Jàǹfààní Kíkún Látinú Kíka Bíbélì Déédéé
“Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 7:22.
1-3. Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń fi àwọn ohun tá à ń kà sílò, báwo ló ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
ARÁBÌNRIN àgbàlagbà kan sọ pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ní àràárọ̀ pé ó jẹ́ kí n mọ ohun tó wà nínú Bíbélì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ju ogójì [40] ìgbà lọ tí arábìnrin yìí ti ka Bíbélì tán, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa kà á. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan kọ̀wé pé Bíbélì tí òun máa ń kà ló jẹ́ kó dá òun lójú pé Jèhófà wà lóòótọ́, èyí sì ti jẹ́ kí òun túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ó tún sọ pé: “Mò ń láyọ̀ gan-an báyìí ju ìgbà tí mi ò kì í ka Bíbélì lọ.”
2 Àpọ́sítélì Pétérù gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ kó máa wù wá láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Pét. 2:2) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ níbẹ̀ sílò, a máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìgbésí ayé wa á sì nítumọ̀. A tún máa ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí àwọn náà fẹ́ràn Ọlọrun tòótọ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ara ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká “ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run.” (Róòmù 7:22) Ọ̀nà mìíràn wo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tún lè gbà ràn wá lọ́wọ́?
3 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wọn, wàá sì túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn pẹ̀lú. Bákan náà, ìmọ̀ Bíbélì á jẹ́ kó o mọ bí Ọlọ́run ṣe máa gba àwọn olódodo là nígbà tó bá pa àwọn èèyàn búburú run. O tún láǹfààní láti máa wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. Jèhófà á sì máa tì ẹ́ lẹ́yìn bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì.
KA BÍBÉLÌ KÓ O SÌ ṢE ÀṢÀRÒ
4. Kí ló túmọ̀ sí láti fi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” ka Bíbélì?
4 Tá a bá ń ka Bíbélì, Jèhófà fẹ́ ká fara balẹ̀ ronú lé e lórí kó bàa lè yé wa dáadáa. Ó sọ fún Jóṣúà pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru.” (Jóṣ. 1:8; Sm. 1:2) Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ńṣe la gbọ́dọ̀ máa jẹnu wúyẹ́wúyẹ́ nígbà tá a bá ń ka Bíbélì? Rárá o. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká má ṣe kánjú kà á, kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti ronú lórí ohun tá a bá kà. Èyí á mú ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ẹsẹ tó máa ràn wá lọ́wọ́ tó sì tún máa mú wa lọ́kàn le. Tó o bá rí gbólóhùn kan, ẹsẹ Bíbélì kan tàbí ìtàn kan tó lè mú kó o túbọ̀ jẹ́ onígboyà, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ kà á. O sì tún lè fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á ní àkàtúnkà. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó ò ń kà á lè wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé tí ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá yé wa dáadáa, a máa rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé e.
5-7. Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé tá a bá ń fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti (a) máa pa òfin Ọlọ́run mọ́; (b) máa hùwà pẹ̀lẹ́; (d) máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro.
5 Nígbà tá a bá ń ka àwọn ibi tó dà bíi pé ó ṣòro láti lóye nínú Bíbélì, ó dára ká má ṣe kánjú kà á, ká lè ronú lórí ohun tá à ń kà. Kí ọ̀rọ̀ yìí bàa lè yé wa dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mẹ́ta kan. Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́: Jẹ́ ká sọ pé arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń fara balẹ̀ ka ìwé Hóséà. Nígbà tó dé orí 4, ó dúró ní ẹsẹ 11 sí 13 kó lè ronú lórí ohun tí ẹsẹ yẹn sọ. (Ka Hóséà 4:11-13.) Kí nìdí tí àwọn ẹsẹ yẹn fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í dojú kọ ìdẹwò láti ṣèṣekúṣe nílé ìwé. Àmọ́, bó ṣe ń ronú lórí àwọn ẹsẹ yẹn, ó ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Jèhófà máa ń rí àwọn nǹkan búburú táwọn èèyàn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Mi ò sì fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́.’ Arákùnrin náà wá pinnu pé òun máa ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó ní ká má ṣèṣekúṣe.
