O Ṣì Lè Láyọ̀ Bí O Tilẹ̀ Rí Ìjákulẹ̀
O Ṣì Lè Láyọ̀ Bí O Tilẹ̀ Rí Ìjákulẹ̀
TA LÓ lè sọ pé òun ò tíì rí ìjákulẹ̀ rí? Kódà, àwọn èèyàn máa ń ṣe ohun tó dun Jèhófà Ọlọ́run, Baba wa tí ń bẹ lọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì ó sì bù kún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 78:41) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, Jèhófà ṣì ń jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tímótì 1: 11.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fa ìjákulẹ̀. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìjákulẹ̀ bà wá láyọ̀ jẹ́? Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe nígbà táwọn nǹkan tó dùn ún ṣẹlẹ̀?
Àwọn Ohun Tó Lè Fa Ìjákulẹ̀
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo” wa. (Oníwàásù 9:11) Láìròtẹ́lẹ̀, ìwà ọ̀daràn, ìjàǹbá tàbí àrùn lè dédé fa ìṣòro ńlá kan, èyí sì lè fa ìjákulẹ̀. Bíbélì tún sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Ńṣe la ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tá a bá ní nǹkan rere kan lọ́kàn tá à ń retí, àmọ́ tí nǹkan ọ̀hún ò bá tètè tẹ̀ wá lọ́wọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn á bá wa, ìjákulẹ̀ dé nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó ti pẹ́ tí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti wà lọ́kàn Duncan, a àmọ́ lẹ́yìn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì yìí, ó rí i pé òun àtìyàwó òun ní láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ káwọn sì padà sílé. Ó ní: “Ìgbà yẹn ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi ti gbogbo nǹkan tojú sú mi. Mi ò ní àfojúsùn kankan mọ́. Kò tún sí nǹkan tó ṣe pàtàkì lójú mi mọ́.” Ó máa ń dun èèyàn wọra tí nǹkan téèyàn ò fẹ́ bá ṣẹlẹ̀. Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Claire ṣe rí lára ẹ̀ nìyẹn, ó sọ pé: “Ìgbà kan wà tí oyún oṣù méje bà jẹ́ lára mi. Ó ti tó ọ̀pọ̀ ọdún báyìí lẹ́yìn tíyẹn ṣẹlẹ̀, àmọ́ títí di ìsinsìnyí, tí mo bá rí ọmọkùnrin kan tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle, mo máa ń rò ó pé ‘Bí ọmọkùnrin mi náà ì bá ti tó rèé, ká ni mo bí i ni.’”
Ó lè dùn ẹ́ tí ẹnì kan bá já ọ kulẹ̀, bóyá kí
olólùfẹ́ sọ fún èèyàn pé òun ò ṣe mọ́, tàbí kí ìgbéyàwó ẹni tú ká tàbí kí ọmọ kan yàyàkuyà tàbí kí ọ̀rẹ́ kan dà wá, ó sì lè jẹ́ pé a ṣe ọ̀rẹ́ wa kan lóore àmọ́ tí kò moore. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àárín àwọn èèyàn aláìpé là ń gbé lákòókò tó le koko yìí, àìmọye nǹkan ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa fa ìjákulẹ̀ fún wa.Àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tiwa fúnra wa náà tún lè fa ìjákulẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá féèlì ìdánwò kan tàbí tíṣẹ́ kan tá à ń lé ò bá bọ́ sí i tàbí tí ẹnì kan tó wù wá láti fẹ́ sọ pé òun ò gbà, ó lè dà bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Nígbà téèyàn wa kan bá kúrò lọ́nà ìgbàgbọ́, ojú lè tì wá, kó máa ṣe wá bíi pé àwa la fà á. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Mary sọ pé: “Ó dà bíi pé ọmọbìnrin mi ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́. Lójú ara mi, àpẹẹrẹ rere tí mo fi lélẹ̀ fún un ló ń tẹ̀ lé. Àmọ́, nígbà tó kẹ̀yìn sí Jèhófà Ọlọ́run tó sì pa gbogbo ẹ̀kọ́ ilé tá a ti kọ́ ọ tì, ṣe ló dà bíi pé èmi ni mi ò ṣiṣẹ́ mi bí iṣẹ́. Gbogbo nǹkan dáadáa yòókù tí mo ti gbé ṣe láyé kò já mọ́ nǹkan kan lójú mi mọ́. Ó kó ìrẹ̀wẹ̀sì tó pọ̀ bá mi.”
