Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
‘Lẹ́yìn bíbu àwọn ìṣù búrẹ́dì náà, [Jésù] pín wọn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀wẹ̀ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.’—MÁT. 14:19.
1-3. Ṣàlàyé bí Jésù ṣe bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn nítòsí ìlú Bẹtisáídà. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná. (Ka Mátíù 14:14-21.) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé nígbà tí àjọyọ̀ Ìrékọjá kù díẹ̀ lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni. Ogunlọ́gọ̀ tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé wà pẹ̀lú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ìtòsí ìlú Bẹtisáídà ni ibi tí wọ́n wà, ní abúlé kan nítòsí Òkun Gálílì, àgbègbè náà sì dá páropáro.
2 Nígbà tí Jésù rí ogunlọ́gọ̀ yẹn, àánú wọn ṣe é, torí náà, ó mú àwọn aláìsàn tó wà láàárín wọn lára dá, ó sì kọ́ wọn ní ohun púpọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó di pé ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn èèyàn náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ wá oúnjẹ rà láwọn abúlé tó wà nítòsí. Ṣùgbọ́n, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ fún wọn ní nǹkan láti jẹ.” Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ yìí rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lójú gan-an, torí pé oúnjẹ tí wọ́n ní lọ́wọ́ kò tó nǹkan rárá, ìyẹn búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì.
3 Jésù gba tàwọn èèyàn náà rò, ó wá ṣe iṣẹ́ ìyanu kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ló wà lákọsílẹ̀, àmọ́ èyí ni iṣẹ́ ìyanu kan ṣoṣo tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó kọ ìwé ìhìn rere sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Máàkù 6:35-44; Lúùkù 9:10-17; Jòhánù 6:1-13) Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ nǹkan bí àádọ́ta àti ọgọ́rùn-ún. Lẹ́yìn tí ó gbàdúrà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bu búrẹ́dì àti ẹja náà sí wẹ́wẹ́. Àmọ́ kàkà tí òun alára ì bá fi pín oúnjẹ fún ogunlọ́gọ̀ náà, ńṣe ló gbé e ‘fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti gbé e kalẹ̀ níwájú ogunlọ́gọ̀ náà.’ Bó ṣe di pé àwọn èèyàn náà jẹun ní àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù nìyẹn o. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ìyanu lèyí! Ẹ tiẹ̀ rò ó wò ná: Jésù tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. *
4. (a) Irú oúnjẹ wo ló jẹ Jésù lógún jù lọ láti máa pèsè, kí sì nìdí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?
Jòh. 6:26, 27; 17:3) Bí àánú tí Jésù ní ṣe mú kó fi búrẹ́dì àti ẹja bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn bẹ́ẹ̀ náà ló mú kó lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Máàkù 6:34) Ó mọ̀ pé àkókò díẹ̀ lòun ní láti lò láyé, òun ò sì ní pẹ́ pa dà sí ọ̀run. (Mát. 16:21; Jòh. 14:12) Ní báyìí tí Jésù ti wà ní ọ̀run, báwo ló ṣe máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? Bó ti ṣe nígbà tó bọ́ ogunlọ́gọ̀ náà ló máa ṣe, ní ti pé ó máa tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje kan bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Àwọn wo wá ni àwọn èèyàn kéréje yẹn? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe lo àwọn èèyàn kéréje kan láti bọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní. Lẹ́yìn náà, nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì tó kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan: Báwo la ṣe lè mọ àwọn èèyàn kéréje tí Kristi ń lò láti bọ́ wa lóde òní?
4 Àmọ́, ohun tó jẹ Jésù lógún jù ni bó ṣe máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó mọ̀ pé téèyàn bá ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí, ìyẹn tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èèyàn máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. (JÉSÙ YAN ÀWỌN ÈÈYÀN KÉRÉJE
5, 6. (a) Ìpinnu pàtàkì wo ni Jésù ṣe kó bàa lè ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa jẹun dáadáa nípa tẹ̀mí lẹ́yìn ikú rẹ̀? (b)Kí ni Jésù ṣe láti múra àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sílẹ̀ fún ojúṣe pàtàkì kan lẹ́yìn ikú rẹ̀?
