Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?

“Raquel mi ọ̀wọ́n,

Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ pé o jẹ́ ìṣírí fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè má mọ̀ pé àwọn ìṣírí tó ò ń fún mi, àtàwọn ọ̀rọ̀ rere rẹ ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”—Jennifer.

ǸJẸ́ o ti gba lẹ́tà ìdúpẹ́ kan tí o kò retí rẹ̀ rí? Ó dájú pé irú ọ̀rọ̀ ìmoore bẹ́ẹ̀ á mú orí rẹ wú. Ó ṣe tán, ìwà ẹ̀dá ni pé ká fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a wúlò, a sì tún ń fẹ́ kí wọ́n mọyì wa.—Mátíù 25:19-23.

Ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ máa ń mú kí àjọṣe tó wà láàárín ẹni tó fúnni ní nǹkan àtẹni tó gbà á túbọ̀ lágbára sí i. Ìyẹn nìkan kọ́ o, téèyàn bá ń dúpẹ́ oore, ńṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù Kristi, ẹni tó máa ń kíyè sí iṣẹ́ rere táwọn ẹlòmíràn ń ṣe.—Máàkù 14:3-9; Lúùkù 21:1-4.

Lóde òní, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ dúpẹ́ oore, bóyá kí wọ́n sọ ọ́ ni o, tàbí kí wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹni tá a ṣe lóore tí kò dúpẹ́, bí ọlọ́ṣà kóni lẹ́rù lọ ni. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn yóò jẹ́ “aláìlọ́pẹ́.” (2 Tímótì 3:1, 2) Bá ò bá kíyè sára, ẹ̀mí àìmoore tó wọ́pọ̀ gan-an lóde òní yóò pa gbogbo ẹ̀mí ìmoore tá a ní.

Kí làwọn òbí lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa dúpẹ́ oore? Àwọn wo ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìmoore, àní báwọn tó yí wa ká ò bá tiẹ̀ moore?

Jíjẹ́ Ẹni Tó Moore Nínú Ìdílé

Àwọn òbí máa ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò. Àmọ́ nígbà míì, àwọn òbí lè rí i pé àwọn ọmọ ò mọyì ohun táwọn ń ṣe fún wọn. Kí làwọn òbí lè ṣe tọ́rọ̀ bá dà báyìí? Ohun pàtàkì mẹ́ta kan wà tí wọ́n ní láti ṣe.

(1) Àpẹẹrẹ. Fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ jẹ́ ọ̀nà tó dára jù láti gbà kọ́ àwọn ọmọ. Bíbélì sọ nípa ìyá tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ tó dáa nípa rẹ̀.” Ibo làwọn ọmọ rẹ̀ ti kọ́ láti máa fi ìmoore hàn? Apá tó ṣẹ́ kù nínú ẹsẹ yẹn jẹ́ ká mọ̀. Ó ní: “Ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú yìn ín.” (Òwe 31:28, Bíbélì New Century Version) Ńṣe ni bàbá àti ìyá tó máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ara wọn máa ń fi han àwọn ọmọ wọn pé irú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń múnú ẹni tá a sọ ọ́ fún dùn, ó sì máa ń mú kí àjọṣe àárín ìdílé túbọ̀ dán mọ́rán. Ó tún jẹ́ àmì pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ lọ́kàn wọn nínú ìdílé náà.

Bàbá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stephen sọ pé: “Mó ń sapá láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ mi nípa dídúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó mi fún oúnjẹ alẹ́.” Kí ni èyí yọrí sí? Stephen sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì kíyè sí i, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn máa túbọ̀ fi ìmoore hàn.” Bó o bá ti ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ aya tàbí ọkọ rẹ, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ló ṣe? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ, kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe wọn nínú ilé ni wọ́n ṣe?

(2) Ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀mí ìmoore dà bí òdòdó. Èèyàn ní láti tọ́jú òdòdó dáadáa téèyàn bá fẹ́ kó lẹ́wà. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìmoore kí wọ́n sì máa dúpẹ́ oore? Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ ohun pàtàkì kan tó lè ranni lọ́wọ́, ó ní: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”—Òwe 15:28.

Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ lè kọ́ àwọn ọmọ yín láti mọ̀ pé tí wọ́n bá rí ẹ̀bùn kan gbà, ọ̀pọ̀ ìsapá lẹni tó fún wọn lẹ́bùn náà ti ṣe àti pé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ló mú un ṣe é? Ṣíṣàṣàrò bí irú èyí yóò mú kí wọ́n ní ẹ̀mí ìmoore, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tèèyàn gbin òdòdó sórí ilẹ̀ rere. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Maria, tó ti tọ́ ọmọ mẹ́ta dàgbà sọ pé: “Ó gba àkókò láti pe àwọn ọmọ jókòó kéèyàn sì ṣàlàyé fún wọn nípa ohun tó mú ẹnì kan fúnni lẹ́bùn, pé ńṣe lonítọ̀hún ronú nípa ẹni, tó sì fẹ́ fi hàn bí òun ṣe bìkítà nípa ẹni náà tó. Àmọ́ mo mọ̀ pé ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́ àwọn ọmọ náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Yàtọ̀ sí pé irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ á mú káwọn ọmọ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n sọ láti fi dúpẹ́, yóò tún jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n dúpẹ́.

Àwọn òbí tó mòye máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n má ṣe rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni pé káwọn èèyàn máa fún àwọn ní nǹkan. a Ìkìlọ̀ kan tó wà ní Òwe 29:21 tó sọ nípa bó ṣe yẹ kí ọ̀gá ṣe sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan àwọn ọmọ pẹ̀lú, ó ní: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.”

Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ kékeré láti mọ bá a ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ èèyàn? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Linda, tó ní ọmọ mẹ́ta sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi máa ń ní káwọn ọmọ wa bá wa lọ́wọ́ sí ṣíṣe káàdì ìdúpẹ́ tá a fẹ́ fi ránṣẹ́ sáwọn èèyàn. A máa ń ní kí wọ́n yàwòrán sínú rẹ̀ kí wọ́n sì kọ orúkọ wọn sínú rẹ̀.” Lóòótọ́, àwòrán náà lè má gún régé, kí ìwé tí wọ́n kọ sì ṣòroó kà, àmọ́ ẹ̀kọ́ tí wọn ò ní gbàgbé làwọn òbí wọn ń kọ́ wọn pé wọ́n ní láti máa dúpẹ́ oore.

(3) Ìforítì. Ìwà ẹ̀dá aláìpé ni láti jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, èyí kì í sì í jẹ́ ká dúpẹ́ oore. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Mátíù 15:19) Síbẹ̀, Bíbélì rọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé: “Kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Éfésù 4:23, 24.

Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí tí wọ́n ní ìrírí mọ̀ pé ríran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀” kò rọrùn. Ọkùnrin tó ń jẹ́ Stephen tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kíkọ́ àwọn ọmọ wa láti fúnra wọn sọ pé, ẹ ṣeun, láìtì wọ́n láti sọ bẹ́ẹ̀, máa ń gba àkókó gan-an.” Ṣùgbọ́n Stephen àtìyàwó rẹ̀ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà sú àwọn. Stephen wá fi kún un pé: “Nítorí ìforítì tá a ní, àwọn ọmọbìnrin wa dẹni tó ń dúpẹ́ oore. Ní báyìí, à ń mú wọn yangàn ni, pé wọ́n máa ń dúpẹ́ oore táwọn èèyàn ṣe fún wọn.”

Ǹjẹ́ O Máa Ń Dúpẹ́ Oore Táwọn Ọ̀rẹ́ àti Aládùúgbò Rẹ Ṣe fún Ọ?

Nígbà míì tá ò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó ṣe wá lóore, kì í ṣe pé a jẹ́ aláìmoore, ó kàn lè jẹ́ pé a gbàgbé ni. Ǹjẹ́ ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣe nǹkan kan láti fi hàn pé òun moore? Láti lè dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká gbé ohun tó wáyé láàárín Jésù àtàwọn adẹ́tẹ̀ kan yẹ̀ wò.

Nígbà tí Jésù ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó pàdé àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ adẹ́tẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì wí pé: ‘Jésù, Olùkọ́ni, ṣàánú fún wa!’ Nígbà tí ó sì tajú kán rí wọn, ó wí fún wọn pé: ‘Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.’ Lẹ́yìn náà, bí wọ́n ṣe ń lọ, ìwẹ̀nùmọ́ wọn ṣẹlẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn, nígbà tí ó rí i pé a ti mú òun lára dá, ó padà, ó ń fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. Ó sì dojú bolẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; síwájú sí i, ó jẹ́ ará Samáríà.”—Lúùkù 17:11-16.

