Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú —Ní Micronesia
ORÍLẸ̀-ÈDÈ Amẹ́ríkà ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Katherine dàgbà sí, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni nígbà tó ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò fi iṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá, àmọ́ àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí i ní àgbègbè ibi tó ti ń wàásù. Ó sọ pé: “Mo ka ìrírí àwọn tó máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó rán ẹni tó máa kọ́ àwọn nípa Rẹ̀ sí àwọn. Ó máa ń wù mí pé kí n bá irú wọn pàdé lóde ẹ̀rí, àmọ́ kò ṣẹlẹ̀ rí.”
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Katherine ti ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan náà yẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú láti kó lọ sí àgbègbè tí àwọn èèyàn á tí túbọ̀ tẹ́tí sí ìhìn rere. Àmọ́ ó tún ń ṣe é bíi pé ó máa ṣòro jù fún òun láti kó lọ síbẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan péré ló tíì kúrò ní àkàtà àwọn òbí rẹ̀, kò sì lò ju ọ̀sẹ̀ méjì níbi tó lọ. Síbẹ̀, ojoojúmọ́ ni àárò ilé máa ń sọ ọ́. Àmọ́, ó wù ú pé kóun náà rí ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú ríran ẹni tó ń fẹ́ láti mọ Jèhófà lọ́wọ́, ìyẹn sì mú kó borí ìbẹ̀rù tó ní. Lẹ́yìn tó ti ṣe ìwádìí nípa àwọn àgbègbè mélòó kan tó lè lọ, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Guam, wọ́n sì fún un láwọn ìsọfúnni tó nílò. Ní oṣù July ọdún 2007, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26], ó kó lọ sí Saipan, ìyẹn erékúṣù kan tó wà lẹ́bàá Òkun Pàsífíìkì tó sì fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] kìlómítà (ibùsọ̀ 6,000) jìn sí ibi tó gbé dàgbà. Kí wá ní àbájáde ìyípadà tó ṣe náà?
Ó RÍ ÌDÁHÙN SÍ ÀDÚRÀ MÉJÌ TÓ GBÀ
Kò pẹ́ tí Katherine dé ìjọ tuntun yẹn tó pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Doris. Obìnrin náà ti tó ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta [45], àmọ́ ó gbà kí Katherine máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Katherine bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Ó sọ pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ tó dáńgájíá ni Doris, mi ò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tí ò ní jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Mi ò tíì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ déédéé rí, torí náà mo ronú pé arábìnrin tó nírìírí jù mí lọ ló yẹ kó máa kọ́ Doris lẹ́kọ̀ọ́. Bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́.” Katherine wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí òun rí arábìnrin yíyẹ tóun lè fa Doris lé lọ́wọ́ kó lè máa bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sì tún pinnu pé òun máa ṣàlàyé fún Doris pé ẹni ọ̀tọ̀ láá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó.
Katherine wá sọ pé: “Àmọ́ kí n tó sọ ọ̀rọ̀ náà fún Doris, òun alára sọ fún mi pé òun fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tóun ní. Lẹ́yìn tí mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo sọ fún un bí Jèhófà ṣe ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí èmi náà dojú kọ irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ mi.” Lẹ́yìn yẹn ni Doris wá sọ fún Katherine pé: “Jèhófà ti lò ẹ́ láti ràn mí lọ́wọ́. Lọ́jọ́ tó o kọ́kọ́ wá sí ilé mi yẹn, ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo ti fi ka Bíbélì, mò ń sunkún, mo sì ń sọ fún Ọlọ́run pé kó rán ẹnì kan sí mi, tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Ìgbà yẹn gan-an lo wá kan ilẹ̀kùn mi. Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi!” Ṣe ni omi lé ròrò sí ojú Katherine bó ṣe ń sọ ohun tí Doris sọ yìí. Katherine sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí Doris sọ jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà mi. Jèhófà jẹ́ kí n rí i pé mo tóótun láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó.”
Doris ṣèrìbọmi ní ọdún 2010, òun náà sì ti ń darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiẹ̀ báyìí. Katherine wá sọ pé: “Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ó gbọ́ àdúrà mi torí ó pẹ́ tó ti ń wù mí pé kí n ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà!” Ní báyìí, tayọ̀tayọ̀ ni Katherine fi ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní erékùṣù Kosrae tó wà lẹ́bàá òkun Pàsífíìkì.
BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÌPÈNÍJÀ MẸ́TA
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló wá láti ilẹ̀ òkèèrè kí wọ́n lè sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní Micronesia. Ọjọ́ orí àwọn tó wá yìí wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún [19] sí mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79]. Ní ọdún 2006 nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Erica wà ní ẹni ọdún mọ́kàndínlógún, òun náà kó lọ sí Guam. Ó wá sọ ohun kan tó fi bi ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn òṣìṣẹ́ onítara tí wọ́n gbé irú ìgbésẹ̀ yìí hàn. Ó ní: “Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń dùn gan-an ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí òùngbẹ òtítọ́ ti ń gbẹ àwọn èèyàn. Inú mi dùn pé Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti kópa nínú apá iṣẹ́ ìsìn yìí. Ìgbésí ayé tó dáa jù nìyẹn!” Ní báyìí, ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún Erica láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Ebeye tó wà ní Erékùṣù Marshall. Àmọ́ ṣá o, kéèyàn ti orílẹ̀-èdè kan lọ sìn ní orílẹ̀-èdè míì máa ń ní àwọn ìpèníjà tiẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta lára àwọn ìpèníjà náà yẹ̀ wò, ká sì rí bí àwọn tó kó lọ sí Micronesia ṣe borí àwọn ìpèníjà náà.
Ìṣúnná owó. Ẹni ọdún méjìlélógún [22] ni Simon nígbà tó lọ sí erékùṣù Palau lọ́dún 2007. Lẹ́yìn tó débẹ̀ ló wá rí i pé owó táá máa wọlé fún òun ò tó nǹkan kan lára iye tóun ń rí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tóun ti wá. Ó ní: “Mo wá rí i pé kìkì ohun tí mo bá nílò nìkan ni mo gbọ́dọ̀ máa rà. Ńṣe ni mo máa ń ṣọ́ irú èlò oúnjẹ tí màá rà báyìí, mo sì máa ń nájà káàkiri kí n tó wá rà á níbi tí nǹkan bá ti rọjú. Tí nǹkan bá sì bà jẹ́, mo máa ń wá àlòkù ohun tó bà jẹ́ lára rẹ̀ kàn, màá sì wá ẹnì kan tó lè bá mi tún un ṣe.” Ojú wo ló fi ń wo ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ tó ń gbé? Simon sọ pé: “Ó jẹ́ kí n mọ ohun tá a lè pè ní kòṣeémánìí àti bí mo ṣe lè jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tó mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì ti rí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. Ní gbogbo ọdún méje tí mo ti lò níbí, ebi ò pa mí sùn rí, mo sì ń ríbi forí pa mọ́ sí.” Mo ti wá rí i pé Jèhófà máa ń ṣètìlẹyìn fún àwọn tó jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn torí kí wọ́n lè máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.—Mát. 6:32, 33.
Àárò ilé. Arábìnrin Erica sọ pé: “A mọwọ́ ara wa gan-an nínú ìdílé wa, torí náà mo ronú pé tí mo bá lọ sílùú míì, àárò ilé á máa sọ mí, ó sì lè mú kí n dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi.” Kí ni Erica ṣe láti kojú ìṣòro yìí? Ó sọ pé: “Kí n tó lọ, mo ka àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa kí àárò ilé máa sọni. Èyí jẹ́ kí n lè múra ọkàn mi sílẹ̀ fún ìpèníjà yẹn. Nínú àpilẹ̀kọ kan tí mo kà, ìyá kan fi dá ọmọ rẹ̀ lójú pé Jèhófà máa bójú tó o nípa sísọ fún un pé: ‘Jèhófà lè bójú tó ẹ ju bí mo ṣe lè bójú tó ẹ lọ.’ Ọ̀rọ̀ yẹn fún mi lókun gan-an ni.” Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Hannah àti ọkọ rẹ̀ Patrick, ń sìn ní Majuro tó wà ní Erékùṣù Marshall. Bí Hannah ṣe kojú ìṣòro àárò ilé ni pé ó pa ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sìn. Arábìnrin Hannah sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bá a ṣe jẹ́ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé, torí pé ìdílé mi làwọn náà. Tí kì í bá ṣe pé àwọn ará wa wọ̀nyí ń fìfẹ́ tì wá lẹ́yìn ni, ì bá tí ṣeé ṣe fún mi láti sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.”
