Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Kí o Sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe
“Níwọ̀n bí [Ọlọ́run] kò ti lè fi ẹnì kankan tí ó tóbi jù ú búra, ó fi ara rẹ̀ búra.”—HÉB. 6:13.
1. Báwo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí ti èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀?
JÈHÓFÀ jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì í sọ òótọ́ nígbà gbogbo, àmọ́ “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Héb. 6:18; ka Númérì 23:19.) Gbogbo nǹkan tó bá ṣèlérí fún aráyé ló máa ń mú ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ló “sì wá rí bẹ́ẹ̀.” Torí náà, nígbà tó fi máa di òpin ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá, “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”—Jẹ́n. 1:6, 7, 30, 31.
2. Kí ni ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi “ṣe é ní ọlọ́wọ̀”?
2 Ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá parí lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe àyẹ̀wò gbogbo nǹkan tó dá, tó sì rí i pé wọ́n dára. Lẹ́yìn èyí, ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:2 wá sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ keje.” Èyí kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ àkókò gígùn kan tí Ọlọ́run fi sinmi kúrò nínú ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run ṣì ń bá a nìṣó. (Héb. 4:9, 10) Bíbélì kò sọ àkókò pàtó tó bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò kan lẹ́yìn tó dá Éfà, ìyàwó Ádámù, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn. À ń retí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi láìpẹ́, èyí tó máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run nípa ilẹ̀ ayé ṣẹ. Ìyẹn ni pé kí ayé di Párádísè níbi tí àwọn èèyàn pípé yóò máa gbé títí láé. (Jẹ́n. 1:27, 28; Ìṣí. 20:6) Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ dájú pé ó máa ṣeé ṣe fún ẹ láti gbádùn irú ìgbésí ayé aláyọ̀ yẹn? Ó dájú pé o lè gbádùn rẹ̀! Torí pé ‘Ọlọ́run tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.’ Ọ̀rọ̀ yìí mú kó dá wa lójú pé ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ yòówù kó wáyé, nígbà tó bá fi máa di òpin ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run, ó dájú pé gbogbo ìlérí rẹ̀ á ti ní ìmúṣẹ.—Jẹ́n. 2:3.
3. (a) Ọ̀tẹ̀ wo ló wáyé lẹ́yìn tí ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe láti paná ọ̀tẹ̀ náà?
3 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé. Sátánì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ áńgẹ́lì, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Òun ló pa irọ́ àkọ́kọ́, ó sì tan Éfà láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà. (1 Tím. 2:14) Éfà náà wá mú kí ọkọ rẹ̀ dara pọ̀ nínú ọ̀tẹ̀ náà. (Jẹ́n. 3:1-6) Kódà nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jù lọ láyé àtọ̀run yìí wáyé, tí Sátánì sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó jẹ́ òpùrọ́, Jèhófà kò rí ìdí tó fi yẹ kí òun búra pé òun ṣì máa mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa wá ṣe kedere nígbà tó bá yá láti ṣàlàyé bí òun ṣe máa paná ọ̀tẹ̀ náà. Ó ní: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ [Sátánì] àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun [Irú-ọmọ tá a ṣèlérí náà] yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́n. 3:15; Ìṣí. 12:9.
ÌBÚRA JẸ́ Ọ̀NÀ TÓ BÓFIN MU LÁTI FÌDÍ Ọ̀RỌ̀ MÚLẸ̀
4, 5. Ohun tó bófin mu wo ni Ábúráhámù máa ń ṣe nígbà míì?
4 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò dájú pé ó pọn dandan fún Ádámù àti Éfà láti búra kí wọ́n lè fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ làwọn ń sọ. Àwọn ẹ̀dá pípé tí wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run tí wọ́n sì fìwà jọ ọ́ kì í búra; òtítọ́ ni wọ́n máa ń sọ nígbà gbogbo, wọ́n sì fọkàn tán ara wọn. Àmọ́, nǹkan yí pa dà nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé wọ ayé. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, nígbà tí irọ́ àti ẹ̀tàn gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn, ó wá di dandan pé bí ọ̀ràn pàtàkì kan bá wáyé, kí wọ́n máa búra láti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ làwọn ń sọ.
