Háránì Ìlú Àtijọ́ Tó Kún Fún Ìgbòkègbodò
Háránì Ìlú Àtijọ́ Tó Kún Fún Ìgbòkègbodò
BÍ ÀWỌN tó mọ Ìwé Mímọ́ bá gbọ́ orúkọ náà Háránì, kíá ni wọ́n á rántí Ábúráhámù, bàbá olóòótọ́ ìgbàanì. Nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà ìyàwó rẹ̀, àti Térà bàbá rẹ̀ pẹ̀lú Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń rìnrìn àjò láti ìlú Úrì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n dúró ní Háránì. Níbẹ̀, Ábúráhámù ní ọ̀pọ̀ ohun ìní tara. Lẹ́yìn tí bàbá Ábúráhámù kú, ó ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣèlérí fún un. (Jẹ́n. 11:31, 32; 12:4, 5; Ìṣe 7:2-4) Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù rán èyí tó dàgbà jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Háránì, tàbí ibì kan tó wà nítòsí láti lọ wá aya fún Ísáákì. Jákọ́bù ọmọ ọmọ Ábúráhámù náà gbé ìlú yìí fún ọdún bíi mélòó kan.—Jẹ́n. 24:1-4, 10; 27:42-45; 28:1, 2, 10.
Ìlú Háránì wà lára àwọn “orílẹ̀-èdè” tí Senakéríbù Ọba Ásíríà mẹ́nu bà pé àwọn ọba Ásíríà ṣẹ́gun nígbà tó ń halẹ̀ mọ́ Hesekáyà Ọba Júdà pé tí kò bá túúbá, àwọn máa kógun jà á. Kì í ṣe ìlú “Háránì” nìkan ni ibi tí wọ́n dárúkọ níbí yìí ń tọ́ka sí, ó tún ń tọ́ka sí àwọn àgbègbè rẹ̀. (2 Ọba 19:11, 12) Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé ìlú Háránì wà lára àwọn ìlú tí ìlú Tírè ń bá ṣòwò, èyí fi hàn pé ìlú Háránì jẹ́ ojúkò ìṣòwò pàtàkì.—Ìsík. 27:1, 2, 23.
Ní báyìí, ìlú kékeré kan ni Háránì jẹ́, ó wà nítòsí ìlú Şanlıurfa, tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Tọ́kì. Àmọ́ ìgbà kan wà tí ìlú Háránì ìgbà àtijọ́ jẹ́ ìlú tó kún fún ìgbòkègbodò. Ìlú Háránì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ayé àtijọ́ tó ṣì ń jẹ́ orúkọ tí wọ́n fi ń pè é nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Orúkọ tó ń jẹ́ lédè Ásíríà ni Harranu, èyí tó lè túmọ̀ sí “Ọ̀nà” tàbí “Ojú Ọ̀nà Àwọn Oníṣòwò,” èyí tó fi hàn pé ojú ọ̀nà tí àwọn èèyàn ń gbà lọ ṣòwò ní àwọn ìlú ńlá ni ìlú Háránì wà. Ohun tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí lára tí wọ́n hú jáde látinú ilẹ̀ ní ìlú Háránì fi hàn pé, ìyá Nábónídọ́sì Ọba Bábílónì ni ìyálóòṣà ní ilé òrìṣà Sin, ìyẹn òrìṣà òṣùpá tí wọ́n ń bọ ní ìlú Háránì. Ìròyìn fi hàn pé Nábónídọ́sì tún ilé òrìṣà yìí ṣe. Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ọba dìde, wọ́n sì tún ṣubú, síbẹ̀ mìmì kan ò mi ìlú Háránì.
Lóde òní, Háránì ti yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí nígbà kan. Ìlú tó lọ́rọ̀ tó sì tún gbajúmọ̀ ni ìlú Háránì ayé àtijọ́, ní pàtàkì láwọn àkókò pàtó kan. Àmọ́, lóde òní, àgbájọ àwọn ilé olórùlé rìbìtì ló para pọ̀ di ìlú Háránì. Àwọn àwókù ilé ńláńlá ayé ìgbàanì sì wà yí i ká. Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ti gbé ìlú Háránì, tó fi mọ́ Ábúráhámù, Sárà àti Lọ́ọ̀tì yóò jí dìde. Ó sì ṣeé ṣé kí wọ́n sọ púpọ̀ sí i fún wa nípa ìlú Háránì àtijọ́, tó kún fún ìgbòkègbodò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn àwókù ilé ní ìlú Háránì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn ilé olórùlé rìbìtì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwòrán ìlú Háránì òde òní