Ní ‘Ọkàn-àyà Tó Mọ́’ Ní Àwọn Àkókò Líle Koko Yìí
Ní ‘Ọkàn-àyà Tó Mọ́’ Ní Àwọn Àkókò Líle Koko Yìí
“KÒ ṢẸ́NI tó lè sọ pé ìwà àìmọ́ kò sí nínú Ṣọ́ọ̀ṣì lóde òní.” Akọ̀ròyìn kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ìyẹn Vittorio Messori, ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nípa ìṣekúṣe tó ń wáyé báyìí ní Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Ítálì. “Ìṣòro náà ò sì lè yanjú tá a bá mú òfin tó sọ pé káwọn àlùfáà má ṣe gbéyàwó kúrò, torí pé bá a bá fi àwọn àlùfáà tí ọ̀ràn yìí kàn dá ọgọ́rùn-ún, ọgọ́rin lára wọn ló ń bá ọkùnrin bíi tiwọn àti àwọn ọmọdékùnrin lò pọ̀.”—La Stampa.
Ìwà ibi tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (2 Tím. 3:1-5) Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti fi hàn, àbájáde ìwà ìbàjẹ́ náà ń ṣàkóbá fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó pe ara wọn ní èèyàn Ọlọ́run. Ọkàn-àyà wọn tó ti díbàjẹ́, tó sì ti di ẹlẹ́gbin, ń mú kí wọ́n máa hu ìwàkiwà. (Éfé. 2:2) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kìlọ̀ pé “láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.” (Mát. 15:19) Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní “ìmọ́gaara ọkàn-àyà,” tàbí ọkàn-àyà tó mọ́. (Òwe 22:11) Torí náà, báwo ni Kristẹni kan ṣe lè ní ọkàn-àyà tó mọ́ láwọn àkókò líle koko yìí?
Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ “Ẹni Mímọ́ Gaara ní Ọkàn-Àyà”?
Bíbélì sábà máa ń lo “ọkàn-àyà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ohun tí ọkàn-àyà ń tọ́ka sí nínú Bíbélì ni “ẹni tí èèyàn jẹ́ ní inú lọ́hùn ún,” òun ló “sì ṣe pàtàkì jù lọ sí Ọlọ́run, ibẹ̀ ni àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run ti ń fìdí múlẹ̀, òun ló sì ń pinnu ìwà tó tọ́ láti hù.” Ọkàn-àyà dúró fún irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún. Bí ìwé tá a tọ́ka sí yẹn ṣe fi hàn, ọkàn-àyà wa ni Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò, òun náà ló sì kà sí pàtàkì jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—1 Pét. 3:4.
Nínú Bíbélì, “mọ́” àti “mọ́ gaara” sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó mọ́ tónítóní. Àmọ́, ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí tún lè tọ́ka sí ìwà àti ìjọsìn ẹnì kan, tí kò lábààwọ́n, tí kò lábùlà, tí kò lẹ́gbin tàbí tí kò díbàjẹ́. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù kéde pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà.” Àwọn tí ọkàn-àyà wọn àti èrò inú wọn mọ́ ló ń tọ́ka sí. (Mát. 5:8) Wọ́n kì í nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí kò dáa, ohun búburú kì í wù wọ́n, wọn kì í sì í ro èròkerò. Ìfẹ́ àti ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà ló mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn, láìsí àgàbàgebè kankan. (Lúùkù 10:27) Ó dájú pé ìwọ náà fẹ́ jẹ́ mímọ́ lọ́nà yẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Láti Jẹ́ “Ẹni Mímọ́ Gaara ní Ọkàn-Àyà”
Ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọlọ́wọ́ mímọ́” kó sì tún “mọ́ ní ọkàn-àyà.” (Sm. 24:3, 4) Àmọ́, lóde òní ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti máa jẹ́ ẹni tó “mọ́ ní ọkàn-àyà.” Sátánì àti ayé tó ń darí yìí, tó fi mọ́ ara àìpé tiwa alára, máa ń mú ká fẹ́ jìnnà sí Jèhófà. Ká lè borí ìṣòro yìí, ó ṣe pàtàkì pé kó máa wù wá láti ní ‘ọkàn-àyà tó mọ́ gaara’ ká sì fọwọ́ pàtàkì mú un. Èyí máa pa wá mọ́, á sì jẹ́ ká máa bá a lọ ní jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ní ọkàn-àyà tó mọ́?