5 Ìbúra jẹ́ ọ̀nà tó bófin mu láti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀, baba ńlá náà Ábúráhámù sì lò ó lọ́nà tó dára ní ìgbà mẹ́ta, ó kéré tán. (Jẹ́n. 21:22-24; 24:2-4, 9) Àpẹẹrẹ kan ni ti ìgbà tó dé láti ibi tó ti lọ ṣẹ́gun ọba Élámù àtàwọn onígbèjà rẹ̀. Ọba Sálẹ́mù àti ọba Sódómù jáde wá pàdé Ábúráhámù. Melikisédékì, ọba Sálẹ́mù tún jẹ́ “àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.” Torí náà, ó bù kún Ábúráhámù, ó sì yin Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ kí Ábúráhámù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Jẹ́n. 14:17-20) Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọba Sódómù fẹ́ san èrè fún Ábúráhámù nítorí pé ó gba àwọn èèyàn ọba náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tó wá gbógun tì wọ́n, Ábúráhámù búra pé: “Mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ti gidi ní ìbúra sí Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, pé, láti orí fọ́nrán òwú dórí okùn sálúbàtà, rárá, èmi kì yóò mú nǹkan kan nínú ohunkóhun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má bàa sọ pé, ‘Èmi ni ó sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’”—Jẹ́n. 14:21-23.
JÈHÓFÀ FI ÌBÚRA ṢÈLÉRÍ FÚN ÁBÚRÁHÁMÙ
6. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Ábúráhámù fi lélẹ̀ fún wa? (b) Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ohun tí Ábúráhámù ṣe?
6 Jèhófà pẹ̀lú búra kí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè gba àwọn ìlérí tó ṣe gbọ́. Ó lo gbólóhùn bíi, “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” (Ìsík. 17:16) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ju ogójì ìgbà lọ tí Jèhófà Ọlọ́run búra. Bóyá àpẹẹrẹ tá a mọ̀ jù lọ lèyí tó wáyé nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Jèhófà ti bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú bíi mélòó kan, èyí tó jẹ́ pé tá a bá pa gbogbo wọn pọ̀, ńṣe ló fi hàn pé irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà máa wá látọ̀dọ̀ Ábúráhámù nípasẹ̀ Ísákì ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 12:1-3, 7; 13:14-17; 15:5, 18; 21:12) Lẹ́yìn náà, Jèhófà dán Ábúráhámù wò lọ́nà tó lágbára gan-an, ó pàṣẹ fún un pé kí ó fi ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ. Láìjáfara, Ábúráhámù ṣègbọràn sí Ọlọ́run, àmọ́ bó ṣe kù díẹ̀ kó fi Ísákì rúbọ báyìí ni áńgẹ́lì Ọlọ́run dá a dúró. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá búra pé: “Mo fi ara mi búra . . . pé nítorí òtítọ́ náà pé o ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì fawọ́ ọmọkùnrin rẹ sẹ́yìn, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun; irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnubodè àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́n. 22:1-3, 9-12, 15-18.
7, 8. (a) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi búra fún Ábúráhámù? (b) Báwo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù ṣe máa jàǹfààní nínú ìlérí tí Ọlọ́run fi ìbúra ṣe?
7 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi búra fún Ábúráhámù pé òun máa mú àwọn ìlérí Òun ṣẹ? Ìdí tó fi búra ni pé ó fẹ́ láti fi àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n máa jẹ́ apá kejì lára “irú-ọmọ” tí a ṣèlérí náà lọ́kàn balẹ̀, kí ìgbàgbọ́ wọn sì túbọ̀ lágbára. (Ka Hébérù 6:13-18; Gál. 3:29) Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé, Jèhófà “mú ìbúra kan wọ̀ ọ́, pé, nípasẹ̀ ohun àìlèyípadà méjì, [ìlérí rẹ̀ àti ìbúra rẹ̀] nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́, kí àwa . . . lè ní ìṣírí tí ó lágbára láti gbá ìrètí tí a gbé ka iwájú wa mú.”
8 Àwọn ẹni àmì òróró nìkan kọ́ ló jàǹfààní nínú ìbúra tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù. Jèhófà búra pé, nípasẹ̀ “irú-ọmọ” Ábúráhámù, àwọn èèyàn ní “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́n. 22:18) Lára àwọn tó máa gba ìbùkún yìí ni “àwọn àgùntàn mìíràn” tó ṣègbọràn sí Kristi, tí wọ́n ń fojú sọ́nà láti máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (Jòh. 10:16) Yálà o ní ìrètí láti lọ sọ́run tàbí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, “gbá” ìrètí tí a gbé ka iwájú rẹ “mú” nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọrun nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.—Ka Hébérù 6:11, 12.
