Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Wọ́n Dúró Ṣinṣin ní “Wákàtí Ìdánwò”

Wọ́n Dúró Ṣinṣin ní “Wákàtí Ìdánwò”

NÍGBÀ tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1914, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rí sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí pé wọn ò fẹ́ lọ́wọ́ sí ogun. (Aísá. 2:2-4; Jòh. 18:36; Éfé. 6:12) Àwọn nǹkan wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fara dà?

Henry Hudson

Nígbà tó di ọdún 1916, wọ́n gbé òfin kan kalẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Òfin yìí fi dandan lé e pé gbogbo ọkùnrin tí kò tíì gbéyàwó tó wà láàárín ọdún méjìdínlógún [18] sí ogójì [40] ọdún ló gbọ́dọ̀ wọṣẹ́ ológun. Àmọ́, tí ẹnì kan bá sọ pé ìgbàgbọ́ òun kò gba òun láyè tàbí pé òun kórìíra kéèyàn máa jagun, òfin yẹn yọ̀ǹda fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti má ṣe wọṣẹ́ ológun. Ìjọba sì gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ tó máa pinnu bóyá kí wọ́n yọ̀ǹda ẹnì kan tàbí kí wọ́n gbé iṣẹ́ míì tó jẹ́ ti ìlú fún un.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin tí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ẹnikẹ́ni tó bá lóun ò fẹ́ lọ jagun, síbẹ̀, wọ́n mú ogójì [40] lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun, wọ́n sì rán àwọn mẹ́jọ lọ sójú ogun ní ilẹ̀ Faransé. Èyí mú kí àwọ́n arákùnrin wa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ké gbàjarè sí olórí orílẹ̀-èdè náà Herbert Asquith. Wọ́n kọ lẹ́tà sí i láti fí ṣàlàyé ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin pé kò yẹ kí wọ́n fi àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n. Wọ́n sì tún fi ìsọfúnni míì ránṣẹ́, èyí tí àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-un ààbọ̀ [5,500] èèyàn buwọ́ lù láti fi bá wọn bẹ̀bẹ̀.

Ni àwọn ará bá tún gbọ́ pé ìjọba ti ní kí wọ́n yìnbọn fún àwọn mẹ́jọ tí wọ́n rán lọ sójú ogun nílẹ̀ Faransé, torí pé wọ́n kọ̀ láti jagun. Àmọ́, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà lórí ìlà, tó ku pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn fún wọn, ní wọ́n bá yí ìdájọ́ tí wọ́n ti ṣe fún wọn pa dà, wọ́n ní kí wọ́n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Bó ṣe di pé wọ́n dá wọn pa dà sílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìyẹn o, ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí kì í ṣe tàwọn ológun.

James Frederick Scott

Nígbà tí ogun yìí ò dáwọ́ dúró, ni wọ́n bá fi kún òfin yẹn, pé àwọn ọkùnrin tó ti ṣègbéyàwó náà gbọ́dọ̀ lọ sójú ogun. Ní ìlú Manchester nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n pe arákùnrin Henry Hudson tó jẹ́ dókítà lẹ́jọ́ torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà tó wá di August 3, ọdún 1916, wọ́n sọ pé ó jẹ̀bi torí pé ó kọ̀ láti jagun. Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n ní kó sanwó ìtanràn, wọ́n sì tún fi í lé àwọn ológun lọ́wọ́. Láàárín ìgbà yẹn náà, nílùú Edinburgh lórílẹ̀-èdè Scotland, wọ́n pe arákùnrin James Frederick Scott tó jẹ́ àpínwèé-ìsìn-kiri lẹ́jọ́. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni nígbà yẹn. Nígbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ náà, wọ́n ní kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Làwọn tó pè é lẹ́jọ́ bá pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà. Kí nìdí? Torí ẹjọ́ kan tí wọ́n ń ṣe pẹ̀lú arákùnrin míì nílùú London, wọ́n sì pinnu pé lọ́tẹ̀ yìí àwọn ò ní pòfo. Arákùnrin Herbert Kipps ni wọ́n pè lẹ́jọ́ níbẹ̀. Wọ́n dá arákùnrin wa lẹ́bi, wọ́n ní kó sanwó ìtanràn, wọ́n sì tún fi í lé àwọn ológun lọ́wọ́.

Nígbà tó fi máa di oṣù September, ọdún 1916, àwọn tó ti kọ̀wé béèrè fún ìyọ̀ǹda pé àwọn ò fẹ́ lọ sójú ogun jẹ́ ọ̀gọ́rùn méjì àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [264]. Márùn-ún péré lára wọn ni wọ́n yọ̀ǹda. Wọ́n ní kí àwọn àádọ́jọ ó lé mẹ́rin [154] lára wọn máa ṣe iṣẹ́ tó ń tánni lókun fáwọn ará ìlú. Àwọn mẹ́tàlélógún [23] ni wọ́n gbé iṣẹ́ tí kò jẹ́ mọ́ ogun jíjà fún lọ́dọ̀ àwọn ológun. Wọ́n fi àwọn méjìlélọ́gọ́rin [82] lé àwọn ológun lọ́wọ́, wọ́n sì ní káwọn míì lọ jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ àwọn ológun. Ìyà yìí pọ̀ débi pé inú bí àwọn ará ìlú gan-an bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ wọ́n. Ni ìjọba bá ní kí wọ́n kó wọn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun, kí wọ́n kó wọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí kì í ṣe tàwọn ológun.

Pryce Hughes

Arákùnrin Edgar Clay àti Pryce Hughes tó pa dà wá sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n gbéṣẹ́ fún níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ìsédò kan nílẹ̀ Wales. Arákùnrin Herbert Senior, ọ̀kan lára àwọn mẹ́jọ tí wọ́n dá pa dà láti ilẹ̀ Faransé nígbà yẹn, ni wọ́n rán lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Wakefield, nílùú Yorkshire. Àwọn míì ṣẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Dartmoor lábẹ́ àwọn ipò tó le koko, pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí sì làwọn ará wa tó pọ̀ jù wà.

Arákùnrin Frank Platt gbà láti ṣe iṣẹ́ tí kò jẹ́ mọ ogun jíjà lọ́dọ̀ àwọn ológun. Àmọ́ torí pé ó kọ̀ láti jagun, wọ́n lù ú nílùkulù wọ́n sí fìyà jẹ ẹ́ bí ẹni máa kú. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n kó ọ̀gbẹ́ni Atkinson Padgett mọ́ àwọn tó máa lọ jagun ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lòun náà bá yarí mọ́ wọn lọ́wọ́ pé òun ò lọ sójú ogun mọ́. Ìyà tí àwọn ológun fi jẹ ẹ́ ò kéré rárá, wọn ò láwọn ò pa á.

Herbert Senior

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa tó gbé láyé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tó túmọ̀ sí láti wà láìdásí-tọ̀túntòsì nínú ayé, wọ́n sapá láti ṣe ohun tó wu Jèhófà Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé “wákàtí ìdánwò” tó nira gan-an làwọn àkókó yẹn, síbẹ̀ àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí rí i pé àwọn ò lọ́wọ́ nínú ogun. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún wa! (Ìṣí. 3:10)—Látinú àpamọ́ wa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.