Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìṣòro Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìṣòro Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́
“Gbogbo àwọn tí ń sá di [Jèhófà] yóò máa yọ̀; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde.”—SM. 5:11.
1, 2. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń fa ìbànújẹ́ tó pọ̀ lóde òní? (b) Yàtọ̀ sí àjálù tó ń dé bá gbogbo aráyé, kí ni àwa Kristẹni ní láti máa fara dà?
ÀJÁLÙ tó ń dé bá gbogbo èèyàn kò yọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sílẹ̀. Àwọn ọ̀daràn ti ṣe ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Ọlọ́run ní jàǹbá, ogun ti jà níbi tí wọ́n wà, wọ́n sì ti rẹ́ wọn jẹ lọ́pọ̀ ìgbà. Ìjábá, òṣì, àìsàn àti ikú náà tún máa ń fa ìbànújẹ́ tó pọ̀. Òótọ́ pọ́ńbélé kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Àìpé tiwa fúnra wa gan-an tún máa ń fa ìṣòro fún wa. Ó lè ṣe wá bíi pé ká sọ ohun tí Dáfídì Ọba sọ, pé: “Nítorí pé àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá; bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi.”—Sm. 38:4.
2 Yàtọ̀ sí àjálù tó ń dé bá gbogbo aráyé, àwa Kristẹni tòótọ́ tún ní òpó igi oró tá à ń gbé. (Lúùkù 14:27) Wọ́n kórìíra wa, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wa, bí wọ́n ti ṣe sí Jésù. (Mát. 10:22, 23; Jòh. 15:20; 16:2) Torí náà, ká tó lè máa tẹ̀ lé Kristi, ó gba pé ká lo gbogbo okun wa, ká sì ní ìfaradà bá a ti ń retí àwọn ìbùkún tí ayé tuntun yóò mú wá.—Mát. 7:13, 14; Lúùkù 13:24.
3. Báwo la ṣe mọ̀ pé kò pọn dandan káwa Kristẹni gbé ìgbésí ayé ìbànújẹ́ ká tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́?
3 Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé kò yẹ kí ìgbésí ayé àwa Kristẹni tòótọ́ ládùn, kó lóyin? Ṣé kìkì ìbànújẹ́ láá máa bá àwa Kristẹni lójoojúmọ́ títí òpin máa fi dé ni? Ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀. Lemọ́lemọ́ ni Bíbélì máa ń pe àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ní aláyọ̀. (Ka Aísáyà 65:13, 14.) Sáàmù 5:11 sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń sá di [Jèhófà] yóò máa yọ̀; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde.” Èyí fi hàn pé, ó ṣeé ṣe fún wa láti ní ayọ̀, ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn dé ìwọ̀n àyè kan, kódà nígbà àjálù. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wa ká sì tún máa láyọ̀.
Jèhófà Jẹ́ “Ọlọ́run Aláyọ̀”
4. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run nígbà táwọn kan ò bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
4 Wo àpẹẹrẹ ti Jèhófà. Òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, abẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni gbogbo ayé àtọ̀run wà. Kò ṣaláìní ohunkóhun, kò sì nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnì kankan. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Alágbára Gíga Jù lọ, ó ní láti dùn ún nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ tó sì sọ ara rẹ̀ di Sátánì. Ó tún ní láti dùn ún nígbà tó di pé àwọn áńgẹ́lì míì bá Sátánì lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ rẹ̀. Tún ronú lórí bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó nígbà tí Ádámù àti Éfà, tó ta yọ nínú àwọn ìṣẹ̀dá tó dá sáyé, kọ̀yìn sí i. Látìgbà náà wá, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ló ń tàpá sí àṣẹ Jèhófà.—Róòmù 3:23.
5. Àwọn nǹkan wo ló máa ń ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́?
5 Ńṣe ni ọ̀tẹ̀ Sátánì túbọ̀ ń peléke sí i. Láti bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà [6,000] ni Jèhófà ti ń fojú ara rẹ̀ rí ìbọ̀rìṣà, ìwà ipá, ìpànìyàn àti ìbálópọ̀ tí kò tọ́. (Jẹ́n. 6:5, 6, 11, 12) Bákan náà, ó ti fetí ara rẹ̀ gbọ́ ọ̀pọ̀ irọ́ burúkú àti ọ̀rọ̀ òdì. Kódà àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ gan-an máa ń ṣohun tó dùn ún láwọn ìgbà míì. Ọ̀kan lára irú ìgbà bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì ń sọ nígbà tó sọ pé: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó, wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́ ní aṣálẹ̀! Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sm. 78:40, 41) Ó máa ń dun Jèhófà púpọ̀ gan-an nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ bá kọ̀yìn sí i. (Jer. 3:1-10) Ó ṣe kedere pé àwọn ohun burúkú máa ń ṣẹlẹ̀, wọ́n sì máa ń ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ gan-an ni.—Ka Aísáyà 63:9, 10.