A kìlọ̀ fún wa nínú Hébérù 3:12, pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” A kò lè jẹ́ “ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà” tá a bá ní ọkàn-àyà ‘tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́.’ Kí làwọn èrò tí Sátánì Èṣù ti tàn kálẹ̀ láti sọ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run di yẹpẹrẹ? Lára rẹ̀ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ẹ̀kọ́ pé ìwà téèyàn bá fẹ́ ló lè máa hù, ẹ̀sìn tó bá sì fẹ́ ló lè máa ṣe àti iyè méjì lórí bóyá Ìwé Mímọ́ ní ìmísí Ọlọ́run. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n fi irú èrò tó ń ṣekú pani bẹ́ẹ̀ tàn wá jẹ. (Kól. 2:8) Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti ṣíṣe àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí rẹ̀, jẹ́ àwọn ohun pàtàkì tó lè mú wa borí àwọn ìṣòro yìí. Ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á jẹ́ kí iná ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà túbọ̀ máa jó, a ó sì túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ń ṣe fún wa. Irú ìfẹ́ àti ìmọrírì yìí ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kọ ìrònú òdì, tá a sì fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára ká lè máa ní ọkàn-àyà tó mọ́.—1 Tím. 1:3-5.
Tá A Bá Fi Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Dẹ Wá Wò
Ìṣòro míì tó tún lè dojú kọ wá bá a ti ń sapá láti ní ‘ọkàn-àyà tó mọ́’ ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti kíkó ohun ìní tara jọ. (1 Jòh. 2:15, 16) Ìfẹ́ owó tàbí ìfẹ́ láti kó ọrọ̀ àtàwọn ohun ìní tara jọ lè sọ ọkàn-àyà wa dìdàkudà, ó sì lè mú kí Kristẹni kan ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn kan ti di aláìṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n ti rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jí owó tàbí àwọn nǹkan míì.—1 Tím. 6:9, 10.
Àmọ́ tá a bá ní ojúlówó ìbẹ̀rù tí kò ní jẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́, tá a nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo tá a sì pinnu láti máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ńṣe là ń fi hàn pé ‘ọkàn-àyà tó mọ́’ ń wù wá. Ìfẹ́ yìí láá jẹ́ ká máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Héb. 13:18) Tá a bá ń ṣe ohun tó tọ́, ìwà àìlábòsí lè yọrí sí ìjẹ́rìí. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Ítálì, tó ń jẹ́ Emilio, tó sì ń wakọ̀ fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ akérò, rí pọ́ọ̀sì kan towó inú rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin-lé-nírínwó [470] owó euro, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97,000] náírà. Ó ya àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́nu nígbà tó gbé owó náà fún ọ̀gá rẹ̀, ìyẹn sì dá owó náà pa dà fún ẹni tí owó náà sọ nù lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jọ díẹ̀ lára àwọn tí Emilio jọ ń ṣiṣẹ́ lójú débi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn méje látinú ìdílé méjì ló sì ti wà nínú òtítọ́ báyìí. Èyí fi hàn pé tá a bá ń hùwà láìṣàbòsí látinú ọkàn-àyà tó mọ́, ó lè mú káwọn míì máa yin Ọlọ́run.—Títù 2:10.
Nǹkan míì tí kò ní jẹ́ kí Kristẹni kan ní ọkàn-àyà tó mọ́ ni, níní èrò tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò burú kí ẹni tí kò tíì gbéyàwó máa ní ìbálòpọ̀, tàbí káwọn tó ti ṣègbéyàwó máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì àti kí ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin pẹ̀lú obìnrin máa bára wọn lò pọ̀, èyí sì lè sọ ọkàn-àyà Kristẹni kan dìdàkudà. Ẹni tó bá ń ṣèṣekúṣe lè máa fi ẹ̀ṣẹ̀ náà pa mọ́. Ó dájú pé ìyẹn ò fi hàn pé onítọ̀hún ní ‘ọkàn-àyà tó mọ́.’