6 Àpẹẹrẹ kejì: Jẹ́ ká sọ pé nígbà tí arábìnrin kan ń ka àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, ó ti kà á dé Jóẹ́lì 2:13 báyìí. (Ka Jóẹ́lì 2:13.) Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kó rántí pé òun gbọ́dọ̀ fìwà jọ Jèhófà, tó jẹ́ ‘olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, tó ń lọ́ra láti bínú, tó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.’ Ó pinnu láti ṣe àwọn ìyípadà kan torí pé ó máa ń fi ìbínú àti ohùn líle sọ̀rọ̀ sí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì.
7 Àpẹẹrẹ kẹta: Ẹ jẹ́ ká sọ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin kan tó ní aya àtàwọn ọmọ, ó sì ń ṣàníyàn nípa bí yóò ṣe máa bójú tó ìdílé rẹ̀. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ó fara balẹ̀ ka ìwé Náhúmù 1:7. Níbẹ̀ ó kà pé Jèhófà mọ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì máa dáàbò bò wọ́n “ní ọjọ́ wàhálà.” Ọ̀rọ̀ yìí tu arákùnrin náà nínú, torí ó jẹ́ kó rí i pé Jèhófà fẹ́ràn òun àti ìdílé òun. Látàrí èyí, kò ṣàníyàn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn náà, ó fara balẹ̀ ka ẹsẹ 15. (Ka Náhúmù 1:15.) Arákùnrin náà tún wá rí i pé ọ̀nà tóun lè gbà fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni pé kí òun máa wàásù ìhìn rere, àní nígbà ìṣòro pàápàá. Torí náà, bó ṣe ń wá iṣẹ́ míì, bẹ́ẹ̀ náà ló ń jáde òde ẹ̀rí ní àárín ọ̀sẹ̀.
8. Ní ṣókí, sọ ohun pàtàkì kan tó o kọ́ nígbà tó ò ń ka Bíbélì.
8 Àwọn àpẹẹrẹ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí kún fún ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n látinú ibi táwọn kan rò pé ó ṣòro láti lóye nínú Bíbélì la ti rí wọn. Tó o bá fi sọ́kàn pé kó o lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lo ṣe ń ka àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà, Jóẹ́lì àti Náhúmù, wàá fẹ́ láti máa fara balẹ̀ ka àwọn ẹsẹ míì tó wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Tá a bá ń ka ìwé àwọn wòlíì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, wọ́n lè sọ wá di ọlọgbọ́n, wọ́n sì lè tù wá nínú. Gbogbo àwọn apá tó kù nínú Bíbélì náà ló lè ràn wá lọ́wọ́. Ńṣe ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí ilẹ̀ tá a ti lè wa ìṣúra iyebíye bíi wúrà àti fàdákà jáde. O ò ṣe kúkú ka Bíbélì látòkè délẹ̀ kó o lè wa àwọn ìṣúra tó wà nínú rẹ̀ jáde, ìyẹn àwọn ìtọ́sọ́nà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
SAPÁ GIDIGIDI KÓ O LÈ LÓYE OHUN TÓ Ò Ń KÀ
9. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Bíbélì lè yé wa dáadáa?
9 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tó ò ń kà yé ẹ dáadáa. Torí náà,
máa ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn èèyàn, àwọn ìlú àtàwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì. Bó o bá ka ohun kan nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n tí o kò mọ bó o ṣe lè fi í sílò, o lè ní kí alàgbà kan tàbí ẹlòmíì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ká lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká túbọ̀ máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Kristẹni kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní tó sapá láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpólò ni orúkọ rẹ̀.10, 11. (a) Báwo ni wọ́n ṣe ran Àpólò lọ́wọ́ tó fi já fáfá sí i gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere? (b) Kí la rí kọ́ lára Àpólò?
10 Júù tó di Kristẹni ni Àpólò, ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, òjíṣẹ́ onítara sì ni. Ìwé Ìṣe sọ pé ó máa ń wàásù nípa Jésù. Àmọ́, Àpólò kò mọ̀ pé Jésù ti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tuntun nípa ìrìbọmi. Torí náà, nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya gbọ́ ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní ìlú Éfésù, wọ́n ṣàlàyé “ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” (Ìṣe 18:24-26) Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe ran Àpólò lọ́wọ́?
