ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Ti Ràn Mí Lọ́wọ́ Ní Ti Tòótọ́
Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kan èmi àti ìyàwó mi Evelyn bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ ojú irin ní ìlú Hornepayne tó wà ní àríwá Ontario ní orílẹ̀-èdè Kánádà. Igbó pọ̀ nílùú yìí gan-an, ó sì tún bọ́ sọ́wọ́ àárọ̀ kùtù, torí náà, òtútù mú gan-an. Arákùnrin kan ní ìjọ àdúgbò ló wá mú wa. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, àwa àti ìdílé arákùnrin náà jọ jẹ oúnjẹ aládùn. Lẹ́yìn náà, àwa, tọkọtaya náà àti ọmọ wọn ọkùnrin rìn gba orí yìnyín láti lọ wàásù láti ilé dé ilé. Ní ọ̀sán ọjọ́ yẹn kan náà ni mo sọ àsọyé mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Àwa márùn-ún la pésẹ̀ sípàdé yẹn, kò sẹ́lòmíì.
KÁ SÒÓTỌ́, kò dùn mí rárá pé àwọn kéréje ló gbọ́ àsọyé tí mo sọ ní ọdún 1957 yẹn. Ìdí ni pé onítìjú èèyàn ni mí. Kódà, nígbà tí mo wà ní kékeré, ńṣe ni mo máa ń sá pa mọ́ tí àwọn àlejò bá wá sí ilé wa, bó tiẹ̀ jẹ́ àwọn tí mo mọ̀.
Mo lè rí ìdí tó fi máa yà yín lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí mo ṣe nínú ètò Jèhófà mú kó pọn dandan fún mi láti máa bá àwọn ẹlòmíì da nǹkan pọ̀, yálà àwọn tá a ti mọra tẹ́lẹ̀ tàbí àwọn tí mi ò mọ̀. Síbẹ̀, mò ń sapá kí n lè ní ìgboyà kí n sì borí ìtìjú mi. Torí náà, mi ò lè sọ pé mímọ̀ọ́ṣe mi ni gbogbo ohun tí mò ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlérí tí Jèhófà ṣe ló ṣẹ sí mi lára, pé: “Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísá. 41:10) Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ràn mí lọ́wọ́ ni ìtìlẹ́yìn tí àwọn ará ń ṣe fún mi. Ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ lára àwọn tí Ọlọ́run ti lò láti ràn mí lọ́wọ́ látìgbà kékeré mi.
OBÌNRIN KAN LO BÍBÉLÌ ÀTI ÌWÉ KÉKERÉ ALÁWỌ̀ DÚDÚ KAN
Ní ọjọ́ kan láàárín ọdún 1941 sí ọdún 1949, ìyẹn ní àárọ̀ ọjọ́ Sunday kan tí oòrùn mú ganrínganrín, obìnrin kan tó ń jẹ́ Elsie Huntingford wá sí oko wa ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Ontario. Màmá mi ló lọ ṣílẹ̀kùn, bàbá mi ò tiẹ̀ yọjú, ńṣe ni wọ́n kàn ń kẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ. Ìdí sì ni pé onítìjú èèyàn ni bàbá mi, àwọn ni mo jọ. Ṣe ni bàbá mi rò pé Arábìnrin Huntingford wá polówó nǹkan fún wa ni tó sì jọ pé màmá mi fẹ́ ra ohun tí a kò nílò, ni bàbá mi bá lọ bá wọn lẹ́nu ilẹ̀kùn, wọ́n sì sọ fún obìnrin náà pé a kò nífẹ̀ẹ́ sí i. Arábìnrin Huntingford wá béèrè pé: “Ṣé pé ẹ kò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Bàbá mi wá fèsì pé: “Bó bá jẹ́ ìyẹn ni, a nífẹ̀ẹ́ sí i.
Ìgbà tí Arábìnrin Huntingford wá sí yìí gan-an ló dáa jù. Ṣọ́ọ̀ṣì kan nílùú Kánádà tí wọ́n ń pè ní United Church of Canada ni àwọn òbí mi ń lọ, wọn ò sì fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré. Àmọ́ kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní lọ síbẹ̀ mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé pásítọ̀ ìjọ lẹ orúkọ gbogbo àwọn tó fi owó ṣètọrẹ mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì to orúkọ náà bí iye tí wọ́n fi sílẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Àwọn òbí mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, torí náà apá ìsàlẹ̀ ni orúkọ wọn sábà máa ń wà, àwọn alàgbà ṣọ́ọ̀ṣì sì máa ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n túbọ̀ gbọnwọ́ sí àpò ìjọ. Pásítọ̀ míì tó wà ní ṣọ́ọ̀ṣì náà tiẹ̀ sọ pé torí àtijẹ àtimu lòun ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, òun alára ò gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Torí bẹ́ẹ̀, a kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì yẹn mọ́, àmọ́ a ṣì ń wá ibi tá a ti lè máa jọ́sìn Ọlọ́run tọkàntọkàn.