5 Baálé ilé tó bá mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ máa ń ṣètò bí ìyà ò ṣe ní jẹ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀. Bákan náà, Jésù tó máa jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni ti ṣètò sílẹ̀ láti rí i dájú pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ á máa rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ lẹ́yìn ikú rẹ̀. (Éfé. 1:22) Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún méjì kí Jésù tó kú, ó ṣe ìpinnu kan tó lágbára. Ó yan àkọ́kọ́ lára àwọn èèyàn kéréje tí yóò máa bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.
6 Lẹ́yìn tí Jésù ti fi gbogbo òru gbàdúrà, ó kó gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jọ, ó sì yan méjìlá lára wọn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. (Lúùkù 6:12-16) Fún ọdún méjì lẹ́yìn náà, òun àtàwọn méjìlá náà mọwọ́ ara wọn gan-an, ó ń kọ́ wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tó yẹ kí wọ́n kọ́, kódà Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ọmọ ẹ̀yìn” ni wọ́n ṣì jẹ́ ní gbogbo àkókò yẹn.” (Mát. 11:1; 20:17) Ó fún wọn ní ìmọ̀ràn tó rí i pé ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Mát. 10:1-42; 20:20-23; Lúùkù 8:1; 9:52-55) Kò sí àní-àní pé ńṣe ló ń múra wọn sílẹ̀ fún ojúṣe pàtàkì kan tí wọ́n á máa ṣe lẹ́yìn ikú rẹ̀ àti lẹ́yìn tó bá pa dà sí ọ̀run.
7. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ojúṣe pàtàkì tí àwọn àpọ́sítélì máa gbájú mọ́?
7 Kí ló máa jẹ́ ojúṣe àwọn àpọ́sítélì náà? Bí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ti ń sún mọ́lé, ó wá ṣe kedere pé “ipò iṣẹ́ àbójútó” kan ni wọ́n máa wà. (Ìṣe 1:20) Àmọ́ ojúṣe pàtàkì wo ni wọ́n máa gbájú mọ́? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ìjíròrò kan tó wáyé láàárín òun àti àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ ojúṣe tó gbé lé àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́. (Ka Jòhánù 21:1, 2, 15-17.) Níṣojú àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì tó kù, Jésù sọ fún Pétérù pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi kéékèèké.” Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí mú kó ṣe kedere pé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ máa wà lára àwọn èèyàn kéréje tí wọ́n á máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Èyí sì fi hàn gbangba pé Jésù fẹ́ràn àwọn ‘àgùntàn rẹ̀ kéékèèké’! *
BÍ WỌ́N ṢE Ń BỌ́ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LÁTÌGBÀ PẸ́ŃTÍKỌ́SÌ
8. Báwo làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ní Pẹ́ńtíkọ́sì ṣe fi hàn pé àwọn mọ ọ̀nà tí Kristi ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn?
8 Àtìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Kristi tó ti jíǹde náà ti ń lo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láti máa bọ́ àwọn ẹni àmì òróró yòókù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ka Ìṣe 2:41, 42.) Èyí sì ṣe kedere sí àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n di Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́jọ́ yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn fún wọn láti máa “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “bá a lọ ní fífi ara wọn fún,” lè túmọ̀ sí pé “kéèyàn fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú nǹkan, tàbí kéèyàn pa gbogbo ọkàn rẹ̀ pọ̀ sórí nǹkan.” Ebi tẹ̀mí ń pa àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni náà, wọ́n sì mọ ibi tó yẹ kí wọ́n lọ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi gbára lé àwọn àlàyé táwọn àpọ́sítélì ṣe nípa àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù. Wọ́n sì fara mọ́ àwọn òye tuntun lórí ìtúmọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Jésù. *—Ìṣe 2:22-36.