Ǹjẹ́ Jésù gbójú fò ó dá pé àwọn mẹ́sàn-án yòókù ò dúpẹ́ oore? Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: ‘Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà? Ṣé a kò rí kí ẹnì kankan padà láti fi ògo fún Ọlọ́run bí kò ṣe ọkùnrin yìí tí ó jẹ́ ará orílẹ̀-èdè mìíràn?’”—Lúùkù 17:17, 18.

Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́sàn-án yòókù kì í ṣe èèyàn burúkú o. Ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n ti fi hàn gbangba pé àwọn gba Jésù gbọ́, wọ́n sì ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ tinútinú, títí kan lílọ tí wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù láti fi ara wọn han àwọn àlùfáà. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọyì oore tí Jésù ṣe fún wọn, wọn ò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn adẹ́tẹ̀ yẹn kò ṣe ohun tí Jésù retí pé kí wọ́n ṣe. Àwa ńkọ́? Nígbà tí ẹnì kan bá ṣe wá lóore, ǹjẹ́ a tètè máa ń dúpẹ́ oore, tàbí ká kọ̀wé láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni náà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀?

Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé dídúpẹ́ oore jẹ́ ìwà tó bójú mu, ó tún jẹ́ ẹ̀rí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú ohun táwọn adẹ́tẹ̀ yẹn ṣe ni pé, àwọn tó fẹ́ ṣe ohun tí inú Kristi dùn sí ní láti máa fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kí wọ́n sì máa dúpẹ́ oore, láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá, ẹ̀yà wọn, tàbí ẹ̀sìn wọn sí.

Wá bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo ni mo dúpẹ́ kẹ́yìn lọ́wọ́ aládùúgbò mi, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi, ẹni tá a jọ ń ṣíṣẹ́, òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn, ẹni tó ń bójú tó ibi ìkẹ́rùsí tàbí ẹlòmíì tó ràn mí lọ́wọ́?’ Gbìyànjú láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó o ṣe fún ọjọ́ kan tàbí méjì, kó o sì wo iye ìgbà tó o dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tàbí tó o kọ ìwé ìdúpẹ́ sáwọn èèyàn? Irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kó o mọ bó ṣe yẹ kó o túbọ̀ máa dúpẹ́ oore.

Àmọ́ ṣá o, ẹni tó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ jù lọ ni Jèhófà Ọlọ́run. Òun ló fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ìgbà wo lo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run kẹ́yìn fáwọn ohun kan tó ti ṣe fún ọ?—1 Tẹsalóníkà 5:17, 18.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore Báwọn Ẹlòmíì Ò Tiẹ̀ Ṣe Bẹ́ẹ̀?

Àwọn ẹlòmíì lè ṣàì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ bó o tiẹ̀ ṣe wọ́n lóore. Ṣùgbọ́n, kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ oore, àní báwọn ẹlòmíì ò tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìdí kan tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ oore.

Tá a bá ń ṣe ohun rere fáwọn tí kò lẹ́mìí ìmoore, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹlẹ́dàá wa olóore ọ̀fẹ́, Jèhófà Ọlọ́run. Jèhófà ò tìtorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò mọyì ìfẹ́ tóun fi hàn sí wọn kó wá dáwọ́ ṣíṣe ohun rere dúró. (Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 4:9, 10) Ó ń mú kí “oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” Bá a bá sapá gidigidi láti máa dúpẹ́ oore láìwo ti pé à ń gbé nínú ayé táwọn èèyàn ti jẹ́ aláìmoore yìí, a ó fi hàn pé a jẹ́ “ọmọ Baba [wa] tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:45.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ti ka ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Orí 18 sọ pé “Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́?”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó o ṣe fún ọjọ́ kan tàbí méjì, kó o sì wo iye ìgbà tó o dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ láti máa dúpẹ́ oore

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kódà, a lè kọ́ àwọn ọmọ kékeré láti máa dúpẹ́ oore