6. Kí ni Ọlọ́run ń ṣe nípa àwọn ohun tó ń bà á lọ́kàn jẹ́?
6 Síbẹ̀, bí àwọn ẹ̀dá Jèhófà ṣe ń ṣohun tí kò fẹ́ kí wọ́n ṣe, tó sì ń dùn ún, kò dí i lọ́wọ́ pé kó má lè ṣohun tó yẹ kó ṣe. Nígbà tí ọ̀ràn kan bá fọ́jú pọ̀, Jèhófà máa ń tètè wá nǹkan ṣe kí aburú tó máa tẹ̀yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà yọ má bàa pọ̀ jù. Ó ti ṣe àwọn nǹkan kan sílẹ̀ torí ọjọ́ iwájú, kí ìfẹ́ rẹ̀ bàa lè di ṣíṣe. Nítorí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe yìí, ó ń láyọ̀ bó ṣe ń retí ìgbà tó máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láre, tíyẹn yóò sì yọrí sí ìbùkún fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin. (Sm. 104:31) Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá a yìí náà, ó ṣì jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tím. 1:11; Sm. 16:11.
7, 8. Nígbà tí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ kó lọ, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà?
7 A mọ̀ pé tó bá dọ̀ràn ká yanjú ìṣòro, a ó lè fi ara wa wé Jèhófà, àmọ́ a ṣì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú bá a ṣe máa kojú ìṣòro tó bá dé bá wa. Lóòótọ́, ìbànújẹ́ sábà máa ń dorí èèyàn kodò nígbà tí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ kó lọ, àmọ́ kó yẹ ká máa banú jẹ́ títí lọ. Nítorí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, ẹ̀dá tó lè ro àròjinlẹ̀ ni wá, ó sì ti fún wa ní ọgbọ́n àti òye, èyí tó ń jẹ́ ká lè gbé ìṣòro wa yẹ̀ wò dáadáa ká sì wá nǹkan ṣe sí i, tó bá ṣeé ṣe.
8 Ohun pàtàkì kan tó lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa kojú àwọn ìṣòro tá à ń bá pàdé nígbèésí ayé ni pé ká gbà pé àwọn ọ̀ràn kan wà tó kọjá agbára wa. Tá a bá ń gbé ara wa lọ́kàn sókè lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kí ìbànújẹ́ wa pọ̀ sí i, kò sì ba ayọ̀ tó yẹ ká máa ní nínú ìjọsìn Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tó bọ́gbọ́n mu tá a lè ṣe lórí ọ̀ràn kan, ohun tó dáa jù ni pé ká fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ ká máa bá ìgbésí ayé wa lọ, ká wá gbájú mọ́ àwọn ohun tó lè ṣe wá láǹfààní. Àpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ wà nínú àwọn ìtàn Bíbélì tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí.
Ìwọ̀nba Ló Yẹ Ká Máa Ro Ọ̀ràn
9. Kí lohun tó bọ́gbọ́n mu tí Hánà ṣe sóhun tó ń bà á lọ́kàn jẹ́?
9 Wo àpẹẹrẹ Hánà, tó di ìyá wòlíì Sámúẹ́lì. Àìrọ́mọbí rẹ̀ ń bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an. Orogún rẹ̀ máa ń pẹ̀gàn rẹ̀ torí bó ṣe yàgàn. Ọ̀rọ̀ yìí máa ń ba Hánà lọ́kàn jẹ́ nígbà míì débi pé ńṣe ló máa ń sunkún tí kò sì ní jẹun. (1 Sám. 1:2-7) Nígbà kan tó lọ sí ibùjọsìn Jèhófà, ó “ní ìkorò ọkàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ń sunkún gidigidi.” (1 Sám. 1:10) Lẹ́yìn tó ti sọ gbogbo ohun tó ń dùn ún fún Jèhófà, Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì sọ fún Hánà pé “máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.” (1 Sám. 1:17) Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ó dájú pé Hánà mọ̀ pé òun ti ṣe gbogbo ohun tóun lè ṣe, Ọlọ́run ló ń ṣe ọmọ, kì í ṣèèyàn. Hánà kò ro ọ̀ràn náà ju bó ṣe yẹ lọ. Ó wá “bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun, ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.”—1 Sám. 1:18.