Báwo la ṣe lè fara dà á nígbà tírú àwọn nǹkan tó dùn wá bí èyí bá ṣẹlẹ̀? Tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe ṣe nígbà táwọn nǹkan tó dùn ún ṣẹlẹ̀, a óò rí ìdáhùn.
Bí Ọ̀ràn Náà Ṣe Máa Yanjú Ni Kó O Gbájú Mọ́
Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà Ọlọ́run fi pèsè ohun tí tọkọtaya àkọ́kọ́ nílò, síbẹ̀ wọ́n ya aláìmoore wọ́n sì ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì, orí kejì àti ìkẹta) Nígbà tó tún yá, Kéènì ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà búburú. Láìka ìkìlọ̀ Jèhófà sí, Kéènì pa àbúrò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1-8) Wo bíyẹn ṣe máa dun Jèhófà tó.
Kí nìdí tí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kò fi kó ìbànújẹ́ bá Ọlọ́run? Ìdí ni pé ó ní in lọ́kàn láti mú kí orí ilẹ̀ ayé kún fún àwọn èèyàn pípé, ó sì ń báṣẹ́ lọ lórí bó ṣe máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Jòhánù 5:17) Torí ìyẹn ló ṣe ṣètò ẹbọ ìràpadà tó sì tún gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. (Mátíù 6:9, 10; Róòmù 5:18, 19) Bí ọ̀ràn náà ṣe máa yanjú ni Jèhófà Ọlọ́run gbájú mọ́ kì í ṣe ìṣòro tó wà nílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ohun rere tó wà níkàáwọ́ wa ni ká máa gbájú mọ́ dípò àwọn ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀. Ó sọ pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
Ojú Tó Yẹ Ká Fi Máa Wo Ìjákulẹ̀
Àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ táá yí ìgbésí ayé wa padà pátápátá. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ lè dédé bọ́ lọ́wọ́ wa, ọkọ tàbí ìyàwó wa lè má sí mọ́, àwọn àǹfààní tá a ní nínú ìjọ lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́. Ìlera wa lè má jí pépé mọ́, a lè di aláìnílélórí tàbí káwọn ọ̀rẹ́ wa pa wá tì. Báwo la ṣe lè fara da irú àwọn ìyípadà yẹn?
Àwọn kan ti rí i pé káwọn ṣètò ohun táwọn máa fi ṣe àkọ́kọ́ nígbèésí ayé àwọn ló dáa. Duncan, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Nígbà témi àtìyàwó mi rí i pé a ò lè padà di míṣọ́nnárì mọ́, ó dún wá kọjá sísọ. Àmọ́ nígbà tó yá, a pinnu pé a ó máa ṣe ohun méjì pàtàkì yìí: àkọ́kọ́ ni pé a ó máa tọ́jú Màmá wa, ìkejì sì ni pé a ó máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ. Nígbà táwọn ìpinnu kan bá dojú kọ wá, a máa ń wo bí ìpinnu yẹn kò ṣe ní ṣàkóbá fún ohun méjì tá a sọ pé a fẹ́ máa ṣe yìí. Èyí mú kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa ṣèpinnu wa.”
Nígbà tí nǹkan tó dùn wá bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa ń bara jẹ́ bíi pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. A lè ti ṣe ìwọ̀n tá a lè ṣe láti tọ́ ọmọ kan, àmọ́ kí ọmọ náà má ya ọmọ dáadáa, ó lè jẹ́ pé pẹ̀lú gbogbo ìsapá wa láti ní ìwé ẹ̀rí táá jẹ́ ká lè ṣiṣẹ́ kan, kò bọ́ sí i fún wa, àwọn ìsapá wa láti wàásù ní ibòmíì tó yàtọ̀ sí ilẹ̀ wa lè má sèso rere. Diutarónómì 32:4, 5.
Èyí lè mú ká máa rò pé aláṣetì ni wá. Lóòótọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá èèyàn sórí ilẹ̀ ayé dun Ọlọ́run, síbẹ̀ ìyẹn ò fi hàn pé aláṣetì ni Ọlọ́run. Bákan náà, pé a ṣe nǹkan kan tí kò tíì yọrí sí rere báyìí kò fi hàn pé aláṣetì ni wá.—Àwa èèyàn lè tètè dà á sí ìbínú tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí Dáfídì Ọba ṣe dun Jèhófà gan-an nígbà tó bá obìnrin kan ṣe panṣágà tó sì pa ọkọ obìnrin náà. Síbẹ̀ Jèhófà kíyè sí i pé Dáfídì ronú pìwà dà látọkànwá, torí náà, ó ń lo Dáfídì lọ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀. Bákan náà, Jèhóṣáfátì olóòótọ́ ọba ṣàṣìṣe nígbà tó lọ bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run gbìmọ̀ pọ̀. Wòlíì Jèhófà sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Nítorí èyí, ìkannú wà sí ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ.” (2 Kíróníkà 19:2, 3) Jèhófà mọ̀ pé àṣìṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yẹn ò sọ Jèhóṣáfátì di ọlọ̀tẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn èèyàn ò ní máa dọ̀tá wa tá a bá ń mú sùúrù fún wọn nígbà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣohun tó dùn wá lónìí lè ṣohun táá wù wá lọ́la.—Kólósè 3:13.