ÀWỌN ÌBÚRA MÍÌ TÓ JẸ MỌ́ ÌLÉRÍ TÍ ỌLỌ́RUN ṢE FÚN ÁBÚRÁHÁMÙ
9. Ìbúra wo ni Ọlọ́run ṣe nígbà tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì?
9 Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti gbé láyé, Jèhófà tún búra pé òun máa mú àwọn ìlérí tí òun ti ṣe fún un ṣẹ. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó rán Mósè pé kó lọ bá àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì nígbà náà sọ̀rọ̀. (Ẹ́kís. 6:6-8) Ọlọ́run sọ pé: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì, mo . . . gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn ní ìbúra láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ tí mo ti ṣe amí rẹ̀ fún wọn, èyí tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” Nípa báyìí, Jèhófà fi hàn pé ńṣe lòun ń búra fún wọn nígbà yẹn.—Ìsík. 20:5, 6.
10. Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́yìn tó dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì?
10 Nígbà tó yá, lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, ó tún fi ìbúra ṣe ìlérí míì fún wọn. Ó ní: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.” (Ẹ́kís. 19:5, 6) Àǹfààní ńlá mà lèyí jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì o! Ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé bí ẹnikẹ́ni tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè náà bá ṣègbọràn sí Jèhófà, ó lè máa fojú sọ́nà pé kí Ọlọ́run sọ òun di ara ìjọba àwọn àlùfáà tí yóò ṣe gbogbo aráyé yòókù láǹfààní. Lẹ́yìn náà, Jèhófà ṣàlàyé pé ńṣe ni òun ń búra fún wọn nígbà tí òun ń ṣèlérí yẹn. Ó ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí . . . sọ gbólóhùn ìbúra fún ọ àti láti wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ.”—Ìsík. 16:8.
11. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nígbà tí Ọlọ́run ní kí wọ́n wá wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú òun kí wọ́n sì di àyànfẹ́ òun?
11 Nígbà yẹn, Jèhófà kò fi dandan mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì búra pé àwọn máa ṣègbọràn sí òun; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fipá mú wọn láti wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fínnú fíndọ̀ sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 19:8) Ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jèhófà Ọlọ́run sọ àwọn nǹkan tó fẹ́ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ yìí máa ṣe. Ó kọ́kọ́ fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá, lẹ́yìn náà ló ní kí Mósè ṣàlàyé síwájú sí i fún wọn nípa àwọn àṣẹ tó wà nínú Ẹ́kísódù 20:22 sí Ẹ́kísódù 23:33. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sọ? “Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dáhùn ní ohùn kan, wọ́n sì wí pé: ‘Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.’” (Ẹ́kís. 24:3) Lẹ́yìn náà, Mósè kọ àwọn òfin náà sínú “ìwé májẹ̀mú,” ó sì kà á sókè ketekete kí gbogbo orílẹ̀-èdè náà lè gbọ́ ọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èèyàn náà jẹ́jẹ̀ẹ́ ní ìgbà kẹta pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe, a ó sì jẹ́ onígbọràn.”—Ẹ́kís. 24:4, 7, 8.
12. Kí ni Jèhófà ṣe nípa májẹ̀mú tó bá àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ dá, kí sì ni àwọn èèyàn náà ṣe?
12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojúṣe tó jẹ́ tirẹ̀ nínú májẹ̀mú Òfin náà nípa ṣíṣètò àgọ́ ìjọsìn àti ẹgbẹ́ àlùfáà, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ kíákíá ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbàgbé pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì “ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sm. 78:41) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ń gba àwọn ìsọfúnni síwájú sí i lórí Òkè Sínáì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní sùúrù mọ́, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í yingin, èrò wọn ni pé Mósè ti pa wọ́n tì. Torí náà wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà, wọ́n sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 32:1, 4) Lẹ́yìn náà, wọ́n wá ṣe ayẹyẹ kan tí wọ́n pè ní “àjọyọ̀ fún Jèhófà,” wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì rúbọ sí ère tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. Nígbà tí Jèhófà rí ohun tí wọ́n ṣe yìí, ó sọ fún Mósè pé: “Ní kíákíá, wọ́n ti yà kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn láti máa rìn.” (Ẹ́kís. 32:5, 6, 8) Ó dunni pé, látìgbà yẹn lọ ló ti di àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n má sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.—Núm. 30:2.
