Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

“Jíjó [ìfẹ́] jẹ́ jíjó iná, ọwọ́ iná Jáà.”ORIN SÓL. 8:6.

1, 2. Ta ló lè jàǹfààní nínú àyẹ̀wò ìwé Orin Sólómọ́nì, kí sì nìdí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ALÀGBÀ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àsọyé ìgbéyàwó tọkọtaya kan tán. Bó ṣe ń wo àwọn tọkọtaya náà, ó ń rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ẹ ò rí i báwọn méjèèjì ṣe di ara wọn lọ́wọ́ mú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí wọ́n sì rọra ń wojú ara wọn tìfẹ́tìfẹ́! Kò sí àní-àní pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an.’ Bí alàgbà yìí tún ṣe ń wo ọkọ àti ìyàwó tuntun náà tí wọ́n rọra ń gbẹ́sẹ̀ níbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu, ó ń ṣe kàyéfì pé: ‘Ǹjẹ́ ìgbéyàwó wọn máa tọ́jọ́? Bọ́dún ti ń gorí ọdún, ṣé ìfẹ́ wọn á máa jinlẹ̀ sí i àbí ṣe lá máa pòórá? Tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ní ìfẹ́ alọ́májàá sí ara wọn, wọ́n lè fara da ohunkóhun kódà títí kan ìṣòro tó le koko. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ń túká, torí náà o lè béèrè pé, Ǹjẹ́ ìfẹ́ àárín tọkọtaya lè wà pẹ́ títí?

2 Ìfẹ́ tòótọ́ ò wọ́pọ̀ kódà nígbà ayé Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ nípa ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú ìwà rere nígbà ayé rẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti rí ọkùnrin kan nínú ẹgbẹ̀rún, ṣùgbọ́n èmi kò tíì rí obìnrin kan nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí. Wò ó! Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí, pé Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán, ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.” (Oníw. 7:26-29) Torí bí àwọn obìnrin àjèjì tó ń jọ́sìn Báálì ṣe ń gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwà ìbàjẹ́ ti gbòde kan débi pé ó ṣòro fún Sólómọ́nì láti rí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tó ń hùwà rere. * Síbẹ̀, nínú orin ewì tí Sólómọ́nì kọ ní ogún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, ìyẹn Orin Sólómọ́nì, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ alọ́májàá lè wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Ó tún jẹ́ kí ohun tí ìfẹ́ náà jẹ́ ṣe kedere àti bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe lè fi ìfẹ́ náà hàn síra wọn. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣègbéyàwó àtàwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó lè kọ́ ohun púpọ̀ nípa ìfẹ́ tòótọ́ tí wọ́n bá fara balẹ̀ gbé ìwé Bíbélì náà yẹ̀ wò.

O LÈ NÍ ÌFẸ́ TÒÓTỌ́

3. Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe kí ìfẹ́ tòótọ́ wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin?

3 Ka Orin Sólómọ́nì 8:6. Sólómọ́nì fi gbólóhùn náà, “ọwọ́ iná Jáà” ṣàlàyé ìfẹ́, gbólóhùn náà sì kẹnú gan-an. Ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́ “ọwọ́ iná Jáà” torí pé Jèhófà ló dá ìfẹ́ yìí sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Jẹ́n. 1:26, 27) Nígbà tí Ọlọ́run dá Éfà obìnrin àkọ́kọ́ tí ó sì fà á lé Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ ewì lo kọ́kọ́ jáde lẹ́nu Ádámù láti fi ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Ó sì dájú pé ọkàn Éfà náà fà mọ́ Ádámù, torí pé ara rẹ̀ ni Ọlọ́run ‘ti mú un wá.’ (Jẹ́n. 2:21-23) Níwọ̀n bí Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti fi ìfẹ́ hàn síra wọn, a jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin àti obìnrin ní ìfẹ́ alọ́májàá tí kì í kùnà sí ara wọn.

4, 5. Ní ṣókí, sọ ìtàn tó wà nínú Orin Sólómọ́nì.