A lè ka ìjákulẹ̀ sí ọ̀kan lára ohun tá a ní láti rí ká tó lè ṣàṣeyọrí. Ojú ara wa lè gbà wá tì nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, tá a bá gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ Sáàmù 32:3-5) Tá a bá kíyè sí i pé a kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé kó dárí jì wá ká sì yí padà ká sì tún pinnu pé láti ìsinsìnyí lọ, a ó máa túbọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀.—1 Jòhánù 2:1, 2.
ká gbé pẹ̀lú ìpinnu, a lè padà sípò ká sì máa bá ìgbésí ayé wa lọ. Nígbà tí Dáfídì Ọba ṣe ohun kan tó dun òun fúnra rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. . . . Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ [Jèhófà] nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín . . . , ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Ìsinsìnyí Ni Kó O Ti Máa Múra Sílẹ̀ De Ìjákulẹ̀
Ó dájú pé a ò lè ṣe ká má bá ìjákulẹ̀ pàdé lọ́nà kan tàbí òmíràn. Kí la lè ṣe tí kò fi ní bá wa lójijì? Ìjákulẹ̀ bá bàbá àgbàlagbà Kristẹni kan tó ń jẹ́ Bruno, èyí sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ohun tó sọ wúlò fún wa, ó sọ pé: “Ní tèmi, ohun tí mo ṣe tí ìjákulẹ̀ tó dé bá mi kò fi bà mí láyọ̀ jẹ́ ni pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ tí mo fi ń sún mọ́ Ọlọ́run. Mo ti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ètò búburú yìí láti máa bá a nìṣó. Láti ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti fi Jèhófà ṣe ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. Mo dúpẹ́ pé mo ti sún mọ́ Ọlọ́run látẹ̀yìnwá. Ìtùnú ló jẹ́ fún mi láti mọ̀ pé Ọlọ́run ò fi mí sílẹ̀, èyí sì ń ràn mí lọ́wọ́ láti fara da ìdààmú ọkàn tó dé bà mi.”
Bá a ṣe ń ronú nípa ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ẹ jẹ́ ká fi ohun kan sọ́kàn, pé: Àwa fúnra wa lè já ara wa kulẹ̀, àwọn míì sì lè já wa kulẹ̀, àmọ́ Ọlọ́run kò ní já wa kulẹ̀ láé. Kódà, Ọlọ́run sọ pé Orúkọ òun, Jèhófà túmọ̀ sí “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Orúkọ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ohun tó bá yẹ kó dà ló máa dà láti lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó ti ṣèlérí pé nípasẹ̀ Ìjọba òun, ìfẹ́ òun á di ṣíṣe “bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba . . . tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù.”—Mátíù 6:10; Róòmù 8:38, 39.
Ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ ká sì máa retí ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run tẹnu wòlíì Aísáyà ṣe nígbà tó sọ pé: “Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Ẹ ò rí i pé ohun ayọ̀ gbáà ni, pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí gbogbo ohun tó ń dùn wá tó ti ṣẹlẹ̀ ò ní wá sí wa lọ́kàn mọ́, wọ́n á ti di nǹkan àtijọ́!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Pé a ṣe nǹkan kan tí kò tíì yọrí sí rere báyìí kò fi hàn pé aláṣetì ni wá
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ohun rere tó wà níkàáwọ́ wa ni ká máa gbájú mọ́ dípò àwọn ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọlọ́run ṣì ń láyọ̀ láìwo ti pé àwọn èèyàn máa ń ṣe ohun tó dùn ún, ìdí ni pé ohun tó ní lọ́kàn ṣì máa ṣẹ dandan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Téèyàn bá ní àwọn ohun tẹ̀mí tó ń lépa, ó máa ṣèrànwọ́ fún un láti fara da ìjákulẹ̀ tó bá wáyé