Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Bìkítà Nípa Rẹ

Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Bìkítà Nípa Rẹ

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Bìkítà Nípa Rẹ

Mátíù 18:12-14

ǸJẸ́ o ti bi ara rẹ rí pé, ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa mi?’ Ọ̀pọ̀ èèyàn náà máa ń bi ara wọn nírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Púpọ̀ nínú wa ló wà nínú ìṣòro àti ìnira, èyí sì lè mú ká máa ṣiyèméjì bóyá Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run tiẹ̀ bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Gbogbo wa ló yẹ ká mọ̀ bóyá Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tàbí kò bìkítà. Nígbà tí Jésù, ẹni tó sún mọ́ Jèhófà jù lọ wà láyé, ó lo àpèjúwe kan tó tuni lára, tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run bìkítà.

Jésù fi ọ̀nà tí olùṣọ́ àgùntàn gbà ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀ ṣàkàwé bí ọ̀rọ̀ wa ṣe jẹ Jèhófà lógún. Ó ní: “Bí ọkùnrin kan bá wá ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì ṣáko lọ, kì yóò ha fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún náà sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá ọ̀kan tí ó ṣáko lọ? Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ó rí i, mo sọ fún yín dájúdájú, yóò yọ̀ púpọ̀ lórí rẹ̀ ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò tíì ṣáko lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” (Mátíù 18:12-14) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe fi èyí ṣàlàyé bọ́rọ̀ olúkúlùkù ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe jẹ Jèhófà lógún tó.

Olùṣọ́ àgùntàn mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti bójú tó ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn òun. Tí ọ̀kan bá jẹ̀ lọ, tó sì sọ nù, olùṣọ́ àgùntàn yóò mọ èyí tó sọ nù lára wọn. Gbogbo wọn pátá ló forúkọ mọ̀. (Jòhánù 10:3) Olùṣọ́ àgùntàn tó bìkítà kò ní sinmi láìjẹ́ pé ó rí èyí tó sọ nù. Àmọ́ nígbà tó bá wá èyí tó sọ nù lọ, kì í ṣe pé ó máa fàwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yòókù sílẹ̀ láìsí àbójútó. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn sábà máa ń kó ẹran wọn jẹ̀ pa pọ̀, tí wọ́n á sì dà pọ̀ mọ́ra. a Nítorí náà, olùṣọ́ àgùntàn tó bá wá èyí tó sọ nù lọ lè fàwọn àgùntàn tó kù sábẹ́ àbójútó àwọn olùṣọ́ àgùntàn yòókù. Tó bá wá rí àgùntàn náà, tí àgùntàn náà kò sì fara pa, inú rẹ̀ yóò dùn gan-an. Yóò gbé àgùntàn tó ti dààmú náà lé èjìká rẹ̀ wá sáàárín agbo padà, níbi tí ààbò wà, tọ́kàn rẹ̀ á sì ti balẹ̀.—Lúùkù 15:5, 6.

Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé àpèjúwe yìí, ó ní, Ọlọ́run kò fẹ́ kí “ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” Jésù ti kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣáájú pé kí wọ́n má ṣe “mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú [òun] kọsẹ̀.” (Mátíù 18:6) Kí ni àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí wá kọ́ wa nípa Jèhófà? Ó kọ́ wa pé Jèhófà jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn tọ́rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn rẹ̀ jẹ lógún gan-an, títí kan “àwọn ẹni kékeré,” ìyẹn àwọn táráyé kà sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run mọ olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ dunjú, wọ́n sì ṣe pàtàkì lójú rẹ̀.

Tó o bá ń fẹ́ kó túbọ̀ dá ọ lójú pé o ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, ńṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run, Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà, kó o sì tún kọ́ bí wàá ṣe túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè ní ìdánilójú bíi ti àpọ́sítélì Pétérù, tó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù ń sọ àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù. Ohun tí Pétérù sọ lẹ́yìn ìgbà náà ni pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kò lè ṣòro fún olùṣọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan láti rí àgùntàn tirẹ̀ yà sọ́tọ̀, torí pé àgùntàn kọ̀ọ̀kan dá ohùn olùṣọ́ àgùntàn tirẹ̀ mọ̀.—Jòhánù 10:4.