4 Yàtọ̀ sí pé ìfẹ́ àárín ọkùnrin àti obìnrin lè jẹ́ alọ́májàá kó sì wà pẹ́ títí, ó tún láwọn nǹkan míì tó lè ṣe. Ìwé Orin Sólómọ́nì ṣàpèjúwe díẹ̀ nínú àwọn nǹkan yìí lọ́nà tó wúni lórí. Sólómọ́nì kọ orin yìí bíi pé ó ń fi ìtàn kọ orin, ìtàn yìí sì dá lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tó wà láàárín ọ̀dọ́bìnrin kan tó wá láti abúlé Ṣúnémù tàbí Ṣúlémù, àti ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Ẹwà ọ̀dọ́bìnrin yìí wọ Sólómọ́nì lójú, ló bá ní kí wọ́n lọ mú un wá torí ọgbà àjàrà tí ọ̀dọ́bìnrin náà ti ń ṣiṣẹ́ kò jìnnà sí àgọ́ tí Sólómọ́nì wà. Àmọ́, ọ̀dọ́bìnrin náà ń sọ látìgbà tí wọ́n ti mú un dé ọ̀dọ̀ Sólómọ́nì pé olùṣọ́ àgùntàn náà ni òun nífẹ̀ẹ́. Gbogbo bí Sólómọ́nì ṣe ń gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra, ọ̀dọ́bìnrin náà ń sọ ọ́ léraléra pé ọ̀dọ́ olólùfẹ́ òun ni ọkàn òun wà. (Orin Sól. 1:4-14) Olùṣọ́ àgùntàn náà wá olólùfẹ́ rẹ̀ wá sí àgọ́ náà, nígbà tí wọ́n sì rí ara wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tó lárinrin bá ara wọn sọ̀rọ̀.—Orin Sól. 1:15-17.

5 Nígbà tí Sólómọ́nì pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ó mú ọ̀dọ́bìnrin náà dání, àmọ́ olùṣọ́ àgùntàn náà tẹ̀ lé olólùfẹ́ rẹ̀. (Orin Sól. 4:1-5, 8, 9) Gbogbo ìsapá Sólómọ́nì kó lè fa ojú ọ̀dọ́bìnrin náà mọ́ra ló já sí pàbó. (Orin Sól. 6:4-7; 7:1-10) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọba jẹ́ kó pa dà sílé rẹ̀. Ewì náà parí nígbà tí ọ̀dọ́bìnrin náà fẹ́ kí olólùfẹ́ rẹ̀ ‘ṣe ara rẹ bí ọmọ akọ àgbàlàǹgbó’ kó sì sáré tete wá pàdé òun.—Orin Sól. 8:14.

6. Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti mọ àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nínú ewì náà?

6 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé “orin tí ó dùn” ni orin ewì tí Sólómọ́nì kọ yìí, ó sì lárinrin, síbẹ̀ kò rọrùn láti mọ ẹni tó ń bá ẹnì kejì sọ̀rọ̀, ẹni tó ń dánìkan sọ̀rọ̀ àti ẹni tó ń ro oríṣiríṣi nǹkan nípa olólùfẹ́ rẹ̀. (Orin Sól. 1:1) Ìwé The New Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ pé, “bí ohun kan ṣe ṣẹlẹ̀ tó fi di ìtàn, bí ìtàn náà ṣe so kọ́ra àtàwọn tó wà nínú ìtàn náà kọ́ ló ń pinnu bóyá ìtàn kan dùn tàbí kò dùn.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí kí ìtàn náà lè ṣù pọ̀ kó sì lè jọ ewì ni Sólómọ́nì ò ṣe dárúkọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, a ṣì lè mọ ẹni tó sọ̀rọ̀, tá a bá ti mọ ohun tẹ́ni náà sọ tàbí ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ fún ẹni náà.

“ÀWỌN ÌFÌFẸ́HÀN RẸ DÁRA JU WÁÌNÌ”

7, 8. Kí la lè sọ nípa “àwọn [ọ̀rọ̀] ìfìfẹ́hàn” tó wà nínú Orin Sólómọ́nì? Sọ àwọn àpẹẹrẹ.

7 “Àwọn [ọ̀rọ̀] ìfìfẹ́hàn” tí ọ̀dọ́bìnrin náà àti olùṣọ́ àgùntàn náà bá ara wọn sọ kún inú ìwé Orin Sólómọ́nì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó gbé ní Ìlà Oòrùn ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn ló sábà máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, tó sì lè má fi bẹ́ẹ̀ nítumọ̀ táwọn èèyàn bá kà á lóde òní, àmọ́ wọ́n nítumọ̀ gidi, èrò tí àwọn ọ̀rọ̀ náà sì gbé síni lọ́kàn kò ṣàjèjì sí wa. Bí àpẹẹrẹ, olùṣọ́ àgùntàn náà sọ pé ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ ni omidan yìí àti pé ojú rẹ̀ dà bíi ti ojú “àdàbà.” (Orin Sól. 1:15) Ọ̀dọ́bìnrin náà sì sọ pé ojú olùṣọ́ àgùntàn náà dà bí àwọn àdàbà. (Ka Orin Sólómọ́nì 5:12.) Dúdú inú ẹyinjú olùṣọ́ àgùntàn náà mọ́ lóló lójú ọ̀dọ́bìnrin náà débi tó fi wé àdàbà tó ń wẹ̀ nínú wàrà.

