Ṣé Ẹ̀kọ́ Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Bá Tàwọn Àpọ́sítélì Mu?
Ṣé Ẹ̀kọ́ Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Bá Tàwọn Àpọ́sítélì Mu?
NÍGBÀ tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, ẹ̀kọ́ èké ti bẹ̀rẹ̀ sí í dà pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ táwọn Kristẹni ń kọ́ni. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí ṣe sọ, lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn kan pa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú àwọn “ìtàn èké.” (2 Tímótì 4:3, 4) Ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni, Jòhánù tó jẹ́ àpọ́sítélì tó kẹ́yìn, kìlọ̀ nípa irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀, ó sì tún kìlọ̀ nípa àwọn èèyàn ‘tí ń gbìyànjú láti ṣi’ àwọn Kristẹni olóòótọ́ lọ́nà.—1 Jòhánù 2:26; 4:1, 6.
Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin táwọn èèyàn wá mọ̀ sáwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì gbìyànjú láti nípa lórí àwọn èèyàn nípa àwọn ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀. Ipa wo ni wọ́n kó nínú
fífi ìsìn èké tan àwọn èèyàn jẹ? Ṣé wọ́n fetí sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti sọ fún wọn?Àwọn Wo Làwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì?
Àwọn tí wọ́n ń pè ní “Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì” làwọn òǹkọ̀wé ìsìn tó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tàbí tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn táwọn àpọ́sítélì ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọkùnrin yìí gbé láyé láti ìparí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni títí lọ dé ìlàjì ọ̀rúndún kejì. a Lára wọn ni Clement tó wá láti ìlú Ròómú, Ignatius tó wá láti ìlú Áńtíókù, Papias tó wá láti ìlú Hirapólísì àti Polycarp tó wá láti ìlú Símínà. Àwọn òǹkọ̀wé kan tí wọn ò sọ orúkọ wọn wà lára àwọn òǹkọ̀wé tó kọ̀wé láàárín àkókò kan náà pẹ̀lú àwọn Bàbá Ìjọ yìí, àwọn ìwé tí wọ́n kọ ni The Didache, Epistle of Barnabas, Martyrdom of Polycarp àti lẹ́tà Clement kejì.
Lóde òní, kò rọrùn láti sọ pé ibi báyìí ni ẹ̀kọ́ àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì ti jọra pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni. Ó dájú pé ohun táwọn ọkùnrin yìí fẹ́ ṣe ni pé kí wọ́n gbé oríṣi ẹ̀sìn Kristẹni míì kalẹ̀ tàbí kí wọ́n máa tì í lẹ́yìn. Wọ́n gbà pé ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe ò dáa. Wọ́n nígbàgbọ́ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, wọ́n sì gbà gbọ́ pé Jésù jíǹde. Àmọ́, wọn ò rí nǹkan kan ṣe sí bí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà ṣe ń gbilẹ̀ sí i. Kàkà kí wọ́n rí nǹkan ṣe sí i, ńṣe làwọn míì nínú wọn tún ń dá kún un.
Ṣé Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Wọn Já Mọ́ Nǹkan kan?
Ẹ̀kọ́ táwọn kan tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ń kọ́ni yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀kọ́ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó kọ̀wé The Didache dábàá pé kí wọ́n kọ́kọ́ máa gbé ọtí ṣáájú búrẹ́dì nígbà Ìrántí Ikú Kristi, tá a tún mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ìyẹn sì yàtọ̀ sóhun tí Jésù tó dá ayẹyẹ náà sílẹ̀ ṣe. (Mátíù 26:26, 27) Òǹkọ̀wé yìí tún sọ pé tí kò bá sí omi tó pọ̀ tó láti fi ṣe batisí nípasẹ̀ ríri ẹnì kan bọmi, ó ní dída omi lé ẹni náà lórí ti tó. (Máàkù 1:9, 10; Ìṣe 8:36, 38) Òǹkọ̀wé yẹn kan náà tún rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa pa àwọn ààtò kan mọ́, irú bíi gbígbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ àti kíka Àdúrà Olúwa lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.—Mátíù 6:5-13; Lúùkù 18:12.
Ọ̀gbẹ́ni Ignatius tiẹ̀ sọ pé ó yẹ kí ìjọ Kristẹni tuntun kan wà tó jẹ́ pé bíṣọ́ọ̀bù kan ṣoṣo lá máa darí ẹ̀, tí bíṣọ́ọ̀bù yẹn á sì “máa wà nípò Ọlọ́run.” Bíṣọ́ọ̀bù yìí lá máa pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà. Àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àìmọye àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu làwọn èèyàn yìí ṣì máa gbé kalẹ̀.—Mátíù 23:8, 9.
Àsọdùn, Ìṣìkàpànìyàn àti Ìbọ̀rìṣà
Àwọn Bàbá Ìjọ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó jìnnà sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ pátápátá torí pé àwọn fúnra wọn gba ìtàn èké tàbí àsọdùn gbọ́. Ọ̀gbẹ́ni Papias fẹ́ mọ òtítọ́, ó sì tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nínú àwọn ìwé tó kọ. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún gbà gbọ́ pé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀, àwọn igi àjàrà máa yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ẹ̀ka, ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan máa yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ẹ̀ka kéékèèké, àwọn ẹ̀ka kéékèèké máa yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ọ̀mùnú, ọ̀mùnú kọ̀ọ̀kan máa yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá
[10,000] ìṣù èso àjàrà, ìṣù èso àjàrà kọ̀ọ̀kan sì máa yọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] èso àjàrà, èso àjàrà kọ̀ọ̀kan sì máa mú tó ẹgbẹ̀rún kan [1,000] lítà ọtí wáìnì jáde.Ọ̀gbẹ́ni Polycarp ṣe tán láti kú dípò kó sẹ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. A gbọ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó mọ Jésù ló ti kẹ́kọ̀ọ́. Nínú àwọn ìwé tó kọ, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì, ó sì dà bíi pé ó gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Kristẹni.