9. Báwo ni àwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé ohun tó jẹ àwọn lógún jù ni bíbọ́ àwọn àgùntàn Jésù?
9 Àwọn àpọ́sítélì náà pọkàn pọ̀ sórí ojúṣe wọn láti máa bọ́ àwọn àgùntàn Jésù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí wọ́n ṣe yanjú ọ̀ràn kan tó gbẹgẹ́ tó sì lè fa ìpínyà, èyí tó wáyé nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Kí sì lohun tó dá wàhálà ọ̀hún sílẹ̀? Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ oúnjẹ lásán ló dá wàhálà sílẹ̀. Wọ́n ń gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Gíríìkì bí wọ́n ṣe ń pín oúnjẹ lójoojúmọ́, àmọ́ wọn kò gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Hébérù. Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe yanjú ìṣòro tó gbẹgẹ́ yìí? “Àwọn méjìlá náà” wá yan àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n tóótun láti bójú tó “iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan” yìí, ìyẹn iṣẹ́ pípín oúnjẹ. Ẹ má gbàgbé pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì yìí ló pín oúnjẹ fún ogunlọ́gọ̀ tí Jésù bọ́ lọ́nà ìyanu. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n wá rí i pé àwọn ní láti gbájú mọ́ ohun míì tó tún ṣe pàtàkì jù, ìyẹn fífi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn. Torí náà, ńṣe ni wọ́n fi ara wọn fún “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”—Ìṣe 6:1-6.
10. Báwo ni Kristi ṣe lo àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù?
10 Nígbà tó fi máa di ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn alàgbà míì tó tóótun dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì náà. (Ka Ìṣe 15:1, 2.) “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù” wá ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ olùdarí. Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ lo àwọn ọkùnrin kéréje tí wọ́n tóótun yìí láti yanjú àwọn àríyànjiyàn lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ni.—Ìṣe 15:6-29; 21:17-19; Kól. 1:18.
11, 12. (a) Kí ló fi hàn pé Jèhófà bù kùn ètò tí Ọmọ rẹ̀ ṣe láti máa bọ́ àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní? (b) Kì nìdí tí kò fi ṣòro láti mọ ọ̀nà tí Kristi ń lò láti bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
11 Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún ètò tí Ọmọ rẹ̀ ṣe láti máa bọ́ àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní? Bẹ́ẹ̀ ni! Àmọ́, báwo la ṣe mọ̀? Ìwé Ìṣe ròyìn pé: “Wàyí o, bí wọ́n [ìyẹn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn-àjò] ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já, Ìṣe 16:4, 5) Ẹ kíyè sí i pé ohun tó mú kí àwọn ìjọ náà máa gbèrú ni pé wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ̀rí tó dájú lèyí sì jẹ́ pé Jèhófà bù kún ètò tí Ọmọ rẹ̀ ṣe láti máa bọ́ àwọn ìjọ. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé ìbùkún Jèhófà nìkan ló lè jẹ́ kéèyàn ṣàṣeyọrí nípa tẹ̀mí.—Òwe 10:22; 1 Kọ́r. 3:6, 7.
wọn a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́. Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (12 Ní báyìí, ọ̀nà tí Jésù máa ń gbà bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti wá ṣe kedere: Ó máa ń tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Ọ̀nà tó sì ń lò láti máa bọ́ àwọn èèyàn kò ṣòro láti mọ̀. Ó ṣe tán, ohun tí àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí àkọ́kọ́ gbé ṣe fi hàn gbangba pé Jèhófà àti Kristi tì wọ́n lẹ́yìn. Ìwé Ìṣe 5:12 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu láti ọwọ́ àwọn àpọ́sítélì ń bá a lọ láti máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn.” * Torí náà, kò sí ìdí fún àwọn tó di Kristẹni láti máa béèrè pé, ‘Àwọn wo gan-an ni Kristi ń lò láti máa bọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀?’ Àmọ́, nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀rúndún kìíní, nǹkan ti yí pa dà.
