Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ wọ́n tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ lẹ́yìn ọdún 70 Sànmánì Kristẹni?
JÉSÙ sọ pé wọ́n máa pa tẹ́ńpìlì Jèhófà run pátápátá. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ọ̀gágun Títù kó àwọn ọmọ ogun Róòmù wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, tí wọ́n sì pa tẹ́ńpìlì náà run. (Mát. 24:2) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Olú Ọba Julian ṣètò bó ṣe máa tún tẹ́ńpìlì náà kọ́.
Olú Ọba Julian ni wọ́n sọ pé ó jẹ kẹ́yìn ní ìlú Róòmù. Ó jẹ́ ìbátan Constantine Ńlá, ọ̀dọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni nígbà ayé rẹ̀ ló sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, nígbà tó di olú ọba ní ọdún 361 Sànmánì Kristẹni, kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ọ mọ́. Àwọn ìwé ìtàn tiẹ̀ pè é ní Julian Apẹ̀yìndà torí pé kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́.
Julian kórìíra ẹ̀sìn Kristẹni gan-an. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà, àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ló pa bàbá rẹ̀ àtàwọn ìbátan rẹ̀ míì. Àwọn òpìtàn sọ pé Julian sọ fún àwọn Júù pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì wọn kọ́ kó lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ Jésù di wòlíì èké. *
Kò sí iyè méjì pé Julian fẹ́ láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Àmọ́ kó dájú pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tún un kọ́. Bó bá sì jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, a kò mọ́ ohun tó mú kó pa iṣẹ́ náà tì. Ohun kan tó dájú ni pé, Julian ò tíì pé ọdún méjì lórí àlééfà gẹ́gẹ́ bí olú ọba tí wọ́n fi pa á. Bó ṣe di pé wọn ò lè tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ mọ́ nìyẹn o!
^ ìpínrọ̀ 5 Ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n tún tẹ́ńpìlì náà kọ́, èyí kò lè sọ Jésù di wòlíì èké, torí kò sọ pé wọn kò ní tún un kọ́. Ohun tó sọ ni pé wọ́n máa pa tẹ́ńpìlì náà run. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣẹ lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.