Inú Rere Máa Ń Yí Ìwà Kíkorò Pa Dà
Inú Rere Máa Ń Yí Ìwà Kíkorò Pa Dà
NÍGBÀ tí George àti Manon ní orílẹ̀-èdè Netherlands lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún obìnrin àgbàlagbà kan, ńṣe ni obìnrin náà fajú ro. Wọ́n gbọ́ pé ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kú, ọkọ tó kọ́kọ́ fẹ́ àti èyí tó fẹ́ tẹ̀ lé e náà ti kú, ó sì tún ní àìsàn oríkèé ara ríro tó lékenkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fara balẹ̀ nígbà tí wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀, síbẹ̀ kò túra ká.
Torí náà, George dábàá pé kí òun àti Manon gbé ìdìpọ̀ òdòdó lọ fún Rie, ìyẹn obìnrin àgbàlagbà náà torí pé kò ní alábàárò, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nígbà tó rí òdòdó náà, inú rẹ̀ dùn gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ yẹn, wọ́n jọ dá ìgbà tí wọ́n máa pa dà wá. George àti Manon lọ lọ́jọ́ náà, àmọ́ kò sẹ́ni tó dáhùn nígbà tí wọ́n kan ilẹ̀kùn. Wọ́n tún wá a lọ sílé lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ wọn kò bá a. Wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ńṣe ni ó ń sá fún àwọn.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, George bá Rie nílé. Ó ní kí wọ́n má ṣe bínú pé wọn kò bá òun lọ́jọ́ tí wọ́n fi àdéhùn sí, pé ilé ìwòsàn ni òun wà ní gbogbo àkókò náà. Ó ní: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé látìgbà tí ẹ̀yin méjèèjì ti lọ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì!” Èyí yọrí sí ìjíròrò tó lárinrin, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀.
Bí Rie ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwà kíkorò rẹ̀ yí pa dà, ó sì di aláyọ̀ àti onínúure. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í kúrò nílé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnikẹ́ni tó bá wá kí i nílé sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́. Àìlera rẹ̀ kò jẹ́ kó lè máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, síbẹ̀ inú rẹ̀ máa ń dùn tí àwọn ará bá wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tó pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin [82], ó lọ sí àpéjọ àyíká kan, ó sì ṣe ìrìbọmi láti fi ẹ̀rí hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Ó kú ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n sì rí ewì kan tó kọ. Nínú ewì náà, ó sọ bí ìdánìkanwà ṣe máa ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn àgbàlagbà, ó sì tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn jẹ́ onínúure. Manon sọ pé: “Nígbà tí mo ka ewì náà, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn, inú mi sì dùn torí pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti fi inú rere hàn sí i.”
Àpẹẹrẹ Jèhófà fúnra rẹ̀ ń mú ká lè máa fi irú ìfẹ́ àti inú rere bẹ́ẹ̀ hàn. (Éfé. 5:1, 2) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò sèso rere bá a ṣe ń “dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run . . . nípa inú rere.”—2 Kọ́r. 6:4, 6.