1 Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì
1 Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
ÌDÍ TÓ FI ṢÒRO: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ronú pé ọgbọ́n orí àwọn èèyàn kan ló wà nínú Bíbélì. Àwọn kan gbà pé àwọn ìtàn inú Bíbélì ò ṣeé gbára lé. Àwọn míì sì sọ pé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ò mọ́gbọ́n dání tàbí pé kò bágbà mu.
BÓ O ṢE LÈ ṢÀṢEYỌRÍ: Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kò tíì ṣèwádìí ohunkóhun nípa Bíbélì ló máa ń sọ pé Bíbélì ò wúlò tàbí pé kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ńṣe lọ̀pọ̀ nínú wọn kàn ń tún ohun tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn ẹlòmíì sọ. Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
Dípò ká máa gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́ láìronú jinlẹ̀ nípa wọn, ẹ ò ṣe jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó wà nílùú Bèróà, lápá àríwá ìlú Gíríìsì òde òní? Wọn ò wulẹ̀ gba gbogbo ọ̀rọ̀ táwọn ẹlòmíì bá sọ fún wọn gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ́ wọn lára láti máa ‘fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ kí wọ́n lè rí i bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyẹn rí.’ (Ìṣe 17:11) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí méjì tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí.
Àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì ṣeé gbára lé. Ọjọ́ pẹ́ táwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ Bíbélì ti ń kọminú sórúkọ àwọn èèyàn àti orúkọ àwọn àdúgbò tí Bíbélì mẹ́nu kàn, wọn ò sì tíì jáwọ́ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ náà, léraléra làwọn ẹ̀rí tó wà ń jẹ́ ká mọ̀ pé àríyànjiyàn àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ wọ̀nyẹn ò lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀ tó sì ń jẹ́ kó yé wa pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé kò sí ọba Ásíríà kankan tó ń jẹ́ Ságónì, bó ṣe wà nínú ìwé Aísáyà 20:1. Àmọ́ láàárín ọdún 1840 sí 1849 àwọn awalẹ̀pìtàn bẹ̀rẹ̀ sí í hú àwọn nǹkan kan jáde tó fi hàn pé ọba yẹn ní ààfin, wọ́n sì wá rí i pé ọ̀kan lára àwọn ọba Ásíríà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ni Ságónì.
Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ tún sọ pé kò sẹ́nì kankan tó ń jẹ́ Pọ́ńtíù Pílátù, ìyẹn Gómìnà tó pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù. (Mátíù 27:1, 22-24) Àmọ́ nígbà tó di ọdún 1961, àwọn awalẹ̀pìtàn rí orúkọ Pílátù àti ipò tó wà nígbà yẹn lára òkúta kan tí wọ́n rí nítòsí ìlú Kesaréà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.
Nígbà tí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ti October 25, ọdún 1999 ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì ṣe jóòótọ́ tó, ó sọ pé: “Lọ́nà àrà, àwọn awalẹ̀pìtàn òde òní ti ráwọn nǹkan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ póòótọ́ làwọn ìtàn tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun, látorí ìtàn àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kúrò ní Íjíbítì, títí dórí ìjọba Dáfídì àti ìtàn nípa ìgbésí ayé Jésù nígbà tó wà láyé.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò dìgbà táwọn awalẹ̀pìtàn bá ráwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé ká tó lè mọ̀ pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìtàn tó wà nínú ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí ṣeé gbára lé.
Ọgbọ́n tó wúlò tó wà nínú Bíbélì ń ṣe onírúurú èèyàn láǹfààní láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Tipẹ́tipẹ́ káwọn èèyàn tó mọ̀ nípa àwọn kòkòrò tín-ín-tìn-ìn-tín tó máa ń fa àrùn ni Bíbélì ti fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká wà ní mímọ́, àwọn ìmọ̀ràn náà sì wúlò títí dòní olónìí. (Léfítíkù 11:32-40; Diutarónómì 23:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, tí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ bá ń fàwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn èèyàn sílò, ìdílé wọn á túbọ̀ láyọ̀. (Éfésù 5:28–6:4) Àwọn èèyàn sì sábà máa ń rí i pé òṣìṣẹ́ tó ṣeé fọkàn tán àti agbanisíṣẹ́ tó ń fọgbọ́n hùwà làwọn tó bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù. (Éfésù 4:28; 6:5-9) Àwọn tó bá ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù tún máa ń jàǹfààní ìlera tó jíire. (Òwe 14:30; Éfésù 4:31, 32; Kólósè 3:8-10) Kò yà wá lẹ́nu, nítorí pé irú àwọn ìmọ̀ràn tó yẹ ká máa retí látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa náà nìyẹn.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè sọ aláìní ìrírí pàápàá di ọlọ́gbọ́n. (Sáàmù 19:7) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣohun tó kàn tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára.
Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 2 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.