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Gabriele nígbà tó ṣèrìbọmi, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ nílé fàájì alaalẹ́. (Sm. 26:4) Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe, tó sì ń hùwà àgàbàgebè nìyẹn o, wọ́n sì wá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Ìbáwí tí Jèhófà fún un yìí mú kó ronú jinlẹ̀. Gabriele rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo ohun tí mi ò fọwọ́ pàtàkì mú tẹ́lẹ̀. Mò ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, láti gbọ́ ohun tí Jèhófà ń sọ gan-an, mo sì tún ń fara balẹ̀ ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Mo wá rí i pé èrè púpọ̀ ló wà nínú kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń múni lọ́kàn yọ̀, mo sì tún rí i pé kíka Bíbélì àti gbígbàdúrà látọkànwá máa ń fúnni lókun gan-an.” Èyí ran Gabriele lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, ó sì tún pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
Ní báyìí Gabriele ti pa dà di aṣáájú-ọ̀nà, òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i jẹ́ kó ṣe kedere pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lè jẹ́ kéèyàn ní ọkàn-àyà tó mọ́, kó sì yàgò fún ìṣekúṣe.—Mát. 24:45; Sm. 143:10.
Béèyàn Ṣe Lè Ní ‘Ọkàn-Àyà Tó Mọ́’ Nígbà Àdánwò
Ìdààmú látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣàtakò, ìṣòro ìgbọ́bùkátà àti àìsàn líle koko lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà míì, ó lè ṣàkóbá fún ọkàn-àyà wọn. Kódà Dáfídì Ọba ní irú ìṣòro yìí, ó sọ pé: “Àárẹ̀ sì mú ẹ̀mí mi nínú mi; ọkàn-àyà mi ti kú tipiri nínú mi.” (Sm. 143:4) Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ nínú ìṣòro yìí? Dáfídì rántí bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti bí òun alára ṣe rí ìdáǹdè gbà. Ó ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe nítorí orúkọ ńlá Rẹ̀. Dáfídì jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ òun lógún. (Sm. 143:5) Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣàṣàrò nípa Ẹlẹ́dàá àti gbogbo ohun tó ti ṣe àtèyí tó ń ṣe fún wa, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ kódà nígbà tá a bá wà lábẹ́ àdánwò.
Tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá tàbí tá a rò pé ẹnì kan ṣẹ̀ wá, inú lè bẹ̀rẹ̀ sí bí wa. Tá a bá ń ronú ṣáá nípa bọ́rọ̀ náà ṣe wáyé, a lè tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó lérò tí kò tọ́ sáwọn ará wa. A lè bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wa sọ́tọ̀, kí ọ̀rọ̀ àwọn ará wa má sì fi bẹ́ẹ̀ jẹ wá lógún mọ́. Àmọ́ ṣé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣì bá ìpinnu tá a ṣe mu láti ní ‘ọkàn-àyà tó mọ́’? Ó ṣe kedere pé ká tó lè dẹni tó ní ọkàn-àyà tó mọ́, a gbọ́dọ̀ máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará wa, ká sì máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún.
Nínú ayé tó kún fún ìwà ìbàjẹ́ àti ìṣekúṣe yìí, àwa Kristẹni tòótọ́ dá yàtọ̀ torí pé a nífẹ̀ẹ́ ‘ọkàn-àyà tó mọ́.’ Ìgbésí ayé wa nítumọ̀ torí pé a ní àlàáfíà tó ń wá látinú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, tó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó “mọ́ ní ọkàn-àyà.” (Sm. 73:1) Ó sì dájú pé a máa wà lára àwọn tó máa láyọ̀, torí gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí, “wọn yóò . . . rí Ọlọ́run” bó ṣe ń gbèjà àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ‘ọkàn-àyà tó mọ́.’—Mát. 5:8.