NÍGBÀ TÍ ÀWỌN ÈPÒ PỌ̀ TÍ ÀWỌN ṢÍRÍ ÀLÌKÁMÀ SÌ KÉRÉ
13, 14. (a) Kí ni Jésù sọ nípa bí wọ́n ṣe máa gbéjà ko ìjọ Kristẹni, ìgbà wo sì ni ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ? (b) Àwọn ọ̀nà méjì wo ni àtakò ti máa wá? (Wo àfikún àlàyé.)
13 Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí àwọn kan máa gbéjà ko ìjọ Kristẹni. Ẹ rántí pé nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ pé ọ̀tá kan máa fún èpò (ìyẹn àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà) sáàárín àlìkámà (ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró) tí afúnrúgbìn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn sínú pápá náà. Ó wá sọ pé wọ́n yóò fi àlìkámà àtàwọn èpò náà sílẹ̀ láti máa dàgbà pọ̀ títí dìgbà ìkórè, èyí tó máa wáyé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 13:24-30, 36-43) Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. *
14 Ọ̀rúndún kìíní làwọn apẹ̀yìndà ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni, àmọ́ àwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ló ń ṣiṣẹ́ “gẹ́gẹ́ bí aṣèdíwọ́,” tí wọn ò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ èké ba ìjọ Kristẹni jẹ́. (2 Tẹs. 2:3, 6, 7) Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí èyí tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì kú, àwọn ẹ̀kọ́ èké wọn wá gbilẹ̀ gan-an, ó sì bá a nìṣó fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún. Bákan náà, láàárín àkókò yẹn, àwọn èpò ti wá pọ̀ gan-an, nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn àlìkámà. Kò sí àwùjọ tàbí ètò kan pàtó tó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn èèyàn. Bó ti wù kí ó rí, nǹkan máa tó yí pa dà. Àmọ́, nígbà wo?
TA NI YÓÒ MÁA PÈSÈ OÚNJẸ TẸ̀MÍ NÍGBÀ ÌKÓRÈ?
15, 16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo ìsapá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn láti lóyè ẹ̀kọ́ òtítọ́ kò já sásán? Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká béèrè?
15 Bí àkókò ìkórè ti ń sún mọ́, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sapá gidigidi láti walẹ̀ jìn nínú Bíbélì kí wọ́n lè mọ ohun náà gan-an tó fi kọ́ni. Ẹ rántí pé láàárín ọdún 1870 sí 1879, àwọn kan tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ kóra jọ, wọ́n sì ń pàdé pọ̀ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọn ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn èpò, ìyẹn àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà tó wà nínú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Orúkọ wo làwọn tó kóra jọ náà ń jẹ́? Wọ́n pe ara wọn ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni wọ́n, wọ́n sì ní ọkàn tó dára. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣèwádìí, wọ́n sì máa ń gbàdúrà kí wọ́n bàa lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.—Mát. 11:25.
16 Gbogbo ìsapá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn láti lóyè ẹ̀kọ́ òtítọ́ kò já sásán. Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yẹn tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké, wọ́n tan ẹ̀kọ́ òtítọ́ kálẹ̀, wọ́n tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì pín in fáwọn èèyàn níbi gbogbo.
Àlàyé tó wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ jáde wọ ọ̀pọ̀ àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa lọ́kàn, wọ́n sì gbà pé ó jẹ́ òótọ́. Ìbéèrè pàtàkì kan wá rèé o: Ṣé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n kóra jọ ní àwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 1914 ni àwùjọ tí Kristi yàn pé kó máa bọ́ àwọn àgùntàn òun? Rárá o. Ní gbogbo àkókò yẹn, wọ́n ṣì ń dàgbà ni. Bákan náà, ètò tí Kristi ṣe láti máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn kò tíì fìdí múlẹ̀ dáadáa. Kò sì tíì tó àkókò láti ya àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà tó jẹ́ èpò kúrò lára àwọn Kristẹni tòótọ́ tó jẹ́ àlìkámà.17. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ láti ọdún 1914?