10. Ohun tó bọ́gbọ́n mu wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó ní ìṣòro kan tí kò lè dá yanjú?
10 Nígbà tí ohun kan ń da àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà láàmú, ó ṣe ohun kan tó jọ ti Hánà. Pọ́ọ̀lù ní àìlera kan tó ń bá a fínra. Ó pè é ní “ẹ̀gún kan” nínú ara òun. (2 Kọ́r. 12:7) Ohun yòówù kí ẹ̀gún náà jẹ́, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú un kúrò, ó bẹ Jèhófà pé kó bá òun yọ ọ́. Ẹ̀ẹ̀melòó ló gbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀ràn yìí? Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni! Lẹ́yìn tó gbàdúrà lẹ́ẹ̀kẹta, Ọlọ́run sọ fún un pé òun ò ní ṣe iṣẹ́ ìyanu láti mú “ẹ̀gún” náà kúrò. Pọ́ọ̀lù fara mọ́ ọn bẹ́ẹ̀, ó sì gbájú mọ́ ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà.—Ka 2 Kọ́ríńtì 12:8-10.
11. Báwo ni àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìdààmú?
11 Àwọn àpẹẹrẹ yìí kò fi hàn pé ó yẹ ká ṣíwọ́ gbígbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀ràn tó ń dà wá láàmú o. (Sm. 86:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Kí ni Jèhófà yóò ṣe lórí irú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ yẹn? Bíbélì tún sọ pé: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Bí Jèhófà ò bá tiẹ̀ mú ìṣòro wa kúrò, ó lè dáhùn àdúrà wa nípa dídáàbò bo ìrònú wa. Lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà nípa ọ̀ràn kan, a lè wá rí i pé ó léwu tá a bá jẹ́ kí àníyàn gbà wá lọ́kàn.
Jẹ́ Kí Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Máa Fún Ọ Láyọ̀
12. Kí nìdí tó fi léwu téèyàn bá jẹ́ kí ìbànújẹ́ pẹ́ lọ́kàn òun?
12 Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Òwe míì tún sọ pé: “Nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” (Òwe 15:13) Ìrẹ̀wẹ̀sì ti mú àwọn Kristẹni kan débi tí wọ́n fi ṣíwọ́ kíka Bíbélì àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀. Àdúrà wọn kò ti ọkàn wọn wá mọ́, wọ́n sì lè máa yẹra fún àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Ó ṣe kedere pé ewu wà nínú kéèyàn jẹ́ kí ìbànújẹ́ pẹ́ lọ́kàn òun.—Òwe 18:1, 14.
13. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìgbòkègbodò tó lè bá wa lé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn wa táá sì fún wa láyọ̀?
13 Àmọ́ tá a bá ní èrò pé nǹkan á dáa, ó máa jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn apá ibi tó ń fúnni ní ayọ̀ àti ìdùnnú nínú ìgbésí ayé wa. Dáfídì sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.” (Sm. 40:8) Tí nǹkan ò bá lọ fún wa bó ṣe yẹ kó lọ, a ò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ ṣíṣe àwọn ohun tá à ń ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run. Àní, ohun tá a fi lè borí ìbànújẹ́ ni pé ká máa lọ́wọ́ nínu ìgbòkègbodò tó ń fúnni láyọ̀. Jèhófà sọ fún wa pé tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ òun déédéé, tá a sì ń ronú lórí ohun tá a kà nínú rẹ̀, a ó máa rí ìdùnnú àti ayọ̀. (Sm. 1:1, 2; Ják. 1:25) “Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni” tó ń gbé wa ró tó sì ń jẹ́ kí ọkàn wa yọ̀ là ń rí gbà látinú Bíbélì àti láwọn ìpàdé.—Òwe 12:25; 16:24.
14. Ìdánilójú wo la ní látọ̀dọ̀ Jèhófà, tó ń fún wa láyọ̀ nísinsìnyí?
14 Ọ̀pọ̀ ohun táá mú ká máa láyọ̀ ni Ọlọ́run ti ṣe fún wa. Àní, ìlérí ìgbàlà tó ṣe jẹ́ ohun kan tó ń fúnni ní ayọ̀ ńlá. (Sm. 13:5) A mọ̀ pé ohun yòówù tí ì báà máa ṣẹlẹ̀ sí wa nísinsìnyí, Ọlọ́run yóò san èrè fún àwọn tó ń fi taratara wá a nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Ka Oníwàásù 8:12.) Irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ hàn lọ́nà tó fani mọ́ra nínú ọ̀rọ̀ tí wòlíì Hábákúkù sọ, ó ní: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má yọ ìtànná, àjàrà sì lè má mú èso jáde; iṣẹ́ igi ólífì lè yọrí sí ìkùnà ní ti tòótọ́, àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú sì lè má mú oúnjẹ wá ní ti tòótọ́; a lè ya agbo ẹran nípa kúrò nínú ọgbà ẹran ní ti tòótọ́, ọ̀wọ́ ẹran sì lè má sí nínú àwọn gbàgede; síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.”— Háb. 3:17, 18.