8 Kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọ́n sọ nínu orin ewì náà ló ń tọ́ka sí ẹwà ara. Wo ohun tí olùṣọ́ àgùntàn náà sọ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu obìnrin náà. (Ka Orin Sólómọ́nì 4:7, 11.) Ó ní “afárá oyin ń kán tótó” ní ètè rẹ̀. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Oyin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ rẹ́ nílé oyin ni wọ́n ń pè ní afárá oyin, ó sì dùn ju oyin tí atẹ́gùn ti fẹ́ sí lọ. Ó tún sọ pé, “Oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n [rẹ̀],” ó túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ún gbọ́ sétí, ó sì lárinrin. Torí náà, nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún ọ̀dọ́bìnrin náà pé, “ìwọ lẹ́wà látòkè délẹ̀, . . . kò sì sí àbùkù kankan lára rẹ,” kì í wulẹ̀ ṣe ẹwà rẹ̀ nìkan ló ní lọ́kàn.

9. (a) Àwọn nǹkan wo ni ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya gbọ́dọ̀ kó mọ́ra. (b) Kí nìdí to fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn tọkọtaya máa sọ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ síra wọn?

9 Àdéhùn ìgbéyàwó kì í ṣe àdéhùn orí ìwé lásán tí kò ní sí ìfẹ́ láàárín tọkọtaya, tí wọn ò sì ní fi ìfẹ́ hàn síra wọn. Kódà, ìfẹ́ la fi ń dá ìgbéyàwó Kristẹni mọ̀ yàtọ̀. Àmọ́ irú ìfẹ́ wo ni ìfẹ́ yìí? Ṣé ìlànà Bíbélì ló ń darí ìfẹ́ yìí? (1 Jòh. 4:8) Ṣé ìfẹ́ yìí dà bí ìfẹ́ tí ìdílé máa ń ní síra wọn? Ǹjẹ́ ìfẹ́ yìí dà bí ìfẹ́ táwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn máa ń ní síra wọn? (Jòh. 11:3) Ṣé ìfẹ́ àárín ọkùnrin àti obìnrin ni? (Òwe 5:15-20) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìfẹ́ tòótọ́ tó so tọkọtaya pọ̀ gbọ́dọ̀ kó gbogbo ìfẹ́ yìí mọ́ra. Ìgbà tẹ́nì kan bá fìfẹ́ hàn sí wa la tó máa ń mọ agbára tí ìfẹ́ ní. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya má ṣe jẹ́ kí kòókòó jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́ mú kí wọ́n má ṣe máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́! Tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́, ọkàn wọn á balẹ̀, wọ́n á sì láyọ̀. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ọkùnrin àti obìnrin tó fẹ́ di tọkọtaya lè má mọ ara wọn títí di ọjọ́ ìgbéyàwó, tírú àwọn bẹ́ẹ̀ bá fi kọ́ra láti máa sọ̀rọ̀ ìfẹ́ fún ara wọn, ó máa jẹ́ kí ìfẹ́ wọn jinlẹ̀, kí wọ́n sì túbọ̀ mọ ara wọn dáadáa.