11 Lẹ́yìn tí Àpólò kúrò ní Éfésù, ó tún ń bá a nìṣó láti máa wàásù ní Ákáyà. Ó fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé fún wọn ní gbangba pé àwọn Júù kò tọ̀nà, àti pé Jésù ni Kristi náà. Ó sì tún ran àwọn tó gba ìhìn rere gbọ́ lọ́wọ́. (Ìṣe 18:27, 28) Níwọ̀n bí Àpólò sì ti lóye ohun tí ìrìbọmi Kristẹni túmọ̀ sí báyìí, “ó ṣe ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà” fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni kí wọ́n lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Bíi ti Àpólò, a gbọ́dọ̀ máa sapá ká lè lóye ohun tá a bá kà nínú Bíbélì. Lẹ́sẹ̀ kan náà, bí ẹnì kan bá dámọ̀ràn ohunkóhun tó máa mú ká lè sunwọ̀n sí i nínú ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún, ká sì fìrẹ̀lẹ̀ gbà á. (Wo àpótí náà, “Ṣé Ohun Tó O Fi Ń Kọ́ni Bá Àwọn Ìtọ́ni Tó Dé Kẹ́yìn Mu?”)
FI OHUN TÓ O BÁ KỌ́ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́
12, 13. Báwo la ṣe lè fọgbọ́n lo Ìwé Mímọ́ láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan máa tẹ̀ síwájú?
12 Bíi ti Pírísílà, Ákúílà àti Àpólò, àwa náà lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tó o bá ran ẹnì kan tó gbọ́ ìwàásù lọ́wọ́ débi pé ó ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀, tó wá ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Tó o bá sì jẹ́ alàgbà, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ bí ẹnì kan nínú ìjọ bá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ torí pé o fi Bíbélì tọ́ ọ sọ́nà nígbà tó wà nínú ìṣòro? A máa láyọ̀ gan-an tá a bá fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí ìgbésí ayé wọn sì dára sí i. * Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
13 Nígbà ayé wòlíì Èlíjà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Bóyá kí wọ́n máa bọ òrìṣà ni o, tàbí kí wọ́n máa sin Ọlọ́run òtítọ́. Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Èlíjà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn sọ lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí kò tíì pinnu láti máa sin Jèhófà lọ́wọ́. (Ka 1 Àwọn Ọba 18:21.) Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹ̀rù ń ba ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ìbátan òun á máa yọ òun lẹ́nu. O lè jíròrò ohun tó wà nínú Aísáyà 51:12, 13 pẹ̀lú rẹ̀. (Kà á.) Ìyẹn lè mú kó pinnu láti máa sin Jèhófà.
14. Kí lo lè ṣe tí wàá fi máa rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì nígbà tó o bá fẹ́ fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
14 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ló wà nínú Bíbélì tó lè fún wa ní ìṣírí, tó lè tọ́ wa sọ́nà, tó sì lè fún wa lókun. Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé báwo ni wàá ṣe máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì nígbà tó o bá fẹ́ lò wọ́n. Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé ko o máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wàá mọ ọ̀pọ̀ gbólóhùn nínú Ìwé Mímọ́. Jèhófà á sì fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ rán ẹ létí àwọn gbólóhùn náà nígbà tó o bá nílò wọn.—Máàkù 13:11; ka Jòhánù 14:26. *
15. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
15 Bíi ti Sólómọ́nì Ọba, máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n. Ọgbọ́n yìí á wúlò fún ẹ tó o bá ń wàásù àti nígbà tó o bá ń bójú tó àwọn ojúṣe rẹ nínú ìjọ. (2 Kíró. 1:7-10) Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn wòlíì ìgbàanì, máa fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí á jẹ́ kó o ní ìmọ̀ tó péye nípa Jèhófà àti àwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe. (1 Pét. 1:10-12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ . . . àti ti ẹ̀kọ́ àtàtà.” (1 Tím. 4:6) Tó o bá ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá lóye rẹ̀ dáadáa, wàá sì mọ bó o ṣe lè fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìgbàgbọ́ rẹ á máa lágbára sí i.
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ
16. (a) Báwo làwọn ará Bèróà ṣe jàǹfààní nítorí pé wọ́n ń ka Bíbélì lójoojúmọ́? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?
16 Àwọn Júù tí wọ́n gbé ní Bèróà máa ń fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún wọn, wọ́n fi ohun tó kọ́ wọn wé ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́. Èyí wá mú kí ọ̀pọ̀ nínú wọn rí i pé òtítọ́ ló fi ń kọ́ àwọn. Látàrí ìyẹn, wọ́n “di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 17:10-12) Ohun tá a rí kọ́ nínú èyí ni pé tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára sí i. Ó sì ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a bá fẹ́ la ayé búburú yìí já sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Héb. 11:1.