Àmọ́, ọ̀gbẹ́ni Polycarp di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ fáwọn kan torí bí wọ́n ṣe bọ̀wọ̀ fún un tó. Ìwé Martyrdom of Polycarp sọ pé lẹ́yìn tí Polycarp kú, àwọn kan tí wọ́n pè ní “olóòótọ́” èèyàn fẹ́ kí wọ́n gbé òkú ẹ̀ fáwọn. Wọ́n gbà pé àwọn egungun ẹ̀ “ṣeyebíye gan-an ju àwọn nǹkan olówó iyebíye lọ, ó sì mọ́ ju wúrà lọ.” Èyí tún wá jẹ́ kó hàn gbangba pé ṣe ni ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà túbọ̀ ń gbòde kan.
Àwọn Ìwé Tí Wọ́n Pè Ní Àfikún Bíbélì
Àwọn kan lára àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì gbà pé Ọlọ́run mí sí àwọn ìwé tí wọ́n pè ní àfikún Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn Bàbá Ìjọ yìí, ìyẹn ọ̀gbẹ́ni Clement, tó wá láti ìlú Róòmù, fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé tí wọ́n ń pè ní Wisdom àti Judith. Ẹni tó kọ ìwé The Epistle of Polycarp tọ́ka sóhun tó wà nínú ìwé Tobit láti fi ti ọ̀rọ̀ tó sọ lẹ́yìn pé téèyàn bá ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn, ó lè jẹ́ kónítọ̀hún bọ́ lọ́wọ́ ikú.
Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni àwọn ìwé Ìhìn Rere kan tan àwọn ìtàn èké kálẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù, àwọn Bàbá Ìjọ yìí sì gbà pé òótọ́ làwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà, wọ́n tiẹ̀ tún máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Ignatius fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé kan tí wọ́n pè ní Gospel of the Hebrews. Ìwé kan sì sọ nípa ọ̀gbẹ́ni Clement tó wá láti ìlú Róòmù pé: “Ó dà bíi pé kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn Ìwé Ìhìn Rere ni ọ̀gbẹ́ni Clement fi mọ̀ nípa Kristi, àmọ́ nípasẹ̀ àwọn ìwé tí kò sí nínú Bíbélì.”
Àṣìṣe Tí Kò Lóǹkà
Àwọn Bàbá Ìjọ yìí fàyè gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àṣìṣe torí lílò tí wọ́n lo ìtàn èké, èrò àwọn abọ̀rìṣà àti èrò àwọn onímọ̀ ọgbọ́n òrí láti fi ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń bọ oòrùn nílẹ̀ Íjíbítì sọ ìtàn àròsọ nípa ẹyẹ kan tí wọ́n sọ pé ó jíǹde lẹ́yìn tó kú, ìyẹn sì ni ọ̀gbẹ́ni Clement rí tọ́ka sí pé ó jẹ́ ẹ̀rí pé àjíǹde wà fáwọn òkú.
Ẹni tó kọ ìwé Epistle of Barnabas náà bomi la òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ó ṣàlàyé Òfin Mósè bíi pé ìtándòwe lásán ni. Ó ní àwọn ẹran tó mọ́, ìyẹn àwọn ẹran tó máa ń jẹ àpọ̀jẹ, tí wọ́n sì tún la pátákò, ṣàpẹẹrẹ àwọn tó máa ń ṣàṣàrò tàbí tí wọ́n máa ń pàpọ̀jẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òǹkọ̀wé náà sọ pé, àlàfo tó wà ní pátákò ẹran yẹn ṣàpẹẹrẹ bí olódodo èèyàn ṣe ń “gbé ní ayé yìí” lẹ́sẹ̀ kan náà tó tún ń wọ̀nà fún ìgbà tá á lọ máa gbé ní ọ̀run. Àwọn ìtúmọ̀ yìí ò bá Ìwé Mímọ́ mu.—Léfítíkù 11:1-3.
Àwọn Ohun Tó Ṣojú Àpọ́sítélì Jòhánù
Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.” (1 Jòhánù 4:1) Ẹ ò rí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ yìí!
Nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni ti pa ẹ̀kọ́ Jésù àti tàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tì. Dípò káwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì yìí wá bí wọ́n ṣe máa paná ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà tó ń gbilẹ̀, ṣe ni wọ́n tún dá kún un. Wọ́n fi májèlé sínú ẹ̀kọ́ òtítọ́ fáwọn èèyàn! Àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ti ara rẹ̀ síwájú, tí kò sì dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi kò ní Ọlọ́run.” (2 Jòhánù 9) Ìkìlọ̀ yìí ń ró gbọnmọgbọnmọ, títí dòní olónìí létí gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn wá ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn èèyàn sábà máa ń pe àwọn òǹkọ̀wé, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ní Bàbá Ìsàlẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn Bàbá Ìsàlẹ̀ yìí gbé láyé láàárín ọ̀rúndún kejì àti ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Kristẹni.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Àwọn kan lára àwọn Bàbá Ìjọ, títí kan Clement, lo ìtàn èké, èrò àwọn abọ̀rìṣà àti èrò àwọn onímọ̀ ọgbọ́n òrí nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ọ̀gbẹ́ni Polycarp ṣe tán láti kú torí ìgbàgbọ́ ẹ̀
[Credit Line]
Látọwọ́: The Granger Collection, New York