéra nínú Bíbélì. Mi ò rẹ́ni sọ fún mi pé mo lè ṣe bẹ́ẹ̀ àfìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú mi dùn gan-an láti mọ̀ pé èèyàn lè rí ìdáhùn tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn nínú Bíbélì láìsí iyàn jíjà àti àwọn èrò tó ń ta kora nípa Ọlọ́run àti Bíbélì.”
Valvanera pàápàá gbà pẹ̀lú nǹkan tí Steven sọ yìí, ó ní: “Gbogbo ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi látinú Bíbélì ló ṣe kedere tó sì bọ́gbọ́n mu. Mo ti wá rí i pé ìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ gba àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì gbọ́ kì í ṣe torí pé à ń gbọ́ ọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ torí pé àlàyé tó bọ́gbọ́n mu wà lórí gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì.” Jo-Anne sọ pé: “Mo túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run, tó jẹ́ òǹṣèwé Bíbélì, torí pé ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè mi wà nínú Bíbélì, Ọlọ́run ti mọ onírúurú ìbéèrè tó ṣeé ṣe káwa èèyàn ní, ó sì ti fàwọn ìdáhùn tó bá a mu wẹ́kú sínú Bíbélì.”
Ṣó o mọ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? O ò ṣe ní kó wá fi bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ẹ́? Tó ò bá mọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn àdírẹ́sì tá a kọ sójú ìwé 4 nínú ìwé ìròyìn yìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò ní ṣòro fún ẹ láti lóye tó o bá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tó o fi tọkàntọkàn ka Bíbélì, tó o sì jẹ́ kí ẹni tó dáńgájíà nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́. O lè lóye Bíbélì!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa onírúurú kókó ọ̀rọ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Ìdáhùn Tó Tẹ́ni Lọ́rùn Látinú Bíbélì
Díẹ̀ lára àwọn kókó ọ̀rọ̀ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jíròrò tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rèé:
• Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí?
• Ibo làwọn òkú wà?
• Ṣé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí?
• Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?
• Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí ìdílé mi máa láyọ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tó o bá fẹ́ lóye Bíbélì . . . gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí rẹ̀, kó o fi tọkàntọkàn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì jẹ́ káwọn ẹ̀lòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́