17 A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé ọdún 1914 ni ìkórè bẹ̀rẹ̀. Ọdún yẹn ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. Jèhófà gbé Jésù gorí ìtẹ́, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn sì bẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 11:15) Láti ọdún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, Jésù àti Baba rẹ̀ wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí láti wá ṣe àyẹ̀wò pàtàkì kan kí wọ́n sì fọ tẹ́ńpìlì náà mọ́. * (Mál. 3:1-4) Nígbà tó wá di ọdún 1919, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn àlìkámà jọ. Ṣé àkókò ti wá tó báyìí fún Kristi láti ṣètò ọ̀nà kan tí yóò máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn? Bẹ́ẹ̀ ni!
18. Nígbà tí Jésù ń sọ asọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, kí ló sọ pé òun máa ṣe? Ìbéèrè pàtàkì wo ló ń fẹ́ ìdáhùn bí ọjọ́ ikẹyìn ṣe bẹ̀rẹ̀?
18 Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ pé òun máa ṣètò ọ̀nà kan tí òun yóò máa lò láti pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí fún àwọn èèyàn ní “àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45-47) Ọ̀nà wo ni? Ohun tí Jésù ṣe ní ọ̀rúndún kìíní náà ló tún máa ṣe. Yóò máa tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́, bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe bẹ̀rẹ̀, ìbéèrè pàtàkì kan tó ń fẹ́ ìdáhùn ni pé, Àwọn wo làwọn èèyàn kéréje náà? A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
^ ìpínrọ̀ 3 Ìpínrọ̀ 3: Ní àkókò míì, Jésù tún ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí. Ó bọ́ àwọn ọkùnrin tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000], láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Ńṣe ló tún pín oúnjẹ náà “fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀wẹ̀ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.”—Mát. 15:32-38.
^ ìpínrọ̀ 7 Ìpínrọ̀ 7: Nígbà ayé Pétérù, gbogbo àwọn ‘àgùntàn kéékèèké’ tí wọ́n á máa bọ́ náà ló ní ìrètí láti lọ sí ọ̀run.
^ ìpínrọ̀ 8 Ìpínrọ̀ 8: Níwọ̀n bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ti ń “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì,” ó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì máa ń kọ́ àwọn èèyàn déédéé. Díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì yìí ló wá di ara Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
^ ìpínrọ̀ 12 Ìpínrọ̀ 12: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì tí kì í ṣe àpọ́sítélì náà rí ẹ̀bùn ẹ̀mí gbà lọ́nà ìyanu, ó jọ pé lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àpọ́sítélì ló máa ń fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí yìí lọ́nà ìyanu tàbí kí wọ́n gbà á níṣojú àpọ́sítélì kan.—Ìṣe 8:14-18; 10:44, 45.
^ ìpínrọ̀ 13 Ìpínrọ̀ 13: Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Ìṣe 20:29, 30 fi hàn pé ọ̀nà méjì ni àtakò sí ìjọ Kristẹni á ti wá. Àkọ́kọ́, àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà (ìyẹn “àwọn èpò”) máa “wọlé wá sáàárín” àwọn Kristẹni tòótọ́. Èkejì, “láàárín” àwọn Kristẹni tòótọ́, àwọn kan máa di apẹ̀yìndà, wọ́n á máa sọ àwọn “ohun àyídáyidà.”
^ ìpínrọ̀ 17 Ìpínrọ̀ 17: Wo àpilẹ̀kọ náà, “Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́,” lójú ìwé 11, ìpínrọ̀ 6 nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.