Nígbà tá à ń wí yìí, wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Kánádà, torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé Bíbélì àti ìwọ̀nba àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé kékeré aláwọ̀ dúdú kan ni Arábìnrin Huntingford fi ń kọ́ ìdílé wa lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó wá rí i pé a ṣeé fọkàn tán àti pé a ò ní fi òun lé àwọn aláṣẹ lọ́wọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A máa ń tọ́jú àwọn ìwé náà dáadáa tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ti parí. *
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arábìnrin Huntingford kojú àtakò àti onírúurú ìdènà, ńṣe ló ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ìtara rẹ̀ yìí wú mi lórí gan-an tí mo fi pinnu pé èmi náà máa sin Jèhófà. Lẹ́yìn ọdún kan táwọn òbí mi ṣèrìbọmi tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èmi náà ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Inú àgbá táwọn àgbẹ̀ fi máa ń fún àwọn ẹran lómi ni wọ́n ti ṣèrìbọmi fún mi ní February 27, ọdún 1949. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni mí nígbà yẹn. Lẹ́yìn ìgbà náà, mo pinnu pé màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
JÈHÓFÀ MÚ KÍ N NÍ ÌGBOYÀ
Àmọ́ kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Fún àwọn àkókò kan, bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ ní báńkì kan, bẹ́ẹ̀ náà ni mo tún ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì kan nítorí mo gbà lọ́kàn ara mi pé mo ní láti ṣiṣẹ́ kí n lè rí owó tí màá fi gbọ́ bùkátà ara mi tí mo bá di aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, torí pé mi ò tíì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́n, bí mo ṣe ń rí owó yẹn náà ni mò ń ná an. Torí náà, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ted Sargent rọ̀ mí pé kí n jẹ́ onígboyà kí n sì nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. (1 Kíró. 28:10) Ìṣírí tó fún mi yẹn mú kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní November ọdún 1951. Owó tó wà lọ́wọ́ mi nígbà yẹn ò ju ogójì [40] dọ́là, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ààbọ̀ náírà, kẹ̀kẹ́ àlòkù kan àti àpò ìfàlọ́wọ́ tuntun kan. Àmọ́ Jèhófà máa ń rí sí i pé ohun tí mo nílò kò wọ́n mi. Mo mà dúpẹ́ o pé Arákùnrin Ted fún mi níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà! Ìyẹn tún mú kí n rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà.
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà tí oṣù August ń parí lọ lọ́dún 1952, ẹnì kan tẹ̀ mí láago láti ìlú Tòróńtò. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Kánádà ni wọ́n ti pè mí pé kí n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní oṣù September. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń tijú gan-an tí mi ò sì tíì dé ẹ̀ka ọ́fíìsì rí, inú mi dùn, torí pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi ti sọ àwọn nǹkan dáadáa fún mi nípa Bẹ́tẹ́lì. Kò sì pẹ́ tí mo débẹ̀ tí ara mi fi mọlé.
“JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ MỌ̀ PÉ Ọ̀RỌ̀ WỌ́N JẸ Ọ́ LÓGÚN”
Lẹ́yìn ọdún méjì tí mo dé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n fi mí rọ́pò Arákùnrin Bill Yacos gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ (tí a wá mọ̀ sí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí) fún Ẹ̀ka Shaw ní ìlú Tòróńtò. * Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] péré ni mí nígbà yẹn, mo sì dà bí ọmọ oko tí kò lajú. Àmọ́, tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ àti tìfẹ́tìfẹ́ ni Arákùnrin Yacos fi kọ́ mi ní ohun tí màá máa ṣe. Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an.
Èèyàn tó ki pọ́pọ́ ni Arákùnrin Yacos, ẹlẹ́rìn-ín ẹ̀yẹ ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó máa ń bẹ̀ wọ́n wò déédéé nílé wọn, àmọ́ kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ní ìṣòro nìkan. Arákùnrin Yacos fún mi ní ìṣírí pé kí èmi náà máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará, kí n máa bẹ̀ wọ́n wò nílé wọn kí n sì máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ó sọ pé: “Ken, jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọ́n jẹ ọ́ lógún. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ kùdìẹ̀ kudiẹ mọ́lẹ̀.”
ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ NI ÌYÀWÓ MI NÍ
Láti January ọdún 1957 ni Jèhófà tún ti ń ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Oṣù yẹn ni mo fẹ́ Evelyn, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹrìnlá ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ká tó ṣègbéyàwó, ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec, níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ló ti ń sìn. Nígbà yẹn, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló jẹ́ abẹnugan ní ẹkùn ìpínlẹ̀ yẹn. Torí náà, iṣẹ́ ìwàásù ò rọrùn rárá fún Evelyn níbẹ̀, àmọ́ kò mikàn ó sì dúró ṣinṣin ti Jèhófà.
Evelyn tún dúró ṣinṣin ti èmi náà. (Éfé. 5:31) Kódà, kété tá a ṣègbéyàwó tán ni ohun kan ṣẹlẹ̀ tó dán ìdúróṣinṣin rẹ̀ wò! A ti ronú pé lẹ́yìn ìgbéyàwó wa a máa lọ sí ìpínlẹ̀ Florida ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ gbafẹ́, àmọ́ ọjọ́ kejì lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni wọ́n ní kí n lọ fún ìpàdé ọlọ́sẹ̀ kan gbáko tó máa wáyé ní Bẹ́tẹ́lì Kánádà tí mo ti ń sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpàdé tí wọ́n ní kí n lọ yìí forí gbárí pẹ̀lú ohun tá a ti fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀, a ṣe tán láti ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá ní ká ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, a fagi lé ètò tá a ṣe láti lọ gbafẹ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó wa. Èmi gba ìpàdé yẹn lọ, ìyàwó mi sì ń jáde òde ẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ kan tí kò jìn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn tún yàtọ̀ sí ti Quebec tó wà tẹ́lẹ̀, ó fara dà á.
Nígbà tí ọ̀sẹ̀ yẹn máa fi parí, ohun ìyàlẹ́nu kan ṣẹlẹ̀, wọ́n ní kí n lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní àríwá Ontario. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ni, mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ, mi ò sì ní ìrírí rárá. Àmọ́ a gbára lé Jèhófà, a sì gbéra. Ìgbà tí òtútù máa ń mú gan-an ní orílẹ̀-èdè Kánádà ló bọ́ sí. A wọ ọkọ̀ ojú irin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń pa dà sí ibi tí wọ́n ti ń sìn. Wọ́n fún wa níṣìírí gan-an ni! Kódà, arákùnrin kan tiẹ̀ rọ̀ wá títí pé ká lọ sùn sínú yàrá tó wà nínú ọkọ ojú irin níbi tí òun fúnra rẹ̀ fẹ́ sùn tẹ́lẹ̀, kó má bàa jẹ́ pé orí ìjókòó tá a ti wà náà la máa sùn sí mọ́jú. Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, tó jẹ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwùjọ kékeré tó wà ní Hornepayne wò, ìbẹ̀wò yẹn ni mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.
Ọ̀pọ̀ ìyípadà ni èmi àti ìyàwó mi ṣe bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ní apá ìparí ọdún 1960 nígbà tá à ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè, mo gba ìwé ìkésíni kan pé kí n wá sí kíláàsì kẹrìndínlógójì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ní Brooklyn, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó máa bẹ̀rẹ̀ ní February ọdún 1961, tó sì máa gba oṣù mẹ́wàá gbáko. Inú mi dùn gan-an, àfi ti pé wọn ò pe ìyàwó mi sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kí òun àtàwọn arábìnrin míì tọ́rọ̀ kàn kọ lẹ́tà pé àwọn gbà pé kí àwa ọkọ fi wọ́n sílẹ̀ nílé, ó kéré tán fún oṣù mẹ́wàá tá a fi máa wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Ìyàwó mi sunkún, àmọ́ ó gbà pé kí n lọ, pé inú òun dùn torí pé ẹ̀kọ́ iyebíye ni màá gbà ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì.
Ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà nílé ẹ̀kọ́ yẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Kánádà ni ìyàwó mi ti ń sìn. Òun àti Arábìnrin Margaret Lovell ni wọ́n jọ ń gbé nínú yàrá kan náà, ẹni àmì òróró ni arábìnrin yẹn ó sì yááyì gan-an. Ká sòótọ́, èmi àti ìyàwó mi ṣàárò ara wa gan-an. Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún àwa méjèèjì láti pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tí kálukú wa ń ṣe ní ibi tí a wà. Ó wú mi lórí gan-an bí ìyàwó mi ṣe gbà tinútinú láti yááfì àkókò tó yẹ ká jọ fi wà pa pọ̀ torí ká bàa lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀.
Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí oṣù mẹ́ta ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Arákùnrin Nathan Knorr, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ kárí ayé nígbà yẹn fi ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ̀ mí. Ó béèrè lọ́wọ́ mi bóyá màá fẹ́ láti fi Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀ níbi tí mo bá ẹ̀kọ́ náà dé kí n sì pa dà lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà láti darí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tó máa wáyé fún àkókò díẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà níbẹ̀. Àmọ́ Arákùnrin Knorr sọ fún mi pé kì í ṣe dandan kí n gbà láti lọ. Ó ní mo sì lè yàn láti parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mò ń gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tí mo bá sì ṣe tan, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ mí di míṣọ́nnárì. Ó tún wá sọ fún mi pé tí mo bá sì gbà láti lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì mọ́, àti pé dípò kí n pa dà sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n lè ní kí n pa dà sí pápá ní orílẹ̀-èdè Kánádà. Ó wá fún mi láyè láti bá ìyàwó mi sọ ọ́, kí n sì pinnu ohun tí màá ṣe.
Níwọ̀n bí mo ti mọ ọwọ́ tí ìyàwó mi fi mú ohunkóhun tó bá ti jẹ mọ́ iṣẹ́ Ọlọ́run, ojú ẹsẹ̀ ni mo sọ fún Arákùnrin Knorr pé, “Ohunkóhun tí ètò Jèhófà bá ti fẹ́ ká ṣe, tayọ̀tayọ̀ la máa fi ṣe é.” A ti gbà pé ibi tó bá wu ètò Jèhófà pé ká lọ la máa lọ, tó bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí ohun tó wù wá.
Torí náà, ní April ọdún 1961, mo fi Brooklyn sílẹ̀, mo sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Kánádà láti lọ darí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Lẹ́yìn yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì níbẹ̀. Àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé wọ́n tún pè mí sí kíláàsì ogójì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó máa bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1965. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n ní kí ìyàwó mi kọ lẹ́tà pé òun gbà pé kí n fi òun sílẹ̀ nílé ní gbogbo àkókò tí màá fi wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Àmọ́ ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, òun náà gba lẹ́tà pé ká jọ máa bọ̀. Ńṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún àwa méjèèjì.
Lẹ́yìn tá a dé Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Arákùnrin Knorr sọ fún wa pé wọ́n máa rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti kọ́ èdè Faransé lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ tiwa náà wà lára wọn, ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa, ńṣe ni wọ́n tún rán wa pa dà lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà! Wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka (tí à ń pè ní olùṣekòkárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka báyìí). Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n péré ni mí, mo sì sọ fún Arákùnrin Knorr pé, “Ọmọ kékeré ni mí.” Àmọ́ ó fi mí lọ́kàn balẹ̀. Èmi náà sì jẹ́ kó mọ́ mi lára láti máa fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó dàgbà tí wọ́n sì nírìírí jù mí lọ ní Bẹ́tẹ́lì kí n tó ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì.
ILÉ Ẹ̀KỌ́ NI BẸ́TẸ́LÌ
Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ti fún mi láǹfààní tó gadabú láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ẹlòmíì. Mo mọyì àwọn tá a jọ wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka gan-an ni, mo sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Mo tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, tí wọ́n ti ní ipa kan tàbí òmíràn lórí ìgbésí ayé wa, ní Bẹ́tẹ́lì níbí àti láwọn ìjọ tá a ti sìn.
Iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ti fún mi láǹfààní láti kọ́ àwọn ẹlòmíì, kí n sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́.” Ó tún sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ìwọ sì ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìtìlẹyìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́rìí, nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:2; 3:14) Nígbà míì, àwọn ará máa ń bi mí láwọn ẹ̀kọ́ tí mo ti kọ́ ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57] tí mo ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ìdáhùn tí mo sábà máa ń fún wọn ni pé kí wọ́n ‘múra tán láti ṣe ohun tí ètò Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe láìjáfara, kí wọ́n sì máa gbára lé Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́.’
Ọjọ́ ọ̀hún rèé bí àná, tí èmi ọ̀dọ́kùnrin kékeré kan tí kò nírìírí tó tún jẹ́ onítìjú dé sí Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ ní gbogbo ọdún yìí wá, Jèhófà ti ń ‘di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.’ Ọ̀pọ̀ igbà ló máa ń tipasẹ̀ inúure táwọn ará ń fi hàn sí mi àti bí wọ́n ṣe ń tì mí lẹ́yìn sọ fún mi pé: “Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Aísá. 41:13.
^ ìpínrọ̀ 10 Ní May 22, ọdún 1945, ni ìjọba orílẹ̀-èdè Kánádà mú ìfòfindè náà kúrò.
^ ìpínrọ̀ 16 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tí ìjọ tó wà ní ìlú kan bá ti ju ẹyọ kan lọ, ẹ̀ka ni wọ́n máa ń pe ìjọ kọ̀ọ̀kan.