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Ènìyàn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn!”
15, 16. Sọ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run tá à ń gbádùn báyìí bá a ṣe ń retí àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú.
15 Bá a ti ń retí àwọn ohun àgbàyanu tó ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú, ìfẹ́ Jèhófà ni pé ká máa gbádùn àwọn ohun rere tó ń pèsè fún wa nísinsìnyí. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí [àwọn èèyàn] máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé [wọn]; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníw. 3:12, 13) Ara ohun tó túmọ̀ sí láti “máa ṣe rere” ni pé ká máa ṣe ohun tó dára fáwọn èèyàn. Jésù sọ pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju rírí gbà lọ. Tá a bá ń ṣe rere sí ọkọ tàbí aya wa, àwọn ọmọ wa, àwọn òbí àtàwọn ẹbí wa míì, a óò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ayọ̀. (Òwe 3:27) Tá a bá ń ṣe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa pẹ̀lẹ́, tá a kó wọn mọ́ra, tá a sì lẹ́mìí ìdáríjì, yóò jẹ́ ká láyọ̀, èyí yóò sì dùn mọ́ Jèhófà nínú. (Gál. 6:10; Kól. 3:12-14; 1 Pét. 4:8, 9) Tá a bá sì ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a óò tún rí èrè gidi níbẹ̀.
16 Ọ̀rọ̀ tá a fà yọ látinú ìwé Oníwàásù ní ìpínrọ̀ tá a kà tán yìí tọ́ka sí àwọn adùn ìgbésí ayé tó mọ níwọ̀n bíi jíjẹ àti mímu. Kódà, tá a bá wà lábẹ́ àdánwò, ẹ̀bùn tara èyíkéyìí tá a bá rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà ṣì lè máa fún wa láyọ̀. Bákan náà, a ò san kọ́bọ̀ fún gbogbo ohun àrímáleèlọ tá à ń rí, irú bí oòrùn tó ń wọ̀, ohun mèremère tó wà lórí ilẹ̀, àwọn ọmọ ẹranko tó ń ṣeré àtàwọn ohun ìyanu míì tó wà nínú ìṣẹ̀dá, síbẹ̀ wíwo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń fún wa láyọ̀. Bá a ṣe ń ronú lórí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ wa fún Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, torí pé òun ni Olùfúnni láwọn ohun rere.
17. Kí ni yóò mú ká ní ìtura pátápátá kúrò nínú wàhálà, kí ló sì ń tù wá nínú báyìí?
17 Paríparì rẹ̀ ni pé ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run, pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù yóò jẹ́ ká ní ìtura pátápátá kúrò nínú àwọn wàhálà tí àìpé ẹ̀dá ń fà, yóò sì jẹ́ ká ní ayọ̀ tí kò lópin. (1 Jòh. 5:3) Ní báyìí ná, ó ń tù wá nínú bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tó ń pọ́n wa lójú. Dáfídì sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò kún fún ìdùnnú, èmi yóò sì máa yọ̀ nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ní ti pé ìwọ ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́; ìwọ ti mọ̀ nípa àwọn wàhálà ọkàn mi.” (Sm. 31:7) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yóò mú kó gbà wà lọ́wọ́ àjálù.—Sm. 34:19.
18. Kí nìdí tó fi yẹ kí ayọ̀ gbilẹ̀ láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run?
18 Ǹjẹ́ ká máa fara wé Jèhófà Ọlọ́run aláyọ̀ bá a ṣe ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀. Ká má ṣe gbà kí èrò tí kò tọ́ ṣí wa lọ́wọ́ sísin Ọlọ́run. Tí ìṣòro bá dé, ǹjẹ́ kí àròjinlẹ̀, ọgbọ́n àti òye máa darí wa. Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbé ọ̀ràn náà sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ, yóò sì jẹ́ ká lè ṣe àwọn ohun tó bá ṣeé ṣe láti mú kí aburú tó lè tẹ̀yìn àjálù kan wá dín kù. Ẹ jẹ́ kí àwọn ohun rere nípa tara àti nípa tẹ̀mí tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà máa fún wa láyọ̀. Tá ò bá jìnnà sí Ọlọ́run, a ó lè máa láyọ̀ torí pé “aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Sm. 144:15.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?
• Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nígbà tá a bá wà nínú wàhálà?
• Kí ló bọ́gbọ́n mu láti ṣe ká lè borí ìdààmú nígbà tí ìṣòro bá dé?
• Báwo la ṣe lè rí ayọ̀ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà wàhálà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Inú Jèhófà máa ń bà jẹ́ nígbà táwọn ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀
[Credit Line]
© G.M.B. Akash/Panos Pictures
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà ti fún wa láwọn ohun táá jẹ́ ká máa láyọ̀