17, 18. (a) Báwo ni ìgbàgbọ́ tó lágbára àti ìfẹ́ ṣe ń dáàbò bo ọkàn wa? (b) Báwo ni ìrètí ṣe ń dàábò bò wá lọ́wọ́ ewu?
17 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a nílò ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìrètí. Ó sọ pé: “Ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀ àti ìrètí ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.” (1 Tẹs. 5:8) Àwọn ọmọ ogun máa ń fi ìgbàyà dáàbò bo àyà wọn. Bákan náà, ó yẹ kí àwa Kristẹni pẹ̀lú máa dáàbò bo ọkàn wa lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí Kristẹni kan bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tó sì tún fẹ́ràn Jèhófà àtàwọn èèyàn tọkàntọkàn, ńṣe ló ń dáàbò bo ọkàn rẹ̀. Kò sì ní fẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kó pàdánù ojú rere Ọlọ́run.
18 Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa àṣíborí kan tá a gbọ́dọ̀ máa dé. Ó sọ pé àṣíborí yìí jẹ́ “ìrètí ìgbàlà.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọmọ ogun máa ń dé àṣíborí kí wọ́n lè dáàbò bo orí wọn. Tá a bá ní ìrètí tó dájú pé Jèhófà lè gbà wá là, ìrètí yìí kò ní jẹ́ ká gba èròkerò láyè nínú ọkàn wa. Bá a sì ṣe lè ní ìrètí yìí ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí ìrètí tá a ní bá dá wa lójú, a ò ní bá àwọn apẹ̀yìndà dà ohunkóhun pọ̀, a ò sì ní fetí sí ọ̀rọ̀ òdì wọn, èyí tó lè yára tàn kálẹ̀ nínú ìjọ. (2 Tím. 2:16-19) Ìrètí yìí á tún mú ká sá fún ohunkóhun tó lè mú ká hùwà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí.
Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ MÁA JẸ́ KÁ LA ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN JÁ
19, 20. Kí nìdí tá a fi mọyì Bíbélì? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì rẹ̀? (Wo àpótí náà, “Ohun Tí Mo Nílò Gan-an Ni Jèhófà Ń Fún Mi.”)
19 Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àkókò òpin, ó túbọ̀ ń ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa gbára lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ìtọ́ni tá à ń rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń mú ká yíwà pa dà, kì í sì í jẹ́ ká gba èrò tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ láyè. Ìṣírí àti ìtùnú tá à ń rí gbà nínú Bíbélì sì máa ń mú ká lè fara da àdánwò èyíkéyìí tí Sátánì àti ayé rẹ̀ lè mú bá wa. Bí Jèhófà ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣamọ̀nà wa, a kò ní yẹsẹ̀ láé lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.
20 Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí “a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” Lára àwọn onírúurú èèyàn náà ni gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo àwọn tó ń fẹ́ láti gbọ́rọ̀ wa tí wọ́n sì gbà pé ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ìgbàlà gbọ́dọ̀ ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Torí náà, tá a bá fẹ́ la ayé búburú yìí já, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì ká sì máa fi àwọn ìtọ́ni inú rẹ̀ sílò. A máa fi hàn pé òótọ́ la mọyì Ọ̀rọ̀ Jèhófà, tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́.—Jòh. 17:17.
^ ìpínrọ̀ 12 Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti mú kí àwọn èèyàn tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì tipátipá, a ò sì gbọ́dọ̀ kàn wọ́n lábùkù. Àpẹẹrẹ Jèhófà ni ká máa tẹ̀ lé. Ká máa ní sùúrù fún àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká má sì fọwọ́ tó le koko mú wọn.—Sm. 103:8.
^ ìpínrọ̀ 14 Tó bá wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan lo rántí nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, àmọ́ ti o kò rántí ìwé tó jẹ́, tó o sì ti gbàgbé orí àti ẹsẹ tó wà ńkọ́? O lè fi ọ̀rọ̀ tó o rántí yẹn wá a nínú atọ́ka tó wà lẹ́yìn Bíbélì tàbí nínú àkójọ ìtẹ̀jáde wa tó wà nínú Watchtower Library, tàbí nínú ìwé atọ́ka Bíbélì, ìyẹn Comprehensive Concordance.