10. Tí tọkọtaya bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́, ipa wo nìyẹn máa ní lórí wọn?

10 Àwọn tọkọtaya tún máa jàǹfààní lọ́nà míì tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́. Sólómọ́nì Ọba ṣèlérí fún Ṣúlámáítì pé òun máa fún un ní “àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rìbìtì-rìbìtì ti wúrà . . . pẹ̀lú àwọn òníní tí a fi fàdákà ṣe.” Ó kó ọ̀rọ̀ dídùn sí i lórí, ó ní ó ‘lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú, ó sì mọ́ gaara bí oòrùn tí ń ràn yòò.” (Orin Sól. 1:9-11; 6:10) Àmọ́ Ṣúlámáítì jẹ́ olóòótọ́ sí olólùfẹ́ rẹ̀. Kí ló fún un lókun tó sì tù ú nínú láwọn àkókò tí òun àti olólùfẹ́ rẹ̀ ò fi sí pa pọ̀? Ó sọ fún wa. (Ka Orin Sólómọ́nì 1:2, 3.) Ọ̀dọ́bìnrin náà ò gbàgbé “àwọn [ọ̀rọ̀] ìfìfẹ́hàn” tí olùṣọ́ àgùntàn náà máa ń sọ. Lójú ọ̀dọ́bìnrin náà, àwọn ọ̀rọ̀ yẹn “dára ju wáìnì” tó ń mú ọkàn yọ̀, orúkọ rẹ̀ sì tuni lára bí “òróró tí a dà jáde” sí orí. (Sm. 23:5; 104:15) Àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọ́n ti jọ sọ fún ara wọn máa jẹ́ kí ìfẹ́ wọn wà pẹ́ títí. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́ torí ó máa jẹ́ kí ìfẹ́ àárín wọn jinlẹ̀ sí i!

Ẹ MÁ ṢE RU ÌFẸ́ SÓKÈ “TÍTÍ YÓÒ FI NÍ ÌTẸ̀SÍ LÁTI RU SÓKÈ”

11. Kí làwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè kọ́ nínú bí Ṣúlámáítì ṣe fi àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù sábẹ́ ìbúra láti má ṣe ru ìfẹ́ sókè nínú rẹ̀?

11 Orin Sólómọ́nì tún kọ́ àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lẹ́kọ̀ọ́, pàápàá jù lọ àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin náà kò nífẹ̀ẹ́ Sólómọ́nì. Ṣúlámáítì fi àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù sábẹ́ ìbúra, ó sọ pé: “Ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” (Orin Sól. 2:7; 3:5) Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé kò dáa ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wà láàárín àwa àti ẹnì kan ṣá. Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí Kristẹni tó fẹ́ lọ́kọ tàbí láya ní sùúrù táá fi rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ gan-an.

12. Kí nìdí tí Ṣúlámáítì fi nífẹ̀ẹ́ olùṣọ́ àgùntàn náà?

12 Kí nìdí tí Ṣúlámáítì fi nífẹ̀ẹ́ olùṣọ́ àgùntàn náà? Lóòótọ́, ó dáa lọ́mọkùnrin, ó sọ pé ó jọ “àgbàlàǹgbó”; ọwọ́ rẹ̀ lágbára bí “òbìrípo wúrà”; àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ sì rẹwà, wọ́n lágbára bí “ọwọ̀n òkúta mábílì.” Àmọ́, yàtọ̀ sí pé ó lágbára, ó sì rẹwà lọ́mọkùnrin, nǹkan míì ṣì wà. Ó sọ pé, “Bí igi ápù láàárín àwọn igi igbó, bẹ́ẹ̀ ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin.” Ohun tó mú kí ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lè sọ ọ̀rọ̀ yìí nípa ọkùnrin kan, a jẹ́ pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an nìyẹn.—Orin Sól. 2:3, 9; 5:14, 15.

13. Kí nìdí tí olùṣọ́ àgùntàn náà fi nífẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́bìnrin náà?

13 Ṣúlámáítì rẹwà gan-an. Ẹwà rẹ̀ pọ̀ débi pé ọba tó ti ní “ọgọ́ta ayaba . . . àti ọgọ́rin wáhàrì àti àwọn omidan tí kò níye” nígbà yẹn, kò lè mójú kúrò lára rẹ̀, síbẹ̀ ọ̀dọ́bìnrin yìí sọ pé òun jẹ́ “ìtànná sáfúrónì lásán-làsàn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ etí òkun,” ó wo ara rẹ̀ bí òdòdó kan lásánlàsàn. Ọ̀dọ́bìnrin náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé lójú olùṣọ́ àgùntàn náà, ó dà “bí òdòdó lílì láàárín àwọn èpò ẹlẹ́gùn-ún.” Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.—Orin Sól. 2:1, 2; 6:8.

14. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn tó fẹ́ lọ́kọ tàbí láya lè kọ́ lárá olùṣọ́ àgùntàn náà àti Ṣúlámáítì?

14 Ìwé Mímọ́ fún àwọn Kristẹni ní ìmọ̀ràn tó lágbára pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Àwọn tó ń wá ọkọ tàbí aya kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wà láàárín àwọn àti ẹni tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà. Ẹni tó ti ṣe ìrìbọmi nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ dẹnu ìfẹ́ kọ. Tí tọkọtaya kan bá máa kojú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́, síbẹ̀ tí wọ́n á máa láyọ̀, tí wọ́n á sì máa jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n sì máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, èyí wà nínú ohun tó yẹ kí Kristẹni kan wò lára ẹni tó máa di ọkọ tàbí aya rẹ̀. Àwọn ohun tí olùṣọ́ àgùntàn náà àti ọ̀dọ́bìnrin náà rí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀.

Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wà láàárín àwọn àti ẹni tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 14)

“ỌGBÀ TÍ A GBÉGI DÍNÀ RẸ̀” NI AYA MI

15. Báwo ni Ṣúlámáítì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn Kristẹni ọkùnrin àti obìnrin tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó?

15 Ka Orin Sólómọ́nì 4:12. Kí nìdí tí olùṣọ́ àgùntàn náà fi sọ pé olólùfẹ́ òun dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀”? Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè wọnú ọgbà tí wọ́n mọ odi yí ká. Ẹni bá fẹ́ wọlé gbọ́dọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tí wọ́n fi àgádágodo tì. Ṣúlámáítì dà bí irú ọgbà yìí torí pé olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ nìkan ni ìfẹ́ rẹ̀ wà fún. Bí Ṣúlámáítì kò ṣe gbà láti fẹ́ ọba láìka gbogbo ìlérí tó ṣe sí, ńṣe ló fi hàn pé òun jẹ́ “ògiri” àti pé òun kì í ṣe “ilẹ̀kùn” tó ṣí sílẹ̀ gbayawu. (Orin Sól. 8:8-10) Lọ́nà kan náà, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń pa ara wọn mọ́ títí wọ́n á fi ni ọkọ tàbí aya.

16. Ẹ̀kọ́ wo ni Orin Sólómọ́nì kọ́ni nípa ìfẹ́sọ́nà?

16 Lọ́jọ́ kan, lákòókò tí ojú ọjọ́ dára nígbà ìrúwé, olùṣọ́ àgùntàn náà sọ pé kí Ṣúlámáítì jẹ́ káwọn jọ nasẹ̀ jáde, àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ò jẹ́ kó lọ. Kó má bàa lọ, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní kó lọ máa ṣọ́ àwọn ọgbà àjàrà. Kí nìdí tí wọn ò fi jẹ́ kó lọ? Ṣé torí pé wọn ò fọkàn tán an ni? Àbí wọ́n rò pé ó fẹ́ lọ ṣèṣekúṣe ni? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, wọ́n fẹ́ dáàbò bo àbúrò wọn ni, kó máa bàa fira rẹ̀ sípò tó lè mú kó ṣèṣekúṣe. (Orin Sól. 1:6; 2:10-15) Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni èyí jẹ́ fáwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó. Tó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ara yín sípò tó léwu, kí ìfẹ́sọ́nà yín lè jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. Ẹ má ṣe máa dá wà lẹ́yin nìkan. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn síra yín, bí kò bá ṣáà ti ní ìwàkiwà nínú, àmọ́ ẹ máa yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe.

17, 18. Àǹfààní wo ló ti rí bá a ṣe jíròrò Orin Sólómọ́nì?

17 Jèhófà dá ìgbéyàwó sílẹ̀ kó lè wà pẹ́ títí. Ó fẹ́ kí ọkọ àti aya nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an. Torí náà, ìfẹ́ àárín wọn sábà máa ń lágbára gan-an nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣègbéyàwó. Àmọ́ kí ìgbéyàwó wọn tó lè wà pẹ́ títí, wọ́n gbọ́dọ̀ máa mú kí ìfẹ́ àárín wọn máa gbóná sí i, kó máa jó lala bí iná tí kì í kú.—Máàkù 10:6-9.

18 Tó o bá ti ṣe tán tó o fẹ́ lọ́kọ tàbí láya, wá ẹni tí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénúdénú. Tó o bá ti rí ẹni yẹn, ẹ jọ mú kí ìfẹ́ àárín yín túbọ̀ máa lágbára sí i, kó má sì sí ohunkóhun tó lè paná ìfẹ́ yín. Ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú Orin Sólómọ́nì nìyẹn. Torí náà, yálà ó ń wá ọkọ tàbí aya tàbí o ti ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ kí o ní ìfẹ́ tòótọ́ torí ó jẹ́ “ọwọ́ iná Jáà.”—Orin Sól. 8:6.

^ ìpínrọ̀ 2 Wo Ilé Ìṣọ́ January 15, 2007, ojú ìwé 31.