ÌBÚRA MÉJÌ MÍÌ
13. Ìlérí wo ni Ọlọ́run fi ìbúra ṣe fún Dáfídì Ọba, báwo ni èyí sì ṣe kan Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà?
13 Nígbà ìṣàkóso Dáfídì Ọba, Jèhófà tún fi ìbúra ṣe ìlérí méjì míì fún àǹfààní gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, ó búra fún Dáfídì pé ìtẹ́ rẹ̀ máa wà títí láé. (Sm. 89:35, 36; 132:11, 12) Èyí túmọ̀ sí pé “ọmọkùnrin Dáfídì” ni a ó pe Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà. (Mát. 1:1; 21:9) Dáfídì fi ìrẹ̀lẹ̀ pe ẹni tó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yìí ní “Olúwa” òun torí pé ipò Kristi máa ga ju tirẹ̀ lọ.—Mát. 22:42-44.
14. Ìlérí wo ni Ọlọ́run fi ìbúra ṣe nípa Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà, báwo la sì ṣe ń jàǹfààní nínú rẹ̀?
14 Ìlérí kejì ni pé, Jèhófà mí sí Dáfídì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọba tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí yóò tún jẹ́ Àlùfáà Àgbà fún gbogbo aráyé. Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ohun méjì tó yàtọ̀ pátápátá ni ipò ọba àti ipò àlùfáà jẹ́. Inú ẹ̀yà Léfì làwọn àlùfáà ti máa ń wá, àwọn ọba sì máa ń wá látinú ẹ̀yà Júdà. Àmọ́, nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa olókìkí ọmọ tó máa jẹ́ ajogún rẹ̀ náà, ó sọ pé: “Àsọjáde Jèhófà fún Olúwa mi ni pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’ Jèhófà ti búra (kì yóò sì pèrò dà) pé: ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì!’” (Sm. 110:1, 4) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ń ní ìmúṣẹ, torí pé Jésù Kristi tó jẹ́ Irú-ọmọ tí a ṣèlérí náà ti ń ṣàkóso ní ọ̀run báyìí. Bákan náà, ó jẹ́ Àlùfáà Àgbà fún gbogbo aráyé ní ti pé ó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó bá ronú pìwà dà kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.—Ka Hébérù 7:21, 25, 26.
ÍSÍRẸ́LÌ TUNTUN ỌLỌ́RUN
15, 16. (a) Ísírẹ́lì méjì wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èwo ni Ọlọ́run sì ń bù kún lóde òní? (b) Àṣẹ wo ni Jésù pa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa jíjẹ́jẹ̀ẹ́?
15 Nítorí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò tẹ́wọ́ gba Jésù Kristi, wọ́n pàdánù ojú rere Ọlọ́run pátápátá, ìrètí tí wọ́n ní láti di “ìjọba àwọn àlùfáà” sì bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Jésù sọ fún àwọn tó jẹ́ aṣáájú àwọn Júù pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mát. 21:43) A bí orílẹ̀-èdè tuntun yẹn nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n pé jọ sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn ni a wá mọ̀ sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” Kò pẹ́ rárá tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ìgbà yẹn fi di ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí.—Gál. 6:16.
16 Orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun Ọlọ́run yìí kò dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ti pé ó ń bá a nìṣó láti máa so èso rere nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. Ìbúra wà lára àṣẹ tí Ọlọ́run fún àwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun náà. Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn kò fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìbúra. Wọ́n máa ń búra èké tàbí kí wọ́n máa búra lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan. (Mát. 23:16-22) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Má ṣe búra rárá . . . Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.”—Mát. 5:34, 37.
Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ
17. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò dáa rárá kéèyàn máa búra? Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé, kí ló túmọ̀ sí pé ká jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni? A máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn. Bí a ti ń ṣe àṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ǹjẹ́ ká lè máa bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Inú Jèhófà náà á sì dùn láti bù kún wa títí ayé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye tó fi ìbúra ṣe.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
Àwọn ìlérí Jèhófà kì í yẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ábúráhámù máa tó rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Jèhófà