Dídá wà. Arákùnrin Simon sọ pé: “Téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé orílẹ̀-èdè kan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ló máa yàtọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ká mi lára pé mi ò lè bá àwọn èèyàn ṣàwàdà kí wọ́n sì lóye mi dáadáa.” Erica sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ débí ṣe ló dà bí i pé mo dá wà, àmọ́ ìyẹn mú kí n ronú nípa ìdí tí mo fi wá síbí. Kì í ṣe torí tara mi ni mo fi wá, torí àtiṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, mo sì mọyì irú àjọṣe bẹ́ẹ̀.” Simon tiẹ̀ sapá láti kọ́ èdè Palauan, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún un láti kó àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní ìjọ yẹn mọ́ra. (2 Kọ́r. 6:13) Bó ṣe sapá láti kọ́ èdè wọ́n mú kí àwọn ará fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí àwọn ará tó wá láti ìlú òkèèrè àtàwọn ará tó wà nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sìn bá ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, ńṣe ni gbogbo wọn á jọ máa gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́. Èrè míì wo làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tún máa ń rí?
‘KÍKÁRÚGBÌN NÍ YANTURU’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí ó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú.” (2 Kọ́r. 9:6) Láìsí àní-àní, ìlànà tó wà nínú gbólóhùn yìí kan àwọn tó bá mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i. Kí ni àwọn tó lọ sìn ní Micronesia ‘kárúgbìn ní yanturu’?
Ní Micronesia, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló ṣì wà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bákan náà èèyàn tún láǹfààní láti rí bí àwọn tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Patrick àti ìyàwó rẹ̀ Hannah náà wàásù ní Angaur, erékùṣù kékeré kan tí àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ò ju okòó lé lọ́ọ̀ọ́dúrún [320] lọ. Lẹ́yìn oṣù méjì tí wọ́n ti ń wàásù níbẹ̀, wọ́n pàdé obìnrin kan tó ń dá tọ́mọ. Ojú ẹsẹ̀ ló gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pẹ̀lú ìháragàgà ló fi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ṣe àwọn ìyípadà tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Hannah sọ pé: “Ní gbogbo ìgbà tá a bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tá a sì ń gun kẹ̀kẹ́ wa pa dà lọ sílé, ńṣe ni èmi àti ọkọ mi máa ń wo ojú ara wa, a ó sì sọ pé: ‘Jèhófà o ṣe o!’” Hannah fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé tí a ò bá wá síbí, Jèhófà á mọ bó ṣe máa jẹ́ kí obìnrin yìí mọ Òun, àmọ́ torí pé à ń sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, a ní àǹfààní láti rí ẹni bí àgùntàn yìí ká sì ràn án lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára èrè tó ga jù lọ tá a tíì rí gbà láyé wa!” Gẹ́gẹ́ bí Erica ṣe sọ, “tó o bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, ayọ̀ tó o máa ní á pọ̀ jọjọ!”
ṢÉ ÌWỌ NÁÀ LÈ ṢE É?
Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ló wà tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ṣé ìwọ náà lè kó lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Gbàdúrà sí Jèhófà kó o sì sọ fún un pé kó jẹ́ kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ. Bá àwọn alàgbà, alábòójútó àyíká tàbí àwọn tó ti láǹfààní láti sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i sọ̀rọ̀ lórí ohun tó o ní lọ́kàn láti ṣe yìí. Tó o bá ti múra tán láti lọ, kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù tó o ti fẹ́ lọ sìn, kó o sì béèrè ìsọfúnni síwájú sí i. * Bóyá ìwọ́ náà lè kún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, àwọn tó ti ṣègbéyàwó tàbí tí kò tíì ṣègbéyàwó tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú tí wọ́n sì rí ayọ̀ tó wà nínú ‘kíkárúgbìn ní yanturu.’
^ ìpínrọ̀ 17 Wo àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ O Lè ‘Ré Kọjá Lọ Sí Makedóníà’?